Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìsapá Àwọn Èèyàn Láti Fòpin sí Ipò Òṣì

Ìsapá Àwọn Èèyàn Láti Fòpin sí Ipò Òṣì

Ìsapá Àwọn Èèyàn Láti Fòpin sí Ipò Òṣì

ÀWỌN ọlọ́rọ̀ ti fòpin sí ipò òṣì nínú ìgbésí ayé tiwọn. Àmọ́ ṣá o, ìgbà gbogbo ni ìsapá láti fòpin sí ipò òṣì tí aráyé wà máa ń já sí pàbó. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé, àwọn ọlọ́rọ̀ ò fẹ́ káwọn èèyàn di ọlọ́rọ̀ bíi tiwọn tàbí kí ohunkóhun ṣàkóbá fún ọrọ̀ wọn. Sólómọ́nì Ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì sọ pé: “Wò ó! omijé àwọn tí a ń ni lára, ṣùgbọ́n wọn kò ní olùtùnú; ọ̀dọ̀ àwọn tí ń ni wọ́n lára sì ni agbára wà.”—Oníwàásù 4:1.

Ǹjẹ́ àwọn èèyàn jàǹkànjàǹkàn àtàwọn tó lẹ́nu láwùjọ lè mú káwọn èèyàn mú ipò òṣì kúrò láyé? Ọlọ́run mí sí Sólómọ́nì láti sọ pé: “Wò ó! asán ni gbogbo rẹ̀ àti lílépa ẹ̀fúùfù. Èyí tí a ṣe ní wíwọ́ ni a kò lè mú tọ́.” (Oníwàásù 1:14, 15) Ìsapá táwọn èèyàn ń ṣe lóde òní láti fòpin sí ipò òṣì jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ yìí.

Àbá Nípa Bí Gbogbo Èèyàn Ṣe Lè Lówó Lọ́wọ́

Ní ọgọ́rùn ọdún kọkàndínlógún, nígbà táwọn orílẹ̀-èdè díẹ̀ kan ń kó ọrọ̀ rẹpẹtẹ jọ látinú ìṣòwò àtàwọn ohun tí ilé iṣẹ́ ń mú jáde, ọ̀rọ̀ bí ipò òṣì ṣe máa dópin làwọn èèyàn jàǹkànjàǹkàn kan gbájú mọ́. Ǹjẹ́ wọ́n lè pín àwọn ohun àmúṣọrọ̀ ayé lọ́gbọọgba?

Àwọn kan rò pé, ìjọba àjùmọ̀ní tàbí ìjọba Kọ́múníìsì lè ṣe é tí kò fi ní sí ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ ní ayé, tí wọ́n yóò sì pín ọrọ̀ lọ́gbọọgba. Àmọ́ ṣá o, èrò yìí kò dùn mọ́ àwọn ọlọ́rọ̀ nínú rárá. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn ló nífẹ̀ẹ́ sí èrò náà pé, kí ẹnì kọ̀ọ̀kan sa gbogbo agbára rẹ̀ fún ìlọsíwájú ìlú, kí ẹni náà sì jàǹfààní nínú ohun tí ìlú pèsè. Ọ̀pọ̀ ló retí pé kí gbogbo orílẹ̀-èdè bẹ̀rẹ̀ sí í lo ètò ìjọba àjùmọ̀ní kí àwọn èèyàn lè máa gbé ìgbé ayé ìrọ̀rùn. Àwọn orílẹ̀-èdè kan tó lọ́rọ̀ lo apá kan lára ètò ìjọba àjùmọ̀ní, wọ́n sì gbé ètò ìdẹ̀rùn kalẹ̀ fáwọn ará ìlú nínú èyí tí wọ́n ti ṣèlérí pé àwọn yóò bójú tó wọn ní gbogbo ọjọ́ ayé wọn. Wọ́n sọ pé àwọn ti fòpin sí ipò òṣì tó burú jáì láàárín àwọn èèyàn àwọn.

Àmọ́ ṣá o, ètò ìjọba àjùmọ̀ní kò tíì mú kí àwọn èèyàn jẹ́ ẹni tí kò mọ tara wọn nìkan gẹ́gẹ́ bó ti ṣèlérí. Èrò pé kí gbogbo èèyàn máa ṣiṣẹ́ fún àǹfààní ará ìlú kí wọ́n má mọ tara wọn nìkan ti já sí pàbó. Inú bí àwọn kan sí bí wọ́n ṣe ń pèsè ohun tí àwọn tálákà nílò, wọ́n sọ pé ohun tí wọ́n ń rí gbà ti mú kí àwọn kan ya ọ̀lẹ. Èyí fi hàn pé òótọ́ lọ̀rọ̀ Bíbélì tó sọ pé: “Kò sí olódodo kankan ní ilẹ̀ ayé tí ń ṣe rere tí kì í dẹ́ṣẹ̀. . . . Ọlọ́run tòótọ́ ṣe aráyé ní adúróṣánṣán, ṣùgbọ́n àwọn fúnra wọn ti ṣàwárí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwéwèé.”—Oníwàásù 7:20, 29.

Ohun míì tí wọ́n gbé ìrètí wọn kà ni wọ́n ń pè ní, ìgbésí ayé bíi tàwọn ará Amẹ́ríkà, ìyẹn èrò pé gbogbo èèyàn tó fẹ́ ṣiṣẹ́ àṣekára yóò di ọlọ́rọ̀. Yíká ayé, ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ló ń lo àwọn ìlànà, bí ìjọba tiwa-n-tiwa, ṣíṣòwò fàlàlà lábẹ́ ìjọba àti ṣíṣòwò káàkiri ayé láìsí ìdílọ́wọ́, èyí tí wọ́n rò pé ó sọ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà di ọlọ́rọ̀. Àmọ́ ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ni kò lè ṣàṣeyọrí bíi ti ilẹ̀ Amẹ́ríkà, ìdí ni pé, kì í ṣe ètò ìṣèlú nìkan ló mú kí àwọn ará Amẹ́ríkà ti Àríwá di ọlọ́rọ̀. Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ohun àmúṣọrọ̀ táwọn orílẹ̀-èdè yìí ní àti bó ṣe rọrùn fún wọn láti ṣòwò níbi gbogbo káàkiri ayé ló mú kí wọ́n di ọlọ́rọ̀. Yàtọ̀ sí pé àwọn èèyàn ń di ọlọ́rọ̀ látinú ètò ìṣòwò ayé tó kún fún ìfagagbága, ó tún ń mú kí àwọn èèyàn pàdánù ohun ìní wọn, tí wọ́n á sì di ẹdun arinlẹ̀. Ǹjẹ́ àwọn orílẹ̀-èdè tó jẹ́ ọlọ́rọ̀ lè ṣèrànwọ́ fún àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣì jẹ́ òtòṣì?

Ṣé Ètò Marshall Ló Máa Fòpin sí Ipò Òṣì?

Lẹ́yìn ogun Àgbáyé Kejì, ṣìbáṣìbo bá ilẹ̀ Yúróòpù, ebi sì fojú ọ̀pọ̀ èèyàn rí màbo. Inú ìjọba ilẹ̀ Amẹ́ríkà kò tún dùn sí bí ètò ìjọba àjùmọ̀ní ṣe ń gbilẹ̀ ní ilẹ̀ Yúróòpù. Nítorí náà, ọdún mẹ́rin ni wọ́n fi ń fi òbítíbitì owó ṣèrànwọ́ láti ṣàtúnṣe àwọn ilé iṣẹ́ àti iṣẹ́ àgbẹ̀ láwọn orílẹ̀-èdè tó bá gbà láti tẹ̀ lé ìlànà ilẹ̀ Amẹ́ríkà. Wọ́n gbà pé Ètò Marshall kẹ́sẹ járí, ìyẹn ètò tí wọ́n ṣe láti ṣàtúnṣe ilẹ̀ Yúróòpù. Ní Ìwọ̀ Oòrùn ilẹ̀ Yúróòpù, ìsapá ilẹ̀ Amẹ́ríkà ń gbilẹ̀, èyí sì mú kí ipò òṣì fẹ́rẹ̀ kásẹ̀ nílẹ̀ níbẹ̀. Ṣé èyí ni ọ̀nà láti gbà fòpin sí ipò òṣì kárí ayé?

Àṣeyọrí tí Ètò Marshall ṣe yìí mú kí ìjọba ilẹ̀ Amẹ́ríkà ṣèrànwọ́ láti mú kí ìdàgbàsókè bá iṣẹ́ àgbẹ̀, ọ̀ràn ìlera, ẹ̀kọ́ ìwé àti ètò ìrìnnà láwọn orílẹ̀-èdè tó jẹ́ òtòṣì. Ilẹ̀ Amẹ́ríkà gbà pé, ìdí táwọn fi ṣe àwọn nǹkan yìí jẹ́ láti ṣe ilẹ̀ àwọn láǹfààní. Àwọn orílẹ̀-èdè míì náà fẹ́ fa ojú àwọn èèyàn mọ́ra, èyí sì mú kí wọ́n ṣèrànwọ́ fún àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ òkèèrè. Lẹ́yìn ọgọ́ta ọdún tí wọ́n ti ná ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ìlọ́po owó tí wọ́n ná sórí Ètò Marshall, ohun tó jẹ́ àbájáde rẹ̀ kò fún wọn láyọ̀ rárá. Lóòótọ́, àwọn orílẹ̀-èdè tó jẹ́ òtòṣì tẹ́lẹ̀ ní ọrọ̀ rẹpẹtẹ, ní pàtàkì, Ìlà Oòrùn Éṣíà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìrànwọ́ yìí tí mú kí ikú àwọn ọmọdé dín kù gan-an, tí ọ̀pọ̀ ọmọ sì rí ẹ̀kọ́ ìwé gbà, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ló ṣì jẹ́ òtòṣì paraku.

Ìdí Tí Ìrànlọ́wọ́ Láti Ilẹ̀ Òkèèrè Kò Fi Kẹ́sẹ Járí

Ṣíṣèrànwọ́ fún àwọn orílẹ̀-èdè tó jẹ́ òtòṣì nira gan-an ju ṣíṣèrànwọ́ fún àwọn orílẹ̀-èdè ọlọ́rọ̀ tí ogun bà jẹ́. Ilẹ̀ Yúróòpù ní àwọn ilé iṣẹ́, ètò ìṣòwò àti ètò ìrìnnà tẹ́lẹ̀. Àtúnṣe ni ọrọ̀ ajé wọn kàn nílò. Àmọ́ bí àwọn orílẹ̀-èdè tó jẹ́ òtòṣì bá tiẹ̀ rí ìrànwọ́ gbà láti ní àwọn ọ̀nà, àwọn ilé ẹ̀kọ́ àtàwọn ilé ìwòsàn tó dáa, àwọn èèyàn á ṣì jẹ́ òtòṣì paraku, nítorí pé àwọn orílẹ̀-èdè náà kò ní iṣẹ́ àtàwọn ohun àmúṣọrọ̀, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní àwọn ọ̀nà táwọn oníṣòwò máa ń gbà.

Àwọn ìṣòro tó ń fa ipò òṣì àtàwọn ìṣòro tí ipò òṣì ń fà lágbára gan-an, wọ́n sì ṣòro láti yanjú. Bí àpẹẹrẹ, àrùn máa ń fa ipò òṣì, ipò òṣì sì máa ń fa àrùn. Àwọn ọmọ tí kò jẹunre kánú kì í ní okun, ọpọlọ wọn kì í sì í jí pépé, èyí kì í sì í jẹ́ kí wọ́n lè tọ́jú àwọn ọmọ wọn nígbà tí àwọn fúnra wọn bá dàgbà. Bákan náà, nígbà tí àwọn orílẹ̀-èdè tó lọ́rọ̀ bá fi ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ ṣèrànwọ́ fún àwọn orílẹ̀-èdè tó jẹ́ òtòṣì, àwọn àgbẹ̀ àtàwọn tó ń ta oúnjẹ kì í rí iṣẹ́ ṣe mọ́, nípa bẹ́ẹ̀, àwọn èèyàn yóò túbọ̀ tòṣì. Fífi owó ránṣẹ́ sí àwọn ìjọba láwọn orílẹ̀-èdè tó jẹ́ òtòṣì lè fa ìṣòro míì, wọ́n lè tètè jí irú àwọn owó bẹ́ẹ̀ kó, tí àwọn èèyàn á sì tipa bẹ́ẹ̀ túbọ̀ di òtòṣì. Kò sí àní-àní pé, ìrànwọ́ láti ilẹ̀ òkèèrè kò kẹ́sẹ járí nítorí pé kò lè yanjú ohun tó ń fa ipò òṣì.

Ohun Tó Ń Fa Ipò Òṣì

Ohun tó ń fa Ipò òṣì paraku ni wíwá tí àwọn orílẹ̀-èdè, àwọn ìjọba àtàwọn èèyàn ń wá ire tara wọn nìkan. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ìjọba láwọn orílẹ̀-èdè tó lọ́rọ̀ kì í fi bẹ́ẹ̀ ṣe ohun tó máa fòpin sí ipò òṣì tí aráyé wà, nítorí pé ìbò ni wọ́n fi yàn wọ́n sípò, wọ́n sì gbọ́dọ̀ tọ́jú àwọn tó dìbò fún wọn. Nítorí náà, wọ́n kò jẹ́ kí àwọn àgbẹ̀ tó wà láwọn orílẹ̀-èdè tó jẹ́ òtòṣì ta ire oko wọn fún àwọn orílẹ̀-èdè tó jẹ́ ọlọ́rọ̀ kí ọjà àwọn àgbẹ̀ tó wà láwọn orílẹ̀-èdè tó jẹ́ ọlọ́rọ̀ má bàa kùtà. Bákan náà, àwọn alákòóso láwọn orílẹ̀-èdè ọlọ́rọ̀ máa ń pèsè owó ìrànwọ́ fún àwọn àgbẹ̀ wọn, kí ọjà wọ́n lè tètè tà ju ti àwọn àgbẹ̀ tó wà láwọn orílẹ̀-èdè tó jẹ́ òtòṣì.

Ó wá ṣe kedere pé ohun tó ń fa ipò òṣì jẹ́ àfọwọ́fà ẹ̀dá, ìyẹn wíwá táwọn èèyàn àti ìjọba ń wá ire tara wọn nìkan. Sólómọ́nì tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ Bíbélì sọ ọ̀rọ̀ náà báyìí, ó ní: “Ènìyàn ti jọba lórí ènìyàn sí ìṣeléṣe rẹ̀.”—Oníwàásù 8:9.

Nítorí náà, ǹjẹ́ ìrètí wà pé ipò òṣì máa dópin? Ǹjẹ́ ìjọba èyíkéyìí lè yí ìwà àwọn èèyàn pa dà?

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]

Òfin Tí Ọlọ́run fún Wọn Láti Borí Ipò Òṣì

Jèhófà Ọlọ́run fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àtijọ́ ní àwọn òfin kan, tó jẹ́ pé tí wọ́n bá ṣègbọràn sí àwọn òfin náà, wọn kò ní di òtòṣì paraku. Òfin sọ pé kí gbogbo ìdílé gba ogún tó jẹ́ ilẹ̀, àyàfi ẹ̀yà Léfì tí wọ́n jẹ́ àlùfáà nìkan ni wọn kò ní gbà. Ogún ìdílé wọn kì í kúrò lọ́wọ́ wọn, nítorí pé wọn kò gbọ́dọ̀ ta ilẹ̀ wọn fún ẹlòmíì títí lọ gbére. Wọ́n gbọ́dọ̀ dá àwọn ilẹ̀ tí wọ́n ti tà pa dà fún ẹni tó ni ilẹ̀ náà tàbí ìdílé rẹ̀ ní òpin àádọ́ta [50] ọdún. (Léfítíkù 25:10, 23) Tó bá ṣẹlẹ̀ pé àìsàn, jàǹbá tàbí ìwà ọ̀lẹ mú kí ẹnì kan ta ilẹ̀ rẹ̀, yóò gba ilẹ̀ náà pa dà ní ọdún Júbílì láìsanwó. Nípa bẹ́ẹ̀, kò ní sí ìdílé tó máa di ìran òtòṣì.

Ohun míì tó fi àánú hàn tí Òfin Ọlọ́run pèsè ni pé kí ẹnì kan tí àjálù bá ta ara rẹ̀ sí oko ẹrú. Onítọ̀hún á kọ́kọ́ gba owó náà láti fi san gbèsè tó jẹ. Tí kò bá ra ara rẹ̀ pa dà kí ọdún keje tó pé, wọ́n á dá a sílẹ̀ lọ́dún keje náà, wọ́n á sì fún un ní irúgbìn àti ohun ọ̀sìn kó bàa lè bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àgbẹ̀ pa dà. Yàtọ̀ síyẹn, tí ọmọ Ísírẹ́lì kan tó jẹ́ tálákà bá yá owó, Òfin kò fàyè gbà á kí wọ́n gba owó èlé lọ́wọ́ rẹ̀. Òfin tún pá a láṣẹ pé kí wọ́n má ṣe kórè etí pápá wọn, kí àwọn tálákà bàa lè pèéṣẹ́ níbẹ̀. Nípa báyìí, ọmọ Ísírẹ́lì kankan kò ní ṣagbe.—Diutarónómì 15:1-14; Léfítíkù 23:22.

Àmọ́, ìtàn fi hàn pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kan di òtòṣì. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì kò ṣègbọràn sí Òfin Jèhófà. Àbájáde èyí sì ni pé, bíi ti ọ̀pọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè, àwọn kan lára wọn di ọlọ́rọ̀ nítorí pé wọ́n ní ilẹ̀, tí àwọn kan sì di tálákà nítorí pé wọn kò ní ilẹ̀. Ipò òṣì wà láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nítorí àwọn kan lára wọn kò pa Òfin Ọlọ́run mọ́, wọ́n sì ń wá ire ti ara wọn nìkan.—Mátíù 22:37-40.