Ìṣòro Tó Ń Fi Hàn Pé Ìrètí Ń Bẹ
Ìṣòro Tó Ń Fi Hàn Pé Ìrètí Ń Bẹ
“Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò yóò wà níhìn-ín.”—2 TÍMÓTÌ 3:1.
ǸJẸ́ o ti gbọ́ nípa èyíkéyìí lára àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ búburú tó wà nísàlẹ̀ yìí rí tàbí kí ó ṣojú rẹ?
● Àìsàn gbẹ̀mígbẹ̀mí tó pa ọ̀pọ̀ èèyàn.
● Ìyàn tó ṣekú pa ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn.
● Ìsẹ̀lẹ̀, ìyẹn ìmìtìtì ilẹ̀ tó ṣekú pa ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn tó sì sọ ọ̀pọ̀ di aláìnílé.
Láwọn ojú ìwé tó tẹ̀ lé èyí, wàá kà nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó máa mú kó o ronú jinlẹ̀ nípa ipò tí ayé yìí wà. Wàá tún rí i pé, Bíbélì sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,” * ni irú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí á máa wáyé.
Àmọ́ ṣá o, a ò kọ àwọn àpilẹ̀kọ́ yìí láti mú kó o gbà pé, à ń gbé nínú ayé tó kún fún ìṣòro. Nítorí ó ṣeé ṣe kí ìwọ́ náà ti fojú ara rẹ rí i. Ìdí tá a fi kọ àwọn àpilẹ̀kọ yìí ni pé, kí wọ́n lè fún ẹ ní ìrètí. Wọ́n máa jẹ́ kó o mọ̀ pé, bí àsọtẹ́lẹ̀ mẹ́fà yìí ṣe ń ṣẹ fi hàn pé “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” kò ní pẹ́ dópin. Nínú ọ̀wọ́ àwọn àpilẹ̀kọ yìí, a tún máa ṣàgbéyẹ̀wò àwọn àtakò kan táwọn èèyàn ń ṣe sí ẹ̀rí pé a wà lọ́jọ́ ìkẹyìn, àwọn àpilẹ̀kọ yìí tún sọ ìdí tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ tó máa mú ká gbà pé ohun tó dára ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
^ Láti mọ ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba irú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú yìí, ka àpilẹ̀kọ náà, “Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Fàyè Gba Ìwà Ibi àti Ìjìyà?” lójú ìwé 16 àti 17 nínú ìwé ìròyìn yìí.