Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

6 Ǹjẹ́ Àdúrà Lè Ràn Wá Lọ́wọ́?

6 Ǹjẹ́ Àdúrà Lè Ràn Wá Lọ́wọ́?

6 Ǹjẹ́ Àdúrà Lè Ràn Wá Lọ́wọ́?

ǸJẸ́ àdúrà lè ṣe wá láǹfààní kankan? Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé àdúrà àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run lè ṣe wọ́n láǹfààní. (Lúùkù 22:40; Jákọ́bù 5:13) Kódà, àdúrà lè ṣe wá láǹfààní tó pọ̀ gan-an tó bá dọ̀rọ̀ àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run àti ìmọ̀lára wa, títí kan ìlera wa pàápàá. Lọ́nà wo?

Ká ní ọmọ rẹ kan rí ẹ̀bùn kan gbà. Ṣé wàá ṣẹ̀ṣẹ̀ máa kọ́ ọ pé ó yẹ kó fi hàn pé òun mọyì nǹkan náà? Àbí wàá ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ ọ pé ó yẹ kó dúpẹ́? Tá a bá mọ inú rò, a ó lè mọ ohun tó tọ́, a ó sì máa ṣe wọ́n. Ǹjẹ́ òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí tó bá kan bíbá Ọlọ́run sọ̀rọ̀? Bẹ́ẹ̀ ni! Ṣàgbéyẹ̀wò àwọn àpẹẹrẹ kan.

Àdúrà ọpẹ́. Tá a bá dúpẹ́ lọ́wọ́ Bàbá wa fún àwọn ohun rere tó ṣe fún wa, ńṣe là ń sọ̀rọ̀ nípa ìbùkún rẹ̀ lórí wa. Èyí lè jẹ́ ká túbọ̀ jẹ́ ẹni tó mọrírì, tó láyọ̀, ẹni tó túbọ̀ ń ṣe nǹkan lọ́nà tó tọ́.—Fílípì 4:6.

Àpẹẹrẹ: Jésù dúpẹ́ lọ́wọ́ Bàbá rẹ̀ fún bó ṣe máa ń fetí sí àdúrà rẹ̀ tó sì máa ń dáhùn rẹ̀.—Jòhánù 11:41.

Àdúrà fún ìdáríjì. Tá a bá tọrọ ìdáríjì lọ́wọ́ Ọlọ́run, èyí á mú kí ẹ̀rí ọkàn wa lágbára, a fi hàn pé a ti ronú pìwà dà, á sì fi hàn pé a mọ bí ẹ̀ṣẹ̀ ṣe burú tó. Ara á tún tù wá lọ́wọ́ ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀.

Àpẹẹrẹ: Dáfídì gbàdúrà láti sọ nípa ìrònúpìwàdà àti ìbànújẹ́ rẹ̀.—Sáàmù 51.

Àdúrà fún ìtọ́sọ́nà àti ọgbọ́n. Bíbẹ Jèhófà pé kó fún wa ní ìtọ́sọ́nà tàbí ọgbọ́n tá a nílò láti ṣe ìpinnu tó dára máa jẹ́ ká rẹ ara wa sílẹ̀ pátápátá. Èyí lè jẹ́ ká mọ̀ pé ó ní ibi tí agbára wa mọ, á sì jẹ́ ká lè gbẹ́kẹ̀ lé Bàbá wa ọ̀run.—Òwe 3:5, 6.

Àpẹẹrẹ: Sólómọ́nì fi ìrẹ̀lẹ̀ béèrè fún ìtọ́sọ́nà àti ọgbọ́n tó fẹ́ fi ṣàkóso Ísírẹ́lì.—1 Àwọn Ọba 3:5-12.

Àdúrà nígbà wàhálà. Tá a bá sọ ohun tó wà lọ́kàn wa fún Ọlọ́run nígbà tá a bá wà nínú ìdààmú, ọkàn wa á balẹ̀, a ó sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà dípò ara wa.—Sáàmù 62:8.

Àpẹẹrẹ: Ásà Ọba gbàdúrà nígbà táwọn ọ̀tá gbéjà kò ó.—2 Kíróníkà 14:11.

Gbígbàdúrà fún ire àwọn ẹlòmíì. Irú àdúrà bẹ́ẹ̀ ń jẹ́ ká borí ìmọtara-ẹni-nìkan, a ó sì wá dẹni tó ń káàánú àwọn ẹlòmíì tó sì ń fọ̀rọ̀ àwọn ẹlòmíì ro ara wa wò.

Àpẹẹrẹ: Jésù gbàdúrà nítorí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀.—Jòhánù 17:9-17.

Àdúrà ìyìn. Tá a bá yin Jèhófà fún àwọn iṣẹ́ àgbàyanu àtàwọn ànímọ́ rẹ̀, ọ̀wọ̀ àti ìmọrírì wa fún un á máa pọ̀ sí i. Irú àdúrà yìí tún lè mú ká túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run tó jẹ́ Bàbá wa.

Àpẹẹrẹ: Dáfídì yin Ọlọ́run látọkàn wá nítorí àwọn ohun tó dá. —Sáàmù 8.

Ìbùkún míì tó tún ní í ṣe pẹ̀lú àdúrà ni “àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ.” (Fílípì 4:7) Ìbùkún ńlá ló jẹ́ láti ní ìbàlẹ̀ ọkàn nínú ayé oníwàhálà yìí. Ó tiẹ̀ ńṣe ara ẹni lóore pàápàá. (Òwe 14:30) Àmọ́, ṣé ìsapá wa ló ń jẹ́ ká ní in? Àbí ohun kan wà tó ṣe pàtàkì ju ìyẹn lọ?

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 10]

Àdúrà lè ṣe wá láǹfààní tó pọ̀ gan-an tó bá dọ̀rọ̀ ìlera, ìmọ̀lára àti ju gbogbo rẹ̀ lọ, àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run