Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Ibo ni “ìjókòó ìdájọ́” tí wọ́n mú àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lọ?
▪ Ìwé Ìṣe 18:12, 13 sọ pé àwọn Júù tó wà ní ìlú Kọ́ríńtì fi ẹ̀sùn kan Pọ́ọ̀lù pé ó ń wàásù lọ́nà tí kò bá òfin mu, wọ́n sì mú un lọ síwájú “ìjókòó ìdájọ́,” tàbí beʹma (ìyẹn ọ̀rọ̀ èdè Gíríìkì tó túmọ̀ sí “àtẹ̀gùn”). Nílùú Kọ́ríńtì àtijọ́, pèpéle kan tó ga tàbí ibì kan tí wọ́n máa ń dúró sí láti sọ̀rọ̀ wà ní gbangba, nítòsí gbàgede tàbí ibi ọjà tí kò fi bẹ́ẹ̀ jìnnà sí sínágọ́gù. Ibi tí pèpéle náà wà mú kó rọrùn láti máa tibẹ̀ bá ọ̀pọ̀ èèyàn sọ̀rọ̀. Mábìlì aláwọ̀ funfun àti aláwọ̀ búlúù tí wọ́n fi àwọn àwòrán mèremère tí wọ́n gbẹ́ ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ ni wọ́n fi kọ́ pèpéle náà. Ó ní yàrá méjì tí wọ́n fi àwọn òkúta wẹ́wẹ́ tó ní oríṣiríṣi àwọ̀ tẹ́ ilẹ̀ rẹ̀, àga ìjókòó gbọọrọ tí wọ́n fi mábìlì ṣe sì wà níbẹ̀.
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé iwájú pèpéle tí wọ́n ti ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ yẹn ni ìjókòó ìdájọ́ níbi tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti jẹ́jọ́ níwájú Gálíò tó jẹ́ alákòóso ìbílẹ̀, tó sì tún jẹ́ Gómìnà ìlú Ákáyà tó wà lábẹ́ àkóso ìlú Róòmù. Orí pèpéle náà ni àwọn aláṣẹ tí wọ́n ń gbẹ́jọ́ máa ń jókòó sí, ibẹ̀ sì ni wọ́n ti máa ń kéde ìdájọ́ wọn fún àwọn èèyàn tó bá pé jọ.
Ní àwọn ìpínlẹ̀ tó wà lábẹ́ àkóso ìlú Gíríìsì, àwọn èèyàn sábà máa ń pé jọ síwájú ibi tí wọ́n ń pè ní beʹma yìí, ibẹ̀ sì ni wọ́n ti máa ń bójú tó àwọn ọ̀ràn tó bá wáyé nílùú. Nínú ìtàn tó wà nínú ìwé Mátíù 27:19 àti Jòhánù 19:13, nípa bí wọ́n ṣe gbọ́ ẹjọ́ Jésù, àwọn ìwé tí wọ́n fi èdè Gíríìkì kọ yìí sọ nípa Pọ́ńtíù Pílátù pé ó ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ látorí ibi tí wọ́n ń pè ní beʹma.—Ìṣe 12:21.
Kí nìdí tí ọ̀nà tí Jésù gbà kú fi fa ìkọ̀sẹ̀ fún àwọn kan lára àwọn Júù?
▪ Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nípa àwọn tó kọ́kọ́ di Kristẹni pé: “Àwa ń wàásù Kristi tí a kàn mọ́gi, lójú àwọn Júù okùnfà fún ìkọ̀sẹ̀ ṣùgbọ́n lójú àwọn orílẹ̀-èdè ọ̀rọ̀ òmùgọ̀.” (1 Kọ́ríńtì 1:23) Kí nìdí tí ọ̀nà tí Jésù gbà kú fi lè fa ìkọ̀sẹ̀ fún àwọn kan?
Ọ̀gbẹ́ni Ben Witherington Kẹta, to máa ń ṣàlàyé àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì, sọ nípa àṣà àwọn ará Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn àti ọ̀nà tí Jésù gbà kú, ó ní: “Ọ̀nà tó ń tini lójú jù lọ téèyàn lè gbà kú nìyẹn láyé ìgbà náà. Kì í ṣe ọ̀nà tó ń pọ́nni lé rárá láti gbà kú nítorí ẹ̀sìn ẹni.” Ọ̀gbẹ́ni Witherington tún sọ pé: “Àwọn èèyàn ayé ìgbà yẹn gbà pé ọ̀nà tí ẹnì kan bá gbà kú máa ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ irú ẹni tó jẹ́. Ẹ̀rí fi hàn nígbà náà pé wọ́n ti ní láti ka Jésù sí ọ̀daràn tó ń dìtẹ̀ sí ìjọba, wọ́n sì gbà pé ìyà tó tọ́ sí ẹrú tó ya ọlọ̀tẹ̀ náà ló yẹ kí wọ́n fi jẹ Jésù.” Tá a bá wo bí àṣà wọn ṣe rí yìí, kò ní bọ́gbọ́n mu láti sọ nígbà náà pé ṣe ni àwọn tó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ẹ̀sìn Kristẹni kàn hùmọ̀ àwọn ìtàn tí wọ́n kọ nípa ikú àti àjíǹde Jésù.