Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

‘Máa Ṣọ́ Ọkàn Rẹ!’

‘Máa Ṣọ́ Ọkàn Rẹ!’

‘Máa Ṣọ́ Ọkàn Rẹ!’

Àpéjọ Àgbègbè Ti Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

ẸṢIN Ọ̀RỌ̀ ỌJỌ́ FRIDAY

“Ní Ti Jèhófà, Ó Ń Wo Ohun Tí Ọkàn-Àyà Jẹ́”​—1 SÁMÚẸ́LÌ 16:7.

ẸṢIN Ọ̀RỌ̀ ỌJỌ́ SATURDAY

“Lára Ọ̀pọ̀ Yanturu Tí Ń Bẹ Nínú Ọkàn-Àyà Ni Ẹnu Ń Sọ”​ —MÁTÍÙ 12:34.

ẸṢIN Ọ̀RỌ̀ ỌJỌ́ SUNDAY

“Fi Ọkàn-Àyà Pípé Pérépéré Sin Jèhófà”​—1 KÍRÓNÍKÀ 28:9.

Ó tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ìgbà tí Bíbélì sọ nípa ọkàn. Lọ́pọ̀ ìgbà, Ìwé Mímọ́ máa ń sọ nípa ọkàn ìṣàpẹẹrẹ, kì í fi bẹ́ẹ̀ sọ nípa ọkàn téèyàn lè fojú rí. Kí ni ọkàn ìṣàpẹẹrẹ? Ó lè tọ́ka sí ohun tí ẹni kan jẹ́ ní inú, ìyẹn ohun tí ẹnì kan ń rò, bí ọ̀rọ̀ ṣe máa ń rí lára rẹ̀ àti ohun tó fẹ́.

Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ṣọ́ ọkàn ìṣàpẹẹrẹ wa? Ọlọ́run mí sí Sólómọ́nì Ọba láti sọ pé: “Ju gbogbo ohun mìíràn tí a ní láti ṣọ́, fi ìṣọ́ ṣọ́ ọkàn-àyà rẹ, nítorí láti inú rẹ̀ ni àwọn orísun ìyè ti wá.” (Òwe 4:23) Bí ọkàn ìṣàpẹẹrẹ wa ṣe rí máa ń nípa lórí irú ìgbésí ayé tí à ń gbé nísinsìnyí àti lórí bí a ṣe máa rí ìyè lọ́jọ́ iwájú. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé Ọlọ́run rí ohun tó wà nínú ọkàn wa. (1 Sámúẹ́lì 16:7) Irú èèyàn tá a jẹ́ ní inú, ìyẹn “ẹni ìkọ̀kọ̀ ti ọkàn-àyà,” ló máa pinnu ojú tí Ọlọ́run máa fi wò wá.—1 Pétérù 3:4.

Báwo la ṣe lè máa ṣọ́ ọkàn wa? A má dáhùn ìbéèrè yìí lọ́nà tó yéni yékéyéké ní àwọn àpéjọ tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ṣe kárí ayé, tó máa bẹ̀rẹ̀ ní oṣù yìí. A pè ọ́ tayọ̀tayọ̀ láti wà níbẹ̀ ní ọjọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta àpéjọ yìí. * Ohun tó o máa kọ́ níbẹ̀ máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti máa hùwà lọ́nà tí yóò máa mú ọkàn Jèhófà Ọlọ́run yọ̀.—Òwe 27:11.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Láti mọ ibi tó sún mọ́ ẹ jù lọ tá a ti máa ṣe àpéjọ náà, jọ̀wọ́ lọ wo ìkànnì wa www.dan124.com. O tún lè béèrè lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lágbègbè rẹ tàbí kó o kọ̀wé sí àwọn tó tẹ ìwé ìròyìn yìí.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 32]

Fọ́tò apá ọ̀tún: Aus dem Fundus der MÜNCHNER OLYMPIAPARK GMBH, München