Ṣó Yẹ Kí Àwọn Kristẹni Máa Ṣayẹyẹ Ọdún Tuntun?
Ṣó Yẹ Kí Àwọn Kristẹni Máa Ṣayẹyẹ Ọdún Tuntun?
NÍ ỌDỌỌDÚN, lóṣù January tàbí February, àwọn ará Éṣíà máa ń gbàlejò èèyàn tó pọ̀ jù lọ lágbàáyé. Ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn ọmọ ilẹ̀ Éṣíà ló máa ń pa dà sọ́dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí wọn láti lọ ṣayẹyẹ Ọdún Tuntun. a
Ayẹyẹ Ọdún Tuntun yìí ni àjọ̀dún tó ṣe pàtàkì jù lọ táwọn ará Éṣíà máa ń ṣe lọ́dọọdún. Òǹkọ̀wé ọmọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà kan sọ pé: “[Ṣe ló] dà bí kí wọ́n pa Ọjọ́ Ọdún Tuntun, Ọjọ́ Kẹrin Oṣù July, Ìdúpẹ́ àti Kérésìmesì pọ̀ sójú kan.” Bí wọ́n ṣe máa ń kà á lórí kàlẹ́ńdà àwọn ará Ṣáínà tí wọ́n ń fi òṣùpá kà, ọjọ́ tí òṣùpá tuntun àkọ́kọ́ bá yọ lọ́dún ni wọ́n máa ń bẹ̀rẹ̀ àjọ̀dún yìí, ó sì lè bọ́ sí àárín January 21 sí February 20 lórí kàlẹ́ńdà àwọn ará Ìwọ̀ Oòrùn. Wọ́n sábà máa ń lo ọ̀pọ̀ ọjọ́ kódà ó máa ń tó ọ̀sẹ̀ méjì tí wọ́n fi máa ń ṣe àjọ̀dún yìí.
Olórí ìdí tí àwọn èèyàn fi ń ṣayẹyẹ Ọdún Tuntun ni láti sàmì sí ìbẹ̀rẹ̀ tuntun, wọ́n fẹ́ dágbére fún ọdún tó ti kọjá, kí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ọdún tuntun. Láti múra sílẹ̀ fún àjọyọ̀ yìí, àwọn èèyàn máa ń tún ilé wọn ṣe kó lè mọ́ tónítóní, wọ́n sì máa ń ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́, wọ́n máa ń ra aṣọ tuntun, wọ́n máa ń se àwọn oúnjẹ tí orúkọ rẹ̀ jẹ mọ́ “oríire” tàbí “aásìkí,” wọ́n máa ń san gbogbo gbèsè tí wọ́n bá jẹ, wọ́n sì máa ń yanjú gbogbo aáwọ̀ tí wọ́n bá ní pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì. Ní Ọjọ́ Ọdún Tuntun yìí, wọ́n máa ń fún ara wọn ní ẹ̀bùn, wọ́n sì máa ń ṣàdúrà ọrọ̀ àti aásìkí fún ara wọn, wọ́n máa ń fún ara wọn ní owó tí wọ́n fi nǹkan pupa dì pọ̀, tí wọ́n ń pè ní owó oríire, wọ́n máa ń jẹ oúnjẹ tó ṣàrà ọ̀tọ̀, wọ́n máa ń yin àwọn nǹkan ìṣeré tó máa ń dún bíi bọ́ǹbù, wọ́n máa ń lọ wo ijó àwọn tó wọṣọ aláràbarà tàbí tàwọn tó múra bíi kìnnìún tàbí kí wọ́n kàn gbádùn ara wọn pẹ̀lú mọ̀lẹ́bí àtàwọn ọ̀rẹ́.
Àwọn àṣà wọ̀nyí ní ìtumọ̀ tó pọ̀ gan-an. Ìwé Mooncakes and Hungry Ghosts: Festivals of China ṣàlàyé pé: “Olórí ohun tó jẹ àwọn ìdílé, ọ̀rẹ́ àtàwọn mọ̀lẹ́bí lógún ni láti rí i dájú pé àwọn ṣoríire, àwọn bọ̀wọ̀ fún àwọn òrìṣà àti àwọn ẹ̀mí, àwọn sì ṣe àwọn nǹkan tó máa jẹ́ káwọn ṣe kòńgẹ́ ire lọ́dún tuntun.” Nítorí onírúurú àṣà ìbílẹ̀ àtàwọn ààtò ìsìn tó wà nínú ṣíṣayẹyẹ Ọdún Tuntun yìí, irú ojú wo ló yẹ kí àwọn Kristẹni fi wo ayẹyẹ yìí? Ṣó yẹ kí àwọn náà lọ́wọ́ sírú àwọn àṣà yìí? Ṣé ayẹyẹ yìí tiẹ̀ wà fún àwọn Kristẹni?
“Máa Rántí Orísun Rẹ̀”
Òwe ilẹ̀ Ṣáìnà kan tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ bí ẹní mọ owó sọ pé: “Tó o bá ń mu omi, máa rántí orísun rẹ̀.” Òwe yìí jẹ́ ká mọ̀ nípa àṣà àwọn ará ilẹ̀ Éṣíà tó ní í ṣe pẹ̀lú bíbọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún àwọn òbí àti àwọn baba ńlá wọn. Torí pé nípasẹ̀ òbí làwọn ọmọ fi wáyé, ó bọ́gbọ́n mú pé káwọn ọmọ bọ̀wọ̀ fún àwọn òbí wọn, ipa pàtàkì nìyẹn sì ń kó nínú ṣíṣayẹyẹ Ọdún Tuntun.
Ọ̀kan lára àwọn nǹkan pàtàkì táwọn ará ilẹ̀ Éṣíà kì í fẹ́ pa jẹ ni Alẹ́ Ọdún Tuntun Ku Ọ̀la. Lálẹ́ ọjọ́ yẹn, ọ̀pọ̀ ìdílé ló máa ń pé jọ láti jẹ àkànṣe àsè. Àsìkò tí gbogbo ìdílé máa ń pàdé pọ̀ nìyí nílẹ̀ Éṣíà, àwọn èèyàn náà sì máa ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá lè ṣe láti rí i dájú pé àwọn wà níbẹ̀. Tí wọ́n bá tẹ́ tábìlì oúnjẹ, kì í ṣe àwọn tó jẹ́ ara ìdílé wọn tó wà níbẹ̀ nìkan ni wọ́n máa ń tẹ́ tábìlì fún, àmọ́ wọ́n tún máa ń tẹ́ tábìlì fún àwọn mọ̀lẹ́bí tó ti kú tí wọ́n sì gbà gbọ́ pé wọ́n wà níbẹ̀ pẹ̀lú wọn nínú ẹ̀mí. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ kan sọ pé níbi àsè yìí, “àwọn mọ̀lẹ́bí máa ń bá àwọn baba ńlá wọn sọ̀rọ̀.” Ìwé míì tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ pé: “Nítorí àjọṣe tí àwọn mọ̀lẹ́bí ń tipa báyìí sọ di àkọ̀tun láàárín àwọn òkú àti alààyè, àwọn baba ńlá yìí máa dáàbò bò wọ́n jálẹ̀ ọdún náà.” Irú ojú wo ló wá yẹ kí àwọn Kristẹni fi wo àṣà yìí?
Àwọn Kristẹni pàápàá ka bíbọ̀wọ̀ fún àwọn òbí àti nínífẹ̀ẹ́ wọn sí ohun pàtàkì. Wọ́n ń tẹ̀ lé ìtọ́ni tí Ọlọ́run fún wọn yìí pé: “Fetí sí baba rẹ tí ó bí ọ, má sì tẹ́ńbẹ́lú ìyá rẹ kìkì nítorí pé ó ti darúgbó.” (Òwe 23:22) Wọ́n tún ń ṣègbọràn sí àṣẹ yìí tó wà nínú Bíbélì pé: “‘Bọlá fún baba rẹ àti ìyá rẹ’; èyí tí í ṣe àṣẹ kìíní pẹ̀lú ìlérí: ‘Kí nǹkan lè máa lọ dáadáa fún ọ, kí ìwọ sì lè wà fún àkókò gígùn lórí ilẹ̀ ayé.’” (Éfésù 6:2, 3) Ó dájú pé àwọn Kristẹni tòótọ́ fẹ́ láti nífẹ̀ẹ́ àwọn òbí wọn, kí wọ́n sì bọlá fún wọn!
Bíbélì pàápàá sọ̀rọ̀ dáadáa nípa àwọn àpèjẹ ìdílé. (Jóòbù 1:4; Lúùkù 15:22-24) Síbẹ̀, Jèhófà pàṣẹ pé: “Kí a má ṣe rí láàárín rẹ ẹnikẹ́ni tí ń . . . wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ abẹ́mìílò tàbí olùsàsọtẹ́lẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tàbí ẹnikẹ́ni tí ń ṣèwádìí lọ́dọ̀ òkú.” (Diutarónómì 18:10, 11) Kí nìdí tí Ọlọ́run fi kà á léèwọ̀ fún wọn? Ìdí ni pé Bíbélì jẹ́ ká mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn tó ti kú. Ó ní: “Nítorí àwọn alààyè mọ̀ pé àwọn yóò kú; ṣùgbọ́n ní ti àwọn òkú, wọn kò mọ nǹkan kan rárá.” Torí pé àwọn òkú kò mọ ohunkóhun, wọn kò lè kópa nínú àwọn ohun tí àwọn alààyè ń ṣe; wọn kò sì lè ràn wá lọ́wọ́ tàbí kí wọ́n pa wá lára. (Oníwàásù 9:5, 6, 10) Jésù Kristi, Ọmọ Ọlọ́run fi ikú wé oorun àsùnwọra, ìgbà àjíǹde sì ni àwọn òkú máa jí kúrò lójú oorun yìí.—Jòhánù 5:28, 29; 11:11, 14.
Bákan náà, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ẹ̀mí búburú tó ń díbọ́n bí ẹni tó kú ni àwọn tí wọ́n ń pè ní àkúdàáyà àti ẹ̀mí àwọn òkú. Kí nìdí tí wọ́n fi ń ṣe bẹ́ẹ̀? Kí wọ́n lè tan àwọn èèyàn jẹ kí wọ́n sì lè mú wọn wá sábẹ́ ìdarí búburú wọn! (2 Tẹsalóníkà 2: 9, 10) Torí náà, àṣẹ tí Ọlọ́run pa yìí máa gbà wá sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ewu tó lékenkà. Torí pé àwọn Kristẹni nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, wọn kò sì fẹ́ kó sínú ewu, wọ́n máa ń yẹra fún àṣà èyíkéyìí tó bá ní ìjọsìn “ẹ̀mí” àwọn mọ̀lẹ́bí tó ti kú nínú tàbí fífi àwọn ẹ̀mí yìí dáàbò bo ara wọn.—Aísáyà 8:19, 20; 1 Kọ́ríńtì 10:20-22.
Yàtọ̀ síyẹn, àwọn Kristẹni fẹ́ láti bọ̀wọ̀ fún “Baba, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí olúkúlùkù ìdílé ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé ti gba orúkọ rẹ̀.” (Éfésù 3:14, 15) Ta ni Baba yìí? Òun ni Jèhófà Ọlọ́run, Ẹlẹ́dàá àti Olùfúnni-ní-Ìyè wa. (Ìṣe 17:26) Torí náà, nígbà tá a bá ń ṣàyẹ̀wò àwọn àṣà tó jẹ mọ́ Ọdún Tuntun yìí, ó yẹ ká máa bi ara wa pé: Irú ojú wo ni Jèhófà fi ń wo àṣà yìí? Ṣé inú rẹ̀ dùn sí i?—1 Jòhánù 5:3.
Bíbọ̀wọ̀ fún Àwọn Òòṣà Ìdílé
Onírúurú àṣà tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ dáadáa ló kúnnú ayẹyẹ Ọdún Tuntun yìí. Lára àwọn àṣà náà ni bíbọ̀wọ̀ fún àwọn òòṣà ìdílé àtàwọn ọlọ́run àjúbàfún, irú bí ọlọ́run ilẹ̀kùn, ọlọ́run ilẹ̀ ayé tàbí ẹ̀mí tó ń ṣọ́ni, ọlọ́run ọrọ̀ tàbí aásìkí àti ọlọ́run ilé-ìdáná tàbí ọlọ́run sítóòfù. Jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò àṣà tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ dáadáa nípa bí wọ́n ṣe máa ń jọ́sìn ọlọ́run ilé-ìdáná. b Àwọn ará ilẹ̀ Éṣíà gbà gbọ́ pé ní ọjọ́ díẹ̀ ṣáájú Ọdún Tuntun, ọlọ́run yìí máa ń rìnrìn àjò lọ sí ọ̀run, láti lọ gba ìròyìn wá nípa ìdílé náà fún Olú Ọba Jade tó jẹ́ olórí gbogbo àwọn òòṣà ilẹ̀ Ṣáínà. Níwọ̀n bí wọ́n ti retí pé ọlọ́run ilé-ìdánà yìí máa mú ìròyìn rere wá nípa wọn, àwọn ìdílé máa ń fi oúnjẹ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ ṣe ìdágbére fún un, wọ́n sì máa ń fi súìtì àtàwọn mindin-mín-ìndìn rúbọ sí i. Kó lè tètè pa dà lọ, àwọn ìdílé náà máa ń ya àwòrán rẹ̀, wọ́n á fi àwọn súìtì náà sí i lẹ́nu nínú àwòrán náà, wọ́n á sì finá sun ún níta. Tó bá wá di Alẹ́ Ọdún Tuntun Ku Ọ̀la, wọ́n á fi àwòrán tuntun tó jẹ́ ti ọlọ́run yìí sórí sítóòfù tí wọ́n fi ń dáná, kó lè pa dà wá sínú ilé wọn lọ́dún tuntun.
Ó lè dà bíi pé kò sóhun tó burú nínú ọ̀pọ̀ àwọn àṣà tá a mẹ́nu bà yìí, síbẹ̀ àwọn Kristẹni máa fẹ́ láti ṣe ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ nípa ìjọsìn. Jésù Kristi sọ nípa ìjọsìn pé: “Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni ìwọ gbọ́dọ̀ jọ́sìn, òun nìkan ṣoṣo sì ni ìwọ gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún.” (Mátíù 4:10) Ó ṣe kedere pé Ọlọ́run fẹ́ ká jọ́sìn òun nìkan. Kí nìdí? Rò ó wò ná: Jèhófà ni Bàbá wa ọ̀run. Báwo lo ṣe rò pé ó máa rí lára bàbá kan tí àwọn ọmọ rẹ̀ bá kọ̀ ọ́ sílẹ̀ tí wọ́n sì wá ń lọ sọ́dọ̀ bàbá míì? Ó dájú pé ọ̀rọ̀ náà máa ká a lára gan-an?
Jésù mọ Bàbá rẹ̀ ọ̀run sí “Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà,” Jèhófà fúnra rẹ̀ sì sọ fún àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ lọ́nà tó ṣe kedere pé wọn “kò gbọ́dọ̀ ní àwọn ọlọ́run èyíkéyìí mìíràn” níṣojú òun. (Jòhánù 17:3; Ẹ́kísódù 20:3) Torí náà, ohun tó máa múnú Jèhófà dùn ni àwọn Kristẹni tòótọ́ máa fẹ́ láti ṣe, wọn kò ní fẹ́ já Jèhófà kulẹ̀ tàbí kí wọ́n ṣe ohun tó máa ká a lára nípa jíjọ́sìn àwọn ọlọ́run míì.—1 Kọ́ríńtì 8:4-6.
Ìbẹ́mìílò àti Ìgbàgbọ́ Nínú Ohun Asán
Ọdún Tuntun tí wọ́n ń ṣe nílẹ̀ Éṣíà yìí tún ní nǹkan ṣe pẹ̀lú wíwo ìràwọ̀. Wọ́n máa ń fi orúkọ ọ̀kan lára àwọn ẹranko méjìlá tó wà lórí àtẹ sódíákì ilẹ̀ Ṣáínà sọ ọdún kọ̀ọ̀kan lórúkọ, irú bíi dírágónì, ẹkùn, ọ̀bọ, ehoro àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Wọ́n gbà pé àwọn ẹranko yìí ló máa ń pinnu ìwà àti ìṣe àwọn tí wọ́n bá bí ní ọdún yẹn tàbí pé òun ló máa jẹ́ kí àwọn nǹkan kan ṣeé ṣe lọ́dún náà. Torí kí wọ́n lè ṣoríire ni ọ̀pọ̀ èèyàn fi ń lọ́wọ́ sí onírúurú àṣà tó bá Ọdún Tuntun yìí rìn, títí kan jíjọ́sìn ọlọ́run ọrọ̀ tàbí ti oríire. Irú ojú wo ló yẹ káwọn Kristẹni fi wo àṣà yìí?
Jèhófà Ọlọ́run dẹ́bi fún gbogbo àwọn tó “ń jọ́sìn ọ̀run, àwọn tí ń wo ìràwọ̀, àwọn tí ń fúnni ní ìmọ̀ nígbà òṣùpá tuntun nípa àwọn ohun tí yóò dé bá [wọn].” Ó tún fi àwọn tó ń jọ́sìn “ọlọ́run Oríire” àti “ọlọ́run Ìpín” bú. (Aísáyà 47:13; 65:11, 12) Dípò kí wọ́n máa gbẹ́kẹ̀ lé àwọn ohun abàmì tàbí àwọn ohun tí wọn kò lè fojú rí tó ní í ṣe pẹ̀lú ilẹ̀ ọba ẹ̀mí tàbí ìràwọ̀, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ fáwọn olùjọ́sìn tòótọ́ pé: “Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ. Ṣàkíyèsí rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà rẹ, òun fúnra rẹ̀ yóò sì mú àwọn ipa ọ̀nà rẹ tọ́.” (Òwe 3:5, 6) Ó dájú pé, ìgbàgbọ́ nínú ohun asán ń fi àwọn èèyàn sínú ìdè, àmọ́ òtítọ́ Bíbélì ló ń tú wọn sílẹ̀.—Jòhánù 8:32.
Fi Hàn Pé O Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run
Ọ̀tọ̀ ni kéèyàn mọ orísun àwọn àṣà àtàwọn ìgbàgbọ́ tó ní í ṣe pẹ̀lú ayẹyẹ Ọdún Tuntun tí wọ́n ń ṣe nílẹ̀ Éṣíà, ọ̀tọ̀ sì ni kéèyàn pinnu pé òun kò ní lọ́wọ́ sí i. Tó bá jẹ́ pé ọdọọdún ni àwọn èèyàn sábà máa ń ṣe ayẹyẹ Ọdún Tuntun yìí ní àdúgbò tó ò ń gbé tàbí tó bá jẹ́ pé ìdílé rẹ máa ń ṣe ayẹyẹ Ọdún Tuntun, ìpinnu pàtàkì lo ní láti ṣe.
Ká sòótọ́, èèyàn ní láti ní ìgboyà, kó sì ṣe ìpinnu tó lágbára tí kò bá fara mọ́ èrò tí ọ̀pọ̀ èèyàn ní. Obìnrin kan tó jẹ́ Kristẹni nílẹ̀ Éṣíà sọ pé: “Ẹ̀rù bà mí gan-an torí pé gbogbo àwọn èèyàn tó yí mi ká ló ń ṣayẹyẹ Ọdún Tuntun, àmọ́ tí èmi kò bá wọn lọ́wọ́ sí i.” Kí ló ran obìnrin yìí lọ́wọ́? Ó ní: “Torí pé mo kọ́ láti ní ìfẹ́ tó lágbára fún Ọlọ́run nìkan ni mi ò ṣe juwọ́ sílẹ̀.”—Mátíù 10:32-38.
Ṣó o ní ìfẹ́ tó lágbára fún Jèhófà? Ọ̀pọ̀ nǹkan ló gbọ́dọ̀ mú kó o nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Jèhófà Ọlọ́run ló fún ẹ ní ìwàláàyè, kì í ṣe àwọn abàmì òrìṣà. Bíbélì sọ pé: “Nítorí pé ọ̀dọ̀ rẹ ni orísun ìyè wà; nípasẹ̀ ìmọ́lẹ̀ láti ọ̀dọ̀ rẹ ni àwa fi lè rí ìmọ́lẹ̀.” (Sáàmù 36:9) Jèhófà ló pèsè jíjẹ àti mímu fún ẹ, tó sì jẹ́ kó o lè máa láyọ̀ nígbèésí ayé, kì í ṣe ọlọ́run oríire tàbí ọlọ́run ilé-ìdáná. (Ìṣe 14:17; 17:28) Ṣé ìwọ náà máa nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run láti fi hàn pé o moore? Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà máa bù kún rẹ jìngbìnnì tó o bá nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.—Máàkù 10:29, 30.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wọ́n tún máa ń pe ọdún tí wọ́n ń ṣe ní ilẹ̀ Éṣíà yìí ní Ọdún Tuntun Ti Àwọn Ará Ṣáínà, Ọdún Ìgbà Ìrúwé, Chun Jie (lórílẹ̀-èdè Ṣáínà), Tet ( lórílẹ̀-èdè Vietnam), Solnal (lórílẹ̀-èdè Kòríà) tàbí Losar (nílùú Tibet).
b Àwọn àṣà tá a ṣàpèjúwe rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ yìí yàtọ̀ síra láti ibì kan sí òmíràn nílẹ̀ Éṣíà, àmọ́ àwọn ohun tó dọ́gba nípa àwọn àṣà yìí la mẹ́nu bà. Tó o bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i ka Jí! December 22, 1986, ojú ìwé 20 àti 21, àti Jí! January 8, 1970, (Gẹ̀ẹ́sì) ojú ìwé 9 sí 11.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Wọ́n Fi Dá Àwọn Ọ̀rẹ́ àti Àwọn Mọ̀lẹ́bí Lójú Pé Àwọn Nífẹ̀ẹ́ Wọn
Bí ẹnì kan bá dáwọ́ ṣíṣayẹyẹ Ọdún Tuntun dúró, èyí lè ya àwọn ọ̀rẹ́ àti àwọn mọ̀lẹ́bí ẹni náà lẹ́nu. Inú lè bí wọn, ó sì lè ká wọn lára tàbí kí wọ́n tiẹ̀ ronú pé ẹni náà já àwọn kulẹ̀. Àmọ́, ọ̀pọ̀ nǹkan ni èèyàn ṣì lè ṣe láti ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀. Gbọ́ ohun táwọn Kristẹni kan tí wọ́n ń gbé ní àwọn ibi tó yàtọ̀ síra nílẹ̀ Éṣíà sọ:
Jiang: “Kí àsìkò Ọdún Tuntun tó dé ni mo ti máa ń ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí mi, tí mo sì ti máa ń dọ́gbọ́n ṣàlàyé ìdí tí mi ò fi ní báwọn lọ́wọ́ sí àwọn ayẹyẹ kan tí ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń ṣe. Mo máa ń dọ́gbọ́n yẹra fún bíbu ẹnu àtẹ́ lu àwọn ohun tí wọ́n gbà gbọ́, mo sì máa ń fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ dáhùn àwọn ìbéèrè wọn látinú Bíbélì. Èyí máa ń yọrí sí ìjíròrò tó nítumọ̀ látinú Bíbélì.”
Li: “Kó tó dìgbà Ọdún Tuntun yìí ni mo ti máa ń fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ dọ́gbọ́n sọ fún ọkọ mi pé mo ní láti ṣègbọràn sí ohun tí ẹ̀rí ọkàn mi ń sọ kí n lè láyọ̀ tòótọ́. Mo tún ṣèlérí fún un pé mi ò ní dójú tì í tá a bá lọ sọ́dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ nígbà ọdún. Ó yà mí lẹ́nu pé lọ́jọ́ tí àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ fẹ́ jọ́sìn àwọn baba ńlá wọn, ṣe ló mú mi lọ sí ibòmíì kí n lè lọ ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn Kristẹni bíi tèmi.”
Xie: “Mo fi dá àwọn mọ̀lẹ́bí mi lójú pé mo nífẹ̀ẹ́ wọn, mo sì sọ fún wọn pé àwọn ohun tí mo gbà gbọ́ yìí máa jẹ́ kí n di ẹni tó túbọ̀ wúlò. Mo wá ṣiṣẹ́ kára kí n lè ní àwọn ànímọ́ Kristẹni bí ìwà tútù, ọgbọ́n àti ìfẹ́. Nígbà tó yá, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bọ̀wọ̀ fún ẹ̀sìn mi. Ọkọ mi pàápàá tiẹ̀ wá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, òun náà sì di Kristẹni tòótọ́.”
Min: “Mo fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ àti pẹ̀lú ìwà tútù ṣàlàyé fún àwọn òbí mi. Dípò kí n máa ṣàdúrà tó ní í ṣe pẹ̀lú ‘ọlọ́run oríire’ fún wọn, mo sọ fún wọn pé gbogbo ìgbà ni mo máa ń gbàdúrà sí Jèhófà, Ẹlẹ́dàá wa pé kó bù kún wọn, kó sì fún wọn ní ayọ̀ àti àlàáfíà.”
Fuong: “Mo sọ fún àwọn òbí mi pé kò dìgbà tí mo bá dúró dìgbà Ọdún Tuntun kí n tó lọ kí àwọn mọ̀lẹ́bí mi. Léraléra ni mo máa ń lọ sọ́dọ̀ wọn. Èyí mú inú àwọn òbí mi dùn gan-an, wọn ò sì ṣe àríwísí mi mọ́. Àbúrò mi ọkùnrin náà sì bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Bíbélì.”
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 20]
Panorama Stock/age Fotostock