Ohun Tí Bíbélì Sọ
Ibo ni Èṣù ti wá?
Ọlọ́run kọ́ ló dá Èṣù. Áńgẹ́lì kan tí Ọlọ́run dá ló sọ ara rẹ̀ di ẹni ibi, tó fi wá di Èṣù, tí a tún ń pè ní Sátánì. Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fi hàn pé Èṣù ti fìgbà kan rí jẹ́ olóòótọ́ àti aláìlẹ́ṣẹ̀. Èyí wá fi hàn pé áńgẹ́lì olóòótọ́ tó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Ọlọ́run ni Èṣù jẹ́ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀.—Ka Jòhánù 8:44.
Báwo ni áńgẹ́lì rere kan ṣe lè wá di Èṣù?
Ṣe ni áńgẹ́lì tó di Èṣù yàn láti ta ko Ọlọ́run, ó sì tún fa Ádámù àti Éfà, tọkọtaya àkọ́kọ́, sínú ìdìtẹ̀ rẹ̀. Bó ṣe sọ ara rẹ̀ di Sátánì, tó túmọ̀ sí “Alátakò” nìyẹn.—Ka Jẹ́nẹ́sísì 3:1-5; Ìṣípayá 12:9.
Bí àwọn áńgẹ́lì olóye tó kù ṣe ní òmìnira láti yàn bóyá àwọn á ṣe ohun tó tọ́ tàbí èyí tí kò tọ́, náà ni áńgẹ́lì tó sọ ara rẹ̀ di Èṣù ṣe ní òmìnira láti yan èyí tó fẹ́. Àmọ́ ohun tí ọkàn tirẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í fà sí ni pé kí àwọn ẹ̀dá míì máa sin òun. Ògo tó fẹ́ máa gbà yìí jẹ ẹ́ lógún ju pé kó máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run lọ.—Ka Mátíù 4:8, 9; Jákọ́bù 1:13, 14.
Báwo ni Èṣù ṣe wá ń bá a lọ láti máa darí àwọn èèyàn? Ǹjẹ́ ó yẹ kó o máa bẹ̀rù rẹ̀? Wàá rí ìdáhùn àwọn ìbéèrè yìí nínú Bíbélì.