Kí Nìdí Tí Èrò Àwọn Èèyàn Kò Fi Ṣọ̀kan Lórí Ẹ̀mí Mímọ́?
Kí Nìdí Tí Èrò Àwọn Èèyàn Kò Fi Ṣọ̀kan Lórí Ẹ̀mí Mímọ́?
KÍ NI ẹ̀mí mímọ́? Ó lè dà bí ẹni pé ìbéèrè yẹn kò le, àmọ́ ó lè ṣòro láti rí ìdáhùn tó rọrùn. Póòpù Benedict Kẹrìndínlógún sọ fún àwùjọ kan ní orílẹ̀-èdè Ọsirélíà pé: “A fẹ́rẹ̀ẹ́ máà ní òye tó kún rẹ́rẹ́ nípa ohun tí Ẹ̀mí jẹ́.”
Òótọ́ ni pé èrò àwọn èèyàn kì í ṣọ̀kan tó bá dọ̀rọ̀ kí wọ́n dáhùn ìbéèrè yìí pé, Kí ni ẹ̀mí mímọ́? Ohun tó sábà máa ń jẹ́ ìdáhùn ọ̀pọ̀ èèyàn rèé:
• Ẹni gidi kan tó ń gbénú àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi.
• Bí Ọlọ́run ṣe ń fi hàn pé òun wà ní ayé.
• Ẹnì kẹta nínú Mẹ́talọ́kan.
Kí nìdí tí èrò àwọn èèyàn kò fi ṣọ̀kan? Ọ̀rúndún kẹrin Sànmánì Kristẹni ni ìṣòro yẹn bẹ̀rẹ̀ nígbà tí àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn ń sọ pé ẹnì kan tóun náà bá Ọlọ́run dọ́gba ni ẹ̀mí mímọ́. Àmọ́, kì í ṣe ohun tí Ìwé Mímọ́ tàbí àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi ìgbàanì kọ́ni nìyẹn. Ìwé New Catholic Encyclopedia ṣàlàyé pé: “Ó ṣe kedere pé Májẹ̀mú Láéláé kò sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀mí Ọlọ́run bí ẹnì kan . . . Ní kúkúrú, agbára Ọlọ́run ni ẹ̀mí Ọlọ́run.” Ó tún fi kún un pé: “Èyí tó pọ̀ jù nínú ẹsẹ tó wà nínú Májẹ̀mú Tuntun ló sọ̀rọ̀ ẹ̀mí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ohun kan, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan; èyí sì túbọ̀ ṣe kedere nígbà tó ń sọ bí ẹ̀mí àti agbára Ọlọ́run ṣe bára mu.”
Ó dájú pé àwọn èèyàn kò ní sọ pé agbára jẹ́ ẹnì kan. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé nínú ìwádìí kan tí wọ́n ṣe ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ló sọ pé ẹ̀mí mímọ́ kì í ṣe ẹnì kan tàbí “ohun kan tó wà láàyè.” Ṣóòótọ́ ni? Àbí ṣé ká gbà pé òótọ́ ni ohun táwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn ń sọ bí wọ́n ṣe ń tẹnu mọ́ ọn pé, “Ẹ̀mí Mímọ́ jẹ́ Ẹnì kan tó dá dúró bíi ti Baba àti Ọmọ”?
Ká lè rí ìdáhùn tó máa tẹ́ wa lọ́rùn, jẹ́ ká lọ sínú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ṣàpèjúwe ẹ̀mí mímọ́ lọ́nà tó kún rẹ́rẹ́. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà.”—2 Tímótì 3:16.
Kí nìdí tó fi yẹ kó o sapá láti mọ òtítọ́ nípa ẹ̀mí mímọ́? Ìdí ni pé mímọ òtítọ́ yẹn lè jẹ́ kó o mọ bó o ṣe máa rí ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run gbà. Ǹjẹ́ ó máa ń ṣe ẹ́ nígbà míì bíi pé agbára rẹ kò ká àwọn ohun tó ń bá ẹ fínra? Jésù ṣèlérí fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní bíbéèrè, a ó sì fi í fún yín . . . Bí ẹ̀yin . . . bá mọ bí ẹ ṣe ń fi ẹ̀bùn rere fún àwọn ọmọ yín, mélòómélòó ni Baba tí ń bẹ ní ọ̀run yóò fi ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn tí ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀!”—Lúùkù 11:9, 13.
Nínú àwọn àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e, Ìwé Mímọ́ máa jẹ́ ká mọ ohun tí ẹ̀mí mímọ́ jẹ́. A sì máa rí bó ṣe lè ṣe wá láǹfààní nígbèésí ayé wa.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 3]
Ìwé Mímọ́ jẹ́ ká mọ ohun tí ẹ̀mí mímọ́ jẹ́