Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

OHUN TÓ LÈ MÚ KÍ ÌDÍLÉ LÁYỌ̀

Bí O Ṣe Lè Máa Bá Ọmọ Rẹ Sọ̀rọ̀ Láìsí Àríyànjiyàn

Bí O Ṣe Lè Máa Bá Ọmọ Rẹ Sọ̀rọ̀ Láìsí Àríyànjiyàn

NÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ JAPAN, OBÌNRIN KAN TÓ Ń JẸ́ MAKI, * sọ pé:“Ọmọ mi ò tíì ju ọmọ ọdún mẹ́rìnlá [14] lọ tó ti bẹ̀rẹ̀ sí í gbó mi lẹ́nu. Tí mo bá sọ fún un pé ‘Ó yá o, wá jẹun alẹ́,’ á ní, ‘Màá wá jẹ ẹ́ tó bá ti yá mi.’ Tí mo bá béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé ṣé ó ti parí iṣẹ́ ilé tó yẹ kó ṣe, a ní ‘Ẹ máà yọ mí lẹ́nu jàre!’ Ọ̀pọ̀ ìgbà ni a máa ń pariwo mọ́ ara wa.”

Tí ọmọ rẹ bá ṣì jẹ́ ọ̀dọ́, ìforígbárí lè máa wáyé láàárín ẹ̀yin méjèèjì, tọ́rọ̀ bá sì ti rí bẹ́ẹ̀, o gbọ́dọ̀ ṣe sùúrù. Obìnrin ará Brazil kan tó ń jẹ́ Maria, tí ọmọbìnrin rẹ̀ ti tó ọmọ ọdún mẹ́rìnlá [14] sọ pé: “Tí mo bá ní kí ọmọ mi ṣe nǹkan kan, àmọ́ tó wá ń lo agídí, ńṣe ni orí mi máa ń gbóná sí i. Inú á sì bí àwa méjèèjì débi pé a máa pariwo mọ́ ara wa.” Obìnrin ará Ítálì kan tó ń jẹ́ Carmela náà ní irú ìṣòro yìí, ó sọ pé: “Èmi àti ọmọkùnrin mi máa ń bá ara wa jiyàn gan-an, ohun tó sì sábà máa ń gbẹ̀yìn rẹ̀ ni pé, á wọnú yàrá rẹ̀ á sì tilẹ̀kùn mọ́rí.”

Kí nìdí tí àwọn ọ̀dọ́ fi máa ń jiyàn gan-an? Ṣé àwọn ọ̀rẹ́ wọn ló ń kọ́ wọn láti máa ṣe bẹ́ẹ̀ ni? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ bẹ́ẹ̀. Ó ṣe tán, Bíbélì fi yé wa pé ẹni téèyàn bá ń bá rìn lè nípa rere tàbí ipa búburú lórí ẹni. (Òwe 13:20; 1 Kọ́ríńtì 15:33) Àti pé, ọ̀pọ̀ eré ìnàjú tó wọ́pọ̀ lóde òní ń mú kí àwọn ọ̀dọ́ ya aláìgbọràn àti ẹni tí kì í fẹ́ bọ̀wọ̀ fún àgbà.

Àmọ́ àwọn nǹkan míì wà tó tún yẹ kó o gbé yẹ̀wò. Tó o bá ti mọ ipa tí àwọn nǹkan yìí ń ní lórí bí ọmọ rẹ ṣe ń hùwà, á rọrùn láti yanjú ìṣòro tó bá wáyé láàárín ìwọ àti ọmọ rẹ. Jẹ́ ká gbé díẹ̀ yẹ̀ wò nínú wọn.

ỌMỌ RẸ ṢẸ̀ṢẸ̀ Ń KỌ́ BÉÈYÀN ṢE Ń RONÚ

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Nígbà tí mo jẹ́ ìkókó, mo máa ń sọ̀rọ̀ bí ìkókó, ronú bí ìkókó, gbèrò bí ìkókó; ṣùgbọ́n nísinsìnyí tí mo ti wá di ọkùnrin, mo ti fi òpin sí àwọn ìwà ìkókó.” (1 Kọ́ríńtì 13:11) Nínú ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ yìí, ó ṣe kedere pé àwọn ọmọdé àti àwọn àgbàlagbà kì í ronú bákan náà. Bíi ti báwo?

Àwọn ọmọdé kì í fi bẹ́ẹ̀ ro ọ̀rọ̀ jinlẹ̀, tí nǹkan ò bá ti dáa tó lójú tiwọn, a jẹ́ pé ó burú nìyẹn. Àmọ́ àwọn àgbàlagbà máa ń ro ọ̀rọ̀ kọjá ohun tó kàn ṣẹlẹ̀, wọ́n máa ń fara balẹ̀ ronú lórí àwọn ọ̀rọ̀ tó bá lọ́jú pọ̀, wọ́n sì máa ń ronú jinlẹ̀ dáadáa kí wọ́n tó ṣè ìpinnu. Bí àpẹẹrẹ, àwọn àgbàlagbà máa ń fara balẹ̀ yẹ ọ̀rọ̀ wò fínífíní, pàápàá àwọn ọ̀rọ̀ tó máa ń ṣòro láti ṣèpinnu lé lórí, wọ́n á sì ronú lórí bí ohun tí àwọn fẹ́ ṣe á ṣe kan àwọn míì. Ó lè ti mọ́ wọn lára láti máa ronú lọ́nà yìí. Àmọ́ àwọn ọ̀dọ́ ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ kọ́ bí wọ́n á ṣe máa ronú bí àgbàlagbà ni.

Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi gba àwọn ọ̀dọ́ níyànjú pé kí wọ́n kọ́ bí wọ́n ṣe lè ní “ìmọ̀ àti làákàyè.” (Òwe 1:4, Bíbélì Mímọ́) Kódà, gbogbo wa ni Bíbélì rọ̀ pé ká máa lo “agbára ìmọnúúrò” wa. (Róòmù 12:1, 2; Hébérù 5:14) Torí pé ọmọ rẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kọ́ béèyàn ṣe ń ronú, ó lè máa bá ẹ jiyàn kódà lórí àwọn ọ̀rọ̀ tí kò fi bẹ́ẹ̀ tó nǹkan. Nígbà míì, ó tiẹ̀ lè sọ àwọn nǹkan tá á fi hàn pé èrò rẹ̀ kò tọ̀nà. (Òwe 14:12) Tí irú nǹkan báyìí bá ṣẹlẹ̀, báwo lo ṣe lè fèròwérò pẹ̀lú rẹ̀ dípò tí wàá fi máa bá a jiyàn?

GBÌYÀNJÚ ÈYÍ WÒ: Gbà pé ọmọ rẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kọ́ béèyàn ṣe ń ronú ni, kì í ṣe pé ó kàn fẹ́ rin kinkin mọ́ èrò rẹ̀. Tí o bá fẹ́ mọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀, kọ́kọ́ gbóríyìn fún un pé o mọyì bó ṣe fara balẹ̀ ronú. Bí àpẹẹrẹ, o lè sọ pé: “Ọ̀nà tí o gbà ronú yẹn wú mi lórí gan-an, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo ohun tó o sọ ni mo fara mọ́.” Lẹ́yìn náà, jẹ́ kó mọ bó ṣe lè tún èrò rẹ̀ gbé yẹ̀ wò. Bí àpẹẹrẹ, o lè sọ pé: “Ǹjẹ́ o rò pé ohun tí o sọ yìí máa wúlò ní gbogbo ọ̀nà?” Ẹnu lè yà ẹ́ gan-an tó o bá rí bí ọmọ rẹ ṣe tún èrò rẹ̀ pa tó sì ṣe àtúnṣe tó yẹ.

Àmọ́, tó o bá ń fèròwérò pẹ̀lú ọmọ rẹ, má ṣe rò pé ohun tó o bá sọ labẹ gé. Kódà, tó bá tiẹ̀ dà bíi pé ọmọ rẹ kò gba ọ̀rọ̀ tó o bá a sọ, wàá ríi pé ọ̀pọ̀ ohun tó o sọ fún un ló ti fi sọ́kàn, bí kò bá tiẹ̀ ṣe bíi pé òun gba ohun tí o sọ. Máà jẹ́ kó yà ẹ́ lẹ́nu pé lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, ọmọ rẹ lè ti ronú dáadáa lórí ọ̀rọ̀ tó o sọ, kó sì wá fara mọ́ èrò rẹ, ó tiẹ̀ lè máa ṣe bíi pé òun gan-an ló gbé èrò náà kalẹ̀.

Ní orílẹ̀-èdè Japan, ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Kenji sọ pé: “Nígbà míì, èmi àti ọmọkùnrin mi máa ń jiyàn lórí àwọn nǹkan pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ bí ìdí tí kò fi yẹ kó máa fi nǹkan ṣòfò tàbí kó máà fi àbúrò rẹ̀ obìnrin ṣe yẹ̀yẹ́. Àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, mo ríi pé ó fẹ́ kí n máa béèrè ohun tí òun rò tàbí kí n kàn fi hàn pé mo lóye òun. Bí àpẹẹrẹ, ó tẹ́ ẹ lọ́rùn ká ni mo sọ pé: ‘Áà! Ọ̀rọ̀ ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ yé mi ni, àṣé ohun tí ò ń rò nìyẹn.’ Tí mo bá ronú lórí ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn, mo gbà pé ká ní mo máa ń bá ọmọ mi sọ̀rọ̀ lọ́nà yẹn ni, àwọn àríyànjiyàn tó máa ń wáyé láàárín àwa méjèèjì kò ní wáyé.”

ỌMỌ RẸ FẸ́ FI HÀN PÉ ÌPINNU ÒUN DÁ ÒUN LÓJÚ

Àwọn òbí tó lóye máa ń jẹ́ kí ara tu àwọn ọmọ wọn kí wọ́n lè sọ tinú wọn jáde fàlàlà

Ọ̀kan lára àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù nígbà tó o bá ń tọ́ ọmọ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà ni pé kó o múra rẹ̀ sílẹ̀ de ìgbà tí kò ní sí lọ́dọ̀ rẹ mọ́, kí òun náà lè di ẹni tó tójú bọ́. (Jẹ́nẹ́sísì 2:24) Ìmúrasílẹ̀ yìí kan irú ẹni tó fẹ́ jẹ́, ìwà rẹ̀, ohun tó gbà gbọ́ àtàwọn ìlànà tó fẹ́ máa tẹ̀ lé láti fi irú ẹni tí ó jẹ́ hàn. Tí àwọn kan bá tiẹ̀ fúngun mọ́ ọn pé kó ṣe ohun tó burú, ọmọ tó ti pinnu irú ẹni tí òun fẹ́ jẹ́ á ronú kọjá ohun tó kàn lè jẹ́ àbájáde ohun tí òun bá ṣe. Ńṣe ni á bi ara rẹ̀ pé: ‘Irú èèyàn wo ni mí? Àwọn ìlànà wo ni mò ń tẹ̀ lé? Kí ni ẹni tó bá ń tẹ́ lé irú ìlànà yìí máa ṣe nínú irú ipò yìí?’—2 Pétérù 3:11.

Bíbélì sọ nípa ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Jósẹ́fù, tó sapá gidigidi láti yẹra fún ohun tó lè ba ìwà rere rẹ̀ jẹ́. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí aya Pọ́tífárì rọ̀ ọ́ pé kó bá òun sùn, ohun tí Jósẹ́fù sọ ni pé: “Báwo ni èmi ṣe lè hu ìwà búburú ńlá yìí, kí n sì dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọ́run ní ti gidi?” (Jẹ́nẹ́sísì 39:9) Bẹ́ẹ̀ sì rèé, nígbà yẹn, Ọlọ́run kò tíì fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní òfin kankan tó ka àgbèrè léèwọ̀. Síbẹ̀, Jósẹ́fù fòye gbé e pé ìwà yẹn ò dáa lójú Ọlọ́run. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀rọ̀ tó sọ pé, “Báwo ni èmi,” fi irú ẹni tí ó jẹ́ hàn. Ó ti pinnu pé ojú tí Ọlọ́run fi ń wò nǹkan ni òun á máa fi wò ó.—Éfésù 5:1.

Ọmọ tìẹ náà ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ fi irú ẹni tó fẹ́ jẹ́ hàn ni. Ohun tó fẹ́ ṣe yìí sì dáa, torí àwọn ohun tó gbà gbọ́ yìí ni yóò ràn án lọ́wọ́ láti kojú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ kí wọ́n má bàa kó èèràn ràn án. (Òwe 1:10-15) Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé nígbà míì, ó lè máà fẹ́ gba ohun tí ìwọ gan-an bá sọ. Tí ọ̀rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, kí ló yẹ kó o ṣe?

GBÌYÀNJÚ ÈYÍ WÒ: Dípò tí wàá fi máa da ọ̀rọ̀ sí àríyànjiyàn, o lè tún ohun tó wí sọ. Bí àpẹẹrẹ, o lè sọ pé: “Kí n lè lóye ohun tó o ní lọ́kàn dáadáa, ṣé ohun tí ò ń sọ ni pé . . .” O lè wá béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Kí nìdí tó o fi rò bẹ́ẹ̀?” tàbí “Kí ló mú kó o ṣe irú ìpinnu yìí?” Lo àwọn ìbéèrè tó máa mú kó sọ tinú rẹ̀ jáde. Fún un láyè kó sọ bí nǹkan yẹn ṣe dá a lójú tó. Tí ohun tó fẹ́ ṣe kò bá ti burú, tó bá jẹ́ pé ọ̀rọ̀ èyí-wù-mí-ò-wù-ọ́ ni, má rin kinkin mọ́ èrò tìrẹ, jẹ́ kó ṣe ohun tó fẹ́ ṣe, kódà tí o kò bá tiẹ̀ fara mọ́ ọn.

Ó dáa, ó sì tún ṣàǹfààní kéèyàn pinnu irú ẹni tó fẹ́ jẹ́, kí ó sì fi hàn pé èrò òun dá òun lójú. Ó ṣe tán, Bíbélì gbà wá níyànjú pé a kò gbọ́dọ̀ dà bí ìkókó “tí a ń bì kiri gẹ́gẹ́ bí nípasẹ̀ àwọn ìgbì òkun, tí a sì ń gbé síhìn-ín sọ́hùn-ún nípasẹ̀ gbogbo ẹ̀fúùfù ẹ̀kọ́.” (Éfésù 4:14) Torí náà, kì í ṣe pé kí o fún ọmọ rẹ láyè nìkan, àmọ́ gbà á níyànjú pé kí ó kọ́ béèyàn ṣe ń pinnu irú ẹni tó fẹ́ jẹ́, kó sì lè ṣàlàyé àwọn èrò tó bá ní lọ́nà tó fi hàn pé wọ́n dá a lójú.

Ní orílẹ̀-èdè Czech Republic, obìnrin kan tó ń jẹ́ Ivana sọ pé: “Tí mo bá jẹ́ kí àwọn ọmọbìnrin mi mọ̀ pé mo ṣe tán láti gbọ́ tiwọn, ara máa ń tù wọ́n, wọ́n sì máa ń fara balẹ̀ gbé èrò mi yẹ̀ wò kódà tí kò bá tiẹ̀ jọ mọ́ ohun tí wọ́n rò tẹ́lẹ̀. Àmọ́ ṣá, mi ò kì í fipá mú wọn láti gba èrò mi, kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni mo máa ń fún wọn láyè kí wọ́n lè ní èrò tiwọn.”

MÁ ṢE MÁA RIN KINKIN, SÍBẸ̀ MÁ GBA GBẸ̀RẸ́

Àwọn ọ̀dọ́ kan máa ń hùwà bí ọmọdé, ńṣe ni wọ́n máa ń tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ ṣáá kí àwọn òbí wọn lè ṣe ohun tí wọ́n fẹ́. Àfi kó o yáa kíyè sára tí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ń ṣẹlẹ̀ lágbo ilé tìrẹ. Torí pé ìyẹn á kàn mú nǹkan rọlẹ̀ díẹ̀ ni, àmọ́ ohun tí ọmọ rẹ á máa rò ni pé tí òun bá ṣáà ti dá àríyànjiyàn sílẹ̀, òun á rí ohun tí òun fẹ́ gbà. Kí ló yẹ kí o ṣe? Tẹ̀ lẹ́ ìmọ̀ràn Jésù tó ní: “Kí ọ̀rọ̀ yín Bẹ́ẹ̀ ni sáà túmọ̀ sí Bẹ́ẹ̀ ni, Bẹ́ẹ̀ kọ́ yín, Bẹ́ẹ̀ kọ́.” (Mátíù 5:37) Tí ọmọ rẹ bá ti rí i pé o máa ń dúró lórí ohun tí o bá sọ nígbà gbogbo, kò ní máa bá ẹ jiyàn.

Àmọ́ ṣá o, má ṣe máa rin kinkin mọ́ èrò tirẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ká ní ọmọ rẹ sọ pé òun máa pẹ́ níta ju àkókò tí o fún un pé kí ó máa wọlé, jẹ́ kó ṣàlàyé ìdí tó fi rò pé ó yẹ kí o yí àkókò náà pa dà fún òun lọ́jọ́ náà. Ìyẹn kò túmọ̀ sí pé o gba gbẹ̀rẹ́, ńṣe ni ò ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì tó sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí ìfòyebánilò yín di mímọ̀.”—Fílípì 4:5.

GBÌYÀNJÚ ÈYÍ WÒ: Ní gbogbo ìgbà tó o bá fẹ́ ṣe òfin tí àwọn ọmọ rẹ á máa tẹ̀ lé nínú ilé àti iye aago tó o fẹ́ kí wọ́n máa wọlé, pè wọ́n kí ẹ jọ sọ̀rọ̀ nípa òfin náà. Fi hàn pé o ṣe tán láti gbọ́ èrò wọn, kó o sì ro gbogbo ọ̀rọ̀ náà jinlẹ̀ kó o tó ṣe ìpinnu. Bàbá kan tó ń jẹ́ Roberto ní orílẹ̀-èdè Brazil sọ pé: “Àwọn ọ̀dọ́ máa ń mọyì kí àwọn òbí gba ohun tí wọ́n bá sọ rò, tí kò bá ṣáà ti ta ko ohun tí Bíbélì sọ.

Kò sí òbí tí kì í ṣe àṣìṣe. Bíbélì sọ pé: “Gbogbo wa ni a máa ń kọsẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà.” (Jákọ́bù 3:2) Tó o bá ronú pé ìwọ lo fà àríyànjiyàn náà, má ṣe jẹ́ kó wúwo lẹ́nu rẹ láti sọ fún ọmọ rẹ pé kó máà bínú. Tí o bá ṣe àṣìṣe, gbà pé o ṣe àṣìṣe. Ìyẹn á fi hàn pé o jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, o sì ń tipa bẹ́ẹ̀ fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fún àwọn ọmọ rẹ láti tẹ̀ lé.

Ọ̀gbẹ́ni Kenji tún sọ pé: “Lọ́jọ́ kan, àríyànjiyàn kan wáyé láàárín èmi àti ọmọkùnrin mi , àmọ́ lẹ́yìn tí ara mi wálẹ̀ tán, mo tọrọ àforíjì lọ́wọ́ rẹ̀ fún bí mo ṣe fara ya. Ìyẹn jẹ́ kí ara tiẹ̀ náà wálẹ̀, ó sì jẹ́ kó rọrùn fún un láti gbọ́ ohun tí mo fẹ́ sọ.”

^ ìpínrọ̀ 3 A ti yí àwọn orúkọ inú àpilẹ̀kọ yìí pa dà.

BI ARA RẸ PÉ . . .

  • Ṣé èmi náà kì í dá kún àríyànjiyàn tó máa ń wáyé láàárín èmi àti ọmọ mi?

  • Báwo ni ìmọ̀ràn inú àpilẹ̀kọ yìí ṣe lè jẹ́ kí n túbọ̀ lóye irú ẹni tí ọmọ mi jẹ́?

  • Kí ni mo lè ṣe tí èmi àti ọmọ mi á fi lè máa bá ara wa sọ̀rọ̀ láìsí àríyànjiyàn?