Táwọn Èèyàn Bá Ṣe Ohun Tó Dùn Ẹ́
Táwọn Èèyàn Bá Ṣe Ohun Tó Dùn Ẹ́
Ọ̀PỌ̀ èèyàn ló sábà máa ń sọ pé ‘bí adìyẹ bá da àwọn lóògùn nù, àwọn á fọ́ ọ lẹ́yin.’ Ìdí sì ni pé ó máa ń dun àwa èèyàn nígbà tẹ́nì kan bá ṣẹ̀ wá tàbí tó ṣohun tí kò tẹ́ wa lọ́rùn. Ọgbọ́n àbínibí tá a fi ń mọ̀yàtọ̀ láàárín rere àti búburú kì í jẹ́ kó wù wá láti fàyè gba ìwà ìrẹ́jẹ. Lọ́nà wo?
Oríṣiríṣi nǹkan làwọn èèyàn lè ṣe tó lè mú kéèyàn fẹ́ láti gbẹ̀san, irú bíi kí wọ́n gbáni létí, kí wọ́n tini, kí wọ́n búni, kí wọ́n luni, kí wọ́n rẹ́ni jẹ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Báwo ló ṣe máa ń rí lára ẹ tẹ́nì kan bá bú ẹ tàbí tó láálí ẹ ní gbangba? Ó ṣeé ṣe kí ọ̀pọ̀ èèyàn lóde òní fèsì pé, ‘Màá rí i pé mo gbẹ̀san!’
Lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọléèwé girama ló ti mú ẹ̀sùn èké lọ sílé ẹjọ́, kí wọ́n lè gbẹ̀san lára àwọn tíṣà tó máa ń bá wọn wí. Ìyáàfin Brenda Mitchell, tó jẹ́ ààrẹ Àjọ Àwọn Olùkọ́ Nílùú New Orleans sọ pé: “Bí wọ́n bá ti lè fẹjọ́ olùkọ́ kan sùn nílé ẹjọ́, ìyẹn máa ba orúkọ rere tí olùkọ́ yẹn ní jẹ́.” Kódà lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ bá ti fi hàn kedere pé ẹ̀sùn èké ni, ìpalára tí irú ẹ̀sùn bẹ́ẹ̀ bá ti ṣe kì í tán nílẹ̀.
Láwọn iléeṣẹ́, àwọn òṣìṣẹ́ tó túbọ̀ ń pọ̀ sí i tínú ń bí tàbí tí wọ́n dá dúró máa ń gbẹ̀san nípa bíba àwọn ìsọfúnni pàtàkì jẹ́ tàbí kí wọ́n yọ ọ́ kúrò lórí àwọn kọ̀ǹpútà iléeṣẹ́ náà. Àwọn míì máa ń tú àwọn ọ̀rọ̀ àṣírí iléeṣẹ́ náà síta tàbí kí wọ́n jí i, kí wọ́n sì tà á. Yàtọ̀ sí jíjí àwọn ìsọfúnni lórí kọ̀ǹpútà, ìwé ìròyìn The New York Times sọ pé: “Ọ̀pọ̀ òṣìṣẹ́ ló ṣì máa ń jí ẹrù iléeṣẹ́ láti gbẹ̀san.” Torí náà, ọ̀pọ̀ iléeṣẹ́ ló máa ń ní kí òṣìṣẹ́ tó ń rí sí ààbò, tẹ̀ lé ẹni tí wọ́n dá dúró lọ sáyè rẹ̀, kí wọ́n sì dúró tì í títí tó fi máa kó gbogbo ẹrù ẹ̀, tí á sì jáde nínú ọgbà iléeṣẹ́ náà.
Ó máa ń rọrùn fún wa láti gbẹ̀san lára àwọn tó sún mọ́ wa, àwọn bí ọ̀rẹ́, alábàákẹ́gbẹ́ àtàwọn mọ̀lẹ́bí. Tí ẹnì kan bá sọ ohun tó duni tàbí tó ṣe ohun tó káni lára, ìyẹn lè mú kéèyàn fi ìbínú sọ ohun tó máa dun onítọ̀hùn tàbí kéèyàn ṣohun tó máa ká ẹni náà lára. Tí ọ̀rẹ́ rẹ kan bá fi ohùn líle sọ̀rọ̀ sí ẹ, ṣé ohùn líle nìwọ náà á fi fún un lésì? Tí mọ̀lẹ́bí rẹ kan bá múnú bí ẹ lọ́nà kan tàbí òmíràn, ṣó o máa ń wá bí wàá ṣe gbẹ̀san? Ó rọrùn gan-an láti gbẹ̀san lára ẹni tó bá sún mọ́ wa!
Àbájáde Ẹ̀san Kì Í Dáa
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń gbẹ̀san lọ́pọ̀ ìgbà láti tu ara wọn nínú lórí ohun tẹ́nì kan ṣe fún wọn. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé nígbà táwọn ọmọ Jékọ́bù, bàbá ńlá àwọn Hébérù, gbọ́ pé Ṣékémù tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Kénáánì ti fipá bá Dínà, arábìnrin wọn lò pọ̀, inú wọn “bàjẹ́, inú sì bí wọn gidigidi.” (Jẹ́nẹ́sísì 34:1-7) Àwọn méjì lára àwọn ọmọkùnrin Jékọ́bù pète lòdì sí Ṣékémù àti agboolé rẹ̀ torí kí wọ́n lè gbẹ̀san aburú tó ṣe fún arábìnrin wọn. Lẹ́yìn tí wọ́n lo ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ kan, Síméónì àti Léfì wọ ìlú àwọn ará Kénáánì, wọ́n sì pa gbogbo ọkùnrin tó wà níbẹ̀ títí kan Ṣékémù.—Jẹ́nẹ́sísì 34:13-27.
Ṣé gbogbo ìtàjẹ̀sílẹ̀ tí wọ́n ṣe yẹn wá yanjú ọ̀ràn náà? Nígbà tí Jékọ́bù gbọ́ nípa ohun táwọn ọmọkùnrin rẹ̀ ṣe yìí, ó bá wọn wí lọ́nà mímúná, ó ní: “Ẹ ti mú ìtanùlẹ́gbẹ́ wá sórí mi ní sísọ mí di òórùn burúkú lójú àwọn olùgbé ilẹ̀ yìí, . . . wọn yóò kóra jọpọ̀ lòdì sí mi, wọn yóò sì fipá kọlù mí, a ó sì pa mí rẹ́ ráúráú, èmi àti ilé mi.” (Jẹ́nẹ́sísì 34:30) Ó dájú pé, dípò kọ́rọ̀ náà yanjú, òdìkejì ohun tí wọ́n fẹ́ ló ṣẹlẹ̀; ńṣe ni ìdílé Jékọ́bù wá ní láti máa bẹ̀rù àwọn aládùúgbò wọn tínú ń bí. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ torí káwọn èèyàn yìí má bàa wá fìkanra mọ́ ìdílé Jékọ́bù ni Ọlọ́run ṣé fún ìdílé náà nítọ̀ọ́ni pé kí wọ́n kó lọ sí àgbègbè Bẹ́tẹ́lì.—Jẹ́nẹ́sísì 35:1, 5.
Ẹ̀kọ́ ńlá la lè rí kọ́ nínú àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí Ṣékémù fipá bá Dínà lò pọ̀. Tẹ́nì kan bá gbẹ̀san ìyẹn sábà máa ń mú kẹ́ni tí wọ́n gbẹ̀san lára ẹ̀ náà tún fẹ́ láti gbẹ̀san, ẹ̀san á wá tipa bẹ́ẹ̀ máa tẹ̀ léra. Ìyẹn ni Yorùbá fi máa ń sọ pé: ‘Aforóyaró kì í jẹ́ kóró tán nílẹ̀.’
Ìrora Á Túbọ̀ Máa Pọ̀ Sí I
Tá a bá ń fìgbà gbogbo ronú, tá a sì ń sapá láti rí i dájú pé a fìyà jẹ ẹni tó ṣẹ̀ wá, ìyẹn lè ṣàkóbá fún wa. Ìwé Forgiveness—How to Make Peace With Your Past and Get On With Your Life sọ pé: “Ìbínú máa ń gbani lọ́kàn gan-an. Ríronú lórí ohun tó fa ìbínú yẹn sì máa ń gba àkókò àti okun inú ẹni, kì í jẹ́ kínú èèyàn dùn sẹ́ni tó ń bínú sí, ó sì máa ń mú kéèyàn máa ronú lórí bó ṣe máa gbẹ̀san.” Ìyẹn sì bá àpèjúwe Bíbélì tó ṣe kedere yìí mu pé: “Owú jẹ́ ìjẹrà fún àwọn egungun.”—Òwe 14:30.
Ká sòótọ́, báwo ni inú ẹnì kan ṣe lè máa dùn nígbà tó bá ń ní ìkórìíra àti èrò ibi sí ẹlòmíì? Ọ̀gbẹ́ni kan tó máa ń ṣàlàyé ọ̀rọ̀ ìsìn sọ pé: “Tó o bá rò pé ‘ó dáa láti máa gbẹ̀san,’ kíyè sí bí nǹkan ṣe máa ń rí fáwọn tó ti mọ́ lára láti máa gbẹ̀san.”
Jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láwọn apá ibì kan lágbàáyé, níbi tí ìjà ẹ̀sìn àti kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà ti gbóná janjan. Pípa tí wọ́n bá pa ẹnì kan ṣoṣo ló máa ń dá ìpakúpa sílẹ̀, ìyẹn sì sábà máa ń jẹ́ káwọn èèyàn túbọ̀ máa kórìíra ara wọn, kí wọ́n sì máa pa ara wọn. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí àwọn apániláyà ju bọ́ǹbù kan tó sì pa àwọn ọ̀dọ́ méjìdínlógún [18], obìnrin kan tí ìbànújẹ́ bá sọ pé, “Ó yẹ ká san án pa dà fún wọn ní ìlọ̀po-ìlọ́po!” Ohun tó máa ń dá sílẹ̀ ni pé ìwà ìkà á túbọ̀ máa pọ̀ sí i, èyí sì máa ń sún àwọn èèyàn láti lọ́wọ́ nínú ìjà náà.
“Ojú fún Ojú”
Àwọn kan máa ń rò pé Bíbélì gan-an ò lòdì sí gbígbẹ̀san. Wọ́n sọ pé, “Ṣebí Bíbélì gan-an sọ pé ‘ojú fún ojú, eyín fún eyín’?” (Léfítíkù 24:20) Téèyàn ò bá ronú jinlẹ̀, ńṣe lèèyàn máa rò pé òfin tó sọ pé “ojú fún ojú” ti gbígbẹ̀san lẹ́yìn. Àmọ́ òótọ́ ibẹ̀ ni pé òfin yẹn wà láti jẹ́ kí ẹ̀san gbígbà láìnídìí dín kù. Lọ́nà wo?
Tí ọmọ Ísírẹ́lì kan bá bá ẹnì kan tí wọ́n jọ jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì jà tó sì fọ́ ọ lójú, Òfin yìí fàyè gba ìbáwí tó bófin mu. Àmọ́, kì í ṣe ẹni tí wọ́n fọ́ lójú tàbí mọ̀lẹ́bí ẹ̀ ló máa gbégbèésẹ̀ láti ṣohun tó tọ́ fún ẹni tó fọ́ ẹlòmíì lójú. Ohun tí Òfin sọ ni pé kí wọ́n lọ fẹjọ́ sun àwọn aláṣẹ, ìyẹn àwọn onídàájọ́ tí Ọlọ́run yàn, kí wọ́n lè yanjú ọ̀ràn náà bó ti tọ́. Mímọ̀ táwọn èèyàn mọ̀ pé ìyà ẹ̀ṣẹ̀ ẹni tó bá mọ̀ọ́mọ̀ hùwà ìkà tàbí ìwà ipá sí ẹlòmíì ni pé wọ́n máa ṣohun kan náà fóun náà máa jẹ́ kí wọ́n bẹ̀rù gan-an láti ṣohun tí kò dáa. Àmọ́, Òfin yẹn ṣì nítumọ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ.
Ṣáájú kí Jèhófà Ọlọ́run tó ṣe òfin tá a sọ lókè yìí, ó ní kí Mósè sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ kórìíra arákùnrin rẹ nínú ọkàn-àyà rẹ. . . . Ìwọ kò gbọ́dọ̀ gbẹ̀san tàbí kí o di kùnrùngbùn.” (Léfítíkù 19:17, 18) Ó dájú pé ojú tá a fi ń wo gbogbo òfin tó wà nínú májẹ̀mú Òfin náà ló yẹ ká máa fi wo òfin tó sọ pé “ojú fún ojú, eyín fún eyín” gbogbo ẹ̀ sì ni Jésù sọ pé a lè pa pọ̀ sínú òfin méjì, ó ní: “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú rẹ” àti “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.” (Mátíù 22:37-40) Kí ló wá yẹ káwọn Kristẹni tòótọ́ ṣe tí wọ́n bá hùwà tí kò bá ìdájọ́ òdodo mu sí wọn?
Máa Wá Àlàáfíà
Bíbélì ṣàpèjúwe Jèhófà gẹ́gẹ́ bí “Ọlọ́run àlàáfíà,” ó sì rọ àwọn tó ń jọ́sìn rẹ̀ pé kí wọ́n “máa wá àlàáfíà, kí [wọ́n] sì máa lépa rẹ̀.” (Hébérù 13:20; 1 Pétérù 3:11) Àmọ́ ṣó ṣeé ṣe kéèyàn máa wá àlàáfíà lóòótọ́?
Nígbà tí Jésù ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, àwọn èèyàn tutọ́ sí i lára, wọ́n nà án lẹ́gba, àwọn ọ̀tá ẹ̀ ṣenúnibíni sí i, ọ̀rẹ́ ẹ̀ tímọ́tímọ́ kan dà á, kódà àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pa á tì. (Mátíù 26:48-50; 27:27-31) Kí ló wá ṣe? Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé: “Nígbà tí a ń kẹ́gàn rẹ̀, kò bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́gàn padà. Nígbà tí ó ń jìyà, kò bẹ̀rẹ̀ sí halẹ̀ mọ́ni, ṣùgbọ́n ó ń bá a nìṣó ní fífi ara rẹ̀ lé ọwọ́ ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ lọ́nà òdodo.”—1 Pétérù 2:23.
Pétérù ṣàlàyé pé: “Kristi . . . jìyà fún yín, ó fi àwòkọ́ṣe sílẹ̀ fún yín kí ẹ lè tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹkípẹ́kí.” (1 Pétérù 2:21) Bíbélì gba àwọn Kristẹni níyànjú pé kí wọ́n fara wé Jésù, títí kan ohun tó ṣe nígbà tí wọ́n hùwà tí kò bá ìdájọ́ òdodo mu sí i. Lórí kókó yìí, Jésù alára sọ nínú ìwàásù tó ṣe lórí òkè pé: “Ẹ máa bá a lọ láti máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín àti láti máa gbàdúrà fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí yín; kí ẹ lè fi ara yín hàn ní ọmọ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run.”—Mátíù 5:44, 45.
Báwo làwọn tó bá nírú ìfẹ́ tí Kristi ní ṣe máa hùwà pa dà tí ẹnì kan bá ṣẹ̀ wọ́n tàbí tí wọ́n bá ronú pé ẹnì kan ti ṣẹ àwọn? Wọ́n máa ń fi ìmọ̀ràn inú ìwé Òwe 19:11 sọ́kàn pé: “Ìjìnlẹ̀ òye tí ènìyàn ní máa ń dẹwọ́ ìbínú rẹ̀ dájúdájú, ẹwà ni ó sì jẹ́ níhà ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti gbójú fo ìrélànàkọjá.” Wọ́n tún máa ń fi ìmọ̀ràn yìí sílò pé: “Má ṣe jẹ́ kí ibi ṣẹ́gun rẹ, ṣùgbọ́n máa fi ire ṣẹ́gun ibi.” (Róòmù 12:21) Ó dájú pé ìyẹn yàtọ̀ sí ẹ̀mí ìforóyaró tó kúnnú ayé lónìí! Tá a bá ní ìfẹ́ tòótọ́ tó jẹ́ ti Kristẹni, ìyẹn ò ní jẹ́ ká fẹ́ láti máa gbẹ̀san, á sì jẹ́ ká lè máa “gbójú fo ìrélànàkọjá” torí pé ìfẹ́ “kì í kọ àkọsílẹ̀ ìṣeniléṣe.”—1 Kọ́ríńtì 13:5.
Ṣó wá túmọ̀ sí pé táwọn kan bá hùwà ipá sí wa tàbí tí wọ́n halẹ̀ mọ́ wa lọ́nà kan tàbí òmíràn, àfi ká gbà á mọ́ra? Rárá o! Nígbà tí Pọ́ọ̀lù sọ pé, ẹ “Máa fi ire ṣẹ́gun ibi,” ìyẹn ò túmọ̀ sí pé kí Kristẹni kan wá gbàgbàkugbà láyè torí ẹ̀sìn. Kàkà bẹ́ẹ̀, táwọn oníwà ipá bá gbéjà kò wá, a lẹ́tọ̀ọ́ láti gbèjà ara wa. A lè pe àwọn ọlọ́pàá táwọn èèyàn burúkú bá gbéjà kò wá tàbí tí wọ́n bá gba ohun ìní wa. Tó bá jẹ́ pé iléèwé tàbí ibiṣẹ́ ló ti ṣẹlẹ̀, a lè pe àwọn aláṣẹ.—Róòmù 13:3, 4.
Síbẹ̀, ó ṣe pàtàkì láti fi sọ́kàn pé kò rọrùn láti rí ìdájọ́ òdodo gbà nínú ayé tá a wà yìí. Kódà, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti fi gbogbo ọjọ́ ìgbésí ayé wọn wá ìdájọ́ òdodo, àmọ́ tọ́wọ́ wọn ò tẹ̀ ẹ́, ìyẹn ti yọrí sí ìbànújẹ́, ó sì ti múnú bí wọn.
Ohun tí Sátánì ń fẹ́ ni pé kí ìkórìíra àti gbígba ẹ̀san mú káwọn èèyàn kẹ̀yìn síra wọn. (1 Jòhánù 3:7, 8) Ó ṣe pàtàkì gan-an nígbà náà pé ká fàwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì yìí sọ́kàn pé: “Ẹ má ṣe gbẹ̀san ara yín, ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ṣùgbọ́n ẹ yàgò fún ìrunú; nítorí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: ‘Tèmi ni ẹ̀san; dájúdájú, èmi yóò san ẹ̀san, ni Jèhófà wí.’” (Róòmù 12:19) Tá a bá ń fọ̀rọ̀ lé Jèhófà lọ́wọ́, a máa bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀dùn ọkàn, ìbínú àti ìwà ipá.—Òwe 3:3-6.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 22]
“Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú rẹ,” kí o sì “nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ”
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ìfẹ́ “kì í kọ àkọsílẹ̀ ìṣeniléṣe.” —1 Kọ́ríńtì 13:5