Bẹ́ Ẹ Ṣe Lè Máa Ṣọ́wó Ná
Ohun Tó Lè Mú Kí Ìdílé Láyọ̀
Bẹ́ Ẹ Ṣe Lè Máa Ṣọ́wó Ná
Ọkọ sọ pé: “Ńṣe ni Laura, a ìyàwó mi kàn ń ná ìná àpà, àwọn nǹkan tí mi ò rò pé a nílò ló máa ń rà sílé. Kò sì jọ pé ó mọ bá a ṣe ń tọ́jú owó! Èyí sì ti dá ìṣòro sílẹ̀ nígbà tá a bá ní láti ná owó tá ò rò tẹ́lẹ̀. Àkíyèsí tí mo ṣe ni pé, tówó kan bá ti dọ́wọ́ ìyàwó mi, àfi kó ná an.”
Ìyàwó sọ pé: “Bóyá mo mọ owó tọ́jú o tàbí mi ò mọ̀ ọ́n tọ́jú, ohun kan ṣáà ni pé ọkọ mi ò mọ iye tí wọ́n ń ta oúnjẹ, àwọn nǹkan ẹ̀ṣọ́ ilé àtàwọn nǹkan téèyàn ń lò nínú ilé, èmi sì ni mo máa ń wà nílé lọ́pọ̀ ìgbà. Mo mọ àwọn nǹkan tá a nílò, mo sì máa ń rà wọ́n láìka ohun tó lè yọrí sí.”
Ọ̀RỌ̀ owó sábà máa ń le débi pé kì í rọrùn fún tọkọtaya láti sọ ọ́ nítùbí-ìnùbí. Abájọ tó fi jẹ́ pé òun ló sábà máa ń fa wàhálà láàárín tọkọtaya.
Àwọn tọkọtaya tí kì í bá fojú tó tọ́ wo owó sábà máa ń ní ìdààmú ọkàn, wọ́n máa ń ṣawuyewuye, wọn kì í sì í gbádùn ara wọn, ó tún lè ṣàkóbá fún àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run pàápàá. (1 Tímótì 6:9, 10) Ó lè di dandan fáwọn òbí tí kò bá fọgbọ́n ṣètò owó tí wọ́n fẹ́ ná àti bí wọ́n ṣe fẹ́ ná an láti máa ṣe àfikún iṣẹ́, ìyẹn sì lè máà jẹ́ káwọn ọmọ wọn gbádùn wọn, àwọn náà sì lè máà gbádùn ara wọn, wọ́n sì lè máà ráyè láti fún àjọṣe wọn pẹ̀lú Jèhófà lókun. Wọn ò sì ní fi ẹ̀kọ́ tó dáa kọ́ àwọn ọmọ wọn nípa owó.
Bíbélì sọ pé: “Owó . . . jẹ́ fún ìdáàbòbò.” (Oníwàásù 7:12) Àmọ́ owó lè jẹ́ ààbò fún ìgbéyàwó àti ìdílé yín kìkì tẹ́ ẹ bá mọ bẹ́ ẹ ṣe máa bá ẹnì kejì yín sọ̀rọ̀ tó bá jẹ mọ́ owó, kì í kàn ṣe bẹ́ ẹ ṣe fẹ́ máa ná an nìkan. b Dípò tọ́rọ̀ owó á fi máa dá wàhálà sílẹ̀, ìdè ìgbéyàwó yín á túbọ̀ lágbára tẹ́ ẹ bá ń fara balẹ̀ jíròrò ọ̀rọ̀ owó.
Kí wá nìdí tí ọ̀rọ̀ owó fi ń dá ọ̀pọ̀ ìṣòro sílẹ̀ nínú ìgbéyàwó? Kí lẹ sì lè ṣe tí ìjíròrò nípa owó á fi máa yanjú ìṣòro yín dípò kó dá wàhálà sílẹ̀?
Kí Ló Máa Ń Fa Ìṣòro?
Ohun tó sábà máa ń fa ìṣòro owó kì í ṣe bí wọ́n ṣe náwó bí kò ṣe àìfọkàntánni tàbí ìbẹ̀rù. Bí àpẹẹrẹ, ohun tí ọkọ kan tó ń béèrè pé kí ìyàwó òun ṣàlàyé bó ṣe ná gbogbo owó tó ná ń sọ ni pé òun ò fi bẹ́ẹ̀ fọkàn tán an pé ó lè náwó ìdílé dáadáa. Bákan náà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìbẹ̀rù pé nǹkan kan lè ṣẹlẹ̀ tó sì lè kó ìṣòro owó bá ìdílé ló ń ṣe ìyàwó kan tó bá ń sọ pé ọkọ òun ò tọ́jú owó tó pọ̀ tó.
Ohun míì tó tún máa ń fa àríyànjiyàn lórí ọ̀rọ̀ owó láàárín tọkọtaya ni bí wọ́n ṣe tọ́ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn dàgbà. Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Matthew, tó ti gbéyàwó láti ọdún mẹ́jọ sẹ́yìn sọ pé: “Ìdílé tí wọ́n ti mọ bá a ṣe ń ṣọ́wó ná ni ìyàwó mi ti wá. Kì í bẹ̀rù bíi tèmi. Ọ̀mùtí ni bàbá mi, fìkan-ràn-kan ló sì máa ń fi sìgá ṣe, ọ̀pọ̀ ọdún ni wọn ò fi níṣẹ́ lọ́wọ́. A kì í sábà láwọn ohun kòṣeémáàní nílé, èyí sì wá jẹ́ kí n dẹni tó ń bẹ̀rù gbèsè.
Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ìbẹ̀rù yìí máa ń mú kí n hùwà tó kù díẹ̀ káàtó sí ìyàwó mi lórí ọ̀rọ̀ owó.” Ohun yòówù kó máa fa awuyewuye lórí ọ̀rọ̀ owó nínú ìdílé yín, kí lẹ lè ṣe tí owó á fi ṣàǹfààní fún ìgbéyàwó yín, dípò tá á fi máa dá àríyànjiyàn sílẹ̀?Ohun Mẹ́rin Tó Lè Jẹ́ Kẹ́ Ẹ Ṣàṣeyọrí
Bíbélì kì í ṣe ìwé tó ń ṣàlàyé bá a ṣe ń náwó. Àmọ́ ó láwọn ìmọ̀ràn tó gbéṣẹ́ tó lè ran àwọn tọkọtaya lọ́wọ́ láti borí ìṣòro owó. Ẹ ò ṣe gbé àwọn ìmọ̀ràn Bíbélì yẹ̀ wò, kẹ́ ẹ sì gbìyànjú àwọn àbá tó wà nísàlẹ̀ yìí.
1. Ẹ kọ́ láti máa sọ̀rọ̀ owó nítùbí-ìnùbí. “Ọgbọ́n wà pẹ̀lú àwọn tí ń fikùn lukùn.” (Òwe 13:10) Nítorí bí wọ́n ṣe tọ́ ẹ dàgbà, ó lè má rọrùn fún ẹ láti báwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa owó, àgàgà tó bá jẹ́ ìyàwó tàbí ọkọ rẹ. Síbẹ̀, ìwà ọgbọ́n ló jẹ́ tó o bá kọ́ bó o ṣe lè sọ̀rọ̀ tó ṣe pàtàkì yìí. Bí àpẹẹrẹ, o ò ṣe sọ ipa tó o rò pé ó ṣeé ṣe kọ́wọ́ táwọn òbí ẹ fi mú ọ̀rọ̀ owó ti ní lórí rẹ fún ìyàwó tàbí ọkọ rẹ. Bákan náà, gbìyànjú láti lóye ipa tí ibi tí wọ́n ti tọ́ ìyàwó tàbí ọkọ rẹ dàgbà ní lórí rẹ̀.
Ẹ ò ní láti dúró dìgbà tí ìṣòro bá yọjú kẹ́ ẹ tó jíròrò nípa owó. Òǹkọ̀wé Bíbélì kan béèrè pé: “Àwọn méjì ha lè jọ rìn pọ̀ bí kò ṣe pé wọ́n ti pàdé nípasẹ̀ àdéhùn?” (Ámósì 3:3) Báwo lẹ ṣe lè lo ìlànà yìí? Tẹ́ ẹ bá yan ọjọ́ kan pàtó láti máa jíròrò ọ̀ràn tó jẹ mọ́ owó, èyí á dín ìṣòro tí àìgbọ́ra ẹni yé máa ń dá sílẹ̀ kù.
GBÌYÀNJÚ ÈYÍ WÒ: Ẹ yan ọjọ́ kan tẹ ó fi máa jíròrò ọ̀rọ̀ owó ìdílé yín. Ẹ lè yan ọjọ́ àkọ́kọ́ lóṣooṣù tàbí ẹ̀ẹ̀kan lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ lọ́jọ́ kan pàtó. Ẹ jẹ́ kí ìjíròrò náà ṣe ṣókí, tó bá ṣeé ṣe, kó máa ju nǹkan bí ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] lọ. Ìgbà tára bá tu ẹ̀yin méjèèjì ni kẹ́ ẹ yàn. Kẹ́ ẹ sì pinnu láti má ṣe sọ̀rọ̀ owó láwọn àkókò kan pàtó, bí ìgbà tẹ́ ẹ bá ń jẹun tàbí ìgbà táwọn ọmọ yín bá wà pẹ̀lú yín.
2. Ẹ fohùn ṣọ̀kan lórí irú ojú tẹ́ o fi máa wo owó tó ń wọlé. “Nínú bíbu ọlá fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ẹ mú ipò iwájú.” (Róòmù 12:10) Tó bá jẹ́ ìwọ nìkan lowó ń wọlé fún, o lè bọlá fún ìyàwó tàbí ọkọ rẹ tó o bá ń wo owó náà gẹ́gẹ́ bí owó ìdílé, dípò kó o máa wò ó gẹ́gẹ́ bíi tìẹ.—1 Tímótì 5:8
Tó bá sì jẹ́ pé ẹ̀yin méjèèjì lowó ń wọlé fún, ẹ lè bọlá fún ara yín tẹ́ ẹ bá ń sọ iye tó wọlé fún ọ̀kọ̀ọ̀kan yín àtàwọn nǹkan pàtàkì tẹ́ ẹ fi owó náà ṣe. Tó ò bá sọ àwọn nǹkan yìí fún ẹnì kejì rẹ, ó ṣeé ṣe kí ẹnì kejì rẹ má fọkàn tán ẹ, èyí sì lè da àárín yín rú. Ó lè má pọn dandan pé kó o sọ fún ẹnì kejì rẹ kó o tó ra àwọn nǹkan pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́. Àmọ́ tó o bá ń jíròrò nǹkan olówó ńlá pẹ̀lú ìyàwó tàbí ọkọ́ rẹ kó o tó rà á, èyí á fi hàn pé o mọyì èrò ẹnì kejì rẹ.
GBÌYÀNJÚ ÈYÍ WÒ: Ẹ fohùn ṣọ̀kan lórí iye kan pàtó tí ẹnì kọ̀ọ̀kan yín lè ná láìjẹ́ pé ẹ fi tó ara yín létí. Rí i dájú pé ò ń fi tó ìyàwó tàbí ọkọ rẹ létí tó o bá ti fẹ́ ná owó tó ju iye tẹ́ ẹ jọ fohùn ṣọ̀kan lé lórí.
3. Ẹ kọ ìwéwèé yín sílẹ̀. “Tó o bá wéwèé, tó o sì ṣiṣẹ́ kára, wàá ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan.” (Òwe 21:5, ìtumọ̀ Contemporary English Version) Ọ̀nà kan láti wéwèé fún ọjọ́ ọ̀la tẹ́ ò sì ní fiṣẹ́ àṣekára yín ṣòfò ni pé kẹ́ ẹ wéwèé owó tí ìdílé yín máa ná. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Nina, tó ti wà nílé ọkọ fún ọdún márùn-ún sọ pé: “Tó o bá wo àkọsílẹ̀ owó tó wọlé fún ẹ àti bó o ṣe ná an lórí ìwé, á yà ẹ́ lẹ́nu, á sì jẹ́ kó o mọye tó o ná gan-an. Ó ṣe tán, ìwé ò lè purọ́.”
Kò yẹ kí ètò tẹ́ ẹ ṣe lórí bẹ́ ẹ ṣe fẹ́ náwó lọ́jú pọ̀. Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Darren, tó ti gbéyàwó láti ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n [26] sẹ́yìn, tó sì ti lọ́mọ ọkùnrin méjì sọ pé: “Inú àpòòwé la kọ́kọ́ máa ń fowó tá a fẹ́ ná sí. A máa ń fowó tá a fẹ́ ná lọ́sẹ̀ kọ̀ọ̀kan sínú oríṣiríṣi àpòòwé. Bí àpẹẹrẹ, a ní àpòòwé tá à ń lò fún oúnjẹ, eré ìnàjú àtèyí tá à ń lò fún irun gígẹ̀. Tówó bá tán nínú àpòòwé kan, a máa ń yá owó látinú òmíràn, àmọ́ a máa ń rí i pé a dá a pa dà sínú àpòòwé náà kó tó pẹ́ jù.” Ó ṣe pàtàkì pé kẹ́ ẹ wéwèé, kẹ́ ẹ sì máa ṣàkọsílẹ̀ àwọn ohun tẹ́ ẹ̀ ń rà tàbí tẹ́ ẹ̀ ń lò tó jẹ́ pé kì í ṣe ojú ẹsẹ̀ lẹ̀ ń sanwó wọn.
GBÌYÀNJÚ ÈYÍ WÒ: Ẹ kọ àwọn ìnáwó tí kì í yí pa dà tẹ́ ẹ máa ń ṣe. Ẹ fohùn ṣọ̀kan lórí iye tẹ́ ẹ gbọ́dọ̀ tọ́jú nínú owó tó ń wọlé. Kẹ́ ẹ wá kọ àwọn nǹkan tówó ẹ̀ máa ń yí pa dà, irú bí oúnjẹ, owó mànàmáná àti owó tẹ́ ẹ̀ ń ná sórí tẹlifóònù. Lẹ́yìn náà, kẹ́ ẹ wá máa ṣàkọsílẹ̀ gbogbo owó tẹ́ ẹ̀ ń ná fóṣù bíi mélòó kan. Tó bá pọn dandan, ẹ ṣàtúnṣe ọ̀nà ìgbésí ayé yín kẹ́ ẹ máa bàa jẹ gbèsè.
4. Ẹ pinnu ẹni táá máa bójú tó ojúṣe kan tàbí òmíràn. “Ẹni méjì sàn ju ẹnì kan, torí pé ọ̀pọ̀ nǹkan ni wọ́n lè ṣe láṣeyọrí bí wọ́n ṣe jọ ń ṣiṣẹ́.” (Oníwàásù 4:9, 10, ìtumọ̀ New Century Version) Nínú àwọn ìdílé kan, ọkọ ló máa ń gbọ́ bùkátà ìdílé. Nínú àwọn ìdílé míì sì rèé, aya ló ń gbọ́ bùkátà. (Òwe 31:10-28) Ọ̀pọ̀ tọkọtaya ló sì yàn láti jọ máa gbọ́ bùkátà ìdílé. Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Mario tó ti gbéyàwó láti ọdún mọ́kànlélógún [21] sẹ́yìn sọ pé: “Ìyàwó mi ló máa ń sanwó àwọn nǹkan tí kì í ṣe ojú ẹsẹ̀ là ń sanwó wọn. Èmi ni mò ń bójú tó sísanwó orí, owó ilé àtàwọn owó nǹkan tá a rà tá a sì ń san díẹ̀díẹ̀. A máa ń fi bí nǹkan ṣe ń lọ sí tó ara wa létí, a sì jọ ń ṣiṣẹ́ pọ̀.” Ọ̀nà yòówù kẹ́ ẹ máa gbà ṣe é, ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé kẹ́ ẹ máa ṣiṣẹ́ pa pọ̀.
GBÌYÀNJÚ ÈYÍ WÒ: Tẹ́ ẹ bá ti ronú lórí ohun tí ẹnì kan lè ṣe àtèyí tí kò lè ṣe, ẹ pinnu ẹni táá máa bójú tó ojúṣe kan tàbí òmíràn. Lẹ́yìn oṣù bíi mélòó kan, ẹ ṣàyẹ̀wò bẹ́ ẹ ti ṣe sí lórí ọ̀rọ̀ yìí. Ẹ múra tán láti ṣe àwọn àyípadà tó bá yẹ. Kó bàa lè ṣeé ṣe fún ẹ láti mọyì iṣẹ́ tí ìyàwó tàbí ọkọ rẹ ń ṣe, bóyá bíi sísanwó àwọn nǹkan tẹ́ ẹ̀ kì í sanwó wọn lójú ẹsẹ̀ tàbí lílọ ra nǹkan lọ́jà, o lè máa gba iṣẹ́ ẹnì kejì rẹ ṣe lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan.
Ohun Tó Yẹ Kí Ìjíròrò Yín Nípa Owó Dá Lé
Ẹ má ṣe jẹ́ kí ìjíròrò nípa owó bomi paná ìfẹ́ yín. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Leah tó ti wà nílé ọkọ fún ọdún márùn-ún rí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí. Ó ní: “Èmi àti ọkọ mi ti kọ́ bá a ṣe ń fi tọkàntọkàn sọ̀rọ̀ owó, tá ò sì ní fi igbá kan bọ̀ kan nínú. Àbájáde rẹ̀ ni pé, ní báyìí, àwa méjèèjì jọ ń ṣiṣẹ́ pọ̀, ìfẹ́ wa sì ń lágbára sí i.”
Nígbà tí tọkọtaya bá jọ ń jíròrò bí wọ́n ṣe fẹ́ náwó, ńṣe ni wọ́n ń fi hàn pé ohun táwọn ń retí àti àfojúsùn àwọn dọ́gba àti pé àwọn ṣera wọn lọ́kan. Tí wọ́n bá jọ ń sọ̀rọ̀ kí wọ́n tó ra nǹkan olówó ńlá, ńṣe ni wọ́n ń fi hàn pé àwọn mọyì èrò àti bí nǹkan ṣe rí lára ẹnì kejì àwọn. Tí wọ́n bá ń fún ara wọn láyè láti ná iye owó kan pàtó láìjẹ́ pé wọ́n sọ fún ara wọn, èyí á fi hàn pé wọ́n fọkàn tán ara wọn. Àwọn nǹkan wọ̀nyí ló ń jẹ́ kí ìdè ìgbéyàwó túbọ̀ lágbára sí i. Èyí sì ṣe pàtàkì gan-an ju ọ̀rọ̀ owó lásán lọ, torí náà kò ní dáa kẹ́ ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ owó máa dá àríyànjiyàn sílẹ̀.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Orúkọ wọn gan-an kọ́ nìyí.
b Bíbélì sọ pé “ọkọ ni orí aya rẹ̀,” torí náà ojúṣe ọkọ ni láti mọ bí wọ́n á ṣe máa náwó ìdílé wọn, iṣẹ́ ẹ̀ sì ni láti máa fìfẹ́ bá ìyàwó ẹ̀ lò, tí kò sì ní mọ tara ẹ̀ nìkan.—Éfésù 5:23, 25.
BI ARA Ẹ PÉ . . .
▪ Ìgbà wo lèmi àti aya tàbí ọkọ mi sọ̀rọ̀ owó gbẹ̀yìn nítùbí-ìnùbí?
▪ Kí ni mo lè sọ, tí mo sì lè ṣe tó máa fi hàn pé mo mọrírì ìrànlọ́wọ́ tí ìyàwó tàbí ọkọ mi ń ṣe lórí ìṣúnná owó ìdílé wa?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Èwo ló ṣe pàtàkì sí ẹ jù, owó àbí ìgbéyàwó rẹ?