Jeremáyà Kò Jáwọ́ Nínú Ṣíṣe Ìfẹ́ Ọlọ́run
Kọ́ Ọmọ Rẹ
Jeremáyà Kò Jáwọ́ Nínú Ṣíṣe Ìfẹ́ Ọlọ́run
ṢÉ ÌGBÀ míì máa ń wà tí nǹkan máa ń tojú sú ẹ, tó sì máa ń ṣe ẹ́ bíi pé kó o jáwọ́ nínú ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run?— a Ó sábà máa ń ṣe ọ̀pọ̀ èèyàn bẹ́ẹ̀. Ó ṣe Jeremáyà náà bẹ́ẹ̀ nígbà tó wà ní ọ̀dọ́. Àmọ́ kò jẹ́ kí ohun tí àwọn èèyàn sọ tàbí tí wọ́n ṣe kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá òun. Jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa bí Jeremáyà ṣe jẹ́ ẹni tí Ọlọ́run yàn láàyò, bó tiẹ̀ ń ṣe é bíi pé kó jáwọ́ nínú ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run.
Kí wọ́n tó bí Jeremáyà ni Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́ ti yàn án láti jẹ́ wòlíì tó máa kìlọ̀ fún àwọn èèyàn tí kò ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Ǹjẹ́ o mọ ohun tí Jeremáyà sọ fún Jèhófà ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn ìgbà náà?— “Kíyè sí i, èmi kò tilẹ̀ mọ ọ̀rọ̀ sọ, nítorí pé ọmọdé lásán ni mí.”
Báwo lo ṣe rò pé Jèhófà dá Jeremáyà lóhùn?— Jèhófà fi í lọ́kàn balẹ̀, ó sì jẹ́ kó mọ ohun tó yẹ kó ṣe, Ó ní: “Má ṣe wí pé, ‘ọmọdé lásán ni mí.’ Ṣùgbọ́n ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn tí èmi yóò rán ọ lọ ni kí o lọ; ohun gbogbo tí mo bá sì pa láṣẹ fún ọ ni kí o sọ. Má fòyà.” Kí nìdí tí Jèhófà fi ní kó má fòyà? Ó ní: “Nítorí mo wà pẹ̀lú rẹ láti dá ọ nídè.”—Jeremáyà 1:4-8.
Síbẹ̀, gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ lókè, Jeremáyà ṣì rẹ̀wẹ̀sì. Yẹ̀yẹ́ tí àwọn èèyàn sì fi ṣe torí pé ó ń sin Ọlọ́run ló mú kó rẹ̀wẹ̀sì. Ó ní, ‘ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń fi mí rẹ́rìn-ín, tí wọ́n sì ń fi mí ṣẹ̀sín láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀.’ Torí náà ó pinnu pé òun kò ní ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run mọ́. Ó ní: “Èmi kì yóò mẹ́nu kàn [Jèhófà], èmi kì yóò sì sọ̀rọ̀ mọ́ ní orúkọ rẹ̀.” Àmọ́ ṣé ó fiṣẹ́ Ọlọ́run sílẹ̀ lóòótọ́?
Jeremáyà sọ pé: “Nínú ọkàn-àyà mi, [ọ̀rọ̀ Jèhófà] sì wá dà bí iná tí ń jó, tí a sé mọ́ inú egungun mi; pípa á mọ́ra [ti] sú mi.” (Jeremáyà 20:7-9) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀rù máa ń ba Jeremáyà lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ìfẹ́ tó ní fún Jèhófà kò ní jẹ́ kó kọ iṣẹ́ Ọlọ́run sílẹ̀. Jẹ́ ká wo bí Ọlọ́run ṣe dáàbò bo Jeremáyà torí pé kò jáwọ́ nínú ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run.
Jèhófà ní kí Jeremáyà kìlọ̀ fún àwọn èèyàn pé ìlú Jerúsálẹ́mù máa pa run tí wọ́n bá kọ̀ láti yí pa dà kúrò nínú ìwà búburú wọn. Nígbà tí Jeremáyà jíṣẹ́
yìí fún àwọn èèyàn náà, wọ́n bínú, wọ́n sì wí pé: “Ìdájọ́ ikú tọ́ sí ọkùnrin yìí.” Àmọ́ Jeremáyà rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n “ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà.” Lẹ́yìn náà, ó ní: ‘Kí ẹ mọ̀ dájú pé, bí ẹ bá fi ikú pa mí, ẹ̀jẹ̀ aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ ni ẹ mú wá sórí ara yín nítorí lóòótọ́ ni Jèhófà rán mi sí yín.’ Ǹjẹ́ o mọ ohun tó wá ṣẹlẹ̀?—Bíbélì sọ pé: “Nígbà náà ni àwọn ọmọ aládé àti gbogbo àwọn ènìyàn náà sọ fún àwọn àlùfáà àti fún àwọn wòlíì pé: ‘Ìdájọ́ ikú kò tọ́ sí ọkùnrin yìí, nítorí ó bá wa sọ̀rọ̀ ní orúkọ Jèhófà Ọlọ́run wa.’” Torí náà, Jèhófà dáàbò bo Jeremáyà nígbà tí kò jẹ́ kí ìbẹ̀rù mú kó jáwọ́ nínú ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Jẹ́ ká wá wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Úríjà tóun náà jẹ́ wòlíì Jèhófà, ó ṣe ohun tó yàtọ̀ gedegbe sí èyí tí Jeremáyà ṣe.
Bíbélì sọ pé: ‘Úríjà sì ń sọ tẹ́lẹ̀ ṣáá lòdì sí ìlú ńlá yìí àti lòdì sí ilẹ̀ yìí ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ọ̀rọ̀ Jeremáyà.’ Àmọ́ nígbà tí inú bí Jèhóákímù Ọba sí Úríjà, ṣé o mọ ohun tí Úríjà ṣe?— Ẹ̀rù bà á, ó fi iṣẹ́ tí Ọlọ́run rán an sílẹ̀, ó sì sá lọ sí Íjíbítì. Torí náà, ọba rán àwọn èèyàn lọ pé kí wọ́n lọ wá a, kí wọ́n sì mú un pa dà wá. Nígbà tí wọ́n mú un dé, ǹjẹ́ o mọ ohun tí ọba búburú yìí ṣe?— Ó fi idà pa Úríjà!—Jeremáyà 26:8-24.
Kí lo rò pé ó mú kí Jèhófà dáàbò bo Jeremáyà àmọ́ tí kò dáàbò bo Úríjà?— Ó ṣeé ṣe kí ẹ̀rù ti ba Jeremáyà bó ṣe ba Úríjà, àmọ́ Jeremáyà kò fi iṣẹ́ Jèhófà sílẹ̀ kó wá sá lọ. Kò jáwọ́ nínú ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ lára Jeremáyà?— Ẹ̀kọ́ náà ni pé ó lè ṣòro fún wa nígbà míì láti ṣe àwọn ohun tí Ọlọ́run ní ká ṣe, síbẹ̀, ó yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé e, ká sì máa ṣègbọràn sí i.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Tó bá jẹ́ ọmọdé lò ń ka ìwé yìí fún, má gbàgbé láti dánu dúró níbi tó o bá ti rí àmì dáàṣì (—), kó o sì jẹ́ kí ọmọ náà sọ tinú rẹ̀.
Ìbéèrè:
○ Iṣẹ́ wo ni Ọlọ́run yàn fún Jeremáyà?
○ Kí nìdí tí Jeremáyà fi fẹ́ láti jáwọ́ nínú ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run?
○ Kí nìdí ti Ọlọ́run fi dáàbò bo Jeremáyà àmọ́ tí kò dáàbò bo Úríjà?
○ Ẹ̀kọ́ wo lo ti rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ Jeremáyà?