Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìrìn Àjò Ayé Àtijọ́ Tó Kọjá Òkun Mẹditaréníà

Ìrìn Àjò Ayé Àtijọ́ Tó Kọjá Òkun Mẹditaréníà

Ìrìn Àjò Ayé Àtijọ́ Tó Kọjá Òkun Mẹditaréníà

Lóde òní, ó rọrùn fún àwọn èèyàn láti wọ ọkọ̀ òfuurufú láti apá ibì kan láyé lọ sí apá ibòmíràn. Ǹjẹ́ kò ní yà ẹ́ lẹ́nu láti mọ̀ pé àwọn èèyàn rin ìrìn-àjò lọ sọ́nà tó jìn nígbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì?

NÍ NǸKAN bí ẹgbẹ̀rún [1,000] ọdún ṣáájú kí Kristi tó wá sáyé, Sólómọ́nì Ọba ṣe ọ̀wọ́ ọkọ̀ òkun tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ọkọ̀ òkun ọba Tírè láti kó àwọn ohun iyebíye láti ọ̀nà jíjìn wá sí Ísírẹ́lì. (1 Àwọn Ọba 9:26-28; 10:22) Ní ọ̀gọ́rùn-ún ọdún kẹsàn-án ṣáájú Sànmánì Kristẹni, èbútékọ̀ Jópà tó wà létí Òkun Mẹditaréníà nílẹ̀ Ísírẹ́lì ni Jónà ti wọ ọkọ̀ òkun tó ń lọ sí Táṣíṣì. a (Jónà 1:3) Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rin ìrìn àjò lórí òkun láti Kesaréà ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì lọ sí Pútéólì tó ń jẹ́ Pozzuoli lóde òní, ìyẹn ibi tí omi tí ya wọ ilẹ̀ ní Ítálì.—Ìṣe 27:1; 28:13.

Àwọn òpìtàn mọ̀ pé nígbà tó fi máa di ìgbà ayé Pọ́ọ̀lù, àwọn oníṣòwò láti àgbègbè Òkun Mẹditaréníà máa ń gba Òkun Pupa lọ sí ilẹ̀ Íńdíà. Nígbà tó sì máa di àárín ọgọ́rùn-ún ọdún kejì, àwọn awakọ̀ òkun kan ti tukọ̀ dé orílẹ̀-èdè Ṣáínà. b Àmọ́ kí la mọ̀ nípa ìrìn àjò tó kọjá Òkun Mẹditaréníà lọ sí apá ìwọ̀ oòrùn ayé? Báwo ni àwọn atukọ̀ ayé àtijọ́ ṣe rìn jìnnà tó ní apá ibẹ̀ yẹn?

Ìrìn Àjò Táwọn Ará Fòníṣíà Ayé Àtijọ́ Rìn Lojú Òkun

Ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ṣáájú ìgbà ayé Pọ́ọ̀lù, àwọn tó máa ń rin ìrìn-àjò lórí òkun ní ibì kan tí wọ́n ti máa ń lọ ṣòwò ní Ìwọ̀ Oòrùn ayé. Àwọn èèyàn gbà pé àwọn ará Fòníṣíà tí ìlú ìbílẹ̀ wọn wà ní Lẹ́bánónì òde òní rìnrìn àjò dé àgbègbè Òkun Àtìláńtíìkì ní ọdún 1200 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Ní nǹkan bí ọdún 1100 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ìkọjá òkun tóóró ti Gibraltar ni wọ́n tẹ ìlú Gadir dó sí, òun ló ń jẹ́ ìlú Cádiz nísinsìnyí ní èbúté orílẹ̀-èdè Sípéènì. Lára àwọn ohun àmúṣọrọ̀ tó wà níbẹ̀ ni fàdákà tí wọ́n máa ń wà jáde látinú ilẹ̀, àwọn oníṣòwò tó ń gba orí òkun Àtìláńtíìkì sì tún máa ń kó àwọn irin aláwọ̀ fàdákà wá síbẹ̀.

Òpìtàn Gíríìkì tó ń jẹ́ Herodotus sọ pé, ní ọgọ́rùn-ún ọdún keje ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Fáráò Nékò ti ilẹ̀ Íjíbítì kó àwùjọ ọkọ̀ òkun àwọn ará Fòníṣíà jọ sórí Òkun Pupa. Èrò rẹ̀ ni pé kí àwọn ará Fòníṣíà tukọ̀ yíká ilẹ̀ Áfíríkà láti ìlà oòrùn sí ìwọ̀ oòrùn.

Nígbà tó fi máa di ìgbà yẹn, àwọn awakọ̀ òkun ará Fòníṣíà ti ń ṣe ìwádìí káàkiri etíkun ilẹ̀ Áfíríkà fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún. Síbẹ̀, tí kì í bá ṣe ti ìjì alágbára àti ìgbì òkun ni, àwọn awakọ̀ òkun tó forí lé apá gúúsù Etíkun Àtìláńtíìkì ì bá ti lọ jìnnà. Ọ̀gbẹ́ni Herodotus sọ nípa ìrìn àjò ìwádìí tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń lọ yìí, ó ní, orí Òkun Pupa làwọn awakọ̀ òkun ará Fòníṣíà ti bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò wọn, wọ́n sì gba apá ìlà oòrùn etíkun ilẹ̀ Áfíríkà lọ sí apá gúúsù Òkun ilẹ̀ Íńdíà. Nígbà tó fi máa di nǹkan bí àárín ọdún náà, wọ́n bọ́ sórí ilẹ̀, wọ́n gbin nǹkan oko, wọ́n sì gbé ibẹ̀ fún àkókò tó tó láti kórè, lẹ́yìn náà wọ́n ń bá ìrìn àjò wọn lọ. Ọ̀gbẹ́ni Herodotus sọ pé, ní ọdún kẹta, wọ́n lọ yíká àgbègbè náà, wọ́n wọnú Mẹditaréníà, wọ́n sì pa dà sí ilẹ̀ Íjíbítì.

Ọ̀gbẹ́ni Herodotus parí àkọsílẹ̀ rẹ̀ nípa sísọ pé àwọn ará Fòníṣíà ròyìn àwọn ohun tóun kò lè gbà gbọ́ tó fi mọ́ èyí tí wọ́n sọ pé àwọn rí oòrùn lápá ọ̀tún nígbà ìrìn àjò wọn yíká ìkángun ilẹ̀ Áfíríkà. Á ṣòro gan-an fún ará Gíríìsì àtijọ́ láti gba èyí gbọ́. Ẹni tó jẹ́ pé àríwá ayé ló ti lo gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, ìhà gúúsù ló sì ti máa ń rí oòrùn. Nítorí náà, tó bá ń lọ sí ìwọ̀ oòrùn, apá òsì rẹ̀ ni oòrùn máa ń wà. Àmọ́ ní àgbègbè ilẹ̀ kan tí omi yí ká tó ń jẹ́ Cape of Good Hope, tó wà ní gúúsù agbede méjì ayé, àríwá lèèyàn ti máa ń rí oòrùn ọ̀sán gangan, ìyẹn téèyàn bá wà ní apá ọ̀tún ẹni tó ń lọ sí ìwọ̀ oòrùn.

Fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ni àkọ́sílẹ̀ Ọ̀gbẹ́ni Herodotus yìí fi dá àríyànjiyàn sílẹ̀ láàárín àwọn òpìtàn. Ó jọ ohun tí kò ṣeé gbà gbọ́ fún ọ̀pọ̀ èèyàn pé àwọn atukọ̀ ojú omi nígbà pípẹ́ sẹ́yìn ti lọ yíká ilẹ̀ Áfíríkà. Àmọ́, àwọn ọ̀mọ̀wé gbà pé Fáráò Nékò pàṣẹ pé káwọn èèyàn lọ sí irú ìrìn àjò ìwádìí bẹ́ẹ̀, irú ìrìn àjò bẹ́ẹ̀ sì ṣeé ṣe nítorí òye àti ìmọ̀ táwọn èèyàn ní nígbà yẹn. Òpìtàn Lionel Casson sọ pé, “Irú ìrìn àjò òkun bẹ́ẹ̀ ṣeé ṣe. Kò sí ìdí tí àwùjọ ará Fòníṣíà kò fi lè rin irú ìrìn-àjò tí wọ́n rìn yìí níwọ̀n àkókò tí wọ́n fi rìn ín lọ́nà tí Ọ̀gbẹ́ni Herodotus gbà ṣàlàyé.” A kò lè fi ìdánilójú sọ bí àkọsílẹ̀ Herodotus ti jóòótọ́ tó. Àmọ́, ó fún wa ní òye nípa ìsapá táwọn èèyàn ti ṣe láti rìnrìn àjò òkun lọ sí àgbègbè táwọn èèyàn kò mọ̀ rí ní ìjímìjí.

Ọ̀gbẹ́ni Pytheas Tukọ̀ Lọ sí Àríwá

Kì í ṣe àwọn ará Fòníṣíà nìkan ni àwọn èèyàn Mẹditaréníà tó kọ́kọ́ tukọ̀ gba apá ìwọ̀ oòrùn lọ sí òkun Àtìláńtíìkì. Ìlú Massalia tí wọ́n ń pè ní Marseilles nílẹ̀ Faransé wà lára àwọn ìlú òkèèrè táwọn ará Gíríìsì tó ń rìnrìn àjò òkun dá sílẹ̀. Òwò ojú omi àti ti orí ilẹ̀ ló mú ìlú náà lọ́rọ̀. Àwọn oníṣòwò láti ìlú Massalia máa ń fi wáìnì, òróró àti idẹ ti Mẹditaréníà ránṣẹ́ sí àríwá, wọ́n sì ń gba irin àti idẹ láti àríwá. Láìsí àní-àní, àwọn ará Massalia, fẹ́ lọ sí ibi táwọn ọjà wọ̀nyí ti ń wá. Nítorí náà, ní nǹkan bí ọdún 320 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Pytheas tó jẹ́ ará Massalia gbéra láti lọ sí ilẹ̀ àríwá jíjìnnà náà.

Nígbà tí Pytheas pa dà dé, ó kọ ìwé kan nípa ìrìn àjò rẹ̀ tó pe àkọlé rẹ̀ ní On the Ocean. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwé rẹ̀ tó fi èdè Gíríìkì ìpilẹ̀ṣẹ̀ kọ kò sí mọ́, ó kéré tán àwọn òǹkọ̀wé méjìdínlógún [18] ló fa ọ̀rọ̀ yọ látinú ìwé náà. Àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n fà yọ yìí fi hàn pé Pytheas fara balẹ̀ ṣàpèjúwe àwọn òkun, àwọn ìgbì òkun, ojú ilẹ̀ àtàwọn èèyàn tó ń gbé àgbègbè ibi tó ṣèbẹ̀wò sí. Ó tún lo gígùn òjìji ọ̀pá ìwọnlẹ̀ láti fi mọ ọ̀gangan ibi tí oòrùn ọjọ́kanrí wà, ó sì fi èyí ṣírò bí ibi tó ti rin ìrìn-àjò gbà níhà àríwá ṣe jìnnà tó.

Ohun tó mú kí Pytheas ṣe ohun tó ṣe yìí ni ìfẹ́ tó ní sí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì. Àmọ́, kì í fi bẹ́ẹ̀ ṣe torí ìwádìí nípa ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ló fi rìnrìn àjò tó rìn náà. Kàkà bẹ́ẹ̀ àwọn ọ̀mọ̀wé ti dábàá pé ìfẹ́ òwò ṣíṣe tó ní nínú ìlú Massalia ló mú kó náwó nára sí ìrìn àjò náà, èyí ló sì mú kó wá ọ̀nà ojú òkun tó lọ sí àwọn etíkun jíjìnnà rere níbi tí wọ́n ti lè rí idẹ àti irin. Ibo wá ni Pytheas lọ?

Ó Lọ sí Brittany Ilẹ̀ Faransé, Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti Ìkọjá Wọn

Ó jọ pé Pytheas tukọ̀ yí ká Iberia, ó sì gba etíkun Gaul lọ sí Brittany nílẹ̀ Faransé níbi tó gúnlẹ̀ sí létíkun. Àkọsílẹ̀ tó ṣe nípa ibi tí oòrùn wà nígbà tó wọn ibi tó jọ pé ilẹ̀ òun òfuurufú ti pàdé, bá apá ibi kan mu ní àríwá Brittany. c

Àwọn èèyàn àgbègbè Brittany mọ bá a ṣe ń kan ọkọ̀ òkun, wọ́n sì mọ bá a ṣe ń tukọ̀, wọ́n máa ń bá ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ṣòwò. Ìlú Cornwall tó wà ní ìkángun gúúsù ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì jẹ́ ibi tí irin pọ̀ gan-an sí, ìyẹn tó jẹ́ apá pàtàkì lára idẹ. Ibẹ̀ ni Pytheas tún lọ lẹ́yìn náà. Nínú ìròyìn rẹ̀, ó ṣàpèjúwe bí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ti tóbi tó, ó sì sọ pé ó rí bí ilẹ̀ onígun mẹ́ta. Èyí fi hàn pé ó ti ní láti tukọ̀ yí ká erékùṣù náà.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò mọ ojú ọ̀nà ibi tí Pytheas gbà rin ìrìn-àjò rẹ̀ gan-an, ó lè ti tukọ̀ gba àárín ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti ilẹ̀ Ireland, tó sì wá gúnlẹ̀ sí erékùṣù Isle of Man, tó wà ní ibì kejì tó bá àkọsílẹ̀ tó ṣe nípa ọ̀gangan ibi tí oòrùn wà mu. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìlú Lewis ní Outer Hebrides, tó ré kọjá ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ Scotland ló ti ṣe ìdiwọ̀n ẹlẹ́ẹ̀kẹta. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé láti ibẹ̀, ó ń bá ìrìn àjò náà lọ ní apá àríwá lọ sí erékùṣù Orkney Islands, ní àríwá ilẹ̀ Scotland tí kì í ṣe orí omi nítorí àkọsílẹ̀ rẹ̀ tí Pliny Àgbà fà yọ ròyìn pé ilẹ̀ náà jẹ́ erékùṣù ogójì [40].

Nígbà tí Pytheas tukọ̀ fún ọjọ́ mẹ́fà ní àríwá ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ó kọ̀wé pé òun rí ilẹ̀ kan tí wọ́n ń pè ní ilẹ̀ Thule. Àwọn òǹṣèwé ayé àtijọ́ kan máa ń tọ́ka sí bí Pytheas ṣe ṣàpèjúwe ilẹ̀ Thule pé ó jẹ́ ilẹ̀ tí oòrùn kì í wọ̀ lọ́gànjọ́ òru. Láti ibẹ̀, ó tukọ̀ fún ọjọ́ kan, ó kọ̀wé pé, òun dé ibi tí òkun ti “dì.” Ibi tí ilẹ̀ Thule tí Pytheas ṣàwárí wà ti dá ọ̀pọ̀ àríyànjiyàn sílẹ̀, àwọn kan sọ pé erékùṣù Faeroe Island ló wà, àwọn míì sọ pé ilẹ̀ Norway ló wà, àwọn kan tún sọ pé ilẹ̀ Iceland ló wà. Ibikíbi tí ilẹ̀ Thule ì báà wà, àwọn òǹkọ̀wé ayé àtijọ́ gbà pé ó jẹ́ “ibi tó jìnnà jù lọ ní àríwá ibì kan.”

Ká sáà gbà pé Pytheas pa dà sí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó sì gba ojú ọ̀nà kan náà tó gbà lọ pa dà, lẹ́yìn náà tó sì parí títukọ̀ yí ká erékùṣù náà. A kò mọ̀ bóyá ó tún lọ ṣàwárí nǹkan ní etíkun àríwá ilẹ̀ Yúróòpù kó tó pa dà sí Mẹditaréníà. Ohun yòówù kó jẹ́, Pliny Àgbà fa ọ̀rọ̀ Pytheas yọ pé ó jẹ́ aláṣẹ lórí àwọn àgbègbè tí wọ́n ti ń rí idẹ. Ilẹ̀ Jutland jẹ́ ibi àtijọ́ kan tí wọ́n ti ń wa ohun iyebíye jáde, ó jẹ́ apá kan ilẹ̀ Denmark òde òní, ó sì wà ní gúúsù etíkun Òkun Baltic. Ó dájú pé Pytheas ti ní láti mọ àwọn àgbègbè yìí nígbà tó ń ṣèbẹ̀wò sí èyí tó wù ú lára àwọn èbúté ìlà oòrùn ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, àmọ́ lóhun tá a mọ̀, kò sọ pé òun ṣèbẹ̀wò sáwọn ibẹ̀ yẹn fúnra òun.

Ọ̀gbẹ́ni Julius Caesar ni arìnrìn àjò Mẹditaréníà tá a tún mọ̀ tó kọ̀wé nípa ìrìn àjò tó rìn lọ sí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, tó sì gúnlẹ̀ sí gúúsù erékùṣù náà lọ́dún 55 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Nígbà tó máa di ọdún 6 Sànmánì Kristẹni, ìpolongo míì tí Róòmù ṣe ti dé àríwá ilẹ̀ Jutland.

Wọ́n Mú Ibi Tí Wọ́n Dé Gbòòrò Sí I

Ìrìn àjò ìwádìí táwọn ará Fòníṣíà àti Gíríìkì ṣe mú kí ìmọ̀ wọn pọ̀ sí i nípa Mẹditaréníà àti Òkun Àtìláńtíìkì, nípa àgbègbè gúúsù Áfíríkà títí dé àríwá Arctic tó jìnnà réré. Ayé ìgbà yẹn kún fún ṣíṣe àwárí, òwò, mímú ìmọ̀ ẹni pọ̀ sí i, rírin ìrìn àjò lọ sí ibi tó jìnnà réré, gbogbo èyí sì mú kí wọ́n ní èrò àti ìmọ̀ tó pọ̀ sí i.

Àwọn àkọsílẹ̀ nípa ìwádìí ayé àtijọ́ tó ṣì wà ló mú ká mọ̀ nípa ìrìn àjò òkun mélòó kan táwọn atukọ̀ òkun tó jẹ́ onígboyà ti lọ, tó sì yọrí sí rere. Àwọn atukọ̀ mélòó ló pa dà síbi tí wọ́n ti gbéra, tí wọn ò sì kọ nǹkan kan nípa ibi tí wọ́n ṣèbẹ̀wò sí? Àwọn mélòó ló ti tukọ̀ láti ìlú ìbílẹ̀ wọn sí etíkun jíjìnnà réré tí wọn ò sì pa dà mọ́? Kò sẹ́ni tó lè dáhùn ìbéèrè wọ̀nyí. Àmọ́, a lè fòye mọ nǹkan kan nípa bí ẹ̀sìn Kristẹni ṣe tàn kalẹ̀ níbẹ̀rẹ̀.— Wo àpótí tó wà lókè yìí.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Orúkọ yìí ni wọ́n sábà máa fi ń pe àgbègbè kan ní gúúsù orílẹ̀-èdè Sípéènì táwọn òǹkọ̀wé Gíríìkì àti Róòmù ń pè ní Tartessus.

b Fún àlàyé síwájú sí i nípa ìrìn àjò lórí òkun lọ sí apá ìlà oòrùn, ka àpilẹ̀kọ náà, “Ṣáwọn Míṣọ́nnárì Dé Ìpẹ̀kun Ìlà Oòrùn Ayé?” nínú Ilé Ìṣọ́ January 1, 2009.

c Àmọ́ lóde òní, ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ 48° 42’ N, lápá Àríwá ayé.

 [Àpótí tó wà ní ojú ìwé 29]

Ìhìn Rere Náà Ni A “Wàásù Nínú Gbogbo Ìṣẹ̀dá”

Ní nǹkan bí ọdún 60 sí 61 Sànmánì Kristẹni, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé ìhìn rere ni a ti “wàásù nínú gbogbo ìṣẹ̀dá tí ń bẹ lábẹ́ ọ̀run.” (Kólósè 1:23) Ṣé ohun tó ń sọ ni pé àwọn Kristẹni ti wàásù ní Íńdíà, apá ibi tó jìnnà ní Ìlà Oòrùn ayé, Áfíríkà, Sípéènì, Gaul, Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Baltics àti Thule tí Ọ̀gbẹ́ni Pytheas ṣàwárí? Kò jọ pé ohun tó ń sọ nìyẹn, àmọ́ a ò lè sọ ní pàtó.

Síbẹ̀, kò sí àní-àní pé, wọ́n ti wàásù ìhìn rere náà lọ́nà tó gbòòrò. Bí àpẹẹrẹ, àwọn Júù àtàwọn aláwọ̀ṣe Júù tí wọ́n di Kristẹni ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, mú ìgbàgbọ́ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ní yìí lọ sí, ó kéré tán, ọ̀nà tó jìn bíi Pátíà, Élámù, Mídíà, Mesopotámíà, Arébíà, Éṣíà Kékeré, àwọn apá kan nílẹ̀ Líbíà lọ sí Kírénè àti Róòmù, àwọn ìlú yìí ló para pọ̀ jẹ́ ayé táwọn tí Pọ́ọ̀lù ń bá sọ̀rọ̀ nígbà yẹn mọ̀.—Ìṣe 2:5-11.

[Àwòrán/Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 26, 27]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

Ọ̀gbẹ́ni Herodotus kọ̀wé pé, apá ọ̀tún làwọn atukọ̀ sọ pé àwọn ti rí oòrùn nígbà tí wọ́n ń tukọ̀ yíká ìkángun ilẹ̀ Áfíríkà

[Àwòrán ilẹ̀]

ÁFÍRÍKÀ

ÒKUN MẸDITARÉNÍÀ

ÒKUN ÍŃDÍÀ

ÒKUN ÀTÌLÁŃTÍÌKÌ

[Àwòrán/Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 28, 29]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

Ìrìn àjò òkun tó gbòòrò tí Pytheas ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì tó jẹ́ atukọ̀ òkun rìn

[Àwòrán ilẹ̀]

IRELAND

ICELAND

NORWAY

Òkun Àríwá

ILẸ̀ GẸ̀Ẹ́SÌ

BRITTANY

IBERIAN PENINSULA

ETÍKUN ÀRÍWÁ ÁFÍRÍKÀ

ÒKUN MẸDITARÉNÍÀ

Marseilles