Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

KÓKÓ Ọ̀RỌ̀ | ÀWỌN IRỌ́ TÍ KÒ JẸ́ KÁWỌN ÈÈYÀN NÍFẸ̀Ẹ́ ỌLỌ́RUN

Wọ́n Parọ́ Pé Ọlọ́run Kò Lórúkọ

Wọ́n Parọ́ Pé Ọlọ́run Kò Lórúkọ

OHUN TÍ Ọ̀PỌ̀ ÈÈYÀN GBÀ GBỌ́

“Kò dájú pé àwọn èèyàn gbà pé Ọlọ́run ní orúkọ àti pé tó bá ní, a ò tíì mọ orúkọ yẹn.”—Ọ̀jọ̀gbọ́n David Cunningham, nínú ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìsìn.

ÒTÍTỌ́ TÍ BÍBÉLÌ JẸ́ KÁ MỌ̀

Ọlọ́run sọ pé: “Èmi ni Jèhófà. Èyí ni orúkọ mi.” (Aísáyà 42:8) Lédè Hébérù, “Jèhófà” ni orúkọ Ọlọ́run, ó túmọ̀ sí “Alèwílèṣe.”—Ẹ́kísódù 3:14.

Jèhófà fẹ́ ká máa lo orúkọ òun. Bíbélì sọ pé: “Ẹ ké pe orúkọ rẹ̀. Ẹ sọ àwọn ìbánilò rẹ̀ di mímọ̀ láàárín àwọn ènìyàn. Ẹ mẹ́nu kàn án pé orúkọ rẹ̀ ni a gbé ga.”—Aísáyà 12:4.

Jésù lo orúkọ Ọlọ́run. Nígbà tó ń gbàdúrà, ó sọ fún Jèhófà pé: “Mo sì ti sọ orúkọ rẹ di mímọ̀ fún wọn [àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù], ṣe ni èmi yóò sì sọ ọ́ di mímọ̀.” Kí nìdí tí Jésù fi jẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ mọ orúkọ Ọlọ́run? Ó sọ pé: “Kí ìfẹ́ tí ìwọ [Ọlọ́run] fi nífẹ̀ẹ́ mi lè wà nínú wọn àti èmi ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú wọn.”—Jòhánù 17:26.

ÌDÍ TÍ Ọ̀RỌ̀ NÁÀ FI ṢE PÀTÀKÌ

Ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn kan tó ń jẹ́ Walter Lowrie sọ pé: “Ẹni tí kò bá mọ orúkọ Ọlọ́run kò tíì mọ irú ẹni tó jẹ́ gan-an, kò sì lè nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tó bá jẹ́ pé ńṣe ló kàn mọ̀ ọ́n lóréfèé.”

Bí wọ́n ṣe fi orúkọ mìíràn rọ́pò orúkọ Ọlọ́run dà bí ìgbà tí wọ́n gé orúkọ Ọlọ́run kúrò nínú Bíbélì

Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Victor kì í pa ṣọ́ọ̀ṣì jẹ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, síbẹ̀ ó máa ń ṣe é bíi pé kò mọ Ọlọ́run rárá. Ó sọ pé: “Nígbà tí mo wá mọ orúkọ Ọlọ́run, ńṣe ló dà bíi pé wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ mú mi mọ̀ ọ́n. Ó ti pẹ́ tí mo ti ń gbọ́ nípa rẹ̀, àmọ́ mo ṣẹ̀ṣẹ̀ wá mọ̀ ọ́n báyìí. Mo ti wá mọ irú Ẹni tó jẹ́ gan-an, ìyẹn sì ti jẹ́ kí n di ọ̀rẹ́ rẹ̀.”

Jèhófà máa ń sún mọ́ àwọn tó bá ń lo orúkọ rẹ̀. Ó ṣèlérí fún “àwọn tí ń ronú lórí orúkọ rẹ̀” pé: “Èmi yóò sì fi ìyọ́nú hàn sí wọn, gan-an gẹ́gẹ́ bí ènìyàn ṣe ń fi ìyọ́nú hàn sí ọmọ rẹ̀ tí ń sìn ín.” (Málákì 3:16, 17) Ọlọ́run máa ń san èrè fún àwọn tó ń ké pe orúkọ rẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń ké pe orúkọ Jèhófà ni a ó gbà là.”—Róòmù 10:13.