Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bíbélì Máa Ń yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà

Bíbélì Máa Ń yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà

Bíbélì Máa Ń yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà

KÍ LÓ jẹ́ kí obìnrin kan nílẹ̀ Philippines lè jáwọ́ nínú ọtí àmupara, tí ìdílé rẹ̀ fi wá tòrò? Kí nìdí tí ọkùnrin ará Ọsirélíà kan tó fẹ́ràn jíja kàrátè gan-an fi di èèyàn Ọlọ́run tó ní ẹ̀mí àlàáfíà? Gbọ́ ohun tí wọ́n sọ.

“Ó pẹ́ kí n tó lè yí pa dà pátápátá.”—CARMEN ALEGRE

ỌDÚN TÍ WỌ́N BÍ MI: 1949

ORÍLẸ̀-ÈDÈ MI: PHILIPPINES

IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: Ọ̀MÙTÍ PARAKU

ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ: Wọ́n bí mi ní ìlú San Fernando tó wà ní àgbègbè Camarines Sur. Ṣùgbọ́n ìlú Antipolo ní Ìpínlẹ̀ Rizal ni mo ń gbé látìgbà tí mo ti dàgbà. Antipolo jẹ́ ìlú kékeré kan tó wà ní ilẹ̀ olókè tó ní àwọn igi àti koríko púpọ̀. Kò fi bẹ́ẹ̀ sí ariwo nígbà tí mo kọ́kọ́ débẹ̀. Nígbà yẹn, mi kì í sábà rí kí ẹnikẹ́ni máa rìn níta tí ilẹ̀ bá ti ṣú. Àmọ́ ní báyìí, ìlú Antipolo ti di ìlú ńlá tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń gbé.

Nígbà díẹ̀ lẹ́yìn tí mo kó dé Antipolo, mo pàdé ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Benjamin, kò sì pẹ́ tí a fi fẹ́ra wa. Ìgbé ayé lọ́kọláya nira fún mi ju bí mo ṣe rò lọ. Mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í mutí gan-an láti fi pa ìrònú rẹ́. Bí mo ṣe di oníwà líle nìyẹn, ó sì hàn nínú ìwà tí mò ń hù sí ọkọ mi àti àwọn ọmọ mi. Ṣe ni mo máa ń kanra mọ́ wọn ṣáá, mi kì í sì í ní sùúrù fún wọn. Mi ò bọ̀wọ̀ fún ọkọ mi rárá. Nípa bẹ́ẹ̀, ìdílé wa kò tòrò.

BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ: Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni Editha tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n ọkọ mi, obìnrin yìí ló sì dábàá pé kí èmi àti ọkọ mi Benjamin bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ni àwa náà bá gbà bẹ́ẹ̀ nírètí pé ó máa jẹ́ kí ìdílé wa lè tòrò.

Bá a ṣe ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa lọ, a rí ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ àtàtà kọ́. Ọ̀rọ̀ inú Ìṣípayá 21:4 wọ̀ mí lọ́kàn gan-an. Ohun tí ẹsẹ yẹn sọ nípa àwọn tó máa wà nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé, tí Ìjọba Ọlọ́run máa mú wá lọ́jọ́ iwájú, ni pé Ọlọ́run “yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́.” Mo fẹ́ wà lára àwọn tó máa gbádùn ìbùkún wọ̀nyẹn.

Mo wá rí i pé mo ní láti ṣe àyípadà pàtàkì nínú ìwà àti ìṣe mi. Ó pẹ́ kí n tó lè yí pa dà pátápátá, àmọ́ níkẹyìn mo jáwọ́ nínú ìmutípara. Mo tún di onínúure àti onísùúrù nínú ìdílé mi. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, mo ń bọ̀wọ̀ fún ọkọ mi, mo sì ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ bó ṣe ń darí ìdílé wa.

Nígbà tí èmi àti Benjamin ọkọ mi bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ohun tí a rí níbẹ̀ wú wa lórí gan-an. Kò sí àwọn ẹni tó ń ta tẹ́tẹ́ láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí tàbí ẹni tó ń mutí para, kò sì sí ojúsàájú láàárín wọn. Wọ́n máa ń yẹ́ gbogbo èèyàn sí, wọ́n sì ń fi ọ̀wọ̀ wọ̀ wọ́n. Ìyẹn jẹ́ kó dá wa lójú pé a ti rí ìsìn tòótọ́.—Jòhánù 13:34, 35.

ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ: Ìdílé wa ti wá tòrò gan-an báyìí. Èmi àti ọkọ mi ń gbádùn ara wa gan-an, inú wa sì ń dùn bá a ṣe ń kọ́ àwọn ẹlòmíì lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àwọn ọmọ wa méjèèjì tí wọ́n ti dàgbà àti aya wọn náà ti bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. A retí pé láìpẹ́ àwọn náà yóò wá dara pọ̀ mọ́ wa láti máa sin Jèhófà. Dájúdájú, èyí gan-an ni ọ̀nà ìgbésí ayé tó dára jù.

“Mo máa ń rò pé mo ti dẹni tí apá ẹnikẹ́ni kò lè ká.”​—MICHAEL BLUNSDEN

ỌDÚN TÍ WỌ́N BÍ MI: 1967

ORÍLẸ̀-ÈDÈ MI: ỌSIRÉLÍÀ

IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: MO FẸ́RÀN JÍJA KÀRÁTÈ GAN-AN

ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ: Ìlú Albury tó jẹ́ ìlú tó lẹ́wà, tó sì lọ́rọ̀ ní ìpínlẹ̀ New South Wales ni mo gbé dàgbà. Bí ìwà ọ̀daràn ṣe sábà máa ń wà ní ọ̀pọ̀ ìlú ńlá náà ló ṣe wà níbẹ̀. Àmọ́ ṣá o, tí a bá wo ìlú Albury lápapọ̀, ó jẹ́ ìlú tó tòrò.

Àwọn òbí mi kò jẹ́ kí ìyà jẹ mí rárá títí mo fi dàgbà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn òbí mi kọ ara wọn sílẹ̀ nígbà tí mo wà ní ọmọ ọdún méje, wọ́n rí i dájú pé ìyà ohunkóhun kò jẹ èmi àti àbúrò mi àtàwọn ẹ̀gbọ́n mi. Wọ́n fi mí sí ilé ìwé tó dáa, kódà ilé ẹ̀kọ́ àdáni tó dáa jù ládùúgbò yẹn ni mo lọ. Bàbá mi fẹ́ kí n di oníṣòwò tí mo bá ti parí iléèwé. Ṣùgbọ́n eré ìdárayá ni mo fẹ́ràn ní tèmi, mo sì ń ṣe dáadáa gan-an nínú gígun kẹ̀kẹ́ ológeere àti jíja kàrátè. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ níbi kan tí wọ́n ti ń tún mọ́tò ṣe, ìyẹn wá jẹ́ kí n ráyè gbájú mọ́ eré ìdárayá tí mo fẹ́ràn gan-an.

Ohun tó máa ń jẹ mí lógún ni pé kí ara mi le dáadáa kí n lè máa ta pọ́n-ún pọ́n-ún. Nígbà míì, mo máa ń rò pé mo ti dẹni tí apá ẹnikẹ́ni kò lè ká. Bí mo ṣe wà yẹn, ó rọrùn fún mi láti ṣi agbára mi lò. Àmọ́ bí ọ̀gá tó kọ́ mi ní kàrátè jíjà ṣe kíyè sí i pé agbára kò ní pẹ́ máa gùn mí, ó bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ mi láti jẹ́ ẹni tó ń kóra rẹ̀ níjàánu gan-an tó sì ń hùwà ọmọlúwàbí. Gbogbo ìgbà ló ń jẹ́ kí n mọ bó ti ṣe pàtàkì tó láti jẹ́ onígbọràn àti ẹni tó ṣeé fọkàn tán.

BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ: Nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo wá mọ̀ pé Jèhófà kórìíra ìwà ipá. (Sáàmù 11:5) Lákọ̀ọ́kọ́, mo máa ń wò ó pé jíja kàrátè kì í ṣe ìwà ipá, pé eré ìdárayá tí kì í pa ẹnikẹ́ni lára ni. Mo gbà pé ìwà ọmọlúwàbí tó ń gbìn síni lọ́kàn àti bó ṣe ń kọ́ni láti máa tẹ̀ lé ìlànà, bá ẹ̀kọ́ inú Bíbélì mu. Tọkọtaya Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mú sùúrù fún mi gan-an. Wọn kò sọ fún mi rárá pé kí n fi àwọn eré ìdárayá tó jẹ mọ́ ìjà sílẹ̀, ṣe ni wọ́n kàn ń kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìṣó.

Bí ohun tí mo ń kọ ṣe túbọ̀ ń yé mi sí i, tí mo sì túbọ̀ ń sún mọ́ Jèhófà, ojú tí mo fi ń wo nǹkan wọ̀nyẹn bẹ̀rẹ̀ sí í yàtọ̀ sí ti tẹ́lẹ̀. Nígbà tí mo kẹ́kọ̀ọ́ nípa àpẹẹrẹ tí Jésù Ọmọ Jèhófà fi lélẹ̀, ó wú mi lórí gan-an. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù jẹ́ alágbára, kò yọwọ́ ìjà sí ẹnikẹ́ni. Ohun tó sọ nínú Mátíù 26:52 wọ̀ mí lọ́kàn gan-an. Ó ní: “Gbogbo àwọn tí wọ́n bá ń mú idà yóò ṣègbé nípasẹ̀ idà.”

Bí mo ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà sí i, bẹ́ẹ̀ ni mo ṣe túbọ̀ ń nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, tí mo sì ń bọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún un. Ó wú mi lórí gan-an pé ọ̀rọ̀ mi lè jẹ Ẹlẹ́dàá wa tó ní ọgbọ́n àti agbára ńláǹlà lógún. Ó tún dùn mọ́ mi gan-an nígbà tí mo kẹ́kọ̀ọ́ pé, kódà bí mo bá já Jèhófà kulẹ̀, tàbí mo ronú pé mi ò lè tẹ̀ síwájú mọ́, pé mo fẹ́ dáwọ́ dúró, kò ní pa mí tì láé, tí mo bá sáà ti ń gbìyànjú ohun tí mo lè ṣe láì jáwọ́. Mo rí ìtùnú púpọ̀ nínú ìlérí rẹ̀ tó ṣe pé: “Èmi, Jèhófà Ọlọ́run rẹ, yóò di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú, Ẹni tí ń wí fún ọ pé, ‘Má fòyà. Èmi fúnra mi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́.’” (Aísáyà 41:13) Bí mo ṣe wá mọ̀ pé irú ìfẹ́ báyìí ni Ọlọ́run ní sí mi, mo pinnu pé gbogbo ohun tó bá gbà ni máa ṣe.

Mo mọ̀ pé láti fi kàrátè jíjà sílẹ̀ máa jẹ́ ohun tó nira jù lọ fún mi. Àmọ́ mo mọ̀ pé ìyẹn ló máa dùn mọ́ Jèhófà, ó sì dá mi lójú pé gbogbo ohun tó bá gbà láti lè sin Jèhófà ló yẹ kéèyàn ṣe. Ohun tó wá mú kí ọkàn mi ṣí kúrò níbẹ̀ pátápátá ni ọ̀rọ̀ Jésù tí mo kà nínú Mátíù 6:24, tó sọ pé: “Kò sí ẹnì kan tí ó lè sìnrú fún ọ̀gá méjì.” Mo rí i pé kò ní ṣeé ṣe fún mi láti máa sin Jèhófà bó ṣe yẹ, kí n sì tún máa lọ ja kàrátè, torí jíja kàrátè yẹn tún máa gbà mí lọ́kàn tó bá yá. Àkókò tó wàyí láti yan èyí tó máa jẹ́ ọ̀gá mi nínú Jèhófà àti kàrátè jíjà.

Kò rọrùn fún mi rárá láti fi kàrátè jíjà sílẹ̀. Oríṣiríṣi èrò ló ń jàgùdù lọ́kàn mi. Lápá kan, inú mi ń dùn pé mo ń ṣe ohun tó ń mú inú Jèhófà dùn. Ṣùgbọ́n, ó tún ń ṣe mí bíi pé mo ti dalẹ̀ ọ̀gá tó kọ́ mi ní kàrátè jíjà. Àwọn tó máa ń kópa nínú àwọn eré tó la ìjà jíjà lọ máa ń ka dída ẹnì kejì sí ẹ̀ṣẹ̀ tí kò ní ìdáríjì. Àwọn míì tiẹ̀ máa ń gbà pé kàkà kí àwọn máa gbé ìtìjú yẹn káàkiri, ikú yá ju ẹ̀sín.

Ó tì mí lójú gan-an láti lọ ṣàlàyé ìdí tí mo fi fẹ́ jáwọ́ nínú kàrátè jíjà fún ọ̀gá tó kọ́ mi. Ni mi ò bá lọ síbẹ̀ mọ́, mo sì pa ọ̀gá yẹn àtàwọn ẹlẹ́gbẹ́ mi tá a jọ wà níbẹ̀ tì pátápátá. Mo mọ̀ pé ohun tó dáa ni mo ṣe bí mo ṣe jáwọ́ nínú kàrátè jíjà. Síbẹ̀, ọkàn mi ń dá mi lẹ́bi bí mi ò ṣe lo àǹfààní yẹn láti fi ṣàlàyé ìgbàgbọ́ mi nísinsìnyí fún wọn. Ṣe ni mo wò ó bíi pé mo já Jèhófà kulẹ̀ kí n tiẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ sí í sìn ín. Gbogbo èyí máa ń bà mí lọ́kàn jẹ́ gan-an. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé mo gbìyànjú láti gbàdúrà sí Jèhófà àmọ́ ẹkún ni mo kàn ń sun bí mo ṣe ń kẹ́dùn.

Ó dájú pé Jèhófà rí nǹkan rere kan nínú mi, torí ó mú kí àwọn ará lọ́kùnrin lóbìnrin fà mí mọ́ra, kí wọ́n sì máa ṣaájò mi. Ìfẹ́ tí wọ́n fi hàn sí mi, bí wọ́n ṣe tù mí nínú àti bí wọ́n ṣe bá mi dọ́rẹ̀ẹ́ wú mi lórí púpọ̀. Ìtàn Bíbélì nípa Dáfídì àti Bátí-ṣébà tù mí nínú gan-an. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Dáfídì dá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó burú gan-an, Jèhófà dárí jì í torí pé ó ronú pìwà dà tọkàntọkàn. Bí mo ṣe ṣàṣàrò nípa ìtàn tí mo kà yìí kò jẹ́ kí n ronú jù mọ́ nípa àwọn àṣìṣe mi.

ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ: Kí n tó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mi ò fi bẹ́ẹ̀ bìkítà nípa ẹnikẹ́ni, tara mi nìkan ni mo mọ̀. Ṣùgbọ́n ní ọlá Jèhófà àti ìrànlọ́wọ́ ìyàwó mi àtàtà tá a ti jọ wà pọ̀ láti ọdún méje, mo ti dẹni tó túbọ̀ ń gba tàwọn ẹlòmíì rò báyìí. Ọlọ́run ti bù kún wa ní ti pé ó fún wa láǹfààní láti kọ́ àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì títí kan àwọn tó wà nínú ìpọ́njú. Bí mo ṣe ń rí i pé ìfẹ́ Jèhófà ń sọ ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn dayọ̀, ìyẹn ń fún mi láyọ̀ púpọ̀ ju ayọ̀ tí mo lè rí látinú dídi akọni olókìkí nídìí kàrátè jíjà lọ.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 14]

“Ó wú mi lórí gan-an pé ọ̀rọ̀ mi lè jẹ Ẹlẹ́dàá wa tó ní ọgbọ́n àti agbára ńláǹlà lógún”

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

“Ẹ Ṣeun Gan-an fún Ọ̀wọ́ Àpilẹ̀kọ Alárinrin Yìí!”

Ṣé o gbádùn àwọn ìrírí tí o ṣẹ̀ṣẹ̀ kà tán yìí? Wọ́n wulẹ̀ jẹ́ méjì péré nínú èyí tó ju àádọ́ta [50] irú àwọn àpilẹ̀kọ bẹ́ẹ̀ tó ti ń jáde nínú Ilé Ìṣọ́ láti August 2008. Ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà” ti wá di èyí tí ọ̀pọ̀ àwọn òǹkàwé wa fẹ́ràn gan-an. Kí nìdí tí àwọn àpilẹ̀kọ yìí fi máa ń wu ọ̀pọ̀ èèyàn láti kà?

Ipò ìgbésí ayé àwọn èèyàn tí a máa ń sọ̀rọ̀ wọn nínú àwọn àpilẹ̀kọ yìí máa ń yàtọ̀ síra. Kí àwọn kan nínú wọn tó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà Ọlọ́run, wọ́n tí gbé àwọn nǹkan kan ṣe ní ìgbésí ayé, àmọ́ wọn kò mọ ibi tí ìgbésí ayé wọn dorí kọ. Àwọn ìṣòro tó le gan-an ló ń bá àwọn míì fínra ní tiwọn. Irú bíi kí wọ́n máa bínú sódì tàbí lílo oògùn olóró tàbí mímutí para. Láti kékeré ni àwọn míì ti mọ Jèhófà tí wọ́n sì ń sìn ín, àmọ́ wọ́n tún fìgbà kan yà kúrò nínú ìjọsìn rẹ̀. Gbogbo àwọn ìrírí yìí fi hàn pé ó ṣeé ṣe láti ṣe àwọn àyípadà tó yẹ láti lè rí ojú rere Ọlọ́run. Àti pé ṣíṣe irú àwọn àyípadà bẹ́ẹ̀ máa ń ṣeni láǹfààní. Ipa wo ni àwọn ìrírí yìí máa ń ní lórí àwọn òǹkàwé wa?

Òǹkàwé wa kan ṣàlàyé nípa bí àpilẹ̀kọ kan nínú Ilé Ìṣọ́ February 1, 2009 ṣe ran àwọn ẹlẹ́wọ̀n kan tó wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n àwọn obìnrin lọ́wọ́.

◼ Obìnrin náà sọ pé: “Ọ̀pọ̀ àwọn ẹlẹ́wọ̀n yẹn rí i pé ìgbé ayé àwọn jọ ti àwọn tí wọ́n sọ ìrírí wọn nínú àwọn àpilẹ̀kọ náà. Àwọn àwòrán bí wọ́n ṣe rí tẹ́lẹ̀ àti ìgbà tí wọ́n yí pa dà, àti àlàyé nípa irú ẹni tí wọ́n jẹ́ tẹ́lẹ̀ tó máa ń wà nínú àpilẹ̀kọ yẹn wúlò gan-an. Ọ̀pọ̀ àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà ló jẹ́ pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ló ṣẹlẹ̀ sí àwọn náà. Àwọn ẹlẹ́wọ̀n méjì ló bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lẹ́yìn tí wọ́n ka àwọn àpilẹ̀kọ yẹn.”—C. W.

Àwọn ìrírí tó máa ń wà nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ wọ̀nyẹn ti ní ipa tó jinlẹ̀ lórí àwọn kan. Bí àpẹẹrẹ, àpilẹ̀kọ kan nínú Ilé Ìṣọ́ April 1, 2011, sọ ìrírí ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Guadalupe Villarreal, tó jáwọ́ nínú àṣà bíbá ọkùnrin lò pọ̀ torí kó lè máa sin Jèhófà. Wo méjì péré lára ọ̀pọ̀ lẹ́tà tá a rí gbà láti ọ̀dọ̀ àwọn tó ka ìrírí ọkùnrin yìí.

◼ “Ìrírí Guadalupe wọ̀ mí lọ́kàn gan-an. Ó wúni lórí gidigidi láti rí bí èèyàn ṣe lè yí pa dà pátápátá téèyàn bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀!”—L. F.

◼ “Tẹ́lẹ̀, mo máa ń gbìyànjú láti sọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún gbogbo èèyàn, títí kan àwọn abẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀. Àmọ́ lẹ́nu àìpẹ́ yìí, mo kàn rí pé mo sábà máa ń gbójú fo irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ tàbí kí n má tiẹ̀ fẹ́ láti bá wọn sọ̀rọ̀ rárá. Àpilẹ̀kọ yìí ti ràn mí lọ́wọ́ gan-an. Ó jẹ́ kí n lè máa wo irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ bí Jèhófà ṣe ń wò wọ́n, ìyẹn bíi pé àwọn náà lè di olùjọsìn Jèhófà lẹ́yìn wá ọ̀la.”—M. K.

Ìrírí míì tó tún wú ọ̀pọ̀ òǹkàwé wa lórí gan-an ni ti obìnrin kan tó ń jẹ́ Victoria Tong, tí ìrírí rẹ̀ wà nínú Ilé Ìṣọ́ August 1, 2011. Victoria ṣàlàyé ìṣòro tó ní nígbà èwe rẹ̀. Ó sọ pé èrò pé Jèhófà kò lè nífẹ̀ẹ́ òun gba òun lọ́kàn, kódà lẹ́yìn tí òun ti ń sìn ín fún ọ̀pọ̀ ọdún. Ó sì wá sọ ohun tó jẹ́ kó bẹ̀rẹ̀ sí í gbà pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ òun. Gbọ́ ohun tí àwọn òǹkàwé kan sọ nípa ìrírí obìnrin yìí.

◼ “Ìrírí Victoria wọ̀ mí lọ́kàn gan-an. Ọ̀pọ̀ àwọn àjálù ló ti dé bá mi. Mo sábà máa ń ro èrò òdì nípa ara mi, kódà lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tí mo ti di Ẹlẹ́rìí tó ti ṣe ìrìbọmi. Ṣùgbọ́n ìrírí Victoria jẹ́ kí n túbọ̀ gbìyànjú gan-an láti lè máa rí dáadáa tí Jèhófà rí nínú mi.”—M. M.

◼ “Nígbà tí mo ṣì kéré, mo sapá gidigidi kí n tó lè bọ́ lọ́wọ́ wíwo àwòrán ìṣekúṣe tó ti di bára kú fún mi. Láìpẹ́ yìí, mo tún pa dà jìn sí ọ̀fìn yẹn kan náà. Mo ti lọ bá àwọn alàgbà nínú ìjọ Kristẹni wọ́n sì ti ràn mí lọ́wọ́, mo sì ti ń borí ìṣòro mi yẹn. Àwọn alàgbà fi dá mi lójú pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ mi, pé yóò sì ṣíjú àánú wò mí. Síbẹ̀ mo ṣì máa ń ka ara sí ẹni tí kò wúlò, bíi pé kò sí bí Jèhófà ṣe lè fẹ́ràn mi. Ìrírí Victoria tí mo kà ràn mí lọ́wọ́ gan-an ni. Mo ti wá rí i pé tí mo bá ti ń rò ó pé bóyá ni Ọlọ́run fi lè dárí jì mí, ṣe ló dà bí ìgbà tí mo ń sọ pé ẹbọ ìràpadà Ọmọ rẹ̀ kò lè wẹ ẹ̀ṣẹ̀ mi nù. Ṣe ni mo gé àpilẹ̀kọ náà dání kí n lè máa kà á kí n sì máa ṣe àṣàrò lé e lórí nígbàkigbà tí ìrònú pé mi ò wúlò bá tún fẹ́ gbà mí lọ́kàn. Ẹ ṣeun gan-an fún ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ alárinrin yìí!”—L. K.