Sún Mọ́ Ọlọ́run
“Ẹ Máa Bá A Nìṣó Ní Bíbéèrè, A Ó sì Fi Í fún Yín”
Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Olúwa, kọ́ wa bí a ṣe ń gbàdúrà.” (Lúùkù 11:1) Jésù sọ àpèjúwe méjì nínú ìdáhùn rẹ̀ tó fi kọ́ wa ní bí a ṣe lè gbàdúrà, kí Ọlọ́run sì gbọ́ àdúrà wa. Tó bá ti rú ọ lójú rí pé bóyá ni Ọlọ́run máa ń gbọ́ àdúrà rẹ, ó dájú pé wàá fẹ́ mọ ìdáhùn Jésù.—Ka Lúùkù 11:5-13.
Àpèjúwe àkọ́kọ́ dá lórí ẹni tó ń gbàdúrà. (Lúùkù 11:5-8) Nínú ìtàn náà, àlejò kan dé sí ilé ọkùnrin kan ní òru. Kò sì ní oúnjẹ tó máa fún àlejò náà. Torí pé ọ̀rọ̀ náà bọ́ sí kánjúkánjú, ọkùnrin yìí lọ tọrọ búrẹ́dì lọ́wọ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan láìro ti pé ọ̀gànjọ́ òru ni. Ọ̀rẹ́ rẹ̀ yìí kọ́kọ́ lọ́ra láti dìde torí òun àti ìdílé rẹ̀ ti sùn. Àmọ́ láì tiẹ̀ tijú rárá, ọkùnrin yìí ṣáà ń bẹ ọ̀rẹ́ rẹ̀ ṣáá, nígbà tó yá, ọ̀rẹ́ rẹ̀ dìde, ó sì fún un ní nǹkan tó ń fẹ́. *
Kí ni àpèjúwe yìí kọ́ wa nípa àdúrà? Jésù fi kọ́ wa pé kò yẹ ká jẹ́ kó sú wa, ìyẹn ni pé ká máa bá a nìṣó ní bíbéèrè, ní wíwá kiri àti ní kíkan ilẹ̀kùn. (Lúùkù 11:9, 10) Kí nìdí? Ṣé ohun tí Jésù wá ń sọ ni pé Ọlọ́run máa ń lọ́ra láti dáhùn àdúrà wa ni? Rárá o! Ohun tí Jésù ń sọ ni pé Ọlọ́run kò dà bí ọ̀rẹ́ tí kò tètè dá ọkùnrin yẹn lóhùn, torí pé ó máa ń yá Ọlọ́run lára láti ṣe ohun tí àwọn tó ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ bá béèrè. A ń fi hàn pé a ní irú ìgbàgbọ́ yìí tí a bá ń tẹra mọ́ àdúrà, tí a ò sì jẹ́ kó sú wa. Tí a bá ń bá a lọ ní bíbéèrè, ṣe ni a ń fi hàn pé òótọ́ la nílò ohun tí à ń béèrè, àti pé ó dá wa lójú pé Ọlọ́run máa ṣe é fún wa, tó bá ti bá ìfẹ́ rẹ̀ mu.—Máàkù11:24; 1 Jòhánù 5:14.
Àpèjúwe kejì dá lórí Jèhófà tó jẹ́ “Olùgbọ́ àdúrà.” (Sáàmù 65:2) Jésù béèrè pé: “Baba wo ní ń bẹ láàárín yín tí ó jẹ́ pé, bí ọmọ rẹ̀ bá béèrè ẹja, bóyá tí yóò fi ejò lé e lọ́wọ́ dípò ẹja? Tàbí bí ó bá tún béèrè ẹyin, tí yóò fi àkekèé lé e lọ́wọ́?” Ìdáhùn ìbéèrè yìí kò lọ́jú pọ̀ rárá, torí pé kò sí baba onífẹ̀ẹ́ tí yóò fún àwọn ọmọ rẹ̀ ní ohun tó máa pa wọ́n lára. Jésù wá sọ ìtumọ̀ àpèjúwe yìí: Tí àwọn baba tó jẹ́ ẹ̀dá aláìpé bá ń “fi ẹ̀bùn rere fún” àwọn ọmọ wọn, “mélòómélòó ni Baba tí ń bẹ ní ọ̀run yóò fi ẹ̀mí mímọ́,” ìyẹn ẹ̀bùn tó dára jù lọ, fún àwọn ọmọ rẹ̀ tó ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀-ayé! *—Lúùkù 11:11-13; Mátíù 7:11.
Ó máa ń yá Ọlọ́run lára láti ṣe ohun tí àwọn tó ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ bá béèrè lọ́wọ́ rẹ̀
Kí ni àpèjúwe yìí kọ́ wa nípa Jèhófà tó jẹ́ “Olùgbọ́ àdúrà”? Jésù fẹ́ ká mọ Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Baba tó ń tọ́jú wa, tó sì ṣe tán láti pèsè ohun tí àwọn ọmọ rẹ̀ nílò. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn tó ń sin Jèhófà lè sọ ohun tó ń jẹ wọ́n lọ́kàn fún un fàlàlà nínú àdúrà wọn. Bí wọ́n sì ṣe mọ̀ pé ohun tó dára jù lọ ni Ọlọ́run ń fẹ́ fún wọn máa ń mú kí wọ́n fara mọ́ ohun tó bá ṣe fún wọn, kódà bí kì í bá ṣe ohun tí wọ́n ń retí pé kó ṣe fún wọn nìyẹn. *
Bíbélì kíkà tá a dábàá fún April
^ ìpínrọ̀ 4 Àpèjúwe Jésù máa ń bá ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú àṣà àti ìṣe àwọn èèyàn mu. Ojúṣe pàtàkì ni àwọn Júù ka ṣíṣe àlejò sí. Ìdílé kọ̀ọ̀kan máa ń ṣe búrẹ́dì púpọ̀ lóòjọ́, torí náà àwọn Júù sábà máa ń tọrọ lọ́wọ́ ara wọn tí búrẹ́dì wọn bá tán. Bákan náà, tí wọ́n bá jẹ́ tálákà, ilẹ̀ ni gbogbo ìdílé náà máa sùn sí nínú yàrá kan ṣoṣo.
^ ìpínrọ̀ 6 Jésù sábà máa ń lo ọ̀rọ̀ náà “mélòómélòó” láti fi àwọn ohun tí a ti mọ̀ kọ́ wa ní àwọn ohun pàtàkì tí a kò tíì mọ̀, kó lè fìdí ọ̀rọ̀ rẹ̀ múlẹ̀.
^ ìpínrọ̀ 7 Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa bí o ṣe lè máa gbàdúrà, kí Ọlọ́run sì gbọ́ àdúrà rẹ, ka orí 17 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.