Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Ó Yẹ Kó O Máa Pa Sábáàtì Mọ́?

Ṣé Ó Yẹ Kó O Máa Pa Sábáàtì Mọ́?

Ṣé Ó Yẹ Kó O Máa Pa Sábáàtì Mọ́?

NÍ NǸKAN bí ọdún 1989, àwùjọ kékeré ti àwọn ẹlẹ́sìn Mẹ́tọ́díìsì kógun lọ sí Suva tó jẹ́ olú ìlú Fíjì. Àtọkùnrin àtobìnrin àtàwọn ọmọdé múra bí wọ́n ṣe máa ń múra lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì, wọ́n pín ara wọn sí àwùjọ-àwùjọ, àwùjọ kọ̀ọ̀kan sì dúró sójú ọ̀nà. Wọ́n dá gbogbo ọkọ̀ èrò dúró, wọ́n tún dá ọkọ̀ òfuurufú tó ń ná orílẹ̀-èdè yẹn àtàwọn orílẹ̀-èdè míì dúró. Kí nìdí tí wọ́n fi ń ṣe gbogbo èyí? Ìdí ni pé wọ́n fẹ́ fi dandan gbọ̀n mú káwọn èèyàn pa dà sí pípa Sábáàtì mọ́.

Ní orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, gbogbo ilé alágbèékà tuntun tí wọ́n kọ́ lọ́dún 2001 gbọ́dọ̀ ní ẹ̀rọ agbéniròkè tó máa ń dá dúró fúnra rẹ̀ ní gbogbo àjà kọ̀ọ̀kan. Kí nìdí? Ìdí ni pé kí àwọn Júù tó jẹ́ olùfọkànsìn tí wọ́n máa ń bẹ̀rẹ̀ Sábáàtì láti ìrọ̀lẹ́ Friday sí ìrọ̀lẹ́ Saturday má bàa ṣiṣẹ́, iṣẹ́ tí wọ́n sì ń sọ náà ni pé kéèyàn kàn tẹ bọ́tìnnì ẹ̀rọ agbéniròkè lásán.

Ní orílẹ̀-èdè Tonga, tó wà ní Gúúsù Òkun Pàsífíìkì, kò sí ẹnì kankan tó gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ lọ́jọ́ Sunday. Lọ́jọ́ yìí, wọn ò fàyè gba ọkọ̀ òfuurufú kankan láti balẹ̀ sí orílẹ̀-èdè náà, wọn ò sì gba ọkọ̀ òkun láyè láti gúnlẹ̀ sí èbúté. Àwọn èèyàn ibẹ̀ gbà pé gbogbo ìwé àdéhùn tí wọ́n bá fọwọ́ sí lọ́jọ́ yẹn kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀. Òfin orílẹ̀-èdè Tonga sọ pé kí gbogbo èèyàn “ka” ọjọ́ Sunday “sí mímọ́,” láìka irú ẹ̀sìn téèyàn ń ṣe sí. Kí nìdí? Ìdí ni pé kí gbogbo àwọn tó wà lórílẹ̀-èdè náà lè pa Sábáàtì mọ́.

Gẹ́gẹ́ bí àwọn àpẹẹrẹ tá a ti sọ ṣáájú yìí ṣe fi hàn, ọ̀pọ̀ ló rò pé Ọlọ́run fẹ́ káwọn máa ya ọjọ́ kan sọ́tọ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ fún pípa Sábáàtì mọ́. Kódà, àwọn kan sọ pé pípa Sábáàtì mọ́ ṣe pàtàkì jù lọ, wọ́n sì gbà pé, ó ṣe pàtàkì téèyàn bá fẹ́ rí ìgbàlà ayérayé. Èrò àwọn míì sì ni pé, nínú gbogbo àwọn àṣẹ Ọlọ́run, pípa Sábáàtì mọ́ ló ṣe pàtàkì jù lọ. Kí ni Sábáàtì? Ǹjẹ́ Bíbélì ní káwọn Kristẹni máa ya ọjọ́ kan sọ́tọ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ fún pípa Sábáàtì mọ́?

Kí Ni Sábáàtì?

Ọ̀rọ̀ náà “Sábáàtì” wá látinú ọ̀rọ̀ Hébérù tó túmọ̀ sí “ìsinmi, àìṣiṣẹ́.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìtàn inú ìwé Jẹ́nẹ́sísì sọ pé Jèhófà Ọlọ́run sinmi kúrò nínú iṣẹ́ ìṣẹ̀dá lọ́jọ́ keje, àmọ́ ìgbà ayé Mósè ló ṣẹ̀ṣẹ̀ tó pàṣẹ pé káwọn èèyàn òun máa pa ọjọ́ ìsinmi oníwákàtí mẹ́rìnlélógún mọ́ tàbí pa Sábáàtì mọ́. (Jẹ́nẹ́sísì 2:2) Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní Íjíbítì lọ́dún 1513 ṣáájú Sànmánì Kristẹni (Ṣ.S.K.), Jèhófà pèsè mánà fún wọn lọ́nà ìyanu nínú aginjù. Ó fún wọn ní ìtọ́ni nípa bí wọ́n á ṣe máa kó mánà, ó sọ pé: “Ọjọ́ mẹ́fà ni ẹ ó fi kó o, ṣùgbọ́n ní ọjọ́ keje, sábáàtì ni. Ní ọjọ́ náà, ìkankan kì yóò kóra jọ.” (Ẹ́kísódù 16:26) Bíbélì sọ pé “àwọn ènìyàn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí pa sábáàtì mọ́ ní ọjọ́ keje,” látìgbà tí oòrùn bá ti wọ̀ nírọ̀lẹ́ Friday títí di ìrọ̀lẹ́ Saturday nígbà tí oòrùn bá wọ̀.—Ẹ́kísódù 16:30.

Ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn tí Jèhófà ti fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ìtọ́ni yìí, ó fún wọn ní òfin kan nípa pípa Sábáàtì mọ́, ó sì fi sára Òfin Mẹ́wàá tó fún Mósè. (Ẹ́kísódù19:1) Apá kan lára òfin kẹrin sọ pé: “Máa rántí ọjọ́ sábáàtì láti kà á sí ọlọ́wọ̀, kí ìwọ ṣe iṣẹ́ ìsìn, kí o sì ṣe gbogbo iṣẹ́ rẹ ní ọjọ́ mẹ́fà. Ṣùgbọ́n ọjọ́ keje jẹ́ sábáàtì fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ.” (Ẹ́kísódù 20:8-10) Pípa Sábáàtì mọ́ wá di apá pàtàkì nínú ìgbésí ayé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.—Diutarónómì 5:12.

Ṣé Jésù Pa Sábáàtì Mọ́?

Bẹ́ẹ̀ ni, Jésù pa Sábáàtì mọ́. Bíbélì sọ nípa rẹ̀ pé: “Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àkókò dé, Ọlọ́run rán Ọmọ rẹ̀ jáde, ẹni tí ó ti ara obìnrin jáde wá, tí ó sì wá wà lábẹ́ òfin.” (Gálátíà 4:4) Orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ni wọ́n bí Jésù sí, èyí sì ti jẹ́ kó wà lábẹ́ Òfin, ara òfin náà sì ni pípa Sábáàtì mọ́. Ẹ̀yìn ikú Jésù ni Ọlọ́run tó mú májẹ̀mú Òfin kúrò. (Kólósè 2:13, 14) Tá a bá mọ ìgbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí wáyé, èyí máa jẹ́ ká lóye èrò Ọlọ́run nípa ọ̀ràn náà.—Wo àtẹ tó wà  lójú ìwé 15.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù sọ pé: “Ẹ má ṣe rò pé mo wá láti pa Òfin tàbí àwọn Wòlíì run. Èmi kò wá láti pa run, bí kò ṣe láti mú ṣẹ.” (Mátíù 5:17) Àmọ́, kí ni ọ̀rọ̀ náà “láti mú ṣẹ” túmọ̀ sí? Àpẹẹrẹ kan rèé: Tí wọ́n bá gbé ilé kan fún kọ́lékọ́lé kan pé kó tún un ṣe, kò kàn ní wó ilé náà dànù, ńṣe lá kàn ṣàtúnṣe sí i. Àmọ́ tó bá parí iṣẹ́ náà tó sì tẹ́ ẹni tó gbéṣẹ́ fún un lọ́rùn, ìgbà yẹn ló mú àdéhùn náà ṣẹ, wọ́n kò sì ní béèrè ohunkóhun lọ́wọ́ rẹ̀ mọ́. Bẹ́ẹ̀ náà ló rí nínú ọ̀ràn ti Jésù, kò rú Òfin tàbí kó bà á jẹ́, kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ló mú un ṣẹ, ìyẹn ni pé ó tẹ̀ lé òfin délẹ̀délẹ̀. Níwọ̀n bó sì ti mú “àdéhùn” Òfin náà ṣẹ, àwọn èèyàn Ọlọ́run kò sí lábẹ́ àdéhùn náà mọ́.

Ṣé Òfin Yìí Wà Fáwọn Kristẹni?

Níwọ̀n bí Kristi ti mú Òfin ṣẹ, ṣé ó tún pọn dandan káwọn Kristẹni máa pa Sábáàtì mọ́? Lábẹ́ ìdarí ẹ̀mí mímọ́, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù dáhùn, ó ní: “Nítorí náà, ẹ má ṣe jẹ́ kí ènìyàn kankan ṣèdájọ́ yín nínú jíjẹ àti mímu tàbí ní ti àjọyọ̀ kan tàbí ní ti ààtò àkíyèsí òṣùpá tuntun tàbí ní ti sábáàtì; nítorí nǹkan wọnnì jẹ́ òjìji àwọn nǹkan tí ń bọ̀, ṣùgbọ́n ohun gidi náà jẹ́ ti Kristi.”—Kólósè 2:16, 17.

Àwọn ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí yìí jẹ́ ká rí i pé àyípadà ti bá ohun tó ń béèrè lọ́wọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé abẹ́ òfin tuntun làwọn Kristẹni wà báyìí, ìyẹn “òfin Kristi.” (Gálátíà 6:2) Májẹ̀mú Òfin tí Ọlọ́run fún àwọn Ísírẹ́lì nípasẹ̀ Mósè ti wá sópin nígbà tí ikú Jésù mú gbogbo ohun tí òfin wí ṣẹ. (Róòmù 10:4; Éfésù 2:15) Ṣé òfin pípa Sábáàtì mọ́ náà wá sí òpin? Bẹ́ẹ̀ ni. Nítorí pé lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù sọ pé “a ti dá wa sílẹ̀ kúrò nínú Òfin,” ó sọ̀rọ̀ nípa ọ̀kan lára Òfin Mẹ́wàá náà. (Róòmù 7:6, 7) Òfin Mẹ́wàá, tí òfin Sábáàtì wà lára wọn jẹ́ ara Òfin tó wá sópin. Nítorí náà, Ọlọ́run kò ní káwọn olùjọ́sìn òun tún máa pa ọjọ́ kan mọ́ fún Sábáàtì ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀.

A lè ṣàlàyé ìyípadà ẹ̀sìn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sí ẹ̀sìn Kristẹni lọ́nà yìí: Orílẹ̀-èdè kan lè yí òfin ìlú wọn pa dà. Gbàrà tí òfin tuntun náà bá sì ti fẹsẹ̀ múlẹ̀ nílùú náà, àwọn èèyàn kò ní sí lábẹ́ àṣẹ láti máa tẹ̀ lé òfin àtijọ́ mọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan lára òfin tuntun náà lè má yàtọ̀ sí ti àtijọ́, síbẹ̀ àwọn yòókù lè yàtọ̀. Nítorí náà, èèyàn kan ní láti fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò òfin tuntun yìí kó lè mọ àwọn òfin tó ń darí orílẹ̀-èdè náà. Síwájú sí i, ọmọ orílẹ̀-èdè kan tó fẹ́ ire fún ìlú rẹ̀ máa fẹ́ láti mọ ìgbà tí òfin tuntun náà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́.

Bákan náà, Jèhófà fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ní òfin tó lé ni ẹgbẹ̀ta [600], ara wọn ni òfin pàtàkì mẹ́wàá yẹn wà. Àwọn òfin wọ̀nyí ní í ṣe pẹ̀lú ìwà rere, ẹbọ rírú, ọ̀ràn ìlera àti pípa Sábáàtì mọ́. Àmọ́, Jésù sọ pé àwọn ẹni àmì òróró ọmọlẹ́yìn òun máa para pọ̀ di “orílẹ̀-èdè” tuntun kan. (Mátíù 21:43) Láti ọdún 33 Sànmánì Kristẹni (S.K.) ni orílẹ̀-èdè yìí ti gba òfin tuntun tá a gbé karí òfin pàtàkì méjì, ìyẹn nínífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti aládùúgbò. (Mátíù 22:36-40) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé “òfin Kristi” náà ní àwọn ìtọ́ni tó jọ èyí tó wà nínú Òfin tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kò yẹ kó yà wá lẹ́nu pé àwọn kan lára òfin tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yàtọ̀ gan-an, àwọn kan nínú wọn kò sì wúlò mọ́. Òfin pípa ọjọ́ Sábáàtì ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ mọ́ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tí kò wúlò mọ́ yẹn.

Ṣé Ọlọ́run Ti Yí Àwọn Ìlànà Rẹ̀ Pa Dà?

Ṣé kíkúrò lábẹ́ Òfin Mósè bọ́ sí abẹ́ òfin Kristi wá túmọ̀ sí pé Ọlọ́run ti yí àwọn ìlànà rẹ̀ pa dà ni? Rárá. Ńṣe ló dà bí ìgbà tí òbí kan ṣe àtúnṣe sáwọn ìlànà ìdílé nítorí ọjọ́ orí àti ipò àwọn ọmọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni Jèhófà ṣe ṣàtúnṣe sí òfin táwọn èèyàn rẹ̀ á máa tẹ̀ lé. Bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe ṣàlàyé ọ̀rọ̀ náà rèé, ó ní: “Kí ìgbàgbọ́ náà tó dé, a ń ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí wa lábẹ́ òfin, a ń fi wá sínú ìhámọ́ lápapọ̀, a ń wojú ìgbàgbọ́ tí a ti yàn tẹ́lẹ̀ fún ṣíṣípayá. Nítorí náà, Òfin ti di akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ wa tí ń sinni lọ sọ́dọ̀ Kristi, kí a lè polongo wa ní olódodo nítorí ìgbàgbọ́. Ṣùgbọ́n nísinsìnyí tí ìgbàgbọ́ ti dé, a kò sí lábẹ́ akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ kan mọ́.”—Gálátíà 3:23-25.

Báwo ni ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ yìí ṣe kan ọ̀ràn Sábáàtì? Gbé àpèjúwe yìí yẹ̀ wò: Nígbà tí ọmọ kan bá wà nílé ìwé, wọ́n máa ní kó kọ́ iṣẹ́ kan irú bíi fífi igi ṣe oríṣiríṣi nǹkan, ọjọ́ kan lọ́sẹ̀ ló máa fi ń kọ́ iṣẹ́ náà níléèwé. Àmọ́, tó bá bẹ̀rẹ̀ sí í fi ohun tó ti kọ́ yìí ṣiṣẹ́ ṣe, kì í ṣe ọjọ́ kan ṣoṣo lọ́sẹ̀ lá máa fi ohun tó kọ́ náà ṣiṣẹ́ ṣe, kàkà bẹ́ẹ̀, ojoojúmọ́ lá máa fi ṣiṣẹ́ ṣe. Bákan náà, nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà lábẹ́ Òfin náà, wọ́n ní láti máa ya ọjọ́ kan sọ́tọ̀ láàárín ọ̀sẹ̀ fún ìsinmi àti ìjọsìn. Àmọ́ ní ti àwọn Kristẹni, ojoojúmọ́ ni Ọlọ́run ní kí wọ́n máa jọ́sìn òun, kì í ṣe ọjọ́ kan ṣoṣo láàárín ọ̀sẹ̀.

Ṣé ó burú kéèyàn ya ọjọ́ kan sọ́tọ̀ fún ìsinmi àti ìjọsìn láàárín ọ̀sẹ̀? Kò burú o. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti fi ìpinnu yìí sílẹ̀ fún wa láti ṣe, ó sọ pé: “Ẹni kan ka ọjọ́ kan sí pataki ju ọjọ́ miran lọ. Ẹlomiran ka gbogbo ọjọ́ bákan náà. Ẹ jẹ́ kí olukuluku pinnu lọ́kàn ara rẹ̀ nípa irú ọ̀ràn bayi.” (Romu 14:5, Ìròyìn Ayọ̀) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan yàn láti máa ka ọjọ́ kan sí mímọ́ ju ọjọ́ míì lọ, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ ní kedere pé Ọlọ́run kò retí pé káwọn Kristẹni máa pa Sábáàtì ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ mọ́.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 12]

“Ọjọ́ mẹ́fà ni ẹ ó fi kó o, ṣùgbọ́n ní ọjọ́ keje, sábáàtì ni. Ní ọjọ́ náà, ìkankan kì yóò kóra jọ.”—Ẹ́KÍSÓDÙ 16:26

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 14]

“Òfin ti di akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ wa tí ń sinni lọ sọ́dọ̀ Kristi, kí a lè polongo wa ní olódodo nítorí ìgbàgbọ́. Ṣùgbọ́n nísinsìnyí tí ìgbàgbọ́ ti dé, a kò sí lábẹ́ akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ kan mọ́.”—GÁLÁTÍÀ 3:24, 25

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Ìyàtọ̀ Àkókò Láàárín Àwọn Orílẹ̀-Èdè Mú Kó Ṣòro Láti Ṣe Sábáàtì Lọ́jọ́ Kan Náà

Ìyàtọ̀ tó wà láàárín àkókò ní orílẹ̀-èdè kan sí òmíràn mú kó ṣòro fáwọn tó gbà gbọ́ pé àwọn gbọ́dọ̀ máa ṣe Sábáàtì lọ́jọ́ kan náà lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ kárí ayé. Ìyàtọ̀ tó wà láàárín àkókò lápá ibì kan láyé àti apá ibòmíì ṣòro rí pàápàá láti apá ibi tí Òkun Pàsífíìkì wà. Àkókò àwọn orílẹ̀-èdè tó wà ní ìwọ̀ oòrùn ayé máa ń fi wákàtí mẹ́rìnlélógún yàtọ̀ sí tàwọn tó wà ní ìlà oòrùn ayé.

Bí àpẹẹrẹ, ọjọ́ Sunday ní erékùṣù Fíjì àti Tonga jẹ́ ọjọ́ Saturday ní erékùṣù Samoa àti Niue. Nítorí náà, tí ẹnì kan bá ṣe Sábáàtì ní erékùṣù Fíjì lọ́jọ́ Saturday, iṣẹ́ làwọn tí wọ́n jọ ń ṣe ẹ̀sìn kan náà ní erékùṣù Samoa á máa ṣe lọ́jọ́ yẹn nítorí pé ọjọ́ Friday lọjọ́ yẹn lọ́dọ̀ tiwọn, kìlómítà ẹgbẹ̀rún kan àti ogóje ó lé márùn-ún [1,145] làwọn erékùṣù yìí sì jẹ́ síra wọn.

Ọjọ́ Sunday làwọn ẹlẹ́sìn Seventh-Day Adventists tó wà ní orílẹ̀-èdè Tonga máa ń ṣe Sábáàtì, èrò wọn sì ni pé ìyẹn ló máa jẹ́ kí àwọn lè máa ṣe Sábáàtì lọ́jọ́ kan náà pẹ̀lú àwọn ọmọ ìjọ wọn ní erékùṣù Samoa tó wà ní àádọ́ta lé lẹ́gbẹ̀rin [850] kìlómítà sí wọn. Àmọ́ ṣá o, lákòókò kan náà yìí, iṣẹ́ làwọn ẹlẹ́sìn Seventh-Day Adventists tó wà ní orílẹ̀-èdè Fíjì ní ẹgbẹ̀rin [800] kìlómítà sí wọn ń ṣe lọ́jọ́ Sunday nítorí pé ọjọ́ Saturday ni wọ́n ń ṣe Sábáàtì lọ́dọ̀ tiwọn!

[Àwòrán]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

\

\

\

\ SAMOA

\

— ― ― ― ― ― ― ―

FÍJÌ \

Sunday \ Saturday

\

\

TONGA \

\

\

\

[Àtẹ ìsọfúnni tó wà ní ojú ìwé 15]

 (Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

Àwọn Ohun Tó Yẹ Ká Rántí Nípa Sábáàtì Rèé:

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹsẹ Bíbélì kan sọ pé ká máa pa Sábáàtì mọ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, ó yẹ ká mọ̀ dájú ìgbà tí Ọlọ́run pàṣẹ yìí.

4026 Ṣ.S.K. ṢÁÁJÚ ÌGBÀ AYÉ MÓSÈ

ỌLỌ́RUN DÁ ÁDÁMÙ Kò sí òfin pípa Sábáàtì mọ́ ṣáájú

ìgbà ayé Mósè àtàwọn ọmọ Ísírẹ́lì.

Diutarónómì 5:1-3, 12-14.

1513 Ṣ.S.K. ÒFIN TÍ ỌLỌ́RUN FÚN ÀWỌN ỌMỌ ÍSÍRẸ́LÌ

ỌLỌ́RUN FÚN ÀWỌN Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nìkan ni Ọlọ́run fún ní

ỌMỌ ÍSÍRẸ́LÌ NÍ ÒFIN òfin pípa Sábáàtì mọ́. (Sáàmù 147:19, 20)

Òfin jẹ́ “àmì” láàárín Jèhófà

àtàwọn ọmọ Ísírẹ́lì.—Ẹ́kísódù 31:16, 17.

Sábáàtì ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ wulẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn

sábáàtì tí Ọlọ́run pàṣẹ pé káwọn ọmọ

Ísírẹ́lì máa pa mọ́.—Léfítíkù 16:29-31;

23:4-8; 25:4, 11; Númérì 28:26.

33 S.K. ÒFIN KRISTI

ÒFIN TÓ WÀ FÚN Ní ọdún 49 Sànmánì Kristẹni nígbà táwọn

ÀWỌN ỌMỌ ÍSÍRẸ́LÌ àpọ́sítélì àtàwọn àgbà ọkùnrin tó wà ní

WÁ SÓPIN Jerúsálẹ́mù ń jíròrò ohun tí Ọlọ́run fẹ́

káwọn Kristẹni máa ṣe, wọn ò mẹ́nu kan

pípa Sábáàtì mọ́.—Ìṣe 15:28, 29.

Ominú kọ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sí àwọn

Kristẹni tí wọ́n sọ pé káwọn èèyàn máa

ka àwọn ọjọ́ kan sí pàtàkì.

Gálátíà 4:9-11.

2010 S.K.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]

Àwọn ìwé ìròyìn gbé ìròyìn nípa àwọn àwùjọ ẹlẹ́sìn Mẹ́tọ́díìsì tí wọ́n dúró sójú ọ̀nà tí wọ́n sì ń fi dandan gbọ̀n fẹ́ kí orílẹ̀-èdè Fíjì pa dà sí pípa ọjọ́ Sábáàtì mọ́

[Credit Line]

Látọwọ́ Fiji Times