Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Kí nìdí tí ìkànìyàn fi wáyé lákòókò tí wọ́n bí Jésù ní ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù?

Gẹ́gẹ́ bí ìwé Ìhìn Rere Lúùkù ṣe sọ, nígbà tí Késárì Ọ̀gọ́sítọ́sì pàṣẹ pé káwọn èèyàn fi orúkọ sílẹ̀ jákèjádò Ilẹ̀ Ọba Róòmù, “gbogbo ènìyàn sì ń rin ìrìn àjò lọ láti forúkọ sílẹ̀, olúkúlùkù sí ìlú ńlá tirẹ̀.” (Lúùkù 2:1-3) Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ni ìlú Jósẹ́fù tó jẹ́ alágbàtọ́ Jésù, nígbà tí Jósẹ́fù àti Màríà sì rin ìrìn àjò kí wọ́n lè pa àṣẹ Késárì mọ́ ni wọ́n bí Jésù ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Wọ́n máa ń ṣe irú ìforúkọsílẹ̀ yìí kó bàa lè rọrùn láti gba owó orí, kí wọ́n sì lè fipá mú àwọn èèyàn wọnú iṣẹ́ ológun.

Ó ti pẹ́ tí wọ́n ti ń ṣe irú ìkànìyàn yìí lórílẹ̀-èdè Íjíbítì kí ìlú Róòmù tó ṣẹ́gun wọn ní ọdún 30 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Àwọn ọ̀mọ̀wé gbà pé ńṣe ni àwọn ará Róòmù kọ́ àṣà ìkànìyàn látọ̀dọ̀ àwọn ará Íjíbítì, tí wọ́n sì wá ń ṣe é ní gbogbo ilẹ̀ ọba wọn.

Ẹ̀rí kan tó wà pé wọ́n ti ṣe irú ìkànìyàn yìí ni ti àṣẹ kan tí gómìnà Róòmù kan tó ń ṣàkóso ilẹ̀ Íjíbítì pa ní ọdún 104 Sànmánì Kristẹni. Ẹ̀dà kan ìwé àṣẹ náà, tí wọ́n fi pa mọ́ sí ibi ìkówèésí tó wà ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, kà pé: “Ọ̀gbẹ́ni Gaius Vibius Maximus, tó jẹ́ Ọ̀gágun ní ilẹ̀ Íjíbítì sọ pé: Bá a ṣe rí i pé àkókò ti tó báyìí láti ṣe ìkànìyàn láti ilé dé ilé, ó ṣe pàtàkì pé ká gba gbogbo àwọn tó jẹ́ pé fún ìdí kan kì í ṣe àgbègbè wọn ni wọ́n ń gbé níyànjú pé kí wọ́n pa dà sí ilẹ̀ ìbílẹ̀ wọn láti lọ forúkọ sílẹ̀, kí wọ́n sì lè bójú tó ilẹ̀ wọn.”

Kí nìdí tí Jósẹ́fù fi fẹ́ láti fún Màríà ní ìwé ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀ nígbà tó jẹ́ pé wọn kò tíì ṣègbéyàwó?

Gẹ́gẹ́ bí ìwé Ìhìn Rere Mátíù ṣe sọ, Jósẹ́fù mọ̀ pé Màríà tó “jẹ́ àfẹ́sọ́nà” òun lóyún nígbà tí wọn kò tíì ṣègbéyàwó. Torí pé Jósẹ́fù kò mọ̀ pé oyún Màríà jẹ́ “láti ọwọ́ ẹ̀mí mímọ́,” ó ṣeé ṣe kó ronú pé Màríà ti dalẹ̀ òun, ó sì fẹ́ kọ̀ ọ́ sílẹ̀.—Mátíù 1:18-20.

Láàárín àwọn Júù, ojú ẹni tó ti ṣègbéyàwó ni wọ́n máa fi ń wo àwọn tó ń fẹ́ra wọn sọ́nà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn méjèèjì kò ní máa gbé pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bíi tọkọtìyàwó títí wọ́n fi máa ṣègbéyàwó. Àdéhùn ìfẹ́sọ́nà lágbára gan-an débi pé, bí ọkùnrin tó ń fẹ́ obìnrin kan sọ́nà bá yí ọkàn rẹ̀ pa dà fún ìdí kan tàbí òmíràn, tí kò sì ní ṣeé ṣe fún wọn láti fẹ́ ara wọn mọ́, obìnrin náà kò ní lè lọ́kọ àyàfi tí ọkùnrin tó fi í sílẹ̀ bá fún ní ìwé ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀. Opó ni wọ́n ka obìnrin kan tí ọkùnrin tó ń fẹ́ ẹ sọ́nà bá kú kí wọ́n tó ṣègbéyàwó sí. Tí obìnrin tí ọkùnrin kan ń fẹ́ sọ́nà bá lọ ní ìbálòpọ̀ takọtabo pẹ̀lú ọkùnrin míì, ó ti ṣe panṣágà, ẹjọ́ ikú ni wọ́n sì máa dá fún un.—Diutarónómì 22:23, 24.

Ó ṣeé ṣe kí Jósẹ́fù ti ronú lórí ohun tó máa jẹ́ àbájáde ọ̀rọ̀ náà fún Màríà tí gbogbo èèyàn bá mọ̀ pé ó ti lóyún. Lóòótọ́, Jósẹ́fù mọ̀ pé ó yẹ kí òun fi ọ̀rọ̀ náà tó àwọn aláṣẹ létí, síbẹ̀ ó fẹ́ bò ó láṣìírí, kò fẹ́ kí wọ́n máa pẹ̀gàn rẹ̀. Torí náà, ó pinnu láti kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ní bòókẹ́lẹ́. Ó ṣe tán, bí obìnrin kan tó ń dá tọ́mọ bá ní ìwé ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀ lọ́wọ́, ìyẹn á fi hàn pé ó ti lọ́kọ rí.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Àṣẹ ìkànìyàn tí gómìnà róòmù tó ń ṣàkóso Íjíbítì pa lọ́dún 104 Sànmánì Kristẹni

[Credit Line]

© The British Library Board, all rights reserved (P.904)