Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Àǹfààní wo ni ikú Jésù ṣe fún wa?

Nígbà tí Ọlọ́run dá èèyàn, ohun tó ní lọ́kàn ni pé kí wọ́n máa gbádùn títí láé lórí ilẹ̀ ayé láìsí àìsàn àti ikú. Ṣùgbọ́n, Ádámù tó jẹ́ èèyàn àkọ́kọ́ tí Ọlọ́run dá ṣàìgbọràn sí Ẹlẹ́dàá, bó ṣe pàdánù àǹfààní láti wà láàyè títí láé nìyẹn. Nítorí pé àtọmọdọ́mọ Ádámù ni wá, a ti jogún ikú láti ọ̀dọ̀ rẹ̀. (Róòmù 5:8, 12; 6:23) Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́ náà, wá rán Jésù Ọmọ rẹ̀ wá sáyé láti fi ikú rẹ̀ ra ohun ti Ádámù pàdánù pa dà.—Ka Jòhánù 3:16.

Jésù kú kí àwa èèyàn lè gbádùn ìyè ayérayé. Ronú nípa bí ìgbésí ayé ṣe máa rí nígbà tí a bá wà láàyè títí láé

Ikú Jésù ló mú kí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ wa àti ìrètí láti wà láàyè títí láé ṣeé ṣe. Bíbélì sọ bí ìgbésí ayé ṣe máa rí lórí ilẹ̀ ayé nígbà tí àìsàn, ọjọ́ ogbó àti ikú kò bá sí mọ́.—Ka Aísáyà 25:8; 33:24; Ìṣípayá 21:4, 5.

Báwo ló ṣe yẹ ká máa rántí ikú Jésù?

Ní alẹ́ tó ṣáájú ikú Jésù, ó sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa fi ètò ráńpẹ́ kan rántí ikú òun. Bá a ṣe ń rántí ikú Jésù lọ́nà yìí ní ọdọọdún máa ń jẹ́ ká lè ronú jinlẹ̀ nípa bí Jésù àti Jèhófà ṣe nífẹ̀ẹ́ wa tó.—Ka Lúùkù 22:19, 20; 1 Jòhánù 4:9, 10.

Ọjọ́ Monday, April 14 ní a máa ṣe Ìrántí ikú Jésù lọ́dún yìí, lẹ́yìn tí oòrùn bá ti wọ̀. A ké sí ọ́ pé kó o dara pọ̀ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ̀.—Ka Róòmù 1:11, 12.