Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

BÍBÉLÌ MÁA Ń YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀWỌN ÈÈYÀN PA DÀ

“Ní Gbẹ̀yìn Gbẹ́yín Mo Ti Wá Ní Ojúlówó Òmìnira.”

“Ní Gbẹ̀yìn Gbẹ́yín Mo Ti Wá Ní Ojúlówó Òmìnira.”
  • ỌDÚN TÍ WỌ́N BÍ MI: 1981

  • ORÍLẸ̀-ÈDÈ MI: AMẸ́RÍKÀ

  • IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: ỌMỌ ONÍNÀÁKÚNÀÁ

ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ:

Ìlú Moundsville tó wà ní ìtòsí Ohio River ní àríwá ìpínlẹ̀ West Virginia ní Amẹ́ríkà ni wọ́n bí mi sí. Ibẹ̀ jẹ́ ìlú tó tòrò. Èmi ni ìkejì nínú àwọn ọmọ mẹ́rin tí àwọn òbí mi bí. Mẹ́ta nínú wa ló jẹ́ ọkùnrin, nítorí náà kò sígbà tí ilé wa máa ń pa rọ́rọ́. Àwọn òbí mi jẹ́ òṣìṣẹ́ aláápọn, olóòótọ́ ni wọ́n, wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn. Lóòótọ́, ìdílé wa kì í ṣe ọlọ́rọ̀ síbẹ̀ ohun tí a nílò kì í wọ́n wa. Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni àwọn òbí mi, láti kékeré wa ni wọ́n sì ti ń gbin àwọn ìlànà Bíbélì sí wa lọ́kàn.

Nígbà tí mo bàlágà, èròkérò mú kí ọkàn mi bẹ̀rẹ̀ sí í ṣí kúrò nínú àwọn ìlànà Bíbélì tí wọ́n ti kọ́ mi. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyè méjì pé téèyàn bá ń tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì bóyá lèèyàn á fi lè gbádùn ara rẹ̀, bóyá sì ni ayé rẹ̀ á fi lè lójú. Mo ronú pé ìgbà téèyàn bá ráyè jayé orí ẹ̀ bó ṣe wù ú ló lè láyọ̀. Bí mi ò ṣe lọ sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́ nìyẹn. Ni ẹ̀gbọ́n mi àti àbúrò mi obìnrin náà bá ya ìyàkuyà bíi tèmi. Àwọn òbí wa ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti pe orí wa wálé, àmọ́ a kọ etí ikún sí wọn.

Mi ò mọ̀ pé ṣe ni irú òmìnira tí mò ń wá yìí máa jẹ́ kí n sọ ìwàkiwà di bárakú. Lọ́jọ́ kan, bí mo ṣe ń bọ̀ láti ilé ìwé, ọ̀rẹ́ mi kan fi sìgá lọ̀ mí. Mo gbà á mo sì mu ún. Láti ọjọ́ yẹn ni mo ti bẹ̀rẹ̀ sí í lọ́wọ́ nínú àwọn ìwà míì tó lè ba ayé mi jẹ́. Nígbà tó yá, mo bẹ̀rẹ̀ sí í lo oògùn olóró nílòkulò, mò ń mu ọtí àmujù, mo sì ń ṣe ìṣekúṣe. Láàárín ọdún mélòó kan lẹ́yìn náà, mo bẹ̀rẹ̀ sí í lo àwọn oògùn olóró tó tún le ju àwọn tí mo ń lò tẹ́lẹ̀, ọ̀pọ̀ nínú wọn sì di bárakú fún mi. Nígbà tí gbogbo èyí wọ̀ mí lẹ́wù tán, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ta oògùn olóró kí n lè máa rí owó ra àwọn nǹkan tó ti di bárakú fún mi yìí.

Gbogbo bí mo ṣe ń gbìyànjú láti pa ẹ̀rí ọkàn mi mọ́lẹ̀ ló ń yọ mí lẹ́nu ṣáá, pé ohun tí mò ń ṣe kò dáa. Àmọ́ mo gbà pé ọ̀rọ̀ mi ti bà jẹ́ kọjá àtúnṣe. Bí mo bá tiẹ̀ wà láàárín èrò lágbo àríyá, ṣe ló máa ń ṣe mí bíi pé mo dá wà, ìdààmú ọkàn á sì bá mi. Nígbà míì, tí mo bá ronú lórí bí àwọn òbí mi ṣe jẹ́ ọmọlúwàbí àti òbí rere, ó máa ń yà mí lẹ́nu bí mo ṣe wá ya ìyàkuyà.

BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ:

Mo ti ro ara mi pin pé mi ò lè yí pa dà, àmọ́ àwọn míì kò rò bẹ́ẹ̀. Lọ́dún 2000, àwọn òbí mi pè mí wá sí àpéjọ àgbègbè àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Mo ṣáà rọ́jú lọ. Àfi bí mo ṣe wá rí i pé ẹ̀gbọ́n mi àti àbúrò mi obìnrin tó ti fi ìjọsìn Ọlọ́run sílẹ̀ náà wá síbẹ̀.

Bí a ṣe wà ní àpéjọ yẹn, mo rántí pé mo wá sí ibi eré àwọn olórin rọ́ọ̀kì tí wọ́n ṣe ní gbọ̀ngàn yìí kan náà ní nǹkan bí ọdún kan sẹ́yìn. Ìyàtọ̀ tí mo rí láàárín agbo eré yẹn àti àpéjọ tí mo wá yìí mú mi ronú jinlẹ̀ gan-an. Nígbà eré yẹn, ṣe ni ibi tí wọ́n ń lò yìí dọ̀tí, tí èéfín sìgá sì gbalẹ̀ kan. Èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn tó wá síbẹ̀ ló ní ẹ̀mí ìkórìíra, orin tí wọ́n ń kọ níbẹ̀ sì ń kó ìdààmú ọkàn báni. Àmọ́ ní àpéjọ yìí àwọn tó ń láyọ̀ ní tòótọ́ ló yí mi ká. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ pẹ́ tí a ti ríra gbẹ̀yìn, tìfẹ́tìfẹ́ ni wọ́n kí mi káàbọ̀. Ibi tí wọ́n ti ṣe àpéjọ náà mọ́ tónítóní, ọrọ̀ tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa ni wọ́n sọ níbẹ̀. Ipa rere tí mo rí pé ẹ̀kọ́ Bíbélì ń ní lórí èèyàn, mú kí n wá máa ṣe kàyéfì nípa ìdí tí mo tiẹ̀ fi kọ irú ẹ̀kọ́ dáadáa bẹ́ẹ̀ sílẹ̀!—Aísáyà 48:17, 18.

“Bíbélì ti jẹ́ kí n jáwọ́ nínú lílo oògùn olóró, mi ò sì tà á mọ́. Ní báyìí èmi náà ti wá di ọmọlúwàbí láwùjọ”

Lẹ́yìn àpéjọ yẹn, mo pa dà sínú ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ohun tí ẹ̀gbọ́n mi àti àbúrò mi gbọ́ tí wọ́n sì rí níbi àpéjọ yẹn wọ̀ wọ́n lọ́kàn gan-an, àwọn náà sì pinnu láti pa dà. Àwa mẹ́tẹ̀ẹ̀ta la sì gbà kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa kọ́ wa ní ẹ̀kọ́ Bíbélì.

Ẹsẹ Bíbélì tó wọ̀ mí lọ́kàn jù ni Jákọ́bù 4:8 tó sọ pé: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.” Mo rí i pé tí mo bá fẹ́ sún mọ́ Ọlọ́run, mo ní láti yí ọ̀nà tí mò ń gbà gbé ìgbé ayé mi pa dà. Lára ìyípadà tí mo ní láti ṣe ni pé kí n jáwọ́ nínú sìgá mímu, lílo oògùn olóró àti ọtí àmujù.—2 Kọ́ríńtì 7:1.

Mo pa àwọn ọ̀rẹ́kọ́rẹ̀ẹ́ tí mò ń bá rìn tẹ́lẹ̀ tì, mo wá yan àwọn ọ̀rẹ́ tuntun láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ipa ribiribi ni Kristẹni alàgbà tó kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kó lórí mi. Ó máa ń pè mí lórí fóònù lóòrèkóòrè, ó sì máa ń yà kí mi tó bá ń kọjá níwájú ilé mi. Ọ̀kan nínú àwọn ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́ ló jẹ́ títí dòní.

Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2001, èmi, ẹ̀gbọ́n mi àti àbúrò mi obìnrin ṣe ìrìbọmi láti fi hàn pé a ti ya ara wa sí mímọ́ fún Ọlọ́run. Inú àwọn òbí wa àti àbúrò wa ọkùnrin tí kò fi ìjọsìn Ọlọ́run sílẹ̀ dùn gan-an ni nígbà tí gbogbo wa tún pa dà ń jọ́sìn Jèhófà ní ìṣọ̀kan.

ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ:

Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ èrò mi ni pé àwọn ìlànà Bíbélì ti ń káni lọ́wọ́ kò jù, àmọ́ ní báyìí èmi fúnra mi ti wá gbà pé ààbò gidi ni wọ́n jẹ́. Bíbélì ti jẹ́ kí n jáwọ́ nínú lílo oògùn olóró, mi ò sì tà á mọ́. Ní báyìí èmi náà ti wá di ọmọlúwàbí láwùjọ.

Mo dẹni tó wà lára ẹgbẹ́ àwọn ará tó ń sin Jèhófà kárí ayé. Àwọn wọ̀nyí ní ìfẹ́ tòótọ́ láàárín ara wọn, wọ́n sì ń jọ́sìn Ọlọ́run ní ìṣọ̀kan. (Jòhánù 13:34, 35) Láàárín àwùjọ yìí ni mo ti rí Adrianne aya mi ọ̀wọ́n. Mo nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an, mo sì ń ṣìkẹ́ rẹ̀. Àwa méjèèjì ń láyọ̀ bí a ṣe jọ ń sin Ẹlẹ́dàá wa.

Mi ò gbé ìgbé ayé onímọtara-ẹni-nìkan mọ́, dípò bẹ́ẹ̀ ṣe ni mo yọ̀ǹda ara mi láti máa lo àkókò tó pọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, tí mo sì ń kọ́ àwọn èèyàn ní bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe lè ṣe wọ́n láǹfààní. Ohun tí mò ń ṣe yìí ló ń jẹ́ kí n ní ayọ̀ tó ga jù láyé. Ní báyìí, mo lè fi gbogbo ẹnu sọ pé Bíbélì ti yí ìgbésí ayé mi pa dà. Ní gbẹ̀yìn gbẹ́yín mo ti wá ní ojúlówó òmìnira.