Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Ọ̀nà wo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà nígbà tó rìnrìn àjò rẹ̀ àkọ́kọ́ lọ sí Róòmù?
▪ Ìwé Ìṣe 28:13-16 sọ pé ọkọ̀ òkun tí Pọ́ọ̀lù wọ̀ lọ sí Ítálì dé sí Pútéólì (tí wọ́n ń pè ní Pozzuoli báyìí), níbi tí omi ti ya wọlẹ̀ nílùú Naples. Ó gba Ọ̀nà Ápíà tó jẹ́ ọ̀nà pàtàkì tó lọ sí ìlú Róòmù.
Orúkọ aláṣẹ Róòmù kan tó ń jẹ́ Appius Claudius Caecus ni wọ́n fi sọ ojú ọ̀nà náà. Òun ló bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ọ̀nà náà lọ́dún 312 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Ọ̀nà yìí fẹ̀ tó nǹkan bíi mítà mẹ́rin ààbọ̀ sí mítà mẹ́fà, ó sì fi ẹgbẹ̀ta-dín-mẹ́tàdínlógún [583] kìlómítà jìn sí gúúsù ìlà oòrùn Róòmù. Àwọn òkúta ńláńlá tí wọ́n kó láti òkè ayọnáyèéfín ni wọ́n fi ṣe é. Ọ̀nà yìí ni wọ́n máa ń gbà láti ìlú Róòmù lọ sí èbúté tó wà nílùú Brundisium (tí wọ́n ń pè ní Brindisi báyìí), ibẹ̀ sì ni àwọn èèyàn ti ń wọkọ̀ lọ sí apá Ìlà Oòrùn ayé. Àwọn arìnrìn-àjò máa ń dúró láwọn ibùdó tó wà ní nǹkan bíi kìlómítà mẹ́rìnlélógún síra, àwọn ibùdó yìí sì ni wọ́n ti máa ń ra àwọn ohun èlò, ibẹ̀ ni wọ́n ti máa ń gun ẹṣin míì tàbí kí wọ́n wọ ọkọ̀ míì láti máa bá ìrìn àjò wọn lọ, wọ́n sì tún máa ń sùn níbẹ̀.
Àmọ́, ó jọ pé ẹsẹ̀ ni Pọ́ọ̀lù fi rìn ní tiẹ̀. Ìrìn tó rìn lójú Ọ̀nà Ápíà tó igba-ó-lé-méjìlá [212] kìlómítà. Lára ibi tó gbà kọjá ni ibi irà tí wọ́n ń pè ní Pontine Marshes, ibí yìí ló mú kí òǹkọ̀wé ará Róòmù kan ṣàròyé púpọ̀ nípa yànmùyánmú àti òórùn burúkú. Ní àríwá irà yẹn ni Ibi Ọjà Ápíọ́sì wà, ọjà yìí fi nǹkan bíi kìlómítà márùnlélọ́gọ́ta [65] jìn sí Róòmù. Apá ibẹ̀ náà ni Ilé Èrò Mẹ́ta wà tó fi nǹkan bí àádọ́ta [50] kìlómítà jìn sí Róòmù. Ibi méjì táwọn arìnrìn-àjò máa ń dúró sinmi yìí làwọn Kristẹni láti Róòmù ti dúró de Pọ́ọ̀lù. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù rí wọn “ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, ó sì mọ́kànle.”—Ìṣe 28:15.
Irú wàláà ìkọ̀wé wo ni Lúùkù 1:63 sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀?
▪ Ìwé Ìhìn Rere Lúùkù sọ pé àwọn ọ̀rẹ́ Sekaráyà béèrè orúkọ tó fẹ́ sọ ọmọkùnrin tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bí. Sekaráyà “béèrè fún wàláà kan, ó sì kọ ọ́ síbẹ̀ pé: ‘Jòhánù ni orúkọ rẹ̀.’” (Lúùkù 1:63) Gẹ́gẹ́ bí ọ̀mọ̀wé kan ti sọ nínú ìwé rẹ̀, ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà tí wọ́n túmọ̀ sí “wàláà” ń sọ nípa “wàláà kékeré tí wọ́n máa ń fi igi ṣe, tí wọ́n ń fi ìda kùn.” Wọ́n máa ń so wàláà méjì tí wọ́n fi igi ṣe pọ̀, wọ́n á sì wá fi ìda oyin kùn ún. Òǹkọ̀wé máa ń fi kálàmù kọ nǹkan sórí wàláà náà. Wọ́n lè pa nǹkan tí wọ́n kọ sórí rẹ̀ rẹ́, kí wọ́n lè tún un lò.
Ìwé kan tó sọ nípa bí wọ́n ṣe ń kọ̀wé àti bí wọ́n ṣe ń kàwé nígbà ayé Jésù, ìyẹn Reading and Writing in the Time of Jesus sọ pé: “Àwọn àwòrán láti ìlú Pompeii ní gúúsù Ítálì, àwọn ère láti ibi gbogbo ní Ilẹ̀ Ọba Róòmù àtàwọn ohun tí wọ́n hú jáde káàkiri ilẹ̀ Íjíbítì àti Odi Hadrian tó wà ní Àríwá Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì fi bí wọ́n ṣe ń lo wàláà níbi gbogbo hàn.” Onírúurú èèyàn ti ní láti ní irú àwọn wàláà yìí lọ́wọ́, àwọn bí oníṣòwò àti òṣìṣẹ́ ìjọba, kódà ó ṣeé ṣe káwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní náà ní in lọ́wọ́.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
Ọ̀nà Ápíà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
Wàláà ìkọ̀wé tí ọmọkùnrin kan ń lò níléèwé, ọ̀rúndún kejì sànmánì kristẹni
[Credit Line]
Nípasẹ̀ àṣẹ Ilé Ìkówèésí Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì