ÌJÍRÒRÒ LÁÀÁRÍN ẸLẸ́RÌÍ JÈHÓFÀ ÀTI ẸNÌ KAN
Ǹjẹ́ Ìyà Tó Ń Jẹ Wá Tiẹ̀ Kan Ọlọ́run?
Ìjíròrò kan tó lè wáyé láàárín Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan àti ẹnì kan la fẹ́ gbé yẹ̀ wò yìí. Ẹ jẹ́ ká sọ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó ń jẹ́ Bọ́lá lọ sí ilé obìnrin kan tó ń jẹ́ Ṣadé.
KÍ LÓ DÉ TÍ ỌLỌ́RUN FI JẸ́ KÍRÚ NǸKAN BẸ́Ẹ̀ ṢẸLẸ̀?
Bọ́lá: Ẹ kú ojúmọ́ o. Inú mi dùn láti rí yín. Bọ́lá lorúkọ mi.
Ṣadé: Ṣadé lorúkọ tèmi. Èmi náà láyọ̀ láti rí yín.
Bọ́lá: Mò ń fún gbogbo èèyàn tó wà ládùúgbò yín ní ìwé yìí. Àkọlé rẹ̀ ni Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Òtítọ́? Ẹ gbà, tiyín nìyí.
Ṣadé: Ṣé kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn ló wà nínú rẹ̀?
Bọ́lá: Ohun tó kan gbogbo wa ló wà nínú rẹ̀. Ẹ wo ìbéèrè mẹ́fà tó wà lójú ìwé àkọ́kọ́ nínú ìwé yẹn. Èwo nínú àwọn ìbéèrè yìí—
Ṣadé: Ẹ má wulẹ̀ yọra yín lẹ́nu. Tí ẹ bá ń wàásù fún mi, ẹ kàn ń fi àkókò yín ṣòfò ni.
Bọ́lá: Ṣé kò sí tẹ́ ẹ fi sọ bẹ́ẹ̀?
Ṣadé: Ṣẹ́ ẹ rí i, ẹ jẹ́ ń sòótọ́ fún yín, mi ò rò pé mo nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run.
Bọ́lá: Ṣé ohun tí ẹ ń sọ ni pé ẹ ò gbà pé Ọlọ́run wà rárá?
Ṣadé: Rárá o, mo máa ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì nígbà tí mo wà ní kékeré. Àmọ́, ó ti pẹ́ gan-an báyìí tí mi ò ti lọ mọ́.
Bọ́lá: Ẹ máà bínú o. Kì í ṣe torí kí n lè fi dandan mú kẹ́ ẹ gba ohun tí mo bá sọ fún yín ni mo ṣe wá síbí. Àmọ́ ohun tẹ́ ẹ sọ yìí wọ̀ mí lọ́kàn. Ẹ jọ̀ọ́, kí ló fà á tẹ́ ẹ fi rò pé kò sí Ọlọ́run?
Ṣadé: Jàǹbá ọkọ̀ ṣẹlẹ̀ sí ìyá tó bí mi ní nǹkan bí ọdún mẹ́tàdínlógún sẹ́yìn.
Bọ́lá: Áà, ṣé wọn ò fara pa ṣá?
Ṣadé: Wọ́n fara pa o, kódà wọn ò lè rìn mọ́ látìgbà yẹn.
Bọ́lá: Ó mà ṣe o. Abájọ tí ọkàn yín fi gbọgbẹ́.
Ṣadé: Torí ẹ̀ gan-an ni mo ṣe ń wò ó pé, tó bá jẹ́ pé Ọlọ́run wà, kí ló dé tó fi jẹ́ kírú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀? Kí nìdí tí Ọlọ́run fi ń jẹ́ kí ìyà máa jẹ wá báyìí?
ṢÉ Ẹ̀ṢẸ̀ NI KÉÈYÀN BÉÈRÈ ÌDÍ TÍ ỌLỌ́RUN FI JẸ́ KÁ MÁA JÌYÀ?
Bọ́lá: Ọ̀rọ̀ yín yé mi, ṣàṣà lẹni tí irú rẹ̀ máa ṣẹlẹ̀ sí tí ọkàn rẹ̀ kò ní gbọgbẹ́. Ìwà ẹ̀dá ni pé tí nǹkan aburú bá ṣẹlẹ̀, a máa ń fẹ́ mọ ohun tó fà á. Ẹ jẹ́ mọ̀ pé àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin kan tí Bíbélì sọ pé wọ́n jẹ́ olóòótọ́ ronú lọ́nà bẹ́ẹ̀.
Ṣadé: Ṣé lóòótọ́?
Bọ́lá: Bẹ́ẹ̀ ni. Ẹ jẹ́ kí n fi àpẹẹrẹ kan hàn yín nínú Bíbélì.
Ṣadé: Ó dáa, kò síṣòro.
Bọ́lá: Ẹ wo àwọn ìbéèrè tí wòlíì olóòótọ́ kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Hábákúkù bi Ọlọ́run, nínú ìwé Hábákúkù orí 1, ẹsẹ 2 àti 3, ó kà pé: “Yóò ti pẹ́ tó, Jèhófà, tí èmi yóò fi kígbe fún ìrànlọ́wọ́, tí ìwọ kò sì gbọ́? Yóò ti pẹ́ tó tí èmi yóò fi ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́ kúrò lọ́wọ́ ìwà ipá, tí ìwọ kò sì gbà là? Èé ṣe tí ìwọ fi mú kí n rí ohun tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́, tí ìwọ sì ń wo èkìdá ìdààmú?” Ǹjẹ́ àwọn ìbéèrè yìí ò jọ irú àwọn tẹ́yin náà ń béèrè?
Ṣadé: Ó jọ wọ́n lóòótọ́.
Bọ́lá: Ọlọ́run ò bá Hábákúkù wí torí àwọn ohun tó béèrè yẹn, kò sì sọ fún Hábákúkù pé àìnígbàgbọ́ ló ń dà á láàmú.
Ṣadé: Ẹ̀n-ẹ̀n-ẹ́n!
JÈHÓFÀ Ò FẸ́ KÁ MÁA JÌYÀ
Bọ́lá: Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run ń rí ìyà tó ń jẹ wá, ó sì máa ṣe nǹkan kan nípa rẹ̀.
Ṣadé: Kí lẹ ní lọ́kàn?
Bọ́lá: Ẹ jẹ́ kí n fi ohun kan hàn yín nínú Ẹ́kísódù 3:7. Ẹ jọ̀ọ́, ẹ kà á.
Ṣadé: Ó kà pé: “Jèhófà sì fi kún un pé: ‘Láìsí tàbí-ṣùgbọ́n, mo ti rí ṣíṣẹ́ tí a ń ṣẹ́ àwọn ènìyàn mi tí ń bẹ
ní Íjíbítì níṣẹ̀ẹ́, mo sì ti gbọ́ igbe ẹkún wọn nítorí àwọn tí ń kó wọn ṣiṣẹ́; nítorí tí mo mọ ìrora tí wọ́n ń jẹ ní àmọ̀dunjú.’”Bọ́lá: Ẹ ṣeun. Gẹ́gẹ́ bí ohun tẹ́ ẹ kà nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yẹn, ǹjẹ́ Ọlọ́run máa ń mọ̀ tí àwọn èèyàn rẹ̀ bá wà nínú ìṣòro?
Ṣadé: Bẹ́ẹ̀ ni o, ó dà bíi pé ó ń mọ̀.
Bọ́lá: Tẹ́ ẹ bá sì wò ó dáadáa, kì í ṣe pé ó kàn mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí wa lóréfèé. Ẹ wo apá tó gbẹ̀yìn nínú ẹsẹ yẹn. Ọlọ́run sọ pé: “Mo mọ ìrora tí wọ́n ń jẹ ní àmọ̀dunjú.” Tó bá jẹ́ pé ọ̀rọ̀ wa ò já mọ́ nǹkan kàn lójú Ọlọ́run, ǹjẹ́ ẹ rò pé á lè sọ irú ọ̀rọ̀ yìí?
Ṣadé: Rárá o.
Bọ́lá: Ọ̀tọ̀ ni pé kéèyàn kíyè sí nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀, ọ̀tọ̀ sì ni pé kí nǹkan náà ká èèyàn lára gan-an tàbí kó mọ̀ ọ́n lára.
Ṣadé: Òótọ́ ni.
Bọ́lá: Ẹ jẹ́ ká tún wo ohun míì tó fi hàn pé Ọlọ́run máa ń mọ̀ nígbà táwọn èèyàn rẹ̀ bá wà nínú ìpọ́njú. Ó wà nínú Aísáyà 63:9. Apá àkọ́kọ́ nínú ẹsẹ yẹn sọ pé: “Nínú gbogbo wàhálà wọn, ó jẹ́ wàhálà fún un.” Bá a ṣé rí i yìí, ṣé a wá lè sọ pé ìyà tó ń jẹ àwọn èèyàn kò kan Ọlọ́run?
Ṣadé: Ó jọ pé ó kàn án.
Bọ́lá: Ṣé ẹ rí i, òótọ́ ibẹ̀ ni pé Ọlọ́run ò fọ̀rọ̀ wa ṣeré rárá, inú rẹ̀ ò sì dún bí ìyà ṣe ń jẹ wá. Tí inú wa bá bàjẹ́, inú òun náà máa ń bàjẹ́.
KÍ NÌDÍ TÍ ỌLỌ́RUN KÒ FI TÍÌ WÁ NǸKAN ṢE SÍ I?
Bọ́lá: Kí n tó máa lọ, ohun kan ṣì wà tí máa fẹ́ sọ fún yín.
Ṣadé: Ó yá, mò ń gbọ́.
Bọ́lá: Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Bíbélì sọ fún wa nípa agbára Ọlọ́run. Ìwé Jeremáyà 10:12 ni mo fẹ́ ká jọ kà. Ẹ jọ̀ọ́, ṣé ẹ máa kà á?
Ṣadé: Bẹ́ẹ̀ ni. Ó kà pé: “Òun ni Olùṣẹ̀dá ilẹ̀ ayé nípasẹ̀ agbára rẹ̀, Ẹni náà tí ó fìdí ilẹ̀ eléso múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in nípasẹ̀ ọgbọ́n rẹ̀, àti Ẹni náà tí ó na ọ̀run nípasẹ̀ òye rẹ̀.”
Bọ́lá: Ẹ ṣeun. Ẹ jẹ́ ká ronú díẹ̀ lórí ẹsẹ yẹn ná. Ǹjẹ́ agbára tí Ọlọ́run fi dá ayé àti ọ̀run àti gbogbo nǹkan tó wà nínú rẹ̀ ò ní pọ̀ gan-an?
Ṣadé: Àà, ó máa pọ̀ o.
Bọ́lá: Ẹ ṣeun, tí Ọlọrun bá wá lágbára láti dá gbogbo nǹkan tó wà láyé yìí, ǹjẹ́ kò ní lágbára tó fi máa mójú tó àwọn ohun tó dá?
Ṣadé: Ó dájú pé ó máa ní.
Bọ́lá: Ẹ̀yin ẹ wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí mọ́mì yín. Kí nìdí tí ipò tí wọ́n wà yẹn fi ká yín lára?
Ṣadé: Torí pé àwọn ni ìyá mi, mo sì nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an.
Bọ́lá: Ká wá sọ pé ẹ lágbára láti jẹ́ kára wọn yá lónìí, ǹjẹ́ ẹ ò ní ṣe bẹ́ẹ̀?
Ṣadé: Màá ṣe bẹ́ẹ̀ lójú ẹsẹ̀.
Bọ́lá: Tá a bá ronú lórí ìyẹn, ó máa jẹ́ ká mọ bí ọ̀rọ̀ wa ṣe rí lára Ọlọ́run. Bíbélì sọ pé Ọlọ́run rí ìyà tó ń jẹ wa, ó ń káàánú wa àti pé agbára rẹ̀ kò lópin. Ẹ wo bí Ọlọ́run á ṣe máa kó ara rẹ̀ níjàánu tó, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, á ti dá sí ọ̀ràn aráyé, á sì ti fòpin sí ìyà tó ń jẹ wá lójú ẹsẹ̀.
Ṣadé: Mi ò rò ó báyẹn rí.
Bọ́lá: Tó bá wá rí bẹ́ẹ̀, ṣe kì í ṣe pé ó nídìí pàtàkì tí Ọlọ́run kò fi tíì dá sí ọ̀ràn wa, kó sì fòpin sí gbogbo ìṣòro wa? *
Ṣadé: (Ó mí kanlẹ̀) Ó gbọ́dọ̀ nídìí pàtàkì kan lóòótọ́.
Bọ́lá: Ó dà bíi pé fóònù yín ló ń dún yẹn, màá pa dà wá nígbà míì ká lè túbọ̀ sọ̀rọ̀ lórí kókó yìí.
Ṣadé: Ẹ ṣeun. Màá máa retí yín o. *
Ǹjẹ́ o ní ìbéèrè kan nínú Bíbélì tó ò ń ṣe kàyéfì nípa rẹ̀? Ǹjẹ́ o fẹ́ mọ̀ nípa ọ̀kan lára ohun tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, má ṣe lọ́ra láti béèrè ohun náà lọ́wọ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó o bá bá pàdé. Inú rẹ̀ yóò dùn láti jíròrò ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú rẹ.
^ ìpínrọ̀ 59 Tó o bá fẹ́ àlàyé síwájú sí i, wo orí 11 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.
^ ìpínrọ̀ 62 Lọ́jọ́ iwájú, a máa sọ̀rọ̀ lórí ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìjìyà lábẹ́ irú àpilẹ̀kọ yìí.