Àwọn Àpéjọ Àgbègbè Tí Wọ́n Máa Ń ṣe Nígbà Ẹ̀ẹ̀rùn Nílẹ̀ Rọ́ṣíà Mú Ìbùkún Wá
Àwọn Àpéjọ Àgbègbè Tí Wọ́n Máa Ń ṣe Nígbà Ẹ̀ẹ̀rùn Nílẹ̀ Rọ́ṣíà Mú Ìbùkún Wá
Ọ̀PỌ̀ èèyàn nílẹ̀ Rọ́ṣíà tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ láti máa wo àwọn ewéko, ẹranko àtàwọn nǹkan míì tí Ọlọ́run dá máa ń fi ilé wọn sílẹ̀ ní ìgboro nígbà ẹ̀ẹ̀rùn lọ sí ìgbèríko, ibẹ̀ ni wọ́n ti ń lo àkókò wọn nínú ilé ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn tí wọ́n ń pè ní dachas. Wọ́n ka àkókò yìí sí àǹfààní láti kúrò nínú kòókòó jàn-án-jàn-án àárín ìlú. Ní àwọn ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn mélòó kan tó ti kọjá, ọ̀pọ̀ Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà náà ti lọ sí àwọn ìgbèríko láti ṣe ohun kan tó yàtọ̀.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n fi àṣẹ de àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà pé wọn kò gbọ́dọ̀ wàásù ní àwọn ìlú kan lórílẹ̀-èdè náà, síbẹ̀ wọ́n máa ń péjọ ní gbangba fún ìjọsìn, wọ́n sì ń lo ẹ̀tọ́ òmìnira ẹ̀sìn tí wọ́n ní. Àmọ́ láwọn àkókò kan, ó ṣòro fún wọn láti gba àṣẹ láti lo ibi to rọrùn fún àpéjọ àgbègbè ọdọọdún tí wọ́n máa ń ṣe nígbà ẹ̀ẹ̀rùn, ìyẹn sì jẹ́ nítorí àtakò àti èrò tí kò tọ́ táwọn aláṣẹ ìjọba àtàwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ti ilẹ̀ Rọ́ṣíà ní nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nítorí náà, àwọn Ẹlẹ́rìí ṣètò láti lọ ṣe àpéjọ wọn nínú “igbó.” Láti ọdún 2007 sí 2009, wọ́n ti ṣe irú àpéjọ ìta gbangba bẹ́ẹ̀ ní nǹkan bí ogójì [40] ìgbà ní ibi mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] káàkiri ilẹ̀ Rọ́ṣíà.
Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó ti ń lọ sí àpéjọ ní Rọ́ṣíà fún ọ̀pọ̀ ọdún sọ pé: “Ní àwọn ọdún tó ti kọjá, a
máa ń gba àwọn pápá ìṣeré àtàwọn ilé ńlá ní àwọn ìlú ńlá, ọ̀pọ̀ àwọn olóòótọ́ ọkàn àtàwọn aláṣẹ àdúgbò ló sì má ń sọ ohun tó dára nípa ètò wa nítorí ìmọ́tótó àti ìwàlétòlétò wa tí wọ́n rí. Àmọ́ nísinsìnyí ó ti di dandan pé ká lọ ṣe àpéjọ wa nínú igbó níbi tí àwọn ẹranko ń gbé. Ó dùn wa gan-an pé àwọn èèyàn kò lè rí àpéjọ àgbàyanu tí àwọn èèyàn tó wá síbẹ̀ jẹ́ onírúurú ìran, tí ipò ìgbésí ayé wọn yàtọ̀ síra, tó sì jẹ́ pé ẹ̀sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n ń ṣe tẹ́lẹ̀.”Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́rìí sí i pé, àkókò aláyọ̀ làwọn àpéjọ náà jẹ́ lóòótọ́, àmọ́ ó sọ ohun kan, ó ní: “Ohun ayọ̀ ni láti rí àwọn tá a jọ jẹ́ Ẹlẹ́rìí tí wọ́n ń forí ṣe fọrùn ṣe, tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́, tí wọ́n sì ń fara da onírúurú ìṣòro láti sin Jèhófà, àmọ́, ká sòótọ́, ó máa ń ni wá lára gan-an, inú wa kì í sì í dùn nígbà tí àwọn aláṣẹ ìjọba bá sọ pé kò ní ṣeé ṣe fún wa láti ṣe àpéjọ wa níbi tó yẹ ká ti ṣe é. Ó tún ń dí òmìnira wa lọ́wọ́ láti sin Ọlọ́run Olódùmarè lọ́nà ẹ̀yẹ.” Báwo làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ṣe kójú ìṣòro yìí?
Àpéjọ Inú Igbó Káàkiri Orílẹ̀-Èdè Náà
Ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé ọjọ́ tí wọ́n fẹ́ ṣe àpéjọ á ti wọlé dé tán kí àwọn aláṣẹ ìlú tó fagi lé àdéhùn nípa ibi tí wọ́n fẹ́ lò fún àpéjọ náà, ọjọ́ díẹ̀ ló máa kù fún àwọn tó ń ṣètò àpéjọ náà láti fi ṣètò ibòmíì fún àwọn tó fẹ́ wá sí àpéjọ náà. Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 2008, àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní Cheboksary lórílẹ̀-èdè Chuvash, ní láti ṣe àpéjọ àgbègbè wọn ní ibi gbalasa kan tí igi birch wà yí ká, tó sì dojú kọ Odò Volga. Iṣẹ́ kékeré kọ́ ni wọ́n máa ṣe kí wọ́n tó lè tún ibẹ̀ ṣe fún lílò. Lára àwọn ẹgbàá dín láàádọ́rin [1,930] tí wọ́n retí pé wọ́n máa wá sí àpéjọ náà, àwọn ẹgbàá dín ní ọ̀ọ́dúnrún [1,700] ni wọ́n máa sùn sí ilẹ̀ àpéjọ náà ní gbogbo ọjọ́ àpéjọ náà. Wọ́n nílò ilé ìwẹ̀ àti ọpọ́n ìfọwọ́ tó ní omi tútù àti gbígbóná, wọ́n nílò ilé ìgbọ̀nsẹ̀ àti iná mànàmáná. Wọ́n á sì tún se oúnjẹ fún gbogbo àwọn tó wá.
Àwọn arákùnrin ṣiṣẹ́ kára láti pèsè ohun tí wọ́n nílò yìí. Wọ́n rí àwọn káfíńtà, oníṣẹ́ iná mànàmáná àti ti omi ẹ̀rọ. Àwọn àádọ́ta dín nírínwó [350] Ẹlẹ́rìí Jèhófà yọ̀ǹda ara wọn láti ṣiṣẹ́, mẹ́rìnlá lára wọn gbé ilẹ̀ àpéjọ náà fún ọjọ́ mẹ́wàá. Wọ́n la pákó, wọ́n kó àwọn ègé koríko, wọ́n pàgọ́, wọ́n ṣe ibi ìwẹ̀ àti ibi ìgbọ̀nsẹ̀. Àwọn arákùnrin míì lọ sí àárín ìlú láti ra àwọn ohun tí wọ́n fẹ́ lò. Nítorí pé kò sí ibi tí wọ́n lè kó oúnjẹ tí wọ́n ti sè pa mọ́ sí, wọ́n pinnu pé àwọn á máa se oúnjẹ gbígbóná lẹ́ẹ̀mẹ́ta lójúmọ́ fún àwọn tó wá sí àpéjọ náà. Àwọn tó ń bójú tó ìṣètò ibi àpéjọ náà lọ gba àwọn tó máa se oúnjẹ fún àwọn tó wá sí àpéjọ náà. Ní àpapọ̀, àwọn ọgọ́rùn-ún márùn-ún [500] gbé àgọ́ tiwọn wá, àwọn àádọ́jọ [150] gba ilé sí ìtòsí ilẹ̀ àpéjọ náà, àwọn mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] sì sùn sórí koríko nínú ilé tí wọ́n ń kó àwọn ẹṣin sí, àwọn yòókù sùn sínú àgọ́ tí àwọn tó ṣètò àpéjọ náà pa sórí ilẹ̀ àpéjọ náà.
Nígbà tí àwọn tí wọ́n wá sí àpéjọ náà dé, wọ́n rí àga oníke tí wọ́n tò lọ súà. Wọ́n ṣe pèpéle méjì sí iwájú àwọn àga náà, wọ́n sì fi òdòdó ṣe ọ̀ṣọ́ sí i, ọ̀kan fún àwọn tó ń sọ èdè Rọ́ṣíà àti èkejì fún àwọn tó ń sọ èdè Chuvash. Gbogbo èèyàn ló gbádùn ẹ̀kọ́ Bíbélì náà, wọ́n sì mọyì iṣẹ́ bàǹtàbanta táwọn tó yọ̀ǹda ara wọn ṣe. Ọ̀kan lára àwọn tó ń se oúnjẹ sọ pé, “Tó bá jẹ́ pé mi ò fi ojú ara mi rí i ni, mi ò bá má gbà gbọ́ pé èèyàn lè rí ètò tó dáńgájíá tó sì dára bíi tiyín yìí!” Àwọn kan fi àpéjọ náà wé Àjọyọ̀ Àtíbàbà tí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì máa ń ṣe ní àkókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì.
Ní àwọn ìlú ńlá míì, ọjọ́ kan ṣoṣo péré ni
àwọn Ẹlẹ́rìí sábà máa fi ń wá ibòmíì tí wọ́n ti máa ṣe àpéjọ àgbègbè nítorí ìyípadà òjijì tó dé. Ohun tó ṣẹlẹ̀ nìyẹn nílùú Nizhniy Novgorod níbi tí àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn ti ṣiṣẹ́ tọ̀sán tòru lórí ilẹ̀ tí ẹnì kan yá wọn fún àpéjọ tí wọ́n fẹ́ ṣe. Wọ́n ní láti gé koríko, igi àti igbó tó wà níbẹ̀, wọ́n sì ní láti fọ́n oògùn apakòkòrò síbẹ̀ láti pa àwọn iná àti eèrà tó wà níbẹ̀. Nígbà táwọn tó wá ṣe àpéjọ máa fi dé síbẹ̀ ní ọjọ́ Friday, àwọn òṣìṣẹ́ tó yọ̀ǹda ara wọn ti kó àga oníke ẹgbẹ̀rún méjì [2,000] wá àtàwọn ilé ìgbọ̀nsẹ̀ mẹ́wàá, wọ́n sì gbé ọpọ́n ìfọwọ́ tó ní omi síbẹ̀. Wọ́n tún ṣe pèpéle, wọ́n gbé jẹnẹrétọ̀ àti ẹ̀rọ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ síbẹ̀. Arákùnrin kan sọ pé: “Ohun tó yani lẹ́nu jù lọ ni pé àwọn tó ṣiṣẹ́ tọ̀sán tòru náà kò gbà kí á máa kan sáárá sí wọn pé wọ́n jẹ́ akọni. Wọ́n ń bá a lọ láti máa fi ìrẹ̀lẹ̀ ṣiṣẹ́ fún àǹfààní àwọn èèyàn nígbà àpéjọ náà. Wọ́n lo gbogbo okun wọn kí ara bàa lè tu tọkùnrin tobìnrin tó wá sí àpéjọ náà kí wọ́n sì lè gbádùn ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.”Arákùnrin míì sọ pé: “Gbogbo wa la ṣiṣẹ́ pa pọ̀ ní ìṣọ̀kan. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìgbà àkọ́kọ́ nìyẹn tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yìí máa ṣètò àpéjọ ìta gbangba tí àkókò tí wọ́n ní láti fi ṣètò náà kò sì tó nǹkan, wọ́n ṣètò gbogbo nǹkan dáadáa kí ìpínyà ọkàn máa bàa fi bẹ́ẹ̀ sí nígbà tí àpéjọ náà bá ń lọ lọ́wọ́. Pẹ̀lú gbogbo ẹ̀ náà, kò rẹ̀ wá, ńṣe ló dà bíi pé Jèhófà fún ẹnì kọ̀ọ̀kàn wa ní ìyẹ́ tá a fi ń fò!”
Ẹ̀mí Ọlọ́run Ń Ṣiṣẹ́
Bí wọ́n ṣe yanjú ìṣòro ọ̀ràn àpéjọ ti mú kí ìṣọ̀kan túbọ̀ wà láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n jọ ṣe iṣẹ́ náà, ó sì máa ń fi hàn pé ẹ̀mí Ọlọ́run ń ṣiṣẹ́. Nílùú Smolensk, nígbà tí àpéjọ ku ọ̀la, ọ̀pọ̀ ilé tí wọ́n ti gbà pé káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà dé sí ni àwọn tó ni wọ́n sọ pé àwọn kò gbé e fún wọn mọ́. Alàgbà kan ròyìn pé: “Nígbà tí àwọn ọkọ̀ gbé àwọn tó wá sí àpéjọ náà dé ní aago kan òru, kò sí ilé tí wọ́n máa dé sí. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún nítorí kò sí ohun tí mo lè ṣe fún wọn. Mo gbàdúrà sí Jèhófà, mo sì bẹ̀ ẹ́ pé kó bá wa yanjú ìṣòro náà. Inú mi dùn gan-an pé lẹ́yìn wákàtí kan tá a ti ń wá ibòmíì tí wọ́n máa dé sí, a rí ilé fún gbogbo wọn! Ìyanu ló jẹ́ fún wa, ó sì tún ń fi hàn pé Jèhófà kì í fi àwọn olóòótọ́ sílẹ̀!” Ní àpéjọ kan tí wọ́n ṣe nínú igbó, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá ilé tí wọ́n máa dé sí lọ sí abúlé kan. Àwọn ará abúlé náà ní kí ẹgbẹ̀rún méjì [2,000] àwọn Ẹlẹ́rìí dé sí ilé àwọn nígbà àpéjọ yẹn, ìyẹn sì jẹ́ nítorí ìwà rere àwọn Ẹlẹ́rìí tó ń gbé agbègbè náà.
Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan sọ̀rọ̀, ó ní: “Pé a lè ṣe àpéjọ náà jẹ́ ẹ̀rí tó dájú pé ó ṣe pàtàkì ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà nínú ohun gbogbo.” Èyí sì ṣe pàtàkì gan-an, pàápàá nígbà tí àwọn èèyàn kan bá wá láti dá àpéjọ rú. Nílùú Novoshakhtinsk, àwọn àlùfáà Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ilẹ̀ Rọ́ṣíà àtàwọn alátakò wá síbẹ̀, wọ́n ń kọ orin, wọ́n sì ń fi makirofóònù wọn pariwo kí wọ́n lè bo ohùn ẹni tó ń bá àwùjọ sọ̀rọ̀ ní àpéjọ náà mọ́lẹ̀. Àmọ́ àwọn ọlọ́pàá kò jẹ́ kí wọ́n da àpéjọ náà rú. Nígbà tí obìnrin kan lára àwọn ẹlẹ́sìn Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì tí wọ́n wá da àpéjọ náà rú dákú nítorí ooru tó mú un, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbé e lọ sí ibi tí wọ́n ti ń gba Ìtọ́jú Pàjáwìrì ní àpéjọ náà, wọ́n sì tọ́jú rẹ̀. Ó yà á lẹ́nu gan-an pé àwọn Ẹlẹ́rìí lè tọ́jú òun.
Ohun Tí Wọ́n Rí Yà Wọ́n Lẹ́nu
Nítorí ọ̀ràn àwọn apániláyà tó gbòde kan, àwọn agbófinró máa ń wá sí gbogbo ibi tí ọ̀pọ̀ èèyàn bá ti ń ṣe àpéjọ ní orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, àwọn ará ìlú tí wọ́n fẹ́ ṣe ojúmìító náà máa ń wá síbẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan lára àwọn ọlọ́pàá adìgbòlùjà wá sí ibi àpéjọ kan tí wọ́n ṣe nínú igbó nílùú Volzhskiy. Ọ̀kan lára wọn sọ fóònù alágbèéká rẹ̀ nù nígbà tí àpéjọ náà ń lọ lọ́wọ́, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sì lọ bá a wá a ní Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Àwọn Ohun Tó Sọ Nù Tá A Rí He. Kété lẹ́yìn náà, ọ̀gá rẹ̀ fóònù rẹ̀, ó fẹ́ mọ̀ bóyá àwọn èèyàn fẹ́ dá ìjà sílẹ̀ ní àpéjọ náà. Ọlọ́pàá náà dáhùn pé: “Gbogbo nǹkan ń lọ lálàáfíà, ẹgbẹ̀rún márùn-ún [5,000] èèyàn ló wà níbí, kò sí ìjà. Kò sì sí ìwà ipá kankan níbí! Ìyẹn á jẹ́ kẹ́ ẹ̀ mọ̀ pé nǹkan àrà ọ̀tọ̀ ló ń ṣẹlẹ̀ níbí. Ẹ wò ó, mo sọ fóònù mi nù, wọ́n bá mi rí i, wọ́n sì dá a pa dà fún mi!”
Bí ilẹ̀ àpéjọ náà ṣe mọ́ tónítóní gan-an wú ẹ̀ṣọ́ kan lórí púpọ̀, ó sì yà á lẹ́nu pé bí àwọn ọmọdé ṣe pọ̀ tó níbí yìí, òun kò rí bébà súìtì kankan nílẹ̀. Ẹni tó yá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ilẹ̀ tí wọ́n fi ṣe àpéjọ náà pàdé ọlọ́pàá kan tí wọ́n ti fi tó létí pé àwọn ẹlẹ́sìn kan ti péjọ síbì kan. Ọkùnrin náà mú ọ̀gá ọlọ́pàá náà lọ sí àjà kẹta ilé rẹ̀, wọ́n dúró ní ọ̀dẹ̀dẹ̀ ilé náà tó dojú kọ ilẹ̀ àpéjọ náà, ó sọ pé: “Ìwọ náà, wò wọ́n! Ṣebí ìwọ náà rí wọn. O ò rí pé wọ́n wà létòlétò!” Ó ya ẹni tó ni ilẹ̀ náà lẹ́nu pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò mu ọtí tàbí sìgá, kò sì jọ pé ẹnì kankan lo ibẹ̀ nígbà tí wọ́n lọ, àní wọ́n kó gbogbo pàǹtí oúnjẹ wọn kúrò nílẹ̀. Ó sọ pé: “Ńṣe ló dà bíi Párádísè!”
Ìṣọ̀kan Wà Láàárín Àwọn Èèyàn Ọlọ́run
Lẹ́yìn àpéjọ kan táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe nínú igbó, ohun tí olórí abúlé kan rí mú kó sọ pé: “Mo rí i pé ẹ kì í kọjá àyè yín àmọ́ ẹ lágbára gan-an. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwa kì í kó àwọn èèyàn mọ́ra, ẹ̀yin ń mú kí àwọn èèyàn wà ní ìṣọ̀kan!” Àwọn èèyàn láti ibi gbogbo káàkiri orílẹ̀-èdè títóbi yìí, láti ìlú Kaliningrad títí dé ìyànníyàn ìlú Kamchatka ló mọyì ìṣọ̀kan tí wọ́n rí láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run ní àpéjọ wọn níbi tí wọ́n ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Kò sí bí ipò pàjáwìrì ṣe lè mú kí ètò àti ìwéwèé wọ́n yí pa dà tó, ohun kan wà tí kò lè yí pa dà, ìyẹn ni ọ̀wọ̀ tí wọ́n ní fún àwọn aláṣẹ ìjọba àtàwọn èèyàn.
Ipò yòówù kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà bá ara wọn, wọ́n ń bá a nìṣó láti máa fi ayọ̀ ṣe àpéjọ wọn níbi tí wọ́n ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Àdúrà wọn “nípa àwọn ọba àti gbogbo àwọn tí ó wà ní ipò gíga” ni pé, “kí [àwọn] lè máa bá a lọ ní gbígbé ìgbésí ayé píparọ́rọ́ àti dídákẹ́jẹ́ẹ́ pẹ̀lú fífọkànsin Ọlọ́run lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́ àti ìwà àgbà.”—1 Tímótì 2:2.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 27]
Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó yọ̀ǹda ara rẹ̀ láti ṣàtúnṣe ibi tí wọ́n ti máa ṣe àpéjọ ìta gbangba
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 29]
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ń bá a nìṣó láti máa gbé “ìgbésí ayé píparọ́rọ́ àti dídákẹ́jẹ́ẹ́ pẹ̀lú fífọkànsin Ọlọ́run lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́”
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn ṣiṣẹ́ pa pọ̀ láti gbá ilẹ̀ mọ́ kí àpéjọ tó bẹ̀rẹ̀ àti láti pèsè oúnjẹ fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn tó wá sí àpéjọ
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Gbogbo èèyàn ló gbádùn ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n sì mọyì iṣẹ́ bàǹtàbanta tí àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn ṣe