“Àkókò Tí A Yàn Kalẹ̀” Ti Sún Mọ́lé
“Àkókò Tí A Yàn Kalẹ̀” Ti Sún Mọ́lé
BÓ ṢE rí lára wòlíì Hábákúkù, àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù náà ń fẹ́ láti rí bí ìjìyà ṣe máa dópin. Lẹ́yìn tí wọ́n ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tí Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe láti yanjú ìṣòro tó wà lórí ilẹ̀ ayé, wọ́n wá bi Jésù pé: “Nígbà wo ni nǹkan wọ̀nyí yóò ṣẹlẹ̀, kí ni yóò sì jẹ́ àmì wíwàníhìn-ín rẹ [nínú agbára Ìjọba] àti ti ìparí ètò àwọn nǹkan?” (Mátíù 24:3) Nígbà tí Jésù dáhùn, ó ní Jèhófà Ọlọ́run nìkan ló mọ àkókò pàtó tí Ìjọba náà máa bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ lórí ilẹ̀ ayé. (Mátíù 24:36; Máàkù 13:32) Àmọ́ Jésù àtàwọn míì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé tó máa jẹ́ ká mọ̀ pé àkókò náà ti sún mọ́lé.— Wo àpótí tó wà lápá ọ̀tún.
Ó dájú pé wàá gbà pé àwọn nǹkan yìí ń ṣẹlẹ̀ níbi gbogbo lónìí. Jésù tún sọ tẹ́lẹ̀ pé iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì máa kárí ibi gbogbo lórí ilẹ̀ ayé. Ó sọ pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.”—Mátíù 24:14.
Ohun tó sì ń ṣẹlẹ̀ lónìí gan-an nìyẹn. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe iṣẹ́ yẹn. Àwa Ẹlẹ́rìí tá a ju mílíọ̀nù méje lọ ń sọ àwọn ohun tí Ìjọba náà máa ṣe fún àwọn èèyàn ní ilẹ̀ tó tó igba àti mẹ́rìndínlógójì [236], a tún ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti máa gbé ìgbésí ayé wọn níbàámu pẹ̀lú àwọn ìlànà òdodo Ọlọ́run, ẹni tó jẹ́ ìfẹ́ rẹ̀ láti fi òpin sí ìjìyà àti ìrora. Máa bá a nìṣó láti máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run, èyí á jẹ́ kó o nírètí láti gbé nínú ayé tí kò ti ní sí ìjìyà mọ́ títí láé.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 8]
Àwọn Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Tó Sọ Nípa Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn
• Ogun tí a kò rí irú rẹ̀ rí
• Àwọn ìsẹ̀lẹ̀ ńláǹlà
• Àìtó oúnjẹ
• Àjàkálẹ̀ àrùn
• Ìwà àìlófin tó ń pọ̀ sí i
• Ìfẹ́ ọ̀pọ̀ ń di tútù
• Pípa ilẹ̀ ayé run
• Ìfẹ́ tó burú jáì fún owó
• Ṣíṣàìgbọràn sí òbí
• Ìfẹ́ tara-ẹni-nìkan
• Àìní ìfẹ́ àdánidá
• Àwọn èèyàn kò ṣeé bá ṣe àdéhùn kankan
• Àìní ìkóra-ẹni-níjàánu láàárín onírúurú èèyàn láwùjọ
• Ìfẹ́ ohun rere túbọ̀ ń dàwátì
• Nínífẹ̀ẹ́ fàájì ju Ọlọ́run lọ
• Ọ̀pọ̀ ló ń fẹnu lásán pe ara wọn ní Kristẹni
• Ọ̀pọ̀ wòlíì èké gbòde kan
• Inúnibíni sí àwọn Kristẹni tòótọ́
• Àwọn èèyàn kò kọbi ara sí àwọn ìkìlọ̀ tó wà nínú Bíbélì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Kárí ayé ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń kọ́ àwọn èèyàn nípa Ìjọba Ọlọ́run