Ìyà Máa Dópin Láìpẹ́!
Báwo ló ṣe máa rí lára rẹ ká sọ pé ò ń gbé inú ayé kan tí kò sí ìyà, ìwà ọ̀daràn, ogun, àìsàn àti àjálù? Ṣé inú rẹ ò ní dùn, ká ní láràárọ̀ tó o bá jí, ọkàn ẹ balẹ̀ pé kò séwu, kò sí ìṣòro àìríjẹ àìríná, kò sí ẹ̀tanú, ìnira tàbí ìrẹ́jẹ? Ǹjẹ́ o rò pé àwọn nǹkan yìí lè ṣẹlẹ̀ àbí wọ́n kàn dà bí àlá tí kò lè ṣẹ? Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, kò sí ẹnì kankan tàbí ètò tí èèyàn gbé kalẹ̀ tó lè ṣe ohun tá a sọ yìí! Àmọ́ ṣá o, Ọlọ́run ti ṣèlérí pé òun máa fòpin sí gbogbo ohun tó fa ìyà tó ń jẹ aráyé títí kan àwọn tí a mẹ́nu kàn nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú. Kíyè sí àwọn ìlérí yìí nínú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run:
ÌJỌBA RERE NI YÓÒ MÁA ṢÀKÓSO
“Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀ èyí tí a kì yóò run láé. Ìjọba náà ni a kì yóò sì gbé fún àwọn ènìyàn èyíkéyìí mìíràn. Yóò fọ́ ìjọba wọ̀nyí túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn, òun fúnra rẹ̀ yóò sì dúró fún àkókò tí ó lọ kánrin.”—Dáníẹ́lì 2:44.
Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ àkóso kan ní ọ̀run. Ọlọ́run ti yan Jésù Kristi láti ṣàkóso dípò àwọn èèyàn tó ń ṣàkóso lónìí, Jésù máa rí i dájú pé ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ lọ́run àti láyé. (Mátíù 6:9, 10) Kò sí ìjọba èèyàn kankan tí yóò rọ́pò ìjọba náà torí àkóso yìí ni “ìjọba àìnípẹ̀kun ti Olúwa àti Olùgbàlà wa Jésù Kristi.” Ó sì dájú pé yóò mú kí àlàáfíà gbilẹ̀ títí láé.—2 Pétérù 1:11.
Ẹ̀SÌN ÈKÉ KÒ NÍ SÍ MỌ́
“Sátánì fúnra rẹ̀ a máa pa ara rẹ̀ dà di áńgẹ́lì ìmọ́lẹ̀. Nítorí náà, kì í ṣe ohun ńlá bí àwọn òjíṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú bá ń pa ara wọn dà di òjíṣẹ́ òdodo. Ṣùgbọ́n òpin wọn dájúdájú yóò rí bí iṣẹ́ wọn.”—2 Kọ́ríńtì 11:14, 15.
Àṣírí àwọn ẹ̀sìn èké máa tú pé Èṣù ni baba ìsàlẹ̀ wọn, Ọlọ́run sì máa pa gbogbo wọn run. Ìwà ẹ̀tanú àti ìpakúpa tó kún inú ọ̀pọ̀ ìsìn lónìí á dópin pátápátá. Èyí á jẹ́ kí gbogbo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ “Ọlọ́run tòótọ́ àti alààyè” máa jọ́sìn rẹ̀ ní “ìgbàgbọ́ kan” àti “ní ẹ̀mí àti òtítọ́.” Èyí yóò sì yọrí sí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan!—1 Tẹsalóníkà 1:9; Éfésù 4:5; Jòhánù 4:23.
GBOGBO ÈÈYÀN MÁA DI PÍPÉ
“Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yóò sì wà pẹ̀lú wọn. Yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”—Ìṣípayá 21:3, 4.
Bí Jèhófà Ọlọ́run ṣe gbà kí Jésù, Ọmọ rẹ̀, kú fún aráyé ló máa jẹ́ kí Ìlérí yìí ṣẹ. (Jòhánù 3:16) Nígbà tí Jésù bá ń ṣàkóso, yóò sọ aráyé di pípé. Ìyà tó ń jẹ àwa èèyàn á di ohun ìgbàgbé torí pé ‘Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yóò wà pẹ̀lú aráyé’ yóò sì “nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn.” Àìpé àti ìyà tó ń bá wa fínra yóò di ohun àtijọ́, “àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.”—Sáàmù 37:29.
ÀWỌN Ẹ̀MÍ ÈṢÙ KÒ NÍ SÍ MỌ́
“Ó [Jésù Kristi] sì gbá dírágónì náà mú, ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà, ẹni tí í ṣe Èṣù àti Sátánì, ó sì dè é fún ẹgbẹ̀rún ọdún. Ó fi í sọ̀kò sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ náà, ó tì í, ó sì fi èdìdì dí i lórí rẹ̀, kí ó má bàa ṣi àwọn orílẹ̀-èdè lọ́nà mọ́.”—Ìṣípayá 20:2, 3.
Jésù á de Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀, yóò sì jù wọ́n sínú “ọ̀gbun àìnísàlẹ̀,” ìyẹn ni pé wọn ò ní lè ta pútú tàbí ṣi àwọn èèyàn lọ́nà mọ́. Wọn ò tiẹ̀ ní lè fi agbára burúkú wọn darí àwọn èèyàn mọ́. Ẹ ò rí i pé ìtura ńlá gbáà ló máa jẹ́ láti wà nínú ayé kan tó ti bọ́ lọ́wọ́ ìdarí Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀!
“ÀWỌN ỌJỌ́ ÌKẸYÌN” YÓÒ DÓPIN
Jésù sọ pé “ìpọ́njú ńlá” ló máa kádìí “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.” Ó ní: “Nígbà náà ni ìpọ́njú ńlá yóò wà, irúfẹ́ èyí tí kò tíì ṣẹlẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé títí di ìsinsìnyí, rárá o, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò tún ṣẹlẹ̀ mọ́.”—Mátíù 24:21.
Ìpọ́njú ńlá ló máa jẹ́ ní ti pé àwọn àjálù tí kò ṣẹlẹ̀ rí á bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹlẹ̀. “Ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè,” tá a mọ̀ sí Amágẹ́dọ́nì ni yóò mú ìpọ́njú ńlá náà wá sí òpin.—Ìṣípayá 16:14, 16.
Níbi gbogbo, àwọn tó fẹ́ràn òtítọ́ ń fojú sọ́nà pé kí ayé burúkú yìí dópin. Jẹ́ ká wo díẹ̀ lára àwọn ìbùkún tí wọ́n máa gbádùn lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run.
DÍẸ̀ LÁRA OHUN TÍ ỌLỌ́RUN FẸ́ ṢE RÈÉ:
Ọlọ́run máa dá “ogunlọ́gọ̀ ńlá” èèyàn nídè wọnú ayé tuntun níbi tí àlàáfíà ti máa gbilẹ̀: Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé “ogunlọ́gọ̀ ńlá” èèyàn tí kò níye á “jáde wá láti inú ìpọ́njú ńlá náà,” Ọlọ́run yóò sì pa wọ́n mọ́ wọnú ayé tuntun òdodo. (Ìṣípayá 7:9, 10, 14; 2 Pétérù 3:13) Àwọn èèyàn yìí yóò gbà pé Jésù Kristi, “Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run, tí ó kó ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ” ló gba àwọn là.—Jòhánù 1:29.
Ọ̀pọ̀ ìbùkún ni a máa rí nínú ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: Nínú ayé tuntun, “ilẹ̀ ayé yóò kún fún ìmọ̀ Jèhófà bí omi ti bo òkun.” (Aísáyà 11:9) Lára ẹ̀kọ́ tí Ọlọ́run máa kọ́ wa ni ìtọ́ni nípa bí a ṣe lè gbé pọ̀ ní àlàáfíà àti bí a ṣe lè hùwà tó bá ayé tuntun mu. Ọlọ́run ṣèlérí pé: “Èmi, Jèhófà, ni Ọlọ́run rẹ, Ẹni tí ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní, Ẹni tí ń mú kí o tọ ọ̀nà tí ó yẹ kí o máa rìn.”—Aísáyà 48:17.
Àwọn èèyàn wa tó ti kú máa jíǹde: Nígbà tí Jésù wà láyé, ó jí Lásárù ọ̀rẹ́ rẹ̀ tó kú dìde. (Jòhánù 11:1, 5, 38-44) Ńṣe ló ń fi ìyẹn sọ fún àwọn èèyàn pé òun á túbọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́nà tó gbòòrò nínú Ìjọba Ọlọ́run.—Jòhánù 5:28, 29.
Àlàáfíà àti òdodo máa gbilẹ̀ títí láé: Tí Kristi bá ń ṣàkóso, ìwà àìlófin máa di ohun ìgbàgbé. Báwo la ṣe mọ̀? Ìdí ni pé Jésù lágbára láti mọ ohun tó wà lọ́kàn èèyàn, á sì lo agbára yìí tó bá ń ṣèdájọ́ kó lè mọ ẹni tó jẹ́ olóòótọ́ àti ẹni tó jẹ́ ibi. Kò ní gbà kí àwọn tó kọ̀ láti yí ìwà ibi wọn pa dà gbé nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ti ṣètò.—Sáàmù 37:9, 10; Aísáyà 11:3, 4; 65:20; Mátíù 9:4.
Díẹ̀ péré nìyí lára ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó jẹ́ ká mọ bí ọjọ́ ọ̀la ṣe máa dùn tó. Nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso ayé, “ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà” máa wà títí láé. (Sáàmù 37:11, 29) Gbogbo ohun tó ń fa ìnira àti ìyà tó ń bá aráyé fínra yóò di àwátì. Ọkàn wa balẹ̀ pẹ̀sẹ̀ torí pé Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ti ṣèlérí pé: “Wò ó! Mo ń sọ ohun gbogbo di tuntun. . . . Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ṣeé gbíyè lé, wọ́n sì jẹ́ òótọ́.”—Ìṣípayá 21:5.