Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìdáhùn sí Ìbéèrè Mẹ́rin Nípa Òpin Ayé

Ìdáhùn sí Ìbéèrè Mẹ́rin Nípa Òpin Ayé

Ìdáhùn sí Ìbéèrè Mẹ́rin Nípa Òpin Ayé

JÉSÙ KRISTI sọ tẹ́lẹ̀ pé lọ́jọ́ iwájú, ‘òpin yóò dé.’ Ó ṣàlàyé nípa àkókò yẹn, ó ní: “Nígbà náà ni ìpọ́njú ńlá yóò wà, irúfẹ́ èyí tí kò tíì ṣẹlẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé títí di ìsinsìnyí, rárá o, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò tún ṣẹlẹ̀ mọ́.”—Mátíù 24:14, 21.

Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nípa òpin àti ohun tí apá ibòmíì nínú Bíbélì sọ mú kí àwọn ìbéèrè pàtàkì kan wáyé. O ò ṣe ṣí Bíbélì rẹ kó o ka ìdáhùn àwọn ìbéèrè náà.

1 Kí Ló Máa Dópin?

Bíbélì kò kọ́ni pé ayé máa pa run. Onísáàmù kan sọ pé: “[Ọlọ́run] fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀ sórí àwọn ibi àfìdímúlẹ̀ rẹ̀; a kì yóò mú kí ó ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n fún àkókò tí ó lọ kánrin, tàbí títí láé.” (Sáàmù 104:5) Bákan náà, Bíbélì kò kọ́ni pé gbogbo ohun alààyè máa pa run nínú iná ńlá. (Aísáyà 45:18) Jésù fúnra rẹ̀ fi hàn pé àwọn èèyàn kan máa la òpin náà já. (Mátíù 24:21, 22) Kí wá ni Bíbélì sọ pé ó máa dópin?

Ìjọba àwọn èèyàn tó ti kùnà máa dópin. Ọlọ́run mí sí wòlíì Dáníẹ́lì láti sọ pé: “Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀ èyí tí a kì yóò run láé. Ìjọba náà ni a kì yóò sì gbé fún àwọn ènìyàn èyíkéyìí mìíràn. Yóò fọ́ ìjọba wọ̀nyí túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn, òun fúnra rẹ̀ yóò sì dúró fún àkókò tí ó lọ kánrin.”—Dáníẹ́lì 2:44.

Ogun àti ìbàyíkájẹ́ máa dópin. Nígbà tí Sáàmù 46:9 ń ṣàlàyé ohun tí Ọlọ́run máa ṣe, ó ní: “Ó mú kí ogun kásẹ̀ nílẹ̀ títí dé ìkángun ilẹ̀ ayé. Ó ṣẹ́ ọrun sí wẹ́wẹ́, ó sì ké ọ̀kọ̀ sí wẹ́wẹ́; Ó sun àwọn kẹ̀kẹ́ nínú iná.” Bíbélì tún kọ́ni pé Ọlọ́run yóò “run àwọn tí ń run ilẹ̀ ayé.”—Ìṣípayá 11:18.

Ìwà ọ̀daràn àti àìṣẹ̀tọ́ máa dópin. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣèlérí pé: “Àwọn adúróṣánṣán ni àwọn tí yóò máa gbé ilẹ̀ ayé, àwọn aláìlẹ́bi sì ni àwọn tí a óò jẹ́ kí ó ṣẹ́ kù sórí rẹ̀. Ní ti àwọn ẹni burúkú, a óò ké wọn kúrò lórí ilẹ̀ ayé gan-an; àti ní ti àwọn aládàkàdekè, a ó fà wọ́n tu kúrò lórí rẹ̀.” aÒwe 2:21, 22.

2 Ìgbà Wo Ni Òpin Máa Dé?

Jèhófà Ọlọ́run ti yan “àkókò” tó máa fòpin sí ìwà ibi, táá sì fìdí Ìjọba rẹ̀ múlẹ̀. (Máàkù 13:33) Àmọ́, Bíbélì fi hàn kedere pé a kò lè ṣírò ọjọ́ náà gan-an tí òpin máa dé. Jésù sọ pé: “Ní ti ọjọ́ àti wákàtí yẹn, kò sí ẹnì kankan tí ó mọ̀ ọ́n, àwọn áńgẹ́lì ọ̀run tàbí Ọmọ pàápàá kò mọ̀ ọ́n, bí kò ṣe Baba nìkan.” (Mátíù 24:36) Àmọ́, Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ ipò tí ayé máa wà ṣáájú kí Ọlọ́run tó mú òpin dé. Òpin náà yóò ti kù sí dẹ̀dẹ̀ nígbà tí gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ tá a fẹ́ sọ yìí bá ń ṣẹlẹ̀ ní àkókò kan náà kárí ayé.

Rògbòdìyàn ìṣèlú, ìbàyíkájẹ́ àti rúkèrúdò láàárín àwọn èèyàn á máa ṣẹlẹ̀ lọ́nà tí a kò rí irú rẹ̀ rí. Nígbà tí Jésù dáhùn ìbéèrè àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nípa òpin ayé, ó sọ pé: “Nítorí orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè àti ìjọba sí ìjọba, ìsẹ̀lẹ̀ yóò wà láti ibì kan dé ibòmíràn, àìtó oúnjẹ yóò wà. Ìwọ̀nyí jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìroragógó wàhálà.” (Máàkù 13:8) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò yóò wà níhìn-ín. Nítorí àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó, ajọra-ẹni-lójú, onírera, asọ̀rọ̀ òdì, aṣàìgbọràn sí òbí, aláìlọ́pẹ́, aláìdúróṣinṣin, aláìní ìfẹ́ni àdánidá, aláìṣeé bá ṣe àdéhùn kankan, afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́, aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu, òǹrorò, aláìní ìfẹ́ ohun rere, afinihàn, olùwarùnkì, awúfùkẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga, olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run.”—2 Tímótì 3:1-5.

Iṣẹ́ ìwàásù tí à ń fi èdè púpọ̀ ṣe kárí ayé ń lọ lọ́wọ́. Jésù sọ pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.”—Mátíù 24:14.

3 Kí Ló Máa Ṣẹlẹ̀ Lẹ́yìn Òpin Ayé?

Bíbélì kò kọ́ni pé a óò kó gbogbo èèyàn rere tó wà láyé lọ sí ọ̀run kí wọ́n lè máa gbé títí láé. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jésù kọ́ni pé ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ní ìbẹ̀rẹ̀ fún aráyé máa ṣẹ. Jésù sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn onínú tútù, níwọ̀n bí wọn yóò ti jogún ilẹ̀ ayé.” (Mátíù 5:5; 6:9, 10) Àwọn tó kú kí òpin tó dé ńkọ́? Bíbélì ṣèlérí pé wọ́n á jíǹde lọ́jọ́ iwájú. (Jóòbù 14:14, 15; Jòhánù 5:28, 29) Kí ló máa ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn òpin náà?

Jésù á máa ṣàkóso láti ọ̀run gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Ọlọ́run. Wòlíì Dáníẹ́lì sọ pé: “Mo rí i nínú ìran òru, sì wò ó! ó ṣẹlẹ̀ pé ẹnì kan bí ọmọ ènìyàn [Jésù tó ti jíǹde] ń bọ̀ pẹ̀lú àwọsánmà ọ̀run; ó sì wọlé wá sọ́dọ̀ Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé [Jèhófà Ọlọ́run], wọ́n mú un wá, àní sún mọ́ iwájú Ẹni náà. A sì fún un [Jésù] ní agbára ìṣàkóso àti iyì àti ìjọba, pé kí gbogbo àwọn ènìyàn, àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè àti àwọn èdè máa sin àní òun. Agbára ìṣàkóso rẹ̀ jẹ́ agbára ìṣàkóso tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin tí kì yóò kọjá lọ, ìjọba rẹ̀ sì jẹ́ èyí tí a kì yóò run.”—Dáníẹ́lì 7:13, 14; Lúùkù 1:31, 32; Jòhánù 3:13-16.

Àwọn ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run máa gbádùn ìlera pípé, ààbò táá wà títí lọ àti ìyè ayérayé. Wòlíì Aísáyà sọ pé: “Dájúdájú, wọn yóò kọ́ ilé, wọn yóò sì máa gbé inú wọn; dájúdájú, wọn yóò gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì máa jẹ èso wọn. Wọn kì yóò kọ́lé fún ẹlòmíràn gbé; wọn kì yóò gbìn fún ẹlòmíràn jẹ.” (Aísáyà 65:21-23) Àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “Wò ó! Àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú aráyé, yóò sì máa bá wọn gbé, wọn yóò sì máa jẹ́ ènìyàn rẹ̀. Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yóò sì wà pẹ̀lú wọn. Yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”—Ìṣípayá 21:3, 4.

4 Kí Lo Gbọ́dọ̀ Ṣe Láti La Òpin Ayé Já?

Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé àwọn kan lára àwọn tó ń gbé láyé ní àkókò òpin á máa pẹ̀gàn pé Ọlọ́run kò ní dá sí ọ̀ràn aráyé, kò sì ní fòpin sí ìwà ìkà tó wà lórí ilẹ̀ ayé. (2 Pétérù 3:3, 4) Síbẹ̀, Pétérù rọ àwọn tó ń gbé láyé lọ́jọ́ wa yìí pé kí wọ́n ṣe àwọn nǹkan tó tẹ̀ lé e yìí.

Kẹ́kọ̀ọ́ látinú ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá. Pétérù sọ pé Ọlọ́run “kò sì fawọ́ sẹ́yìn ní fífìyàjẹ ayé ìgbàanì, ṣùgbọ́n ó pa Nóà, oníwàásù òdodo mọ́ láìséwu pẹ̀lú àwọn méje mìíràn nígbà tí ó mú àkúnya omi wá sórí ayé àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run.” (2 Pétérù 2:5) Pétérù sọ nípa àwọn tó ń pẹ̀gàn pé: “Nítorí, ní ìbámu pẹ̀lú ìdàníyàn wọn, òtítọ́ yìí bọ́ lọ́wọ́ àfiyèsí wọn, pé àwọn ọ̀run wà láti ìgbà láéláé àti ilẹ̀ ayé kan tí ó dúró digbí-digbí láti inú omi àti ní àárín omi nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run; àti nípasẹ̀ ohun wọnnì, ayé ìgbà yẹn jìyà ìparun nígbà tí a fi àkúnya omi bò ó mọ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n nípa ọ̀rọ̀ kan náà, àwọn ọ̀run àti ilẹ̀ ayé b tí ó wà nísinsìnyí ni a tò jọ pa mọ́ fún iná, a sì ń fi wọ́n pa mọ́ de ọjọ́ ìdájọ́ àti ti ìparun àwọn ènìyàn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run.”—2 Pétérù 3:5-7.

Ìlànà tí Ọlọ́run là kalẹ̀ ni kó o máa fi ṣèwàhù. Pétérù sọ pé àwọn tí wọ́n fẹ́ la òpin ayé já ní láti máa gbé ìgbé ayé “ìṣe ìwà mímọ́” kí wọ́n sì máa ṣe “àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run.” (2 Pétérù 3:11) Kíyè sí i pé Pétérù tẹnu mọ́ “ìṣe ìwà mímọ́ àti àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run.” Nítorí náà, ohun tẹ́nì kan máa ṣe ju fífi ẹnu lásán sọ pé òun ní ìgbàgbọ́ tàbí kéèyàn kàn ṣàdédé yí pa dà láti bá Ọlọ́run rẹ́.

Irú àwọn ìwà àti iṣẹ́ wo ló ṣètẹ́wọ́gbà lójú Ọlọ́run? O ò ṣe fi ohun tó o mọ̀ wé ohun ti Bíbélì kọ́ni nípa ọ̀ràn yìí. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn láti ràn ẹ́ lọ́wọ́. Ní kí wọ́n fi hàn ẹ́ nínú Bíbélì rẹ ìdí tí ìdáhùn wọn fi rí bẹ́ẹ̀. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti fi ìgboyà àti ìbàlẹ̀ ọkàn dojú kọ ọjọ́ ọ̀la láìka àwọn ohun tó ń fa ìbẹ̀rù tó yí wa ká sí.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Tún ka àpilẹ̀kọ náà, “Ǹjẹ́ Gbogbo Èèyàn Ló Láǹfààní Kan Náà Láti Mọ Ọlọ́run?” lójú ìwé 22 nínú ìtẹ̀jáde yìí.

b Níbí yìí, Pétérù ń sọ̀rọ̀ nípa ilẹ̀ ayé lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. Mósè tóun náà wà lára àwọn tó kọ Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ilẹ̀ ayé lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. Ó kọ̀wé pé: “Gbogbo ilẹ̀ ayé ń bá a lọ láti jẹ́ èdè kan.” (Jẹ́nẹ́sísì 11:1) Bí ilẹ̀ ayé tí Mósè mẹ́nu kàn kò ṣe lè sọ “èdè kan,” bẹ́ẹ̀ náà ni ilẹ̀ ayé tí Pétérù sọ̀rọ̀ rẹ̀ kò lè pa run. Kàkà bẹ́ẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Pétérù ṣe sọ, àwọn èèyàn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run ló máa pa run.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 7]

Ilẹ̀ ayé kì yóò pa run, àmọ́, àwọn tó ń bà á jẹ́ ló máa pa run