KÓKÓ Ọ̀RỌ̀: ǸJẸ́ Ó YẸ KÉÈYÀN MÁA BẸ̀RÙ ÒPIN AYÉ?
Ǹjẹ́ Ó Yẹ Kéèyàn Máa Bẹ̀rù Òpin Ayé?
Ǹjẹ́ o gbọ́ pé December 21, 2012, ni àwọn kan sọ pé òpin ayé máa dé? Tó o bá gbọ́ nípa rẹ̀ ohun tí o retí pé kó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ yẹn ló máa pinnu irú èrò tó o máa ní báyìí. O lè máa dúpẹ́ pé òpin ayé kò dé, ó sì lè máa dùn ẹ́ pé òpin kò dé lọ́jọ́ yẹn. O sì lè má tiẹ̀ já a kúnra, kó o máa wò ó pé ọ̀run ń ya bọ̀ kì í kúkú ṣe ọ̀rọ̀ ẹnì kan. Ṣé ká gbà pé irú àsọtẹ́lẹ̀ tí kì í ṣe òótọ́ táwọn èèyàn kàn máa ń sọ nípa òpin ayé ni ti December 21, 2012?
“Òpin ayé” tí Bíbélì wá sọ ńkọ́? (Mátíù 24:3, Bíbélì Mímọ́) Àwọn kan ń bẹ̀rù pé nígbà yẹn ṣe ni ilẹ̀ ayé máa jóná ráúráú. Ó sì ń wu àwọn míì pé kó dé torí wọ́n fẹ́ rí ohun tó máa ṣẹlẹ̀ nígbà náà. Àwọn míì sì wà tó jẹ́ pé ó ti sú wọn láti máa gbọ́ pé òpin ayé ti sún mọ́lé. Àmọ́, ṣé kì í ṣe pé àròṣọ lásán-làsàn tí àwọn wọ̀nyí ń gbọ́ ni wọ́n kàn ń yọ ara wọn lẹ́nu lé lórí? Kí ló jẹ́ òótọ́ gan-an nípa òpin ayé?
Ó lè yà ẹ́ lẹ́nu tó o bá gbọ́ ohun tí Bíbélì sọ nípa òpin ayé. Lóòótọ́, ó sọ ìdí tó fi yẹ ká máa fojú sọ́nà fún òpin ayé, àmọ́ ó tún sọ pé tí òpin ayé bá pẹ́ jù kó tó dé ó lè sú àwọn èèyàn. A rọ̀ ẹ́ pé kí o wo bí Bíbélì ṣe dáhùn àwọn ìbéèrè kan tí ọ̀pọ̀ máa ń béèrè nípa òpin ayé.
Ṣé ilẹ̀ ayé máa jóná ráúráú ni?
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: “[Ọlọ́run] fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀ sórí àwọn ibi àfìdímúlẹ̀ rẹ̀; a kì yóò mú kí ó ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n fún àkókò tí ó lọ kánrin, tàbí títí láé.”—SÁÀMÙ 104:5.
Kò sí nǹkan kan tó máa pa ilẹ̀ ayé rẹ́, ì báà jẹ́ iná tàbí ohun míì. Ohun tí Bíbélì sọ ni pé aráyé yóò máa gbé orí ilẹ̀ ayé yìí títí láé. Sáàmù 37:29 sọ pé: “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.”—Sáàmù 115:16; Aísáyà 45:18.
Lẹ́yìn tí Ọlọ́run dá ilẹ̀ ayé, ó sọ pé ó “dára gan-an ni.” Èrò tó ní nípa rẹ̀ kò sì tíì yí pa dà. (Jẹ́nẹ́sísì 1:31) Ìyẹn ló fi jẹ́ pé dípò kó máa ṣètò bí ó ṣe máa pa ayé run, ṣe ló ṣèlérí pé òun máa “pa àwọn tí ó ḿ ba ayé jẹ́ run,” kò ní jẹ́ kí ayé bà jẹ́ kọjá àtúnṣe.—Ìṣípayá 11:18, Ìròhìn Ayọ̀.
O lè máa ṣe kàyéfì nípa ohun tí 2 Pétérù 3:7 sọ. Ó sọ pé: “Àwọn ọ̀run àti ilẹ̀ ayé tí ó wà nísinsìnyí ni a tò jọ pa mọ́ fún iná.” Ṣé kì í ṣe pé ilẹ̀ ayé máa jóná ráúráú ni ibí yìí ń sọ ni? Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé, ìgbà míì máa ń wà tí Bíbélì máa ń lo ọ̀rọ̀ náà “àwọn ọ̀run,” “ilẹ̀ ayé,” àti “iná” lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ láti dúró fún àwọn nǹkan míì. Bí àpẹẹrẹ, Jẹ́nẹ́sísì 11:1 sọ pé: “Gbogbo ilẹ̀ ayé ń bá a lọ láti jẹ́ èdè kan.” Àwùjọ ẹ̀dá èèyàn ni “ilẹ̀ ayé” tó wà nínú ẹsẹ yìí ń tọ́ka sí.
Ohun tí Bíbélì ń sọ bọ̀ tó fi dé 2 Pétérù 3:7 fi hàn pé nǹkan míì ni àwọn ọ̀run, ilẹ̀ ayé àti iná tí ibẹ̀ ń sọ dúró fún. Ẹsẹ 5 àti 6 fi ọ̀rọ̀ yìí wé ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà Ìkún-omi ọjọ́ Nóà. Nígbà yẹn, ayé kan pa run, àmọ́ kò sí nǹkan kan tó ṣe ilẹ̀ ayé wa yìí. Àwùjọ èèyàn oníwà ipá ni “ilẹ̀ ayé” tó pa run nínú Ìkún-omi. “Àwọn ọ̀run” tó sì pa run ni àwọn tó ń jọba lórí àwọn èèyàn nígbà yẹn. (Jẹ́nẹ́sísì 6:11) Lọ́nà kan náà, ṣe ni 2 Pétérù 3:7 ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa bí àwùjọ àwọn èèyàn búburú àti àwọn tó ń jọba lé wọn lórí ṣe máa pa run ráúráú bí ìgbà tí iná bá jó nǹkan run.
Kí ló máa ṣẹlẹ̀ nígbà òpin ayé?
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: “Ayé ń kọjá lọ, bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.”—1 JÒHÁNÙ 2:17.
Gbogbo àwọn èèyàn tí kò ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni “ayé” tó máa kọjá lọ, kì í ṣe ilẹ̀ ayé tí à ń gbé yìí. Ṣe ni ọ̀rọ̀ yìí dà bí ìgbà tí oníṣẹ́ abẹ kan fẹ́ gé ibì kan tó ní àrùn jẹjẹrẹ kúrò lára ẹnì kan kí onítọ̀hún má bàa kú. Bákan náà, Ọlọ́run máa ‘ké àwọn aṣebi kúrò’ Sáàmù 37:9) Tí a bá wò ó lọ́nà yìí, ohun rere ni “òpin ayé” máa jẹ́.
kí àwọn ẹni rere lè wá máa gbádùn lórí ilẹ̀ ayé. (Nǹkan ire tí “òpin ayé” máa yọrí sí yìí ni àwọn ìtumọ̀ Bíbélì kan ń fi hàn tí wọ́n fi lo gbólóhùn náà “ìparí ètò àwọn nǹkan” tàbí “ìpari igbeaye yìí.” (Mátíù 24:3; Bibeli Yoruba Atọ́ka) Nígbà tó ti jẹ́ pé ilẹ̀ ayé àti àwọn èèyàn rere kò ní pa run nígbà òpin ayé, ǹjẹ́ kò bọ́gbọ́n mu pé ìgbà ọ̀tun tàbí ètò àwọn nǹkan tuntun máa rọ́pò ti tẹ́lẹ̀? Bíbélì fi hàn pé ó máa rọ́pò rẹ̀, torí ó sọ̀rọ̀ nípa “ètò àwọn nǹkan tí ń bọ̀.”—Lúùkù 18:30.
Jésù pe ìgbà tó ń bọ̀ yìí ní àkókò àtúndá ayé. Ní àkókò yìí, ó máa mú aráyé pa dà sí ipò tí Ọlọ́run ní lọ́kàn fún wa ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀. (Mátíù 19:28, Ìròhìn Ayọ̀) A máa wá gbádùn
-
Párádísè lórí ilẹ̀ ayé ní àlàáfíà, gbogbo èèyàn yóò sì ní aásìkí.—Aísáyà 35:1; Míkà 4:4.
-
Iṣẹ́ tó dára, tó sì ń tẹ́ni lọ́rùn.—Aísáyà 65:21-23.
-
Ìwòsàn gbogbo onírúurú àìsàn pátá.—Aísáyà 33:24.
-
Ara tó le koko títí lọ dípò ọjọ́ ogbó.—Jóòbù 33:25.
-
Àjíǹde àwọn òkú.—Jòhánù 5:28, 29.
Tí a bá ń ṣe “ìfẹ́ Ọlọ́run,” ìyẹn àwọn ohun tó retí pé ká máa ṣe, a kò ní máa bẹ̀rù òpin ayé. Dípò bẹ́ẹ̀, ṣe ni a ó máa fojú sọ́nà pé kí ó dé.
Ǹjẹ́ òpin ayé ti sún mọ́lé lóòótọ́?
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: “Nígbà tí ẹ bá rí nǹkan wọ̀nyí tí ń ṣẹlẹ̀, kí ẹ mọ̀ pé ìjọba Ọlọ́run sún mọ́lé.”—LÚÙKÙ 21:31.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Richard Kyle sọ nínú ìwé kan tó sọ̀rọ̀ nípa ọjọ́ ìkẹyìn pé “gbogbo nǹkan tó dédé ń dà rú àti rúkèrúdò tó gbilẹ̀ ló jẹ́ kí àwọn èèyàn máa sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé ìgbà báyìí ni òpin ayé máa dé.” Bó sì ṣe máa ń rí nìyẹn, pàápàá nígbà tí àwọn èèyàn kò bá mọ ohun tó ń fa ìdàrúdàpọ̀ àti rúkèrúdò tó ń wáyé.—The Last Days Are Here Again.
Ṣùgbọ́n ní ti àwọn wòlíì inú Bíbélì tó sọ̀rọ̀ nípa àkókò òpin, kì í ṣe àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń rúni lójú lásìkò wọn ni wọ́n ń gbìyànjú láti ṣàlàyé. Ọlọ́run ló mí sí wọn láti ṣàpèjúwe àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó máa fi hàn pé òpin ayé ti dé. Wo díẹ̀ lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí wọ́n sọ, kí o wá fúnra rẹ pinnu bóyá wọ́n ti ń ṣẹlẹ̀ lákòókò wa.
- Ogun, ìyàn, ìmìtìtì ilẹ̀ àti àjàkálẹ̀ àrùn.—
-
Ìwà àìlófin túbọ̀ ń pọ̀ sí i.—Mátíù 24:12.
-
Àwọn èèyàn ń ba ilẹ̀ ayé jẹ́.—Ìṣípayá 11:18.
-
Àwọn èèyàn fẹ́ràn owó, adùn àti ara wọn ṣùgbọ́n wọn kò nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run.—2 Tímótì 3:2, 4.
-
Àwọn ìdílé ń tú ká.—2 Tímótì 3:2, 3.
-
Àwọn èèyàn kò ka àwọn àmì tó ń fi hàn pé òpin ti sún mọ́lé sí.—Mátíù 24:37-39.
-
Iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tó kárí ayé.—Mátíù 24:14.
Jésù sọ pé tí “gbogbo nǹkan wọ̀nyí” bá ti ń ṣẹlẹ̀ kí á mọ̀ pé òpin ayé ti sún mọ́lé. (Mátíù 24:33) Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà pé àwọn ẹ̀rí yìí dájú, a sì ń wàásù ohun tí a gbà gbọ́ yìí fún àwọn èèyàn ní ilẹ̀ igba ó lé mẹ́rìndínlógójì [236].
Ṣé bí òpin kò ṣe dé láwọn àsìkò kan tí àwọn èèyàn rò pé ó máa dé fi hàn pé kò ní dé mọ́?
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: “Ìgbà yòówù tí ó jẹ́ tí wọ́n bá ń sọ pé: ‘Àlàáfíà àti ààbò!’ nígbà náà ni ìparun òjijì yóò dé lọ́gán sórí wọn gẹ́gẹ́ bí ìroragógó wàhálà lórí obìnrin tí ó lóyún; wọn kì yóò sì yèbọ́ lọ́nàkọnà.”—1 TẸSALÓNÍKÀ 5:3.
Bíbélì fi ìparun ayé yìí wé ìrora ìrọbí tí obìnrin máa ń ní tó bá fẹ́ bímọ. Ṣe ni ìrora tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀ yìí máa ń ṣàdédé bẹ̀rẹ̀. A lè fi àkókò tó ṣáájú òpin ayé wé ìgbà tí obìnrin kan bá lóyún. Aláboyún náà ti mọ̀ pé oríṣiríṣi àmì ni òun yóò máa rí kó tó di pé òun bímọ. Dókítà tó ń tọ́jú rẹ̀ lè ti fojú bu ọjọ́ tó máa bímọ; síbẹ̀, tí ọjọ́ náà bá tiẹ̀ yẹ̀, ó ṣì máa dá obìnrin náà lójú pé òun ò ní pẹ́ bímọ. Lọ́nà kan náà, bó ṣe jẹ́ pé òpin kò dé láwọn ìgbà tí àwọn èèyàn fọkàn sí pé ó máa dé kò yí àwọn àmì tó ń fi hàn kedere pé “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” la wà yìí pa dà.—2 Tímótì 3:1.
O lè wá máa ronú pé, ‘Tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ ni àwọn àmì tó ń fi hàn pé òpin ti sún mọ́lé ti fara hàn kedere, kí nìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn ò ṣe dá wọn mọ̀?’ Bíbélì sọ pé tí òpin bá ti ń sún mọ́lé, ọ̀pọ̀ èèyàn kò tiẹ̀ ní ka àwọn àmì tí yóò máa fara hàn sí. Dípò tí wọ́n á fi gbà pé gbogbo nǹkan tó ń burú sí i ń fi hàn pé òpin ayé ti dé, ṣe ni wọ́n á máa fi àwọn tó gbà bẹ́ẹ̀ ṣe yẹ̀yẹ́ pé: “Láti ọjọ́ tí àwọn baba ńlá wa ti sùn nínú ikú, ohun gbogbo ń bá a lọ gẹ́gẹ́ bí ó ti 2 Pétérù 3:3, 4) Èyí ń fi hàn pé, láìka bí àwọn àmì ọjọ́ ìkẹyìn ti fara hàn kedere tó, ọ̀pọ̀ èèyàn kò ní kọbi ara sí i.—Mátíù 24:38, 39.
rí láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìṣẹ̀dá.” (Àpilẹ̀kọ yìí ti ṣọ̀rọ̀ nípa díẹ̀ lára àwọn ẹ̀rí tó wà nínú Bíbélì tó fi hàn pé òpin ti sún mọ́lé. * Ṣé wàá fẹ́ mọ̀ nípa àwọn ẹ̀rí míì? Tó o bá fẹ́ bẹ́ẹ̀, o máa dára kí o sọ fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé kí wọ́n wá máa kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́! Wọ́n lè máa wá bá ẹ nílé tàbí ní ibòmíì tó bá rọrùn fún ẹ, kódà wọ́n lè máa bá ẹ sọ̀rọ̀ látorí fóònù. Gbogbo ohun tó máa ná ẹ kò jù pé kó o yọ̀ǹda àkókò rẹ, àmọ́ ó dájú pé wàá jàǹfààní tó pọ̀ gan-an ni.
^ ìpínrọ̀ 39 Fún ìsọfúnni síwájú sí i, ka orí 9 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àkòrí rẹ̀ ni “Ṣé ‘Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn’ La Wà Yìí?” Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.