Olùsẹ̀san fún Gbogbo Àwọn Tó Ń Sìn Ín
Sún Mọ́ Ọlọ́run
Olùsẹ̀san fún Gbogbo Àwọn Tó Ń Sìn Ín
“O ṢEUN.” Kò sẹ́ni tí irú ọ̀rọ̀ ìmoore yìí kì í dùn mọ́ nígbà tó bá ṣe iṣẹ́ kan dáadáa tàbí tó bá fúnni lẹ́bùn kan látọkànwá. Gbogbo wa là ń fẹ́ káwọn èèyàn mọyì ohun tá a bá ṣe, pàápàá àwọn tá a nífẹ̀ẹ́. Ó dájú pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run wa Jèhófà ju ẹnikẹ́ni lọ. Ǹjẹ́ Ọlọ́run mọyì ìsapá tá à ń ṣe láti máa sìn ín? Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà hùwà sí Ebedi-mélékì, ọkùnrin kan tó fi ẹ̀mí ara rẹ̀ wewu kó lè gba ọ̀kan lára àwọn wòlíì Ọlọ́run sílẹ̀.—Ka Jeremáyà 38:7-13 àti 39:16-18.
Ta ni Ebedi-mélékì? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ onípò àṣẹ kan nínú ààfin Sedekáyà Ọba ilẹ̀ Júdà. * Ebedi-mélékì gbé ayé lákòókò kan náà pẹ̀lú Jeremáyà, ẹni tí Ọlọ́run rán lọ ṣèkìlọ̀ fún ilẹ̀ Júdà aláìṣòótọ́ pé ó máa tó pa run. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ ọba tí kò ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run ló yí i ká, Ebedi-mélékì jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run, ó sì bọ̀wọ̀ fún Jeremáyà gan-an. Wọ́n dán àwọn ànímọ́ tó jọ ti Ọlọ́run tí Ebedi-mélékì ní wò nígbà táwọn ọmọ ọba búburú náà fẹ̀sùn kan Jeremáyà pé ó ṣọ̀tẹ̀ sí ìjọba, wọ́n sì jù ú sínú ìkùdu tó ní ẹrẹ̀, wọ́n fi í sílẹ̀ níbẹ̀ pé kí ó kú. (Jeremáyà 38:4-6) Kí ni Ebedi-mélékì máa ṣe?
Ebedi-mélékì lo ìgboyà, ó sì gbé ìgbésẹ̀ lójú ẹsẹ̀, kò sì bẹ̀rù pé àwọn ọmọ ọba lè gbẹ̀san lára òun. Ó lọ bá Sedekáyà ní gbangba, ó sì sọ pé ohun tí wọ́n ṣe sí Jeremáyà kò dáa. Bóyá ńṣe ló tiẹ̀ nàka sí àwọn ìkà ẹ̀dá náà, nígbà tó sọ fún ọba pé: “Àwọn ọkùnrin yìí ti ṣe ohun búburú . . . sí Jeremáyà.” (Jeremáyà 38:9) Ebedi-mélékì borí, ó sì tẹ̀ lé ìtọ́ni Sedekáyà, ó mú ọgbọ̀n [30] ọkùnrin láti lọ yọ Jeremáyà nínú ihò.
Ebedi-mélékì wá fi ànímọ́ míì tó fani mọ́ra hàn, ìyẹn inú rere. Ó mú “àwọn àkísà gbígbó àti àwọn ègé aṣọ gbígbó . . . ó sì fi ìjàrá náà rọ̀ wọ́n sísàlẹ̀ sí Jeremáyà.” Kí nìdí tó fi mú àkísà àti àwọn ègé aṣọ? Kí Jeremáyà lè fi sí abíyá rẹ̀ kí ara rẹ̀ má bàa bó nígbàtí wọ́n bá ń fà á jáde látinú ẹrẹ̀ jíjìn.—Jeremáyà 38:11-13.
Jèhófà rí ohun tí Ebedi-mélékì ṣe. Ǹjẹ́ Ọlọ́run mọrírì rẹ̀? Ọlọ́run tipasẹ̀ Jeremáyà sọ fún Ebedi-mélékì pé ìparun Júdà ti sún mọ́lé gan-an. Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run fún Ebedi-mélékì ní ohun tí ọ̀mọ̀wé kan pè ní “ìdálójú ìgbàlà.” Jèhófà sọ pé: “Ṣe ni èmi yóò sì dá ọ nídè . . . a kì yóò sì fi ọ́ lé àwọn ènìyàn . . . lọ́wọ́. Láìkùnà, èmi yóò pèsè àsálà fún ọ, . . . ìwọ kì yóò sì tipa idà ṣubú, ìwọ yóò sì ni ọkàn rẹ bí ohun ìfiṣèjẹ.” Kí nìdí tí Jèhófà fi ṣèlérí pé òun á dáàbò bo Ebedi-mélékì? Jèhófà sọ fún un pé: “Nítorí pé o ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú mi.” (Jeremáyà 39:16-18) Jèhófà mọ̀ pé kì í ṣe nítorí pé Ebedi-mélékì ń ṣàníyàn nípa Jeremáyà nìkan ló ṣe ṣe ohun tó ṣe, àmọ́ ó tún jẹ́ nítorí pé ó ní ìgbẹ́kẹ̀lé àti ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run.
Ẹ̀kọ́ tá a rí kọ́ níbẹ̀ ni pé: Jèhófà mọrírì bí a ṣe ń jọ́sìn rẹ̀. Bíbélì fi dá wa lójú pé kì í gbàgbé ohun tó kéré jù lọ pàápàá tá a ṣe nínú ìjọsìn rẹ̀ pẹ̀lú ìgbàgbọ́ kíkún. (Máàkù 12:41-44) Ǹjẹ́ ó wù ẹ́ láti sún mọ́ Ọlọ́run tó mọrírì ìjọsìn rẹ? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, jẹ́ kó dá ọ́ lójú pé bí Bíbélì ṣe sọ, Ọlọ́run jẹ́: “Olùsẹ̀san fún àwọn tí ń fi taratara wá a.”—Hébérù 11:6.
Bíbélì kíkà tá a dábàá fún May:
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
^ Bíbélì pe Ebedi-mélékì ní “ìwẹ̀fà.” (Jeremáyà 38:7) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé orúkọ yìí ni wọ́n fi ń pe ọkùnrin tí wọ́n tẹ̀ lọ́dàá, wọ́n tún ń lò ó láti fi pe onípò àṣẹ tó ń ṣiṣẹ́ ní ààfin ọba.