KÓKÓ Ọ̀RỌ̀ | KÍ LÓ WÀ NÍNÚ BÍBÉLÌ?
Ìròyìn Ayọ̀ Fún Gbogbo Èèyàn
Àjíǹde Jésù túbọ̀ mú kó dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lójú pé òun ni Mèsáyà náà, wọ́n sì fi ìtara kéde ìhìn rere. Ọ̀kan nínú wọn ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, ó rìnrìn àjò káàkiri Éṣíà Kékeré àti àgbègbè òkun Mẹditaréníà. Bó ṣe ń dá àwọn ìjọ sílẹ̀, ló tún ń fún àwọn Kristẹni lókun kí wọ́n lè dúró ṣinṣin tí wọ́n bá kojú ìdẹwò tó lè ba ìwà rere wọn jẹ́ tàbí tí wọ́n bá ṣe inúnibíni tó le koko sí wọn. Láìka àwọn àtakò tó le yẹn sí, ọ̀pọ̀ èèyàn ló di Kristẹni.
Nígbà tó yá, wọ́n sọ Pọ́ọ̀lù sẹ́wọ̀n. Síbẹ̀, inú ẹ̀wọ̀n tó wà yẹn ló ti kọ àwọn lẹ́tà tó fi fún àwọn ìjọ Kristẹni ní ìṣírí tó sì tún gbà wọ́n nímọ̀ràn. Ó kìlọ̀ fún wọn nípa àwọn kan tó lè da ìjọ rú, ìyẹn àwọn apẹ̀yìndà. Ọlọ́run tipasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ fi han Pọ́ọ̀lù nínú ìran pé “àwọn aninilára ìkookò” tí yóò máa “sọ àwọn ohun àyídáyidà” máa wọnú ìjọ Kristẹni kí wọ́n lè “fa àwọn ọmọ ẹ̀yìn lọ sẹ́yìn ara wọn.”—Ìṣe 20:29, 30.
Nígbà tó fi máa di ìparí ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àwọn apẹ̀yìndà ti wọnú ìjọ Kristẹni. Lákòókò yẹn, Jésù tó ti jíǹde, ṣí àwọn ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la payá fún àpọ́sítélì Jòhánù lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Jòhánù kọ, àwọn alátakò tàbí àwọn olùkọ́ èké kò lè dí Ọlọ́run lọ́wọ́ láti ṣe ohun tó ní lọ́kàn láti ṣe sí orí ilẹ̀ ayé àti fún ìran ènìyàn. “Gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ahọ́n àti ènìyàn” ni yóò gbọ́ ìròyìn ayọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run. (Ìṣípayá 14:6) Ọlọ́run yóò sọ gbogbo ilẹ̀ ayé di Párádísè pa dà, gbogbo àwọn tó sì fẹ́ láti ṣèfẹ́ Ọlọ́run máa láǹfààní láti wà níbẹ̀!
Ìròyìn ayọ̀ gbáà mà lèyí o! Á dáa kó o kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa ohun tí Ọlọ́run bá àwa èèyàn sọ nínú Bíbélì. Kó o sì tún mọ àǹfààní tí àwọn ọ̀rọ̀ yìí lè ṣe fún wa lónìí àti lọ́jọ́ iwájú.
O lè ka Bíbélì lórí ìkànnì www.dan124.com. O tún lè ka àwọn ìwé míì lórí ìkànnì yẹn kan náà, irú bíi, Kí Ló Wà Nínú Bíbélì?, Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run! àti Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Yàtọ̀ síyẹn, wàá tún rí àwọn ìwé wa míì tó sọ̀rọ̀ nípa ìdí tí a lè fi gbára lé Bíbélì, àti bí a ṣe lè fi àwọn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ sílò nígbèésí ayé wa àti nínú ìdílé wa. Tí o bá ní ìbéèrè tàbí o fẹ́ àlàyé sí i, o lè béèrè lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
—A gbé e ka ìwé Ìṣe, Éfésù, Fílípì, Kólósè, Fílémónì, 1 Jòhánù, Ìṣípayá.