Ọkùnrin Onírẹ̀lẹ̀ àti Onígboyà
Abala Àwọn Ọ̀dọ́
Ọkùnrin Onírẹ̀lẹ̀ àti Onígboyà
JÓNÀ—APÁ KÌÍNÍ
Ohun tó o máa ṣe: Ibi tí kò sáriwo ni kó o ti ṣe ìdánrawò yìí. Bó o bá ṣe ń ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nísàlẹ̀ yìí, máa fojú inú wò ó bíi pé o wà níbi tọ́rọ̀ náà ti ń ṣẹlẹ̀, jẹ́ kó dà bíi pé ò ń gbọ́ bí àwọn èèyàn náà ṣe ń sọ̀rọ̀. Ronú nípa bí ohun tó ò ń kà yẹn ṣe máa rí lára àwọn èèyàn wọ̀nyẹn. Kó o sì máa fojú inú wò ó bí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́.
1 KA ÌTÀN NÁÀ DÁADÁA.—KA JÓNÀ 1:1-17; 2:10–3:5.
Báwo ni ìró ìjì náà ṣe rí tó o bá fojú inú wò ó?
․․․․․
Báwo lo ṣe rò pé ó rí lára Jónà àtàwọn tó wà nínú ọkọ̀ náà bí wọ́n ṣe ń sọ̀rọ̀ nígbà tí ìjì yẹn ń jà?
․․․․․
Ṣàlàyé ohun tí Jónà lè máa rò lọ́kàn nígbà tó ń rì sínú òkun àti lẹ́yìn tí ẹja ńlá yẹn ti gbé e mì. (Ka Jónà 2:1-9.)
․․․․․
2 ṢÈWÁDÌÍ KÓ O SÌ RONÚ JINLẸ̀.
Irú àwọn èèyàn wo ló ń gbé nílùú Nínéfè, kí ló sì mú kí Jónà kọ́kọ́ lọ́ tìkọ̀ láti lọ wàásù fún wọn? (Náhúmù 3:1)
․․․․․
Ọ̀nà wo lo rò pé ìlú Nínéfè gbà jẹ́ “ìlú ńlá tí ó tóbi lójú Ọlọ́run”? (Jónà 3:3; 2 Pétérù 3:9)
․․․․․
Kí ni òtítọ́ tí Jónà sọ nípa àṣìṣe tó ṣe àti nípa Ọlọ́run rẹ̀ fi hàn nípa irú ẹni tí Jónà jẹ́? (Tún Jónà 1:9, 10 kà.)
․․․․․
Jónà 1:15,16 kà.)
Báwo ni Jónà ṣe mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú ọkọ̀ náà lẹ́yìn tí wọ́n ti jù ú sínú òkun? (Tún․․․․․
3 MÁA FOHUN TÓ O KỌ́ ṢÈWÀ HÙ. ṢÀKỌSÍLẸ̀ Ẹ̀KỌ́ TÓ O KỌ́ NÍPA . . .
Ìbẹ̀rù Èèyàn.
․․․․․
Ìrẹ̀lẹ̀.
․․․․․
Ìgboyà.
․․․․․
Ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn èèyàn, títí kan àwọn èèyàn tá a kà sí ẹni burúkú.
․․․․․
4 KÍ LÓ WÚ Ẹ LÓRÍ JÙ LỌ NÍNÚ ÌTÀN YÌÍ, KÍ SÌ NÌDÍ?
․․․․․
Tó o bá fẹ́ ṣèwádìí síwájú sí i, ka Ilé Ìṣọ́, January 1, 2009, ojú ìwé 25 sí 28.
BÍ O KÒ BÁ NÍ BÍBÉLÌ, LỌ KÀ Á LÓRÍ ÌKÀNNÌ WA, www.watchtower.org