Olivétan Ọ̀dọ́mọdé Onírẹ̀lẹ̀ Tó Túmọ̀ Bíbélì sí Èdè Faransé
Olivétan Ọ̀dọ́mọdé Onírẹ̀lẹ̀ Tó Túmọ̀ Bíbélì sí Èdè Faransé
Ọjọ́ kẹtàlá oṣù September ọdún 1540 ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé. Àwọn ọlọ́pàá wá ṣàyẹ̀wò inú ilé Collin Pellenc. Wọ́n rí àwọn ìwé tí wọ́n fura sí ní yàrá inú lọ́hùn-ún, ìwé ńlá kan sì wà lára àwọn ìwé náà. Lójú ìwé kejì ìwé náà, àwọn ọ̀rọ̀ kan wà níbẹ̀ tó sọ pé: ‘P. Robert Olivetanus, ọ̀dọ́mọdé onírẹ̀lẹ̀ tó jẹ́ àtúmọ̀ èdè.’ Bíbélì àwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo ni! Wọ́n mú Collin Pellenc, wọ́n ní ó jẹ́bí nítorí pé ohun tó gbà gbọ́ kò tọ̀nà, wọ́n sì dáná sún un láàyè.
NÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ Faransé ní àkókò yẹn àti ní àwọn ibòmíì nílẹ̀ Yúróòpù, Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ń lépa àwọn Alátùn-únṣe Ìsìn tó ń ta kò wọ́n, láti fòpin sí ẹ̀kọ́ tí wọ́n kà sí “eléwu,” èyí tí àwọn alátùn-únṣe náà ń kọ́ni. Ọ̀gbẹ́ni Guillaume Farel tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn alátùn-únṣe náà ní ìtara gan-an, ó pinnu pé òun máa mú kí gbogbo àwọn tó ń sọ èdè Faransé tẹ́wọ́ gba èrò Martin Luther, ẹni tó jẹ́ aṣáájú nínú àwọn tó ń ta ko ẹ̀sìn Kátólíìkì. Ọ̀gbẹ́ni Farel, tó wá láti Ìpínlẹ̀ Dauphiné ní gúùsù ìwọ̀ oòrùn orilẹ̀-èdè Faransé mọ̀ pé ọ̀nà tó dára jù lọ láti gbà yí èrò àwọn èèyàn pa dà ni pé kí wọ́n ṣe ìwé jáde, kí àwọn èèyàn sì kà á. Kí ohun tó sọ yìí tó lè ṣeé ṣe, ó nílò Bíbélì, ìwé ìléwọ́ àtàwọn ìwé mìí. Àmọ́ ta ló máa gbé owó sílẹ̀ fún iṣẹ́ náà? Ó wá ìràlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ àwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo, ìyẹn àwùjọ ẹ̀sìn kan tí wọ́n ń wàásù ohun tó wà nínú Bíbélì.
Àpérò Tó Wáyé ní Chanforan
Ní àárín oṣù September ọdún 1532, àwọn barbe, ìyẹn àwọn pásítọ̀ ẹ̀sìn Waldo ṣe àpérò kan ní Chanforan, abúlé kékeré kan nítòsí Turin, ní Ítálì. Àjọṣe ti wà láàárín àwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo àti àwọn aṣáájú Alátùn-únṣe Ìsìn fún ọdún mélòó kan. Nítorí náà, wọ́n pe ọ̀gbẹ́ni Farel àtàwọn ọkùnrin kan wá síbi àpérò náà. Àwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo fẹ́ mọ̀ bóyá ohun táwọn ń kọ́ni bá ẹ̀kọ́ Luther àti ti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ mu. *
Níbi àpérò tó wáyé ní Chanforan yẹn, bí ọ̀rọ̀ ṣe dá ṣáṣá lẹ́nu ọ̀gbẹ́ni Farel mú káwọn tó wà níbẹ̀ gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbọ́. Nígbà tí àwọn pásítọ̀ ẹ̀sìn Waldo fi ògbólógbòó Bíbélì tí wọ́n fọwọ́ kọ ní èdè ìbílẹ̀ wọn han ọ̀gbẹ́ni Farel, ó jẹ́ kí wọ́n rí i pé ó yẹ kí wọ́n gbé owó sílẹ̀ láti fi tẹ Bíbélì ní èdè Faransé. Bíbélì tí wọ́n máa ṣe yìí máa yàtọ̀ sí èyí tí ọ̀gbẹ́n Lefèvre d’Étaples túmọ̀ látinú èdè Látìn lọ́dún 1523, nítorí látinú èdè Hébérù àti Gíríìkì ni wọ́n ti máa túmọ̀ Bíbélì tuntun yìí. Àmọ́, ta ló dáńgájíá láti bójú tó irú iṣẹ́ yìí?
Ọ̀gbẹ́ni Farel mọ ẹni tó lè ṣe iṣé náa. Orúkọ ẹni náà ni Pierre Robert, àmọ́, wọ́n tún mọ̀ ọ́n sí Olivétan, * ìpínlẹ̀ Picardy ní àríwá orílẹ̀-èdè Faransé ni wọ́n ti bí olùkọ́ tó jẹ́ ọ̀dọ́ yìí. Ọ̀gbẹ́ni Olivétan, tó jẹ́ ẹbí John Calvin, wà lára àwọn tó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àtúnṣe sí ìsìn, ó sì jẹ́ ẹni tó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé. Ó tún lo àwọn ọdún mélòó kan ní Strasbourg láti fi kẹ́kọ̀ọ́ àwọn èdè tí wọ́n fi kọ Bíbélì.
Bíi ti ọ̀gbẹ́ni Farel àti ọ̀pọ̀ àwọn míì, Olivétan náà lọ fi ara pa mọ́ sí orílẹ̀-èdè Switzerland. Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ bẹ̀ ẹ́ pé kó gba iṣẹ́ ìtúmọ̀ èdè náà, kí ó sì ṣe é. Lẹ́yìn tó ti kọ̀ bí ìgbà mélòó kan pé òun kò ní lè ṣe iṣẹ́ náà, nígbà tó yá, ó gbà pé òun á túmọ̀ Bíbélì náà “látinú èdè Hébérù àti Gíríìkì sí èdè Faransé.” Bákan náà, nínú ẹgbẹ̀rin [800] nǹkan ọ̀ṣọ́ góòlù tí wọ́n fẹ́ fi ra àwọn ohun tí wọ́n fẹ́ fi tẹ̀ ìwé náà, àwọn Ọmọlẹyìn Waldo fi góòlù ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] sílẹ̀, ìye ńlá sì nìyẹn jẹ́!
Ohùn Tí Kò Dùn àti Orin Tó Dùn
Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1534, Olivétan lọ sí àdádó kan lóri àwọn òkè, ó sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀, ó kó “àwọn olùkọ́ tí kò lè sọ̀rọ̀” sọ́dọ̀, ìyẹn àwọn ìwé rẹ̀. Kò sí ọ̀mọ̀wé òde òní tí kò ní wù láti ní irú àwọn ìwé tí Olivétan ní. Lára àwọn ìwé náà ni Bíbélì èdè Síría, Gíríìkì àti ti Látìn, àwọn ìwé tí wọ́n kọ àlàyé àwọn rábì sí, àwọn ìwé gírámà èdè kálídíà àti ọ̀pọ̀ ìwé míì. Èyí tó ṣe pàtàkì jù lọ ni pé, ó ní Bíbélì èdè Hébérù tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe, tí wọ́n fi èdè Hébérù ìpilẹ̀ṣẹ̀ kọ ní ìlú Venice.
Inú Bíbélì èdè Faransé tí Lefèvre d’Étaples ṣe ni Olivétan ti rí ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ tó fi ṣe ìtúmọ̀ apá Bíbélì táwọn èèyàn ń pè ní Májẹ̀mú Tuntun, àmọ́ ṣá o, ọ̀pọ̀ ìgbà ló tún lo ohun tó rí nínú Bíbélì èdè Gíríìkì tí Erasmus tó jẹ́ ọ̀mọ̀wé Dutch ṣe. Olivétan lo àwọn ọ̀rọ̀ tí kò ti èrò àwọn Kátólíìkì lẹ́yìn. Bí àpẹẹrẹ, ó lo “alábòójútó” dípò “bíṣọ́ọ́bù,” “àṣírí” dípò “ohun ìjìnlẹ̀,” àti “ìjọ” dípò “ṣọ́ọ̀ṣì.”
Nígbà tí Olivétan ń túmọ̀ Bíbélì táwọn èèyàn mọ̀ sí Májẹ̀mú Láéláé, bó ṣe ṣe é ni pé, ó lo ọ̀rọ̀ Hébérù ìpilẹ̀ṣẹ̀ kan fún ọ̀rọ̀ Fáransé kan. Ó ṣàwàdà pé ó ṣoro láti túmọ̀ èdè Hébérù sí èdè Faransé, ó ní, ńṣe ló dà bíi “kéèyàn máa fi ohùn tí kò dùn kọ orin tó dùn”!
Nínú ọ̀rọ̀ èdè Hébérù, Olivétan rí orúkọ Ọlọ́run bó ṣe wà ní lẹ́tà èdè Hébérù mẹ́rin tó sì fara hàn ní ọ̀pọ̀ ẹ̀gbẹ̀rún ìgbà. Ó gbà láti túmọ̀ rẹ̀ sí “Ẹni ayérayé,” ohun tó túmọ̀ rẹ̀ sí yìí ló wá wọ́pọ̀ nínu Bíbélì Faransé táwọn Pùròtẹ́sítáǹtì ṣe. Ní àwọn ibi mélòó kan, ó lo “Jèhófà,” pàápàá nínú Ẹ́kísódù 6:3.
Ó jọni lójú pé ní February 12, ọdún 1535, ìyẹn lẹ́yìn nǹkan bí ọdún kan, atúmọ̀ èdè yìí sọ pé òun ti parí iṣẹ́ náà! Níwọ̀n tó ti sọ pé “òun fúnra òun lòun dá ṣe [ìtumọ̀] náà,” ẹ̀rí fi hàn pé ọdún 1534 sí 1535 ló parí iṣẹ́ bàǹtàbanta náà. Atúmọ̀ èdè náà fi ìrẹ̀lẹ̀ sọ pé, “Mo ti ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe.” Gbogbo ohun tó kù báyìí ni pé kí wọ́n tẹ Bíbélì èdè Faransé tó kọ́kọ́ máa jáde, èyí tí wọ́n túmọ̀ látinú èdè Hébérù àti Gíríìkì ìpilẹ̀ṣẹ̀.
Ní Ibi Iṣẹ́ Pirot
Ọ̀ràn náà wá kan ọ̀gbẹ́ni Pierre de Wingle, tí wọ́n tún ń pè ní Pirot Picard, tó ń tẹ̀wé fún àwọn Alátùn-únṣe Ìsìn, tó sì tún jẹ́ ọ̀rẹ́ Farel. Lẹ́yìn tí Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ti lé e kúrò nílùú Lyon, ó lọ ń gbé ní Neuchâtel, lórílẹ̀-èdè Switzerland, lọ́dún 1533. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í fi owó tí wọ́n rí látọ̀dọ̀ àwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo tẹ ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ìwé “tó ń ta ko ẹ̀sìn.” Bí àpẹẹrẹ, ibi iṣẹ́ rẹ̀ ni wọ́n ti tẹ àwọn ìwé tó sọ pé Máàsì kò dára, lára àwọn ìwé náà sì dé ọ̀dọ̀ Ọba Francis Kìíní ti ilẹ̀ Faransé tó jẹ́ Kátólíìkì.
Ọ̀gbẹ́ni de Wingle wá ṣe bó ṣe ń ṣe, ó mú kí àwọn ẹ̀rọ ìtẹ̀wé rẹ̀ wà ní sẹpẹ́, àmọ́ lákòókò yìí, Bíbélì ló máa tẹ̀! Láti mú kí iṣẹ́ náà yá, ó ní kí
ọkùnrin mẹ́rin tàbí márùn-ún máa lo ọ̀kọ̀ọ̀kan ẹ̀rọ ìtẹ̀wé méjì náà, kí wọ́n máa to àwọn lẹ́tà ìtẹ̀wé náà kí wọ́n sì máa tẹ abala àwọn ìwé náà. Níkẹyìn, “ní June 4, ọdún 1535” ọ̀gbẹ́ni de Wingle buwọ́ lu Bíbélì Olivétan ní ojú ìwé kejì rẹ̀ pé òun ti tẹ̀ ẹ́ parí. Nínú ọ̀rọ̀ ìṣáájú rẹ̀, atúmọ̀ èdè náà sọ pé ìwé náà wà fún àwọn gbáàtúù onígbàgbọ́ tí “ẹ̀kọ́ àtọwọ́dọ́wọ́ tí kò wúlò” ti kó “ìnira àti ẹ̀dùn ọkàn bá.”Gbogbo nǹkan tí wọ́n retí pé kó wà nínú Bíbélì náà ló pé síbẹ̀. Òpó méjì, àwọn orí àtàwọn ìpínrọ̀ àti bí ìwe náà ṣe dùn-ún kà ló fi kún ẹwà ọ̀rọ̀ inú Bíbélì Faransé náà. Àwọn àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé fi hàn pé atúmọ̀ èdè náà dáńgájíá, ó sì ṣiṣẹ́ tó peyé. Àwọn àlàyé ọ̀rọ̀ ìṣáájú inú iwé náà, àwọn àfikún, àwọn àtẹ àtàwọn ewì inú rẹ̀ tún mú kí ìwé náà fani mọ́ra. Ní ìparí ìwé náà, àwọn ọ̀rọ̀ ewì kúkúrú kan wà níbẹ̀ tó sọ pé “Àwọn Ọmọ ẹ́yìn Waldo tí wọ́n máa ń wàásù Ìhìn Rere, ló ń mú ìwé tó jẹ́ ìṣúra yìí lọ sọ́dọ̀ gbogbo èèyàn kí wọ́n lè rí i kà.”
Ojúlówó Ìwé Tí Ó Kùtà
Bíbélì Olivétan tí wọ́n fìgbà kan rí bẹnu àtẹ́ lù ti wá di ohun táwọn èèyàn ń gbóríyìn fún pé ó jẹ́ ojúlówó ìwé tí ọ̀mọ̀wé kọ. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì náà jẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n lò fún ọgọ́rùn-ún ọdún mẹ́ta láti fi túmọ̀ àwọn Bíbélì tí àwọn ẹ̀sìn tó ya kúrò lára Kátólíìkì ṣe.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ẹ̀dà Bíbélì Olivétan ni wọ́n tẹ̀ jáde, àwọn èèyàn kò rà wọ́n dáadáa. Ìdí ni pé kò sí ọ̀nà tí wọ́n máa gbà pín wọn kiri fún títà àti pé ó bọ́ sí ìgbà tí èdè Fraransé ń yára yí pa dà. Yàtọ̀ síyẹn, kò rọ́rùn fún àwọn oníwàásù tó ń rìnrìn àjò àtàwọn tó ń kàwé náa ní bòókẹ́lẹ́ láti máa gbé ìwé tí ó tóbí tó kìlógíráámù márùn-ún kiri!
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀dà kan ìwé náà dé ilé Collin Pellenc nílẹ̀ Faransé, bí a ti sọ ní ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí, síbẹ̀ Bíbélì Olivétan kùtà. Lọ́dún 1670, ìyẹn ní nǹkan bí àádọ́jọ [150] ọdún lẹ́yìn tí ìwé náà ti jáde, ilé ìtàwé kan ní Geneva ṣì ní ẹ̀dà kan ìwé náà táwọn èèyàn kò tíì rà.
“Kò Ní Orúkọ, A Kò Mọ Ibi Tó Ti Wá”
Ọ̀gbẹ́ni Olivétan parí iṣẹ́ rẹ̀, a kò sì gbúròó rẹ̀ mọ́. Ó lo orúkọ míì láti fi ṣe àtúnṣe sí Bíbélì Májẹ̀mú Tuntun àti apá kan lára Bíbélì Májẹ̀mú Láéláé tó ṣe. Ó tún gbájú mọ́ ohun míì tó wù ú jù lọ, ìyẹn iṣẹ́ olùkọ́. Nítorí ó jẹ́ olùkọ́ tó ń ronú jìnlẹ̀, ó ṣe àtúnṣe sí ìwé tó ṣe fún àwọn ọmọdé, ìyẹn ìwé Instruction for Children. Ìwé yìí kọ́ àwọn ọmọdé nípa ìwà rere àti nípa béèyàn ṣe máa mọ èdè Faransé kà, àmọ́ gbogbo nǹkan tó wà nínú ìwé náà ló wá látinú Ìwé Mímọ́. Lára àwọn orúkọ tí kì í ṣe tirẹ̀ tó lò ni Belisem de Belimakom, tó túmọ̀ sí “Kò Ní orúkọ, A Kò Mọ Ibi Tó Ti Wá.”
Olivétan kú lọ́dún 1538 nígbà tó ti lé lẹ́ni ọgbọ̀n ọdún, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Róòmù ló kú sí. Àwọn èèyàn díẹ̀ lónìí ló mọ ipa pàtàkì tí ọ̀dọ́kùnrin ọ̀mọ̀wé yìí tó wá láti Picardy kó nínú bí Bíbélì èdè Faransé ṣe wà káàkiri. Kò fi bẹ́ẹ̀ sí orúkọ rẹ̀ nínú àwọn ìwé atúmọ̀ èdè. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìyẹn gan-an ló wu Louys Robert, ‘ọ̀dọ́mọdé onírẹ̀lẹ̀ tó jẹ́ àtúmọ̀ èdè,’ ẹni tí orúkọ ìnagijẹ rẹ̀ ńjẹ́ Olivétan!
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
^ Fún ìsọfúnni síwájú sí i lórí bí àwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo ṣe di àwọn Alátùn-unṣe Ìsìn, wo Ilé Ìṣọ́ ti March 15, 2002, ojú ìwé 20 sí 23.
^ Orúkọ táwọn òbí rẹ̀ sọ ọ́ ni Louys Robert, òun fúnra rẹ̀ ló fún ara rẹ̀ ní orúkọ kìíní yẹn, Pierre. Ó jọ pé orúkọ ìnagijẹ́ rẹ̀, Olivétan, ń tọ́ka sí ọ̀pọ̀ òróró ólífì tó máa ń lò láti fi tan iná tó fi ń ṣe iṣẹ́ fún ọ̀pọ̀ wákàtí.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 18]
Archives de la Ville de Neuchâtel, Suisse/Photo: Stefano Iori
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 19]
Fọ́tò apá òsì: Alain Leprince - La Piscine-musée, Roubaix/Courtesy of the former Bouchard Museum, Paris
Ti àárín àti ti ọwọ́ ọ̀tún: Société de l’Histoire du Protestantisme Français, Paris
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 20]
Société de l’Histoire du Protestantisme Français, Paris