Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Olùgbọ́ Àdúrà”

“Olùgbọ́ Àdúrà”

Sún Mọ́ Ọlọ́run

“Olùgbọ́ Àdúrà”

1 KÍRÓNÍKÀ 4:9, 10

ṢÉ ÒÓTỌ́ ni pé Jèhófà Ọlọ́run máa ń dáhùn àdúrà àtọkànwá àwọn olóòótọ́ tó ń sìn ín? Ìtàn inú Bíbélì nípa ọkùnrin kan tí a kò mọ ohun púpọ̀ nípa rẹ̀, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jábésì fi hàn pé Jèhófà jẹ́ “Olùgbọ́ àdúrà” ní tòótọ́. (Sáàmù 65:2) Àkọsílẹ̀ kúkúrú yìí la rí níbi tí a kò fọkàn sí, ìyẹn nínú àkọsílẹ̀ àwọn ìlà ìdílé tó bẹ̀rẹ̀ ìwé Kíróníkà Kìíní. Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò 1 Kíróníkà 4:9, 10.

Ẹsẹ méjì yìí ló sọ gbogbo ohun tá a mọ̀ nípa Jábésì. Gẹ́gẹ́ bí ẹsẹ 9 ti wí, ìyá rẹ̀ “pe orúkọ rẹ̀ ní Jábésì, ó wí pé: ‘Mo bí i nínú ìrora.’” a Kí nìdí tó fi yan orúkọ yẹn fún ọmọ rẹ̀? Ṣé ìrora tó ní nígbà tó bí ọmọ yìí pọ̀ ju èyí tí àwọn obìnrin máa ń ní lákòókò ìrọbí ni? Àbí torí pé ó jẹ́ opó tó ń kédàárò pé ọkọ òun kò lè kí ọmọ wọn káàbọ̀ sáyé ni? Bíbélì kò sọ fún wa. Àmọ́ lọ́jọ́ kan ìyá yìí máa rí ìdí tí yóò fi fi ọmọ yìí yangàn. Ó ṣeé ṣe kí àwọn ọmọ ìyá Jábésì jẹ́ adúróṣinṣin, àmọ́ “Jábésì  . . . wá ní ọlá ju àwọn arákùnrin rẹ̀.”

Jábésì jẹ́ ẹni tó máa ń gbàdúrà gan-an. Ohun tó fi bẹ̀rẹ̀ àdúrà rẹ̀ ni pé kí Ọlọ́run bù kún òun. Lẹ́yìn náà, ó béèrè ohun mẹ́ta tó fi hàn pé ìgbàgbọ́ rẹ̀ lágbára.

Ohun àkọ́kọ́ tí Jábésì béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run ni pé: “Sọ ìpínlẹ̀ mi di títóbi.” (Ẹsẹ 10) Ọkùnrin ọlọ́lá yìí kì í ṣe ẹni tó lójú kòkòrò láti gba ilẹ̀ sí i, kì í ṣe ẹni tójú rẹ̀ ń wọ ohun ìní ẹlòmíì. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ nítorí àwọn èèyàn ló ṣe gbàdúrà àtọkànwá, kì í ṣe torí kó lè ní ilẹ̀. Ó lè jẹ́ pé àdúrà rẹ̀ ni pé kí Ọlọ́run jẹ́ kí ìpínlẹ̀ òun pọ̀ sí i láìsí pé òun jagun, kí àwọn èèyàn tó ń jọ́sìn Ọlọ́run tòótọ́ bàa lè pọ̀ sí i níbẹ̀. b

Ohun kejì tí Jábésì béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run ni pé, kí “ọwọ́” rẹ̀ wà pẹ̀lú òun. Ọwọ́ Ọlọ́run ṣàpẹẹrẹ agbára rẹ̀, tí ó ń lò láti fi ran àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ lọ́wọ́. (1 Kíróníkà 29:12) Ojú Ọlọ́run tí ọwọ́ rẹ̀ kò kúrú láti ṣèrànwọ́ fún àwọn tó gbà á gbọ́ ni Jábésì ń wò, kó lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè ọkàn rẹ̀.—Aísáyà 59:1.

Ohun kẹta tí Jábésì béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run ni pé: “Pa mí mọ́ . . . kúrò nínú ìyọnu àjálù, kí ó má bàa ṣe mí lọ́ṣẹ́.” Gbólóhùn náà, “kí ó má bàa ṣe mí lọ́ṣẹ́” lè fi hàn pé kì í ṣe pé Jábésì ń gbàdúrà pé kóun má ṣe rí àjálù, àmọ́ ohun tó ń sọ ni pé kí àjálù má ṣe dorí òun kodò tàbí borí òun.

Àdúrà Jábésì fi èrò rẹ̀ nípa ìjọsìn tòótọ́ hàn, ó sì tún fi ìgbàgbọ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀ nínú Olùgbọ́ àdúrà hàn. Kí ni Jèhófà ṣe? Àwọn ọ̀rọ̀ tó parí àkọsílẹ̀ kúkúrú yìí sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Ọlọ́run mú ohun tí ó béèrè ṣẹ.”

Olùgbọ́ àdúrà kò tíì yí pa dà. Inú rẹ̀ ń dùn sí àdúrà àwọn olùjọ́sìn rẹ̀. Ó dá àwọn tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé nínú rẹ̀ lójú pé: “Ohun yòówù tí ì báà jẹ́ tí a bá béèrè ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ̀, ó ń gbọ́ tiwa.”—1 Jòhánù 5:14.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Orúkọ náà Jábésì wá látinú ohun tó lè túmọ̀ sí “ìrora.”

b Ìwé Targum, ìyẹn ìwé táwọn Júù fi ṣàlàyé Ìwé Mímọ́, túmọ̀ ọ̀rọ̀ Jábésì báyìí pé: “Fi àwọn ọmọ bù kún mi, kí o sì jẹ́ kí ààlà mí gbòòrò sí i, kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn sì pọ̀ sí i níbẹ̀.”