Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà
BÁWO ni obìnrin kan tí kò dìídì nífẹ̀ẹ́ sí Ọlọ́run, tó sì níṣẹ́ tó lè sọ ọ́ di ẹni ńlá ṣe mọ ohun gidi tó yẹ kéèyàn fi ìgbésí ayé rẹ̀ ṣe? Kí ni ọ̀dọ́kùnrin kan tó jẹ́ ẹlẹ́sìn Kátólíìkì tẹ́lẹ̀ kọ́ nípa ikú, tó mú kí ó yí ìgbé ayé rẹ̀ pa dà? Kí sì ni ọ̀dọ́mọkùnrin kan tí ayé ti sú kọ́ nípa Ọlọ́run, tó fi yí ìwà rẹ̀ pa dà, tó sì wá di òjíṣẹ́ Ọlọ́run? Gbọ́ ohun tí wọ́n sọ.
“Ọ̀pọ̀ ọdún ni mo ti máa ń rò ó pé, ‘Kí nìdí tá a fi wà láyé?’”—ROSALIND JOHN
-
ỌDÚN TÍ WỌ́N BÍ MI: 1963
-
ORÍLẸ̀-ÈDÈ MI: ILẸ̀ GẸ̀Ẹ́SÌ
-
IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: IṢẸ́ GBÉ MI DÉPÒ ỌLÁ
ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ:
Àgbègbè Croydon ní South London ni wọ́n bí mi sí. Nínú àwa mẹ́sàn-án tí àwọn òbí mi bí, èmi ni ìkẹfà. Ọmọ erékùṣù St. Vincent ni àwọn òbí mi. Àgbègbè òkun Caribbean ni erékùṣù yìí wà. Ṣọ́ọ̀ṣì Mẹ́tọ́díìsì ni màmá mi ń lọ. Èmi ò nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ nípa Ọlọ́run àmọ́ ó ń wù mí gan-an kí n ní ìmọ̀ àti òye. Tí a bá ti gba ọlidé ní ilé ìwé, mo sábà máa ń lọ yá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé ní ilé ìkówèésí, màá wá lọ jókòó síbi omi adágún kan tó wà ní àdúgbò wa, màá máa kà wọ́n. Ohun tí mo máa ń fi èyí tó pọ̀ jù nínú àkókò ọlidé mi ṣe nìyẹn.
Lẹ́yìn ọdún díẹ̀ tí mo jáde ilé ìwé, mo rí i pé ó ń wù mí láti wá nǹkan ṣe sí ọ̀rọ̀ àwọn tí wọ́n nílò ìrànlọ́wọ́. Torí náà mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn tí kò rí ilé gbé, àwọn aláàbọ̀ ara àti àwọn tí kì í tètè mọ̀wé. Lẹ́yìn ìyẹn, mo lọ sí yunifásítì láti kọ́ ẹ̀kọ́ nípa béèyàn ṣe lè lo àpapọ̀ ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì láti fi bójú tó ọ̀rọ̀ ìlera. Nígbà tí mo gboyè jáde, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ní ìgbéga sí ipò ńláńlá lọ́nà tí mi ò ronú kàn tẹ́lẹ̀. Mo wá ń gbé ìgbé ayé gbẹdẹmukẹ. Mo máa ń dá ṣiṣẹ́ ni, mo máa ń gba àwọn ilé iṣẹ́ ní ìmọ̀ràn nípa iṣẹ́ wọn, mo sì tún máa ń ṣe ìwádìí nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láwùjọ. Gbogbo ohun tí mo nílò fún iṣẹ́ mi kò ju ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà àgbélétan àti ibi tí màá ti lè rí Íńtánẹ́ẹ̀tì lò. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo máa ń lọ sí òkè òkun tí màá lo ọ̀sẹ̀ mélòó kan níbẹ̀. Òtẹ́ẹ̀lì tó bá wù mí ni mo máa ń dé sí, màá gbádùn gbogbo àyíká ẹlẹ́wà tí wọ́n bá ní, màá lo ibi ìṣeré ìmárale wọn, wọ́n á sì tún bá mi wọ́ ara mi kí ara mi lè le dáadáa. Ṣe ni mo rò pé kò tún sí bí èèyàn ṣe lè gbádùn ayé rẹ̀ jù báyẹn lọ. Àmọ́ o, ọ̀rọ̀ àwọn òtòṣì ṣì jẹ mí lógún.
BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ:
Ọ̀pọ̀ ọdún ni mo ti máa ń rò ó pé, ‘Kí nìdí tá a fi wà láyé?’ àti pé ‘Kí nìdí tí Ọlọ́run tiẹ̀ fi dá wa pàápàá?’ Àmọ́ mi ò gbìyànjú rí láti ṣèwádìí nínú Bíbélì. Lọ́jọ́ kan lọ́dún 1999, Margaret àbúrò mi tó ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan tóun náà jẹ́ Ẹlẹ́rìí wá kí mi. Ọ̀rẹ́ rẹ̀ yìí bá mi sọ̀rọ̀ bí ọ̀rẹ́. Àfi bí mo ṣe gbà wẹ́rẹ́ pé kí ọ̀rẹ́ àbúrò mi máa kọ́ mi ní ẹ̀kọ́ Bíbélì. Àmọ́ mi ò tètè tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ Bíbélì tí mò ń kọ́ torí iṣẹ́ mi àti irú ìgbé ayé tí mo ń gbé kì í jẹ́ kí n ráyè.
Lásìkò ẹ̀ẹ̀rùn ọdún 2002, mo ṣí wá sí apá gúúsù ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ England. Mo sì lọ sí yunifásítì níbẹ̀ láti túbọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí wọ́n ṣe ń ṣe ìwádìí nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láwùjọ kí n lè gboyè ọ̀mọ̀wé. Mátíù 6:24 tó sọ pé ẹnì kan kò lè máa sin ọ̀gá méjì. Ẹyọ kan ni ó máa mú, yálà kó sin Ọlọ́run tàbí ọrọ̀. Mo mọ̀ pé mo máa ní láti ṣe ìpinnu nípa ohun tí màá fi sípò àkọ́kọ́ ní ìgbésí ayé mi.
Ìgbà yẹn ni èmi àti ọmọkùnrin mi kékeré bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà déédéé. Lóòótọ́ mo fẹ́ràn ẹ̀kọ́ tí mo ń kọ́ ní yunifásítì, àmọ́ ẹ̀kọ́ Bíbélì tí mo ń kọ́ ló jẹ́ kí n túbọ̀ lóye ohun tó fa àwọn ìṣòro tí àwa èèyàn ń ní àti bí àwọn ìṣòro ọ̀hún ṣe máa yanjú. Mo wá rí i pé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ inúÓ ṣẹlẹ̀ pé ní ọdún 2001, mo ti máa ń lọ síbi tí àwùjọ àwọn Ẹlẹ́rìí kan ti ń pé jọ láti ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nílé ẹnì kan, ìwé Is There a Creator Who Cares About You? * ni wọ́n sì ń kà nígbà yẹn. Láti ìgbà yẹn ló ti dá mi lójú pé Jèhófà Ẹlẹ́dàá wa nìkan ló lè yanjú ìṣòro aráyé. Àmọ́ nígbà tó wá di pé ní yunifásítì tí mo wà, wọ́n ń kọ́ mi pé kò dìgbà tí èèyàn bá gbà pé Ẹlẹ́dàá kan wà kó tó lè mọ ìdí tí a fi wà láàyè. Inú bí mi gan-an. Bí mo ṣe ṣíwọ́ ẹ̀kọ́ náà lẹ́yìn oṣù méjì tí mo bẹ̀rẹ̀ nìyẹn, mo wá gbájú mọ́ bí màá ṣe túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run.
Ohun tí mo kà nínú Òwe 3:5, 6 ló mú kí n yí irú ìgbé ayé tí mò ń gbé pa dà, ẹsẹ yẹn sọ pé: “Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ. Ṣàkíyèsí rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà rẹ, òun fúnra rẹ̀ yóò sì mú àwọn ipa ọ̀nà rẹ tọ́.” Ẹ̀kọ́ tí mo ń kọ́ nípa Ọlọ́run wa onífẹ̀ẹ́ ṣàǹfààní gan-an ju ọrọ̀ àti ipò ńlá tó ṣeé ṣe kí n ní tí mo bá gboyè ọ̀mọ̀wé. Bí mo ṣe túbọ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn tó fi dá ayé àti ohun ribiribi tí Jésù ṣe bí ó ṣe fi ẹ̀mí rẹ̀ rúbọ fún wa, bẹ́ẹ̀ ló ṣe túbọ̀ ń wù mí láti fi ayé mi sin Ẹlẹ́dàá wa. Mo ṣe ìrìbọmi ní April ọdún 2003. Lẹ́yìn náà, mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í yọwọ́ díẹ̀díẹ̀ nínú àwọn ohun tí kò pọn dandan tí mo fi ń dí ara mi lọ́wọ́.
ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ:
Kò sí ohun tí mo lè fi wé àjọṣe tí mo ní pẹ̀lú Jèhófà, ó ṣe iyebíye gidigidi. Mímọ̀ tí mo mọ Jèhófà ti mú kí n ní ìfọ̀kànbalẹ̀, mo sì ń láyọ̀. Mo tún ti wá rí i pé bí mo ṣe ń bá àwọn tó ń fi òótọ́ inú sin Ọlọ́run rìn túbọ̀ ń mú kí inú mi máa dùn.
Ṣe ni ẹ̀kọ́ tí mo ń kọ́ nínú Bíbélì àti ní ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà túbọ̀ ń pa òùngbẹ ìmọ̀ tó ń gbẹ mí. Inú mi máa ń dùn láti sọ ohun tí mo gbà gbọ́ fún àwọn míì. Èyí ni mo wá mú bí iṣẹ́ báyìí, torí ọ̀nà yìí gan-an ni mo lè gbà ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ tí wọ́n á fi lè gbé ìgbé ayé ire, kí wọ́n sì tún máa retí láti wà láàyè nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí. Oṣù June ọdún 2008 ni mo ti bẹ̀rẹ̀ sí í lo àkókò tó pọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Inú mi ń dùn gan-an, ọkàn mi sì balẹ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó jẹ́ kí n mọ ohun pàtàkì tó yẹ kéèyàn fi ayé rẹ̀ ṣe.
“Ikú ọ̀rẹ́ mi dùn mí gan-an.”—ROMAN IRNESBERGER
-
ỌDÚN TÍ WỌ́N BÍ MI: 1973
-
ORÍLẸ̀-ÈDÈ MI: AUSTRIA
-
IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: ẸNI TÓ Ń TA TẸ́TẸ́
ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ:
Ìlú kékeré kan tó ń jẹ́ Braunau lórílẹ̀-èdè Austria ni mo gbé dàgbà. Nǹkan rọ̀ṣọ̀mù lágbègbè ibẹ̀, kò sì fi bẹ́ẹ̀ sí ìwà ọ̀daràn. Ẹlẹ́sìn Kátólíìkì ni ìdílé mi, inú ẹ̀sìn yìí sì ni wọ́n ti tọ́ mi dàgbà.
Ohun kan ṣẹlẹ̀ nígbà tí mo wà lọ́mọdé tó dùn mí gidigidi. Ọdún 1984 ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé, mi ò tíì ju ọmọ ọdún mọ́kànlá
nígbà yẹn. Ó ṣẹlẹ̀ pé lọ́jọ́ kan èmi àti ọ̀kan nínú àwọn ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́ jọ gbá bọ́ọ̀lù. Ṣùgbọ́n ọ̀sán ọjọ́ yẹn kan náà ni ọkọ̀ pa á. Ikú ọ̀rẹ́ mi dùn mí gan-an. Lẹ́yìn jàǹbá náà, ọ̀pọ̀ ọdún ni mo fi ń ronú nípa ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ séèyàn nígbà téèyàn bá kú.Nígbà tí mo jáde ilé ìwé, iṣẹ́ atúnnáṣe ni mò ń ṣe. Tẹ́tẹ́ títa wọ̀ mí lẹ́wù, owóbówó ni mo sì fi ń ta á, síbẹ̀ owó kì í wọ́n mi. Eré ìdárayá tún máa ń gba àkókò mi, mo sì fẹ́ràn orin rọ́ọ̀kì tí wọ́n máa ń lu ìlù rẹ̀ kíkankíkan. Ẹsẹ̀ mi kì í wọ́n ní ilé ijó àti òde àríyá. Ìgbé ayé ọmọ jayé-jayé àti oníṣekúṣe ni mo ń gbé, ìgbésí ayé mi kò sì lójútùú.
BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ:
Ní ọdún 1995, bàbá àgbàlagbà kan tí ó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà fún mi ní ìwé kan. Ìwé yẹn ṣàlàyé ohun tí Bíbélì sọ nípa ìbéèrè náà: Kí ló ń ṣẹlẹ̀ sí èèyàn nígbà tó bá kú? Ikú gbígbóná tí ọ̀rẹ́ mi kú ṣì ń dùn mí, torí náà mo gba ìwé yẹn. Kì í ṣe àkòrí tó sọ̀rọ̀ nípa ikú nìkan ni mo kà, ṣe ni mo ka ìwé náà láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin!
Ìwé náà dáhùn àwọn ìbéèrè tó ń jẹ mí lọ́kàn lórí ọ̀rọ̀ ikú, ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ míì ni mo sì tún kọ́ nínú rẹ̀. Torí pé inú ẹ̀sìn Kátólíìkì ni wọ́n ti tọ́ mi dàgbà, Jésù ni mo mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì jù kéèyàn gbà gbọ́. Àmọ́ ní báyìí tí mo ti wá fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ Bàbá Jésù. Orí mi wú nígbà tí mo wá mọ̀ pé Jèhófà fẹ́ kí àwọn tó bá ń wá òun mọ òun kedere, pé kò fi ara rẹ̀ pa mọ́ fún wa, bẹ́ẹ̀ ni kò ta kété sí wa. (Mátíù 7:7-11) Mo kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà mọ bí nǹkan ṣe máa ń rí lára wa, pé nǹkan máa ń dun Jèhófà, inú rẹ̀ sì máa ń dùn sí nǹkan. Mo tún kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà máa ń mú ọ̀rọ̀ tó bá sọ ṣẹ. Èyí mú kí n fẹ́ mọ̀ sí i nípa àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì, kí n sì tún mọ bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣe ṣẹ. Àwọn ìwádìí tí mo ṣe jẹ́ kí ìgbàgbọ́ mi nínú Ọlọ́run túbọ̀ fẹsẹ̀ múlẹ̀.
Kò pẹ́ tí mo fi rí i kedere pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìkan ló ń fi tọkàntọkàn kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́nà tí wọ́n á fi lè lóye rẹ̀. Tí mo bá ti ń ka ìwé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, mo máa ń fiyè sí àwọn ẹsẹ Bíbélì tí wọ́n bá tọ́ka sí níbẹ̀, màá wá lọ kà wọ́n nínú Bíbélì ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì tó wà lọ́wọ́ mi. Bí mo ṣe ń ṣèwádìí sí i, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe túbọ̀ ń dá mi lójú pé mo ti rí ẹ̀kọ́ òtítọ́ gan-an.
Ẹ̀kọ́ Bíbélì tí mo ń kọ́ jẹ́ kí n mọ̀ pé ohun tí Jèhófà fẹ́ ni pé kí n máa gbé ìgbé ayé mi lọ́nà tó bá àwọn ìlànà rẹ̀ mu. Ohun tí mo kà nínú Éfésù 4:22-24, jẹ́ kí n mọ̀ pé mo ní láti kọ àwọn ìwà mi àtijọ́ tí mo ń hù sílẹ̀, kí n sì “gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀, èyí tí a dá ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run.” Torí náà, mo jáwọ́ nínú ìṣekúṣe. Mo tún rí i pé mo ní láti jáwọ́ nínú tẹ́tẹ́ títa torí pé ó ń múni nífẹ̀ẹ́ owó, ó sì ń sọni di oníwọra. (1 Kọ́ríńtì 6:9, 10) Mo mọ̀ pé kí n tó lè ṣe ìyípadà wọ̀nyí, mo gbọ́dọ̀ ṣíwọ́ wọlé-wọ̀de tí mo ń bá àwọn ọ̀rẹ́ mi tẹ́lẹ̀ ṣe, kí n sì wá àwọn ọ̀rẹ́ tuntun tí a jọ ń tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run.
Ká sòótọ́, kò rọrùn fún mi láti ṣe àwọn ìyípadà yẹn. Àmọ́ mo bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn. Inú ìjọ wọn ni mo sì ti rí àwọn ọ̀rẹ́ tuntun tó ń tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run. Mo sì ń bá a nìṣó láti fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fúnra mi. Àwọn ohun tí mo ṣe yìí jẹ́ kí n lè yí ohun tí mo ń fi ayé mi ṣe tẹ́lẹ̀ pa dà. Mi ò gbọ́ àwọn orinkórin mọ́, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í múra bí ọmọlúwàbí. Lọ́dún 1995, mo ṣe ìrìbọmi mo sì di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ:
Ní báyìí, mi ò lépa owó àti dúkìá mọ́. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ mo máa ń tètè bínú, àmọ́
ní báyìí mo ti di oníwà tútù. Mi kì í sì í dààmú mọ́ nípa ọjọ́ iwájú.Inú mi ń dùn gan-an bí mo ṣe wà lára àwùjọ èèyàn tó wà ní ìṣọ̀kan, tí wọ́n ń sin Jèhófà kárí ayé. Mo ń rí àwọn tí ìṣòro ń bá fínra láàárín wọn, síbẹ̀ tí wọ́n ń sin Ọlọ́run tinútinú. Inú mi máa ń dùn pé ìjọsìn Jèhófà àti ṣíṣe oore fún àwọn èèyàn ni mò ń fi gbogbo agbára mi àti àkókò mi ṣe, kì í ṣe fún títẹ́ ìfẹ́ ara mi lọ́rùn mọ́.
“Mo ti wá mọ ìdí tí mo fi wà láàyè.”—IAN KING
-
ỌDÚN TÍ WỌ́N BÍ MI: 1963
-
ORÍLẸ̀-ÈDÈ MI: ILẸ̀ ENGLAND
-
IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: ÌGBÉSÍ AYÉ TOJÚ SÚ MI
ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ:
Orílẹ̀-èdè England ni wọ́n bí mi sí, àmọ́ nígbà tí mo wà ní ọmọ ọdún méje, ìdílé wa kó lọ sí ilẹ̀ Ọsirélíà. Ìlú Gold Coast tó wà ní àgbègbè Queensland ni à ń gbé, àwọn èèyàn sì sábà máa wá gbafẹ́ ní ibẹ̀. Lóòótọ́ a kì í ṣe ọlọ́rọ̀ nínú ìdílé wa o, àmọ́ ohun tí a nílò kò wọ́n wa.
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìyà ò jẹ mí rárá láti kékeré, mi kì í fi bẹ́ẹ̀ láyọ̀. Ìgbésí ayé sì tojú sú mi. Ọ̀mùtí paraku ni bàbá mi. Mi ò fi bẹ́ẹ̀ fẹ́ràn wọn, pàápàá nítorí pé wọ́n ti máa ń mutí jù àti pé wọ́n máa ń fìyà jẹ màmá mi. Ìgbà tí mo gbọ́ ohun tí ojú rẹ̀ rí nígbà tó ń ṣiṣẹ́ sójà ní ilẹ̀ Malaya ni ìdí tó fi ń hùwà bẹ́ẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ wá yé mi.
Ìgbà tí mo wà ní ilé ẹ̀kọ́ girama ni mo ti bẹ̀rẹ̀ sí í mu ọtí àmujù. Ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún sì ni mo wà tí mo ti kúrò ní ilé ìwé, mo wá lọ wọ iṣẹ́ ọmọ ogun ojú omi. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í lo oògùn olóró, sìgá mímu sì di bárakú fún mi. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ọtí mímu náà tún wọ̀ mí lẹ́wù. Òpin ọ̀sẹ̀ nìkan ni mo máa ń mu ọtí àmujù tẹ́lẹ̀, àmọ́ nígbà tó yá mo kúkú wá sọ ọ́ di ojoojúmọ́.
Láàárín ìgbà tó ku díẹ̀ kí n pé ọmọ ogún ọdún sí ìgbà tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ lé lọ́mọ ogún ọdún, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyè méjì pé bóyá gan-an tiẹ̀ ni Ọlọ́run wà. Mo wá ń rò ó pé, ‘Tí Ọlọ́run bá wà lóòótọ́, kí ló dé tó fi ń jẹ́ kí ìyà máa jẹ àwa èèyàn tó sì ń jẹ́ kí a kú?’ Kódà mo kọ ewì kan tí mo fi dá Ọlọ́run lẹ́bi fún gbogbo aburú tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé.
Mo kúrò nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun ojú omi nígbà tí mo wà ní ọmọ ọdún mẹ́tàlélógún. Lẹ́yìn èyí, mo tún lọ ṣiṣẹ́ ní àwọn ibòmíì. Mo tiẹ̀ lọ lo ọdún kan gbáko ní òkè òkun, síbẹ̀ ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn mi kò lọ. Mi ò ní nǹkan kan lọ́kàn tí mo fẹ́ dáwọ́ lé tàbí tí mo fẹ́ gbé ṣe láyé mi. Kò tiẹ̀ sí nǹkan kan tó wù mí rárá. Gbogbo ọ̀rọ̀ pé èèyàn ní ilé tirẹ̀, èèyàn ní iṣẹ́ gidi lọ́wọ́, èèyàn rí ìgbéga lẹ́nu iṣẹ́, kò já mọ́ nǹkan kan lójú mi. Ohun tí mo fi ń tu ara mi nínú kò ju kí n mu ọtí, kí n sì máa gbọ́ orin.
Mo rántí ìgbà tó wá sí mi lọ́kàn pé ó máa dáa kí n mọ ìdí tí a fi wà láàyè. Ilẹ̀ Poland ni mo wà nígbà náà, mo lọ wo àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ burúkú kan tó wà ní òde ìlú Auschwitz. Mo ti kà nípa ìwà ìkà tó burú jáì tí wọ́n hù níbẹ̀. Ṣùgbọ́n nígbà tí mo wá fi ojú ara mi rí bí àwọn èèyàn tí wọ́n ń fìyà jẹ
níbẹ̀ ṣe pọ̀ tó, ara mi bù máṣọ, àánú wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe mí. Kàyéfì gbáà ló jẹ́ fún mi pé ọmọ aráyé lè máa hu irú ìwà ìkà tó burú jáì bẹ́ẹ̀ sí ọmọnìkejì wọn. Mo rántí pé bí mo ṣe ń rìn yí po ọgbà náà ṣe ni mo ń da omijé lójú, tí mo sì ń béèrè pé, ‘Áà, kí ló dé?’BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ:
Lẹ́yìn tí mo dé láti òkè òkun ní ọdún 1993, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bíbélì kí n lè rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè tó wà lọ́kàn mi. Kò pẹ́ sígbà yẹn, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì kan wá kan ilẹ̀kùn ilé mi, wọ́n sì pè mí sí àpéjọ kan tí wọ́n fẹ́ ṣe ní pápá ìṣeré kan tó wà nítòsí wa. Mo sì lọ.
Kò tíì ju oṣù bíi mélòó kan tí mo dé pápá ìṣeré náà gbẹ̀yìn, àmọ́ bí ibẹ̀ ṣe rí lọ́tẹ̀ yìí yàtọ̀ pátápátá. Ìwà àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà níbẹ̀ dára gan-an, wọ́n wọṣọ lọ́nà tó dáa, àwọn ọmọ wọn sì hùwà ọmọlúwàbí. Ohun tí mo tún rí nígbà tí wọ́n ń jẹ oúnjẹ ọ̀sán yà mí lẹ́nu gan-an. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí ló jẹun lórí pápá ìṣeré náà, àmọ́ nígbà tí wọ́n fi máa kúrò níbẹ̀, tí wọ́n pa dà síbi tí wọ́n jókòó, mi ò rí ẹyọ ìdọ̀tí kan lórí pápá náà! Èyí tó wá jọ mí lójú jù níbẹ̀ ni pé, ó hàn lára gbogbo wọn pé ọkàn wọn balẹ̀ pẹ̀sẹ̀, àlàáfíà sì wà láàárín wọn, ìyẹn sì ni ohun tí mo ti ń wá tipẹ́tipẹ́. Mi ò lè rántí ìkankan nínú gbogbo ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ lọ́jọ́ náà, ṣùgbọ́n mi ò lè gbàgbé ìwà dáadáa tí àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà níbẹ̀ hù. Ó wú mi lórí gan-an ni.
Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn, mo rántí ọ̀rọ̀ mọ̀lẹ́bí mi kan. Ó máa ń ka Bíbélì, ó sì máa ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa oríṣiríṣi ẹ̀sìn. Ó sọ fún mi ní ọdún díẹ̀ ṣáájú ìgbà yẹn pé, Jésù sọ pé ìwà tí àwọn èèyàn tó wà nínú ẹ̀sìn kan bá ń hù ni èèyàn máa fi mọ̀ bóyá ẹ̀sìn tòótọ́ ni wọ́n ń ṣe. (Mátíù 7:15-20) Torí náà, mo wò ó pé ó máa dáa kí n tiẹ̀ mọ ohun tó mú kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yàtọ̀. Ìgbà àkọ́kọ́ sì nìyẹn tó máa ṣe mi bíi pé ire ń bẹ níwájú fún mi àti pé ìrètí ṣì wà fún mi pé ọ̀la ń bọ̀ wá dára.
Ní ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé e, àwọn Ẹlẹ́rìí méjì tó pè mí sí àpéjọ yẹn pa dà wá wò mí. Mo gbà pé kí wọ́n máa kọ́ mi ní ẹ̀kọ́ Bíbélì. Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í bá wọn lọ sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
Bí mo ṣe ń kọ́ ẹ̀kọ́ Bíbélì, òye tí mo ní nípa Ọlọ́run yí pa dà pátápátá. Mo wá mọ̀ pé òun kọ́ ni ó fa ìwà ibi àti ìyà tó ń jẹ aráyé àti pé ó máa ń dùn ún tí àwọn èèyàn bá ń hùwà àìdáa. (Jẹ́nẹ́sísì 6:6; Sáàmù 78:40, 41) Mo pinnu pé màá gbìyànjú kí n má ṣe ohunkóhun tó máa dun Jèhófà. Ṣe ni mo fẹ́ máa mú inú rẹ̀ dùn. (Òwe 27:11) Torí náà, mo jáwọ́ nínú mímu ọtí àmujù àti sìgá mímu, bákan náà mo jáwọ́ nínú ìṣekúṣe. Ní March ọdún 1994, mo ṣe ìrìbọmi, mo sì di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ:
Inú mi ń dùn, ayọ̀ mi kún, ọkàn mi sì balẹ̀. Mo ti kúrò lẹ́ni tó ń fi ọtí pa ìrònú rẹ́. Ní báyìí, mo ti kọ́ bí mo ṣe lè máa fi gbogbo ìṣòro mi lé Jèhófà lọ́wọ́.—Sáàmù 55:22.
Ó ti lé ní ọdún mẹ́wàá báyìí tí èmi àti Karen aya mi arẹwà ti ṣègbéyàwó. Nella ọmọ ìyàwó mi, sì ti di ọmọ àtàtà fún mi. Àwa mẹ́tẹ̀ẹ̀ta máa ń lo àkókò tó pọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, kí a lè ran àwọn míì lọ́wọ́ kí àwọn náà lè mọ Ọlọ́run. Inú mi dùn gan-an ni pé mo ti wá mọ ìdí tí mo fi wà láàyè.
^ Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.