Sún Mọ́ Ọlọ́run
“Èwo Ni Èkínní Nínú Gbogbo Òfin?”
Tí a bá fẹ́ rí ojú rere Ọlọ́run, kí ló yẹ ká máa ṣe? Ṣé òfin tó gùn jànràn janran ló retí pé ká máa tẹ̀ lé ni? Rárá o, kò rí bẹ́ẹ̀. Jésù Ọmọ Ọlọ́run sọ pé a lè fi ọ̀rọ̀ kan ṣoṣo péré ṣe àkópọ̀ gbogbo ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ká máa ṣe.—Ka Máàkù 12:28-31.
Jẹ́ ká kọ́kọ́ wo ohun tó ṣẹlẹ̀ kí Jésù tó sọ ọ̀rọ̀ yìí. Ṣe ni Jésù ń kọ́ àwọn èèyàn nínú tẹ́ńpìlì ní ọjọ́ kọkànlá oṣú Nísàn, ìyẹn ọjọ́ mélòó kan sí ìgbà tí wọ́n máa pa á. Àwọn ọ̀tá rẹ̀ wá ń bí i ní àwọn ìbéèrè tó sábà máa ń fa àríyànjiyàn láwùjọ, kí wọ́n bàa lè gbá ọ̀rọ̀ mú mọ́ ọn lẹ́nu. Bí Jésù ṣe ń dáhùn àwọn ìbéèrè tí wọ́n ń bi í lọ́kọ̀ọ̀kan, wọn kì í rí ọ̀rọ̀ sọ mọ́. Ni ẹnì kan bá bi í pé: “Èwo ni èkínní nínú gbogbo òfin?”—Máàkù 12:28, Bíbélì Mímọ́.
Ìbéèrè tó le nìyẹn. Torí àwọn Júù kan sábà máa ń bá ara wọn jiyàn nípa èwo ni èkíní tàbí èyí tó ṣe pàtàkì jù nínú òfin tó ju ẹgbẹ̀ta [600] tó wà nínú Òfin Mósè. Ó sì jọ pé àwọn míì tún ń jiyàn pé òfin kan kò ju èkejì lọ, torí náà kò tọ́ kéèyàn rò pé àwọn òfin kan ṣe pàtàkì ju òmíràn lọ. Báwo ni Jésù ṣe máa wá dáhùn ìbéèrè yẹn?
Nígbà tí Jésù máa dáhùn, kò tọ́ka sí òfin kan ṣoṣo, òfin méjì ló mẹ́nu kàn. Àkọ́kọ́, ó ní: “Kí ìwọ sì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò-inú rẹ àti pẹ̀lú gbogbo okun rẹ.” (Ẹsẹ 30; Diutarónómì 6:5) Bí Bíbélì ṣe lo “ọkàn-àyà,” “èrò-inú,” “ọkàn,” àti “okun” níbí yìí kò túmọ̀ sí pé ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn dá wà lọ́tọ̀ o. * Ohun tó túmọ̀ sí ni pé: A gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tọkàntara. Ìyẹn ni pé ká fi gbogbo agbára ìrònú wa àti gbogbo ohun tá a jẹ́ àti gbogbo ohun tá a ní nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Bí ìwé kan tó ń ṣàlàyé Bíbélì ṣe sọ ọ́ ni pé: “A gbọ́dọ̀ fi gbogbo nǹkan pátápátá fẹ́ràn Ọlọ́run.” Tó o bá fẹ́ràn Ọlọ́run lọ́nà bẹ́ẹ̀, wàá máa sa gbogbo ipá rẹ lójoojúmọ́ láti gbé ìgbé ayé rẹ lọ́nà tí wàá fi lè rí ojú rere rẹ̀.—1 Jòhánù 5:3.
Ohun kejì tí Jésù sọ ni pé: “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.” (Ẹsẹ 31; Léfítíkù 19:18) Níní ìfẹ́ Ọlọ́run àti ọmọnìkejì wa wọnú ara wọn. Ìyẹn ni pé ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ̀. (1 Jòhánù 4:20, 21) Tí a bá fẹ́ràn ọmọnìkejì wa bí ara wa, bí a ṣe fẹ́ kí wọ́n ṣe sí wa ni a ó máa ṣe sí wọn. (Mátíù 7:12) A ó sì tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tó dá àwa àti àwọn náà ní àwòrán rẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 1:26.
A lè fi gbólóhùn kan péré ṣe àkópọ̀ gbogbo ohun tí Jèhófà fẹ́ kí àwọn olùjọsìn rẹ̀ máa ṣe, òun ni pé kí wọ́n ní ìfẹ́
Báwo ló ṣe ṣe pàtàkì tó pé ká nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti ọmọnìkejì wa? Jésù ní: “Kò sí àṣẹ mìíràn tí ó tóbi ju ìwọ̀nyí lọ.” (Ẹsẹ 31) Ní ibòmíì tí Jésù ti sọ ọ̀rọ̀ yìí nínú Bíbélì, ohun tó sọ ni pé orí àṣẹ méjì yìí ni gbogbo òfin yòókù so kọ́.—Mátíù 22:40.
Ohun tí èèyàn á máa ṣe táá fi rí ojú rere Ọlọ́run kò ṣòroó mọ̀. A lè fi gbólóhùn kan péré ṣe àkópọ̀ gbogbo ohun tó fẹ́ ká máa ṣe, òun ni pé ká ní ìfẹ́. Ohun tí Jèhófà ń fẹ́ kí gbogbo àwọn tó ti ń sin òun látẹ̀yìn wá máa ṣe nìyẹn. Ohun kan náà tó sì ń fẹ́ kí àwọn tí yóò máa sin òun ṣe nìyẹn títí láé. Ṣùgbọ́n kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹnu lásán tàbí bí nǹkan ṣe rí lára ẹni ló ń fi hàn pé èèyàn ní ìfẹ́. Ó gbọ́dọ̀ hàn nínú ìṣe ẹni. (1 Jòhánù 3:18) O ò ṣe kọ́ bí o ṣe lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, Ọlọ́run tó “jẹ́ ìfẹ́” àti bí o ṣe lè fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ rẹ̀?—1 Jòhánù 4:8.
Bíbélì kíkà tá a dábàá fún March
^ ìpínrọ̀ 6 Nínú Bíbélì, ọ̀rọ̀ náà “ọkàn,” túmọ̀ sí èèyàn lódindi látòkè délẹ̀. Torí náà “ọkàn-àyà,” “èrò inú” àti “okun” wà lára ohun tó para pọ̀ jẹ́ “ọkàn.”