Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Irú gègé àti yíǹkì wo ni àwọn èèyàn ń lò láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì?
Ní ìparí ìwé Jòhánù kẹta tí àpọ́sítélì Jòhánù kọ nínú Bíbélì, ó sọ pé: “Mo ní ohun púpọ̀ láti kọ̀wé rẹ̀ sí ọ, síbẹ̀ èmi kò fẹ́ láti máa bá a lọ ní fífi yíǹkì àti gègé kọ̀wé sí ọ.” Tí a bá kàn tú ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí àpọ́sítélì Jòhánù lò nínú ẹsẹ yìí ní olówuuru, ohun tó máa fi hàn ni pé Jòhánù kò fẹ́ máa lo “dúdú [ìyẹn yíǹkì] àti esùsú” láti kọ̀wé mọ́.—3 Jòhánù 13, The Kingdom Interlinear Translation of the Greek Scriptures.
Esùsú gbígbẹ ni wọ́n máa fi ń ṣe gègé tí àwọn akọ̀wé máa ń lò. Ṣe ni wọ́n máa ń fá ẹnu rẹ̀ pẹlẹbẹ wọ́n á wá gbẹ́ ẹ ṣóńṣó. Akọ̀wé lè wá máa fi òkúta tún ibi ṣóńṣó ẹnu rẹ̀ gbẹ́. Gègé esùsú yìí máa ń dà bí gègé ayé òde òní tó ń lo yíǹkì tí ẹnu rẹ̀ jẹ́ irin ṣóńṣó.
Púpọ̀ nínú àwọn yíǹkì tí wọ́n ń lò máa ń jẹ́ àpòpọ̀ oje igi àti màjàlà tàbí irú èédú tó máa ń wà lókè ilé ìdáná. Gbẹrẹfu ni wọ́n máa ń ta yíńkì yìí, ẹni tó bá fẹ́ lò ó yóò wá fi omi pò ó bó ṣe fẹ́, kó tó lò ó. Tí wọ́n bá fi irú yíǹkì yìí kọ̀wé sára òrépèté tàbí awọ, ṣe ni ohun tí wọ́n fi kọ máa gbẹ mọ́ ojú ìwé náà, kò ní rin wọ inú rẹ̀. Torí náà tẹ́nì kan bá fẹ́ ṣàtúnṣe ohun tó kọ, ó lè fi kànrìnkàn tó tutù nù ún kúrò. Ara ohun èlò tí àwọn akọ̀wé ń lò ni kànrìnkàn yìí jẹ́. Kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé nípa bí àwọn yíǹkì ayé àtijọ́ ṣe rí yìí, jẹ́ ká mọ ohun tó ṣeé ṣe kí àwọn tó kọ Bíbélì ní lọ́kàn nígbà tí wọ́n sọ pé orúkọ èèyàn lè di èyí tí wọ́n pa rẹ́ tàbí èyí tí wọ́n nù kúrò nínú ìwé ìrántí Ọlọ́run.—Ẹ́kísódù 32:32, 33; Ìṣípayá 3:5.
Irú àwọn àgọ́ wo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń pa?
Ìwé Ìṣe 18:3 sọ pé iṣẹ́ ọwọ́ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń ṣe ni iṣẹ́ àgọ́ pípa. Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, àwọn tó ń ṣiṣẹ́ àgọ́ pípa máa ń hun irun ràkúnmí tàbí ti ewúrẹ́ láti fi ṣe aṣọ tẹ́ẹ́rẹ́-tẹ́ẹ́rẹ́. Wọ́n á wá rán àwọn aṣọ tẹ́ẹ́rẹ́-tẹ́ẹ́rẹ́ náà pọ̀ láti fi pa àgọ́ fún àwọn arìnrìn-àjò. Ṣùgbọ́n, lásìkò ìgbà yẹn awọ ni wọ́n fi ń pa ọ̀pọ̀ àgọ́. Wọ́n tún máa ń fi aṣọ ọ̀gbọ̀ pa àwọn àgọ́ míì, wọ́n sì máa ń ṣe irú aṣọ ọ̀gbọ̀ yìí ní ìlú Tásù tí wọ́n ti bí Pọ́ọ̀lù. Èyíkéyìí lára wọn ló ṣeé ṣe kí Pọ́ọ̀lù lò, tàbí kó jẹ́ pé gbogbo wọn gan-an ni ó lò lẹ́nu iṣẹ́ àgọ́ pípa. Àmọ́ nígbà tí Pọ́ọ̀lù àti Ákúílà jọ ń ṣiṣẹ́, ó ṣeé ṣe kí Pọ́ọ̀lù máa ṣe aṣọ tí wọ́n fi ń ṣe ibòji sí àwọn ilé àdáni.
Ó lè jẹ́ pé láti kékeré ni Pọ́ọ̀lù ti kọ́ iṣẹ́ yìí. Ohun tí wọ́n rí nínú àwọn ìwé òrépèté ní ilẹ̀ Íjíbítì fi hàn pé láyé ìgbà tí ilẹ̀ Róòmù ń ṣàkóso, nǹkan bí ọmọ ọdún mẹ́tàlá ni àwọn ọmọ ti máa ń bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ṣẹ́ ọwọ́ ní ilẹ̀ Íjíbítì. Tó bá jẹ́ pé láti nǹkan bí ọmọ ọdún mẹ́tàlá yìí ni Pọ́ọ̀lù ti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ṣẹ́, a jẹ́ pé nígbà tó fi máa pé ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún tàbí mẹ́rìndínlógún, á ti mọ bí yóò ṣe máa gé aṣọ sí ìwọ̀n tó ń fẹ́ àti bí ó ṣe fẹ́ kó rí, á sì tún ti mọ bó ṣe máa fi oríṣiríṣi òòlu rán an pa pọ̀ sí bó ṣe fẹ́. Ìwé ìwádìí kan sọ pé: “Ó ṣeé ṣé kí wọ́n kó àwọn irinṣẹ́ tí Pọ́ọ̀lù á máa lò fún un lẹ́yìn tó parí iṣẹ́ tó ń kọ́. Kò lè ṣòro fún Pọ́ọ̀lù láti máa kó àwọn ọ̀bẹ àti òòlu tí wọ́n fi ń ṣe iṣẹ́ àgọ́ pípa yẹn dání káàkiri láti fi ṣiṣẹ́ níbikíbi” tó bá ti gbà pé kó ṣe é láti fi gbọ́ bùkátà ara rẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ míṣọ́nnárì tó ń ṣe.—Ìwé The Social Context of Paul’s Ministry.