Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Òtítọ́ Lè Yí Ìgbésí Ayé Rẹ Pa Dà

Òtítọ́ Lè Yí Ìgbésí Ayé Rẹ Pa Dà

Òtítọ́ Lè Yí Ìgbésí Ayé Rẹ Pa Dà

BÓYÁ o ti gbọ́ ọ̀kan lára irọ́ nípa Ọlọ́run tí àwọn àpilẹ̀kọ yìí tú àṣírí wọn, tàbí wọ́n ti fi kọ́ ẹ. Síbẹ̀, ó lè má rọrùn fún ẹ láti yí ohun tó o gbà gbọ́ pa dà, pàápàá tó bá jẹ́ pé ó ti pẹ́ tí o ti gba àwọn nǹkan náà gbọ́.

A lóye ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀. Àwọn ṣọ́ọ̀ṣì kan kì í fẹ́ káwọn èèyàn máa gbé ẹ̀kọ́ wọn yẹ̀ wò bóyá ó bá Bíbélì mu. Àwọn míì sì máa ń gbìyànjú láti ti ẹ̀kọ́ èké lẹ́yìn nípa sísọ pé Bíbélì ṣòro láti lóye, pé kì í ṣe gbogbo èèyàn ló lè lóye rẹ̀. Àmọ́ ṣá o, gbáàtúù ni ọ̀pọ̀ jù lọ ọmọ ẹ̀yìn Jésù, wọn kò lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga, ṣùgbọ́n wọ́n tètè lóye ohun tí Jésù kọ́ni.—Ìṣe 4:13.

Ìwọ náà lè máa rò pé tí o bá ṣàyẹ̀wò ohun tó o gbà gbọ́ láti mọ̀ bóyá ó jẹ́ òótọ́, ìyẹn á fi hàn pé o kò ní ìgbàgbọ́. Àmọ́, ṣé o rò pé Ọlọ́run á bínú sí ẹ tó o bá fi Bíbélì tó jẹ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó wà fún gbogbo aráyé wádìí ohun tó fẹ́ kó o ṣe? Rárá o, nítorí pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pàápàá gbà ẹ́ níyànjú pé kí ìwọ fúnra rẹ ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́, ó ní: “Kí ẹ lè ṣàwárí fúnra yín ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé.”—Róòmù 12:2.

Mímọ òtítọ́ nípa Ọlọ́run ṣe pàtàkì ju ìmọ̀ èyíkéyìí lọ, ó lè mú kí ìgbésí ayé rẹ dára sí i. (Jòhánù 8:32) Ní báyìí, obìnrin tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Deanne tá a mẹ́nu kàn ní àpilẹ̀kọ́ àkọ́kọ́ ti jẹ́ kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ dá lé ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ. O sọ pé: “Mi ò mọ̀ pé Ìwé Mímọ́ ṣeé lóye bẹ́ẹ̀ àfìgbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nísinsìnyí mo mọ Jèhófà bíi Bàbá mi ọ̀run onífẹ̀ẹ́, kì í ṣe bí Ọlọ́run kan lásán. Ìgbésí ayé mi ti wá dára gan-an.”

Ó ṣeé ṣe kó o ti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àmọ́ kó o rò pé o kò rí nǹkan jèrè. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, má ṣe jáwọ́ nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Ńṣe lọ́rọ̀ ẹni tí wọ́n ti pa irọ́ fún nípa Ọlọ́run àmọ́ tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kí ó sì lóye rẹ̀ dà bí ẹnì kan tó ń rìnrìn àjò lọ sí ibì kan tí kò dé rí, àmọ́ tí wọn kò júwe ọ̀nà fún un dáadáa. Ìrìn-àjò náà lè dára níbẹ̀rẹ̀, àmọ́ tó bá yá gbogbo nǹkan á tojú sú u nígbà tó bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣìnà. Tó bá fẹ́ dé ibi tó ń lọ, ó ní láti lọ bá ẹni tó mọ ọ̀nà náà pé kó júwe ọ̀nà fún òun.

Ṣé wàá fẹ́ mọ òtítọ́ nípa Ọlọ́run? A fẹ́ kó o wá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kàn ní àdúgbò rẹ tàbí kó o lo àdírẹ́sì tó yẹ ní ojú ìwé kẹrin ìwé ìròyìn yìí láti kọ̀wé pé kí wọ́n wá kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nílé rẹ lọ́fẹ̀ẹ́.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 9]

“Kí ẹ lè ṣàwárí fúnra yín ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé.”​—RÓÒMÙ 12:2