Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Máa Ń Fi Iṣẹ́ Ìyanu Ṣèwòsàn?

Ṣé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Máa Ń Fi Iṣẹ́ Ìyanu Ṣèwòsàn?

Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé . . .

Ṣé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Máa Ń Fi Iṣẹ́ Ìyanu Ṣèwòsàn?

▪ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò tíì fìgbà kan rí fi iṣẹ́ ìyanu ṣèwòsàn. Bíi Jésù, ìwàásù ìhìn rere nípa Ìjọba Ọlọ́run ni wọ́n gbà pé ó jẹ́ iṣẹ́ pàtàkì tí àwọn ní láti ṣe. Wọ́n tún gbà gbọ́ pé, kì í ṣe fífi iṣẹ́ ìyanu ṣèwòsàn la fi ń mọ àwọn Kristẹni tòótọ́, àmọ́ ohun mìíràn wà tó ṣe pàtàkì ju ṣíṣe ìwòsàn lọ.

Ká lè mọ̀ pé bí ọ̀rọ̀ ṣe rí nìyẹn, ẹ̀kọ́ ńlá wà fún gbogbo wa nínú ìwòsàn tí Jésù fi iṣẹ́ ìyanu ṣe ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. Ó tipa bẹ́ẹ̀ fi dá wa lójú pé, lábẹ́ ìṣàkóso òun gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Ọlọ́run, “kò [ní] sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’”—Aísáyà 33:24.

Iṣẹ́ ìyanu táwọn èèyàn ń ṣe lónìí ńkọ́? Àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì àtàwọn kan tí kì í ṣe Kristẹni máa ń sọ pé àwọn ń fi iṣẹ́ ìyanu ṣèwòsàn. Àmọ́, Jésù fúnra rẹ̀ ní ká ṣọ́ra fún àwọn èèyàn tó ń sọ pé àwọn ń “ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ agbára” ní orúkọ òun. Ó ní òun máa sọ fún wọn pé: “Èmi kò mọ̀ yín rí! Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin oníṣẹ́ ìwà àìlófin.” (Mátíù 7:22, 23) Nítorí náà, ṣé Ọlọ́run fọwọ́ sí iṣẹ́ ìyanu táwọn èèyàn ń ṣe lónìí?

Ṣàgbéyẹ̀wò ohun tí Bíbélì sọ nípa ìwòsàn tí Jésù ṣe. Tá a bá fi ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó sọ nípa iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe wé ọ̀nà táwọn oníṣẹ́ ìyanu ń gbà ṣèwòsàn lónìí, a máa mọ̀ bóyá Ọlọ́run fọwọ́ sí iṣẹ́ ìyanu táwọn èèyàn ń ṣe lónìí tàbí kò fọwọ́ sí i.

Jésù kò fìgbà kan rí ṣe ìwòsàn láti fi fa ọmọlẹ́yìn tàbí èrò sọ́dọ̀ ara rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu ni Jésù ṣe níbi táwọn èèyàn kò ti rí ohun tó ṣe. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jésù sọ fún àwọn tó fi iṣẹ́ ìyanu wò sàn pé wọn kò gbọ́dọ̀ sọ fún ẹnikẹ́ni.—Lúùkù 5:13, 14.

Jésù kò gba owó nítorí àwọn iṣẹ́ ìyanu tó ṣe. (Mátíù 10:8) Kò sì sí ìgbà kan tí Jésù ṣe àṣetì nígbà tó ń ṣe iṣẹ́ ìyanu. Gbogbo àìsàn tó wà lára àwọn tó wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ló wò sàn pátápátá, ìwòsàn náà kì í sì í ṣe nítorí bóyá wọ́n ní ìgbàgbọ́ tàbí wọn kò ní in. (Lúùkù 6:19; Jòhánù 5:5-9, 13) Jésù tiẹ̀ jí òkú dìde pàápàá!—Lúùkù 7:11-17; 8:40-56; Jòhánù 11:38-44.

Òótọ́ ni pé Jésù ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu yẹn, àmọ́ ohun tó gbájú mọ́ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ kì í ṣe fífi iṣẹ́ ìyanu yí àwọn èèyàn lọ́kàn pa dà. Kàkà bẹ́ẹ̀, iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ni olórí iṣẹ́ rẹ̀. Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti máa sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn, kí wọ́n lè máa kọ́ àwọn èèyàn láti ní ìrètí gbígbádùn ìlera pípé lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run.—Mátíù 28:19, 20.

Òótọ́ ni pé àwọn kan lára àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ní àwọn ẹ̀bùn àrà ọ̀tọ̀ tí wọ́n lè fi ṣèwòsàn, àmọ́ ẹ̀bùn yìí máa dópin. (1 Kọ́ríńtì 12:29, 30; 13:8, 13) Kì í ṣe fífi iṣẹ́ ìyanu ṣèwòsàn la fi ń dá àwọn Kristẹni tòótọ́ mọ̀ lónìí, bí kò ṣe ìfẹ́ ìfara-ẹni-rúbọ tí wọ́n ní láàárín ara wọn. (Jòhánù 13:35) Fífi iṣẹ́ ìyanu ṣèwòsàn lóde òní kò tíì mú kí irú ìfẹ́ yìí so àwọn Kristẹni láti onírúurú ẹ̀yà àti oríṣiríṣi èèyàn pọ̀ ní ìṣọ̀kan.

Àmọ́ ṣá o, àwùjọ àwọn Kristẹni kan wà tí ìfẹ́ so pọ̀ ṣọ̀kan débi pé wọn kì í pa ara wọn tàbí àwọn ẹlòmíì lára, àní nígbà tí àwọn èèyàn bá ń bá ara wọn ja ìjà àjàkú akátá pàápàá. Ta ni wọ́n? Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni. Kárí ayé láwọn èèyàn ti mọ̀ wọ́n pé wọ́n máa ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìfẹ́ Kristi. Tá a bá ní ká sọ ọ́, iṣẹ́ ìyanu gbáà ló jẹ́ pé àwọn èèyàn láti onírúurú ẹ̀yà, orílẹ̀-èdè àti àṣà ìbílẹ̀ wà níṣọ̀kan, ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run nìkan ló sì ń jẹ́ kí èyí ṣeé ṣe. O ò ṣe lọ sí ọ̀kan lára ìpàdé wọn láti rí i fúnra rẹ.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Ṣé Ọlọ́run ló ń ṣe àtìlẹ́yìn fún àwọn tó ń fi iṣẹ́ ìyanu ṣèwòsàn lóde òní? (àwòrán tó wà ní apá ọ̀tún yìí)