Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí ni Èrò Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Nípa Àwọn Ẹlẹ́sìn Ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ Tó Ń Jọ́sìn Pa Pọ̀?

Kí ni Èrò Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Nípa Àwọn Ẹlẹ́sìn Ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ Tó Ń Jọ́sìn Pa Pọ̀?

Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé . . .

Kí ni Èrò Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Nípa Àwọn Ẹlẹ́sìn Ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ Tó Ń Jọ́sìn Pa Pọ̀?

▪ Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ World Christian Encyclopedia, sọ pé, “ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá [10,000] ẹ̀sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló wà kárí ayé.” Nítorí pé èdèkòyédè ti dá wàhálà tó pọ̀ sílẹ̀ láàárín àwọn ẹlẹ́sìn, ọkàn ọ̀pọ̀ èèyàn balẹ̀ pé bí àwọn ẹlẹ́sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ṣe ń jọ́sìn pa pọ̀ báyìí máa mú kí nǹkan dára. Wọ́n gbà gbọ́ pé ìyẹn máa jẹ́ kí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan jọba nínú ayé tó ti pínyà yìí.

Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká máa gbé níṣọ̀kan. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi ìjọ Kristẹni wé ara èèyàn, ẹ̀yà ara kọ̀ọ̀kan wà ní “síso  . .  pọ̀ ní ìṣọ̀kan àti mímú kí wọ́n fọwọ́ sowọ́ pọ̀.” (Éfésù 4:16) Bákan náà, àpọ́sítélì Pétérù gba àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ nímọ̀ràn pé: “Gbogbo yín ẹ jẹ́ onínú kan náà.”—1 Pétérù 3:8.

Àárín àwọn èèyàn tí àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ wọn àti ẹ̀sìn wọn yàtọ̀ síra làwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ gbé. Síbẹ̀, nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa àmúlùmálà ẹ̀sìn, ó sọ pé: “Ìpín wo ni olùṣòtítọ́ ní pẹ̀lú aláìgbàgbọ́?” Lẹ́yìn náà, ó kìlọ̀ fún àwọn Kristẹni pé kí wọ́n “jáde kúrò láàárín wọn.” (2 Kọ́ríńtì 6:15, 17) Ní kedere, ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ ni pé àmúlùmálà ẹ̀sìn kò dára. Kí nìdí tó fi sọ bẹ́ẹ̀?

Àpọ́sítélì yìí ṣàlàyé pé bí Kristẹni tòótọ́ kan àti aláìgbàgbọ́ kan bá jọ ń ṣe ìjọsìn pa pọ̀, kò ní sí ìṣọ̀kan, kò sì ní yọrí sí dáadáa. (2 Kọ́ríńtì 6:14) Àkóbá ló máa ṣe fún ìgbàgbọ́ irú Kristẹni bẹ́ẹ̀. Ńṣe ni àníyàn tí Pọ́ọ̀lù ń ṣe yìí dà bíi ti bàbá kan tó mọ̀ pé àwọn ọmọ kan táwọn jọ ń gbé ládùúgbò ti yàyàkuyà. Nítorí pé ó jẹ́ òbí tó káràmáásìkí nǹkan, ó fọgbọ́n yan àwọn tó yẹ kí àwọn ọmọ rẹ̀ máa bá ṣeré. Inú àwọn èèyàn lè má dùn sí ohun tí bàbá yìí ṣe. Àmọ́, yíyà wọ́n sọ́tọ̀ yẹn ló máa ran àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́ táwọn ọmọ tó ti yàyàkuyà yẹn kò fi ní ṣàkóbá fún wọn. Bí ohun tí Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn ṣe rí nìyẹn, ó mọ̀ pé bí àwọn Kristẹni bá yẹra fún àwọn ẹ̀sìn yòókù nìkan ni wọn kò fi ní tọwọ́ wọn bọ ìwà burúkú tí àwọn ẹlẹ́sìn náà ń hù.

Àpẹẹrẹ Jésù ni Pọ́ọ̀lù tẹ̀ lé nínú ohun tó ṣe yìí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù ló fi àpẹẹrẹ tó tayọ jù lọ lélẹ̀ tó bá dọ̀ràn gbígbé àlàáfíà lárugẹ láàárín àwọn èèyàn, síbẹ̀ kò lọ́wọ́ nínú àmúlùmálà ẹ̀sìn. Ọ̀pọ̀ àwọn olórí ẹ̀sìn bí àwọn Farisí àtàwọn Sadusí ló wà nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù lórí ilẹ̀ ayé. Kódà, àwọn ẹ̀ya ìsìn méjèèjì yìí pawọ́ pọ̀ ta ko Jésù, àní wọ́n jọ dìtẹ̀ láti pa á. Àmọ́ Jésù fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ní ìtọ́ni pé kí wọ́n “ṣọ́ra . . . fún ẹ̀kọ́ àwọn Farisí àti àwọn Sadusí.”—Mátíù 16:12.

Lóde òní ńkọ́? Ṣé ìkìlọ̀ Bíbélì pé ká yẹra fún àmúlùmálà ẹ̀sìn ṣì wúlò? Bẹ́ẹ̀ ni. Ìdí ni pé àmúlùmálà ẹ̀sìn kò lè mú kí oríṣiríṣi ẹ̀sìn ní ìgbàgbọ́ kan náà, kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló máa dà bí ìgbà téèyàn bu omi àti epo pupa sínú abọ́ kan. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí onírúurú ẹ̀sìn bá kóra jọ láti gbàdúrà fún àlàáfíà, Ọlọ́run wo ni wọ́n máa gbàdúrà sí? Ṣé Ọlọ́run Mẹ́talọ́kan ti àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ni? Ṣé Ọlọ́run Brahma ti àwọn ẹlẹ́sìn Híńdù ni? Ṣé Ọlọ́run Búdà ni? Àbí òmíràn?

Wòlíì Míkà sọ tẹ́lẹ̀ pé “ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́,” àwọn èèyàn láti gbogbo orílẹ̀-èdè á sọ pé: “Ẹ wá, ẹ sì jẹ́ kí a gòkè lọ sí òkè ńlá Jèhófà àti sí ilé Ọlọ́run Jékọ́bù; òun yóò sì fún wa ní ìtọ́ni nípa àwọn ọ̀nà rẹ̀, àwa yóò sì máa rìn ní àwọn ipa ọ̀nà rẹ̀.” (Míkà 4:1-4) Kí ló máa jẹ́ àbájáde èyí? Àlàáfíà àti ìṣọ̀kan tó kárí ayé ni, kì í ṣe kíkó onírúurú ẹ̀sìn pa pọ̀ láti máa jọ́sìn ló jẹ́ kó ṣeé ṣe, àmọ́ ó jẹ́ nítorí pé gbogbo èèyàn tẹ́wọ́ gba ẹ̀sìn tòótọ́ kan ṣoṣo.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Àpéjọ tí àwọn ẹ̀sìn ńláńlá nínú ayé para pọ̀ ṣe lọ́dún 2008

[Credit Line]

REUTERS/Andreas Manolis