Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: “Títàpá sí ọ̀pá kẹ́sẹ́ mú kí ó nira fún ọ”?—Ìṣe 26:14.
▪ Ní àkókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì, àwọn àgbẹ̀ máa ń fi kẹ́sẹ́ darí àwọn ẹran wọn nígbà táwọn ẹran náà bá ń túlẹ̀. Kẹ́sẹ́ jẹ́ igi kan tí ẹnu rẹ̀ rí ṣóṣóró, ó gùn tó nǹkan bí ẹsẹ̀ bàtà mẹ́jọ. Irin ẹlẹ́nu ṣóṣóró wà ní ẹnu igi náà lápá kan. Bí ẹran náà bá fara gbá kẹ́sẹ́ náà, ńṣe ló máa ṣe ara rẹ̀ léṣe. Irin pẹlẹbẹ tí wọ́n lè fi yọ ìdọ̀tí, amọ̀ tàbí àwọn ewé tó há sẹ́nu ohun ìtúlẹ̀ ló sábà máa ń wà lápá kejì kẹ́sẹ́ náà.
Nígbà míì, wọ́n máa ń lo kẹ́sẹ́ láti fi jà. Ṣámúgárì tó jẹ́ onídàájọ́ àti jagunjagun ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì fi “ọ̀pá kẹ́sẹ́ màlúù” pa ẹgbẹ̀ta [600] ọmọ Filísínì—Àwọn Onídàájọ́ 3:31.
Ìwé Mímọ́ tún lo ohun èlò yìí lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. Bí àpẹẹrẹ, Ọba Sólómọ́nì sọ pé, ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n èèyàn lè “dà bí ọ̀pá kẹ́sẹ́ màlúù,” tó ń darí ẹni láti ṣe ìpinnu tó tọ́.—Oníwàásù 12:11.
Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, òun náà fi kẹ́sẹ́ ṣe àpèjúwe kan. Ó sọ fún Sọ́ọ̀lù tó ń ṣe inúnibíni sí àwọn Kristẹni pé, kó jáwọ́ “títàpá sí ọ̀pá kẹ́sẹ́.” Ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ ká rí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí ẹran kan tó kọ̀ láti ṣègbọràn sí ẹni tó ń darí rẹ̀. Àmọ́, Sọ́ọ̀lù hùwà ọgbọ́n nítorí pé ó ṣègbọràn sí ìmọ̀ràn Jésù, ó sì yí ọ̀nà ìgbésí ayé rẹ̀ pa dà, ó wá di àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù.
Báwo làwọn Júù ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ṣe ń mọ iye aago tó lù nígbà tí ilẹ̀ bá ti ṣú?
▪ Ní ojúmọmọ, òjìji làwọn Júù ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní fi máa ń mọ iye aago tó lù. Àmọ́, tí kùrukùru bá ṣú bo oòrùn tàbí ti ilẹ̀ bá ti ṣú, wọ́n máa ń lo ohun èlò kan tó ń lo omi láti fi mọ iye aago tó lù. Yàtọ̀ sí àwọn Júù, àwọn ará Íjíbítì, Páṣíà, Gíríìsì àti Róòmù ayé àtijọ́ náà máa ń lo ohun èlò yìí.
Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, The Jewish Encyclopedia, sọ pé, ìwé Míṣínà àti Támọ́dì sọ nípa ohun èlò yìí, “oríṣiríṣi orúkọ ni wọ́n pè é, bóyá láti fi ìyàtọ̀ sírú èyí tó jẹ́, àmọ́ ṣá o, iṣẹ́ kan náà ni gbogbo wọn máa ń ṣe, omi rọra ń kán díẹ̀díẹ̀ nínú ohun èlò náà, ohun tó sì jẹ́ ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n fi pe ohun èlò náà nìyẹn.”
Báwo ni ohun èlò yìí ṣe ń ṣiṣẹ́? Omi máa ń ṣàn jáde nísàlẹ̀ ohun kan tí wọ́n bu omi sí, á wá gba inú ihò kékeré kan lọ sínú ohun míì. Ẹni tó bá wo omi yìí lè wọn omi náà, ibi tí omi náà bá dé nínú ohun tí wọ́n bù ú sí lókè tàbí ohun tó ń kán sí nísàlẹ̀ lẹni náà máa fi mọ iye aago tó lù.
Irú aago yìí làwọn ọmọ ogun Róòmù máa ń lò ní ibùdó wọn láti fi mọ ìṣọ́ tí wọ́n wà ní òru. Wọ́n máa ń fun kàkàkí láti fi hàn pé, àwọn ti bọ́ sí ìṣọ́ míì lóru. Ẹni tó bá gbọ́ ìró kàkàkí yìí máa ń mọ ìgbà tí wọ́n kúrò ní ìṣọ́ kan sí òmíràn, ìyẹn ìgbà tí ọ̀kọ̀ọ̀kan ìṣọ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin bẹ̀rẹ̀ àti ìgbà tó parí.—Máàkù 13:35.