Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Nígbàkigbà Tí Ẹ Bá Ń Gbàdúrà, Ẹ Wí Pé, ‘Baba’”

“Nígbàkigbà Tí Ẹ Bá Ń Gbàdúrà, Ẹ Wí Pé, ‘Baba’”

“Nígbàkigbà Tí Ẹ Bá Ń Gbàdúrà, Ẹ Wí Pé, ‘Baba’”

Kí ni ọ̀rọ̀ náà “Baba” máa ń gbé wá sí ọ lọ́kàn? Ṣé ọkùnrin onífẹ̀ẹ́ kan tó fẹ́ràn ẹni lọ́nà tó jinlẹ̀, tí ọ̀rọ̀ ìdílé rẹ̀ sì jẹ lógún gan-an ni? Àbí ọkùnrin aláìbìkítà kan, bóyá tó tiẹ̀ máa ń fìyà jẹni? Lọ́pọ̀ ìgbà, èrò tó máa wá síni lọ́kàn sinmi lórí irú ẹni tí bàbá ẹni jẹ́.

“BABA” ni Jésù sábà máa ń pe Ọlọ́run tó bá ń bá a sọ̀rọ̀ tàbí tó bá ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. * Nígbà tí Jésù ń kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ bí wọ́n á ṣe máa gbàdúrà, ó sọ pé: “Nígbàkigbà tí ẹ bá ń gbàdúrà, ẹ wí pé, Baba.” (Lúùkù 11:2) Àmọ́, irú baba wo ni Jèhófà jẹ́? Ó ṣe pàtàkì gan-an ká mọ ìdáhùn ìbéèrè yẹn. Kí nìdí? Bí a bá ṣe lóye irú baba tí Jèhófà jẹ́ tó, la ó ṣe sún mọ́ ọn tó, bẹ́ẹ̀ la ó sì ṣe nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tó.

Kò sí ẹlòmíì tó kúnjú òṣùwọ̀n láti ṣàlàyé nípa Baba wa ọ̀run fún wa tó Jésù fúnra rẹ̀. Òun àti Baba rẹ̀ sún mọ́ra tímọ́tímọ́. Jésù sọ pé: “Kò sì sí ẹnì kankan tí ó mọ Ọmọ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ bí kò ṣe Baba, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò mọ Baba ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ bí kò ṣe Ọmọ àti ẹnikẹ́ni tí Ọmọ fẹ́ láti ṣí i payá fún.” (Mátíù 11:27) Nítorí náà ọ̀nà tó dáa jù láti gbà mọ Baba jẹ́ nípasẹ̀ Ọmọ.

Kí la lè kọ́ nípa Baba wa ọ̀run látọ̀dọ̀ Jésù? Ronú lórí ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 3:16) Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ níbí yìí jẹ́ ká mọ̀ pé ìfẹ́ ló gba iwájú nínú ìwà Baba wa ọ̀run. (1 Jòhánù 4:8) Onírúurú ọ̀nà ni Jèhófà gbà ń fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ wa, irú bó ṣe ń fi hàn pé òun tẹ́wọ́ gbà wá, bó ṣe ń lo ìyọ́nú sí wa, bó ṣe ń dáàbò bò wá, bó ṣe ń bá wa wí àti bó ṣe ń pèsè àwọn nǹkan tí a nílò fún wa.

Jésù Jẹ́ Kó Dá Wa Lójú Pé Baba Wa Tẹ́wọ́ Gbà Wá

Tí àwọn ọmọ bá mọ̀ pé inú òbí àwọn dùn sí ohun tí àwọn ṣe, orí wọn máa ń wú, ara wọn sì máa ń yá gágá láti túbọ̀ ṣe dáadáa. Ìwọ náà wo bó ṣe máa jẹ́ ìwúrí tó fún Jésù nígbà tó gbọ́ tí Baba rẹ̀ sọ pé: “Èyí ni Ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà.” (Mátíù 3:17) Jésù náà sì jẹ́ kó dá wa lójú pé Baba wa ọ̀run fẹ́ràn wa, ó sì tẹ́wọ́ gbà wá. Ó sọ pé: “Ẹni tí ó nífẹ̀ẹ́ mi ni Baba mi yóò nífẹ̀ẹ́.” (Jòhánù 14:21) Ẹ ò rí i pé ọ̀rọ̀ yẹn tuni nínú gan-an! Ṣùgbọ́n, ẹnì kan wà tí kò fẹ́ kó o ní irú ìtùnú bẹ́ẹ̀.

Sátánì máa ń gbìyànjú láti mú ká máa ṣiyè méjì pé bóyá ni Baba wa ọ̀run lè tẹ́wọ́ gbà wá. Ó máa ń fẹ́ gbìn ín sí wa lọ́kàn pé a ò tiẹ̀ yẹ lẹ́ni tí Ọlọ́run lè tẹ́wọ́ gbà. Ó sábà máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tí a bá wà nípò tí kò bára dé, irú bíi ìgbà tá a bá darúgbó, ìgbà tí a bá ṣàìsàn tàbí a jẹ́ aláìlera tàbí nígbà tí a bá ń kẹ́dùn torí àwọn àṣìṣe wa tàbí nítorí pé àwọn nǹkan kò rí bá a ṣe rò. Wo àpẹẹrẹ ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Lucas, tó ti ka ara rẹ̀ sí ẹni tí Ọlọ́run ò lè tẹ́wọ́ gbà. Lucas sọ pé nígbà tí òun wà ní ọmọdé, àwọn òbí òun ṣàdédé yí pa dà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ohun tó lòdì pátápátá sí ọ̀pọ̀ nínú ìlànà ìwà rere tí wọ́n ti fi kọ́ òun tẹ́lẹ̀. Bóyá ìyẹn ló wá jẹ́ kó ṣòro fún un láti sún mọ́ Baba rẹ̀ ọ̀run tímọ́tímọ́. Yàtọ̀ sí ìyẹn, Lucas fúnra rẹ̀ jẹ́ oníwàdùwàdù èèyàn, ìyẹn sì máa ń fa ìjàngbọ̀n, pàápàá láàárín òun àti àwọn ẹlòmíì. Àmọ́ ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, aya rẹ̀ tó jẹ́ onísùúrù tó sì máa ń gbà á níyànjú wá ràn án lọ́wọ́ tó fi dẹni tí kì í ṣe wàdùwàdù mọ́. Lucas sábà máa ń sọ pé aya òun yìí jẹ́ “ẹ̀bùn ara ọ̀tọ̀ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run.” Lucas wá mọ̀ pé “Kristi Jésù wá sí ayé láti gba àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.” (1 Tímótì 1:15) Ó sọ pé bí òun ṣe ń ronú jinlẹ̀ nípa ìfẹ́ Ọlọ́run àti bó ṣe máa ń tẹ́wọ́ gbani, òun dẹni tó ń láyọ̀, ọkàn òun sì balẹ̀.

Tí ìwọ náà bá rí i pé, nígbà míì, o ń ṣiyè méjì pé bóyá ni Jèhófà lè fẹ́ràn rẹ tàbí kó tẹ́wọ́ gbà ọ́, o lè ronú lórí ohun tó wà nínú Róòmù 8:31-39. Nínú ẹsẹ yẹn, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi dá wa lójú tìfẹ́tìfẹ́ pé kò sí ohunkóhun tó lè “yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó wà nínú Kristi Jésù Olúwa wa.” *

Baba Ìyọ́nú Oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́

Àánú wa máa ń ṣe Baba wa ọ̀run bí ìyà bá ń jẹ wá. Ọlọ́run “ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́” ni. (Lúùkù 1:78) Jésù gbé ìyọ́nú tí Baba rẹ̀ máa ń ní sí àwa èèyàn aláìpé yọ. (Máàkù 1:40-42; 6:30-34) Àwọn Kristẹni tòótọ́ náà máa ń gbìyànjú láti jẹ́ oníyọ̀ọ́nú bíi ti Baba wọn ọ̀run. Wọ́n máa ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì tó sọ pé: “Ẹ di onínúrere sí ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ní fífi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn.”—Éfésù 4:32.

Ronú nípa ìrírí ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Felipe. Lọ́jọ́ kan, bó ṣe ń lọ sí ibi iṣẹ́, ṣàdédé ni ara bẹ̀rẹ̀ sí í ro ó gidigidi bí ìgbà tẹ́nì kan fi nǹkan gún un láti ẹ̀yìn. Ni wọ́n bá sáré gbé e lọ sí ilé ìwòsàn. Lẹ́yìn tí àwọn dókítà fi wákàtí mẹ́jọ ṣe àyẹ̀wò ara rẹ̀, wọ́n sọ pé apá kan lára òpó tó ń gbé ẹ̀jẹ̀ jáde nínú ọkàn rẹ̀ ti ya nínú lọ́hùn-ún. Wọ́n wá sọ pé àwọn ò wulẹ̀ ní ṣiṣẹ́ abẹ kankan fún un torí pé kò lè lò ju ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] lọ mọ́ tó fi máa gbẹ́mìí mì.

Àwọn kan láti inú ẹ̀sìn tí Felipe ń ṣe wà níbẹ̀, ìyọ́nú tí wọ́n ní sì mú kí wọ́n wá nǹkan kan ṣe lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ láti ràn án lọ́wọ́. Ní kíá, wọ́n ṣètò wọ́n gbé e lọ sí ilé ìwòsàn míì níbi tí wọ́n ti ṣe iṣẹ́ abẹ fún un lójú ẹsẹ̀, wọ́n sì dúró tì í títí iṣẹ́ abẹ náà fi parí. Ó sì dùn mọ́ni pé Felipe yè é. Bí Felipe ṣe ń rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn, ṣe ló máa ń dúpẹ́ pé àwọn ẹni tí àwọn jọ ń sin Ọlọ́run fi ìyọ́nú hàn sí òun. Àmọ́ ó dá Felipe lójú pé Baba wa ọ̀run ló gbin ẹ̀mí ìyọ́nú yẹn sí wọn nínú. Felipe sọ pé: “Ṣe ló dà bíi pé Ọlọ́run dúró tì mí gbágbáágbá bíi baba onífẹ̀ẹ́, tó ń gbé mi ró.” Láìsí àní-àní, ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jèhófà máa ń fi ìyọ́nú rẹ̀ hàn sí wa, nípa dídarí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó wà ní ayé kí wọ́n wá fi í hàn sí wa.

Baba Wa Ń Dáàbò Bò Wá

Tí ọmọ kékeré kan bá rí i pé ewu wà nítòsí, ó lè sáré lọ forí pa mọ́ sọ́dọ̀ bàbá rẹ̀. Ọkàn ọmọdé máa ń balẹ̀ pé kò séwu fún òun tí baba rẹ̀ bá ti fà á mọ́ra tìfẹ́tìfẹ́. Jésù fọkàn tán Jèhófà pátápátá pé ó máa dáàbò bo òun. (Mátíù 26:53; Jòhánù 17:15) Àwa náà lè wá sábẹ́ ààbò Baba wa ọ̀run. Lónìí, ààbò tí Jèhófà ń pèsè fún wa ní pàtàkì jù ni ààbò tẹ̀mí. Ìyẹn ni pé, ó ń dáàbò bò wá kúrò lọ́wọ́ ìpalára nípa tẹ̀mí nípa bó ṣe ń jẹ́ ká mọ ohun tá a máa ṣe ká lè bọ́ lọ́wọ́ ewu tó mú kí ìdè ọ̀rẹ́ wa pẹ̀lú rẹ̀ já. Ọ̀kan lára ọ̀nà tó gbà ń dáàbò bò wá ni ìmọ̀ràn látinú Bíbélì tí a máa ń rí gbà. Ìgbàkigbà tí a bá gba irú ìmọ̀ràn bẹ́ẹ̀, ṣe ló dà bí ìgbà tí Jèhófà ń rìn tẹ̀ lé wa lẹ́yìn tó ń sọ fún wa pé: “Èyí ni ọ̀nà. Ẹ máa rìn nínú rẹ̀.”—Aísáyà 30:21.

Wo àpẹẹrẹ Tiago àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀ méjì, ìyẹn Fernando àti Rafael, tí wọ́n jọ wà nínú ẹgbẹ́ olórin rọ́ọ̀kì kan. Inú wọn dún gidigidi nígbà tí wọ́n yan ẹgbẹ́ olórin wọn pé kí wọ́n wá ṣeré nínú ọ̀kan lára àwọn gbọ̀ngàn ìṣeré orin tó lókìkí jù ní ìlú São Paulo, lórílẹ̀-èdè Brazil. Ṣe ló dá bíi pé ọ̀nà àtidi gbajúmọ̀ ti là fún wọn wàyí. Àmọ́ ẹnì kan tí wọ́n jọ ń sin Ọlọ́run kìlọ̀ fún wọn pé kí wọ́n ṣọ́ra fún ṣíṣe wọléwọ̀de pẹ̀lú àwọn tí ìgbé ayé wọn fi hàn pé wọn kò ka àwọn òfin Ọlọ́run sí. (Òwe 13:20) Ó fi ìrírí ti òun fúnra rẹ̀ ṣe àpẹẹrẹ fún wọn nígbà tó ń fún wọn nímọ̀ràn yìí látinú Bíbélì. Ó sọ fún wọn pé ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́ tí ẹ̀gbọ́n òun ọkùnrin bá rìn ló mú kó ṣe ohun tó lòdì sí ìfẹ́ Ọlọ́run. Tiago àti àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ wá kúkú pinnu láti pa eré orin tì. Ní báyìí, gbogbo wọn ti dẹni tó ń fi àkókò tó pọ̀ ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run. Wọ́n gbà pé bí àwọn ṣe tẹ́tí sí ìmọ̀ràn láti inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló kó àwọn yọ nínú ewu tó lè ba àjọṣe àwọn àti Ọlọ́run jẹ́.

Baba Wa Ọ̀run Máa Ń Bá Wa Wí

Baba onífẹ̀ẹ́ máa ń bá àwọn ọmọ rẹ̀ wí torí ó fẹ́ kí ayé wọn dáa lọ́jọ́ ọ̀la. (Éfésù 6:4) Kò ní gba ìgbàkugbà láyè, àmọ́ kò ní fi ọwọ́ tó le koko jù bá àwọn ọmọ rẹ̀ wí. Bákàn náà, nígbà míì, Baba wa ọ̀run máa ń bá wa wí tó bá yẹ bẹ́ẹ̀. Àmọ́ ṣá, ìfẹ́ ni Ọlọ́run fi máa ń bá wa wí, kì í bá wa wí lọ́nà ìkà. Jésù náà ṣe bíi ti Baba rẹ̀, kò fi ọwọ́ tó le koko mú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ kódà nígbà tí wọn kò tètè ṣe àtúnṣe lórí ohun tó ti sọ fún wọn.—Mátíù 20:20-28; Lúùkù 22:24-30.

Wo bí ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Ricardo ṣe dẹni tó wá mọyì bí Jèhófà ṣe fi ìfẹ́ bá òun wí. Ricardo kò ju ọmọ oṣù méje péré lọ nígbà tí bàbá rẹ̀ pa á tì. Nígbà tí Ricardo wà láàárín ọmọ ọdún mẹ́tàlá sí mọ́kàndínlógún, ó mọ̀ ọ́n lára gan-an pé bàbá òun pa òun tì. Ó kópa nínú àwọn ìwàkíwà kan, ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí í dà á láàmú. Nígbà tó rí i pé ìgbé ayé tí òun ń gbé lòdì sí ìwà Kristẹni, ó tọ àwọn alàgbà ìjọ rẹ̀ lọ fún ìrànlọ́wọ́. Àwọn alàgbà yẹn lo ìmọ̀ràn inú Bíbélì láti fi bá a wí tìfẹ́tìfẹ́, wọ́n sì ṣojú abẹ níkòó fún un. Ricardo mọrírì ìbáwí yẹn, àmọ́ àfọwọ́fà rẹ̀ yìí kó ìnira bá a gidigidi, irú bí àìrí oorun sùn, kó máa sunkún tàbí kí ìdààmú ọkàn bá a. Níkẹyìn, ó wá mọ̀ pé ìbáwí tí wọ́n fún òun yẹn fi hàn pé Jèhófà ṣì nífẹ̀ẹ́ òun. Ricardo rántí ọ̀rọ̀ tó wà nínú ìwé Hébérù 12:6 tó sọ pé: “Ẹni tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ni ó máa ń bá wí.”

Àmọ́ o, ẹ jẹ́ ká rántí pé ìbáwí kò mọ sí jíjẹni níyà tàbí bíbáni wí lórí àìdáa kan. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ìbáwí tún jẹ mọ́ kíkọ́ni lẹ́kọ̀ọ́. Torí náà, Baba ọ̀run lè jẹ́ ká jìyà fúngbà díẹ̀ látinú ohun tí a fi ọwọ́ ara wa fà, láti fi bá wa wí. Síbẹ̀ Bíbélì fi hàn pé ìbáwí Ọlọ́run ń kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ ni, ká lè máa rìn ní ọ̀nà tó tọ́. (Hébérù 12:7, 11) Láìsí àní-àní, ire wa jẹ Baba wa ọ̀run lógún gan-an, ó sì máa ń bá wa wí fún àǹfààní ara wa.

Baba Wa Ọ̀run Ń Pèsè Àwọn Ohun Ti Ara Tá A Nílò

Baba onífẹ̀ẹ́ máa ń wá bó ṣe máa pèsè àwọn ohun tí ìdílé rẹ̀ nílò nípa ti ara, títí kan jíjẹ, mímu àti aṣọ wọn. Ohun tí Jèhófà sì ń ṣe náà nìyẹn. Jésù sọ pé: “Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run mọ̀ pé ẹ nílò gbogbo nǹkan wọ̀nyí.” (Mátíù 6:25-34) Jèhófà ṣèlérí pé: “Dájúdájú, èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà.”—Hébérù 13:5.

Obìnrin kan tó ń jẹ́ Nice rí i pé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ yẹn nígbà tí iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ ọkọ rẹ̀. Ó ṣẹlẹ̀ pé, òun fúnra rẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ fi iṣẹ́ tí wọ́n ti ń sanwó tó pọ̀ fún un sílẹ̀ ni kó lè túbọ̀ ráyè gbọ́ tàwọn ọmọbìnrin rẹ̀ méjèèjì, kó sì lè lo àkókò púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ Ọlọ́run. Ó wá ku bí wọ́n ṣe fẹ́ máa gbọ́ bùkátà wọn wàyí. Obìnrin yìí gbàdúrà sí Jèhófà. Lọ́jọ́ kejì, ọkọ rẹ̀ pa dà lọ sí ibi iṣẹ́ láti lọ kó àwọn ẹrù rẹ̀. Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún un nígbà tí ọ̀gá rẹ̀ sọ fún un pé àyè iṣẹ́ kan ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣí sílẹ̀, ó sì gbà á sí iṣẹ́ yẹn! Bó ṣe di pé iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ ọkọ Nice lọ́jọ́ kan, tó sì rí iṣẹ́ míì lọ́jọ́ kejì nìyẹn. Nice àti ọkọ rẹ̀ dúpẹ́ gidigidi lọ́wọ́ Baba wa ọ̀run fún àṣeyọrí rere yẹn. Ìrírí wọn yìí rán wa létí pé Jèhófà Olùpèsè tó ń fi ìfẹ́ pèsè àwọn ohun tá a nílò, kì í fi àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ rárá.

Bí A Ṣe Lè Fi Hàn Pé A Mọyì Ìfẹ́ Baba Wa

Ká sòótọ́, ìfẹ́ àgbàyanu tí Baba wa ọ̀run ní sí wa kọjá àfẹnusọ! Tá a bá ronú nípa onírúurú ọ̀nà tí Baba wa ọ̀run gbà ń fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn sí wa, irú bó ṣe ń fi hàn pé òun tẹ́wọ́ gbà wá, bó ṣe ń lo ìyọ́nú sí wa, bó ṣe ń dáàbò bò wá, bó ṣe ń bá wa wí àti bó ṣe ń pèsè àwọn nǹkan tí a nílò fún wa, dájúdájú a máa gbà pé kò tún sí Baba rere míì tó dà bíi rẹ̀!

Báwo wá ni a ṣe lè fi hàn pé a mọrírì ìfẹ́ tí Baba wa ọ̀run ní sí wa? Ṣe ni kí á gbìyànjú láti túbọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀ àti àwọn ohun tó ní lọ́kàn láti ṣe. (Jòhánù 17:3) Kí á rí i pé a ń gbé ìgbé ayé tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. (1 Jòhánù 5:3) Kí á máa rí i dájú pé irú ìfẹ́ tó ní sí wa ni àwa náà ń ní sí ọmọnìkejì wa. (1 Jòhánù 4:11) Àwọn ọ̀nà wọ̀nyí ni a lè gbà fi hàn pé a gbà pé Jèhófà ni Baba wa àti pé a kà á sí ọlá ńlá láti jẹ́ ọmọ rẹ̀.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Ọ̀rọ̀ nípa bí Jèhófà ṣe jẹ́ baba wa pọ̀ gan-an nínú Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, Jésù lo ọ̀rọ̀ náà “Baba” ní nǹkan bí ìgbà márùnlélọ́gọ́ta [65] nínú ìwé Ìhìn Rere ti Mátíù, Máàkù àti Lúùkù, ó sì lé ní ọgọ́rùn-ún [100] ìgbà tó lò ó nínú Ìhìn Rere ti Jòhánù. Ó ju ogójì [40] ìgbà lọ tí Pọ́ọ̀lù náà pe Ọlọ́run ní “Baba” nínú àwọn ìwé tó kọ. Jèhófà ni Baba wa ní ti pé òun ló fún wa ní ìwàláàyè wa.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 19]

Bí a bá ṣe lóye irú baba tí Jèhófà jẹ́ tó, la ó ṣe sún mọ́ ọn tó, bẹ́ẹ̀ la ó sì ṣe nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tó

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 22]

A lè fi hàn pé a gbà pé Jèhófà ni Baba wa àti pé a kà á sí ọlá ńlá láti jẹ́ ọmọ rẹ̀

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

JÈHÓFÀ BABA WA Ń FI ÌFẸ́ TÓ NÍ SÍ WA HÀN NÍ ONÚRUURÚ Ọ̀NÀ

Ó Ń FI HÀN PÉ ÒUN TẸ́WỌ́ GBÀ WÁ

Ó Ń FI ÌYỌ́NÚ HÀN SÍ WA

Ó Ń DÁÀBÒ BÒ WÁ

Ó Ń BÁ WA WÍ

Ó Ń PÈSÈ ÀWỌN OHUN TÍ A NÍLÒ