KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | KÍ NÌDÍ TÍ NǸKAN BURÚKÚ FI Ń ṢẸLẸ̀ SÁWỌN ÈÈYÀN RERE?
Àjálù Gbòde Kan!
Ìlú Dhaka tó wà lórílẹ̀-èdè Bangladesh ni obìnrin ẹni ọdún márùndínlógójì [35] kan tó ń jẹ́ Smita * ń gbé. Àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an nítorí pé onínúure ni, ó kóòyàn mọra, ó sì láájò àwọn èèyàn. Obìnrin rere ni lọ́ọ̀dẹ̀ ọkọ, ó sì máa ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run. Ṣàdédé ni Smita bẹ̀rẹ̀ àìsàn, ọ̀sẹ̀ yẹn ò sì kolẹ̀ tó fi gbẹ́mìí mì! Nígbà tí àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ gbọ́, ó yà wọ́n lẹ́nu gan-an.
Bíi ti Smita, èèyàn dáadáa làwọn èèyàn mọ James àti ìyàwó rẹ̀ sí. Àwọn méjèèjì ti lé díẹ̀ ní ọmọ ọgbọ̀n [30] ọdún. Wọ́n rìnrìn àjò lọ sọ́dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ wọn tó ń gbé létíkun Ìwọ̀ Oòrùn ilẹ̀ Amẹ́ríkà. Orí ìrìn àjò yẹn ni wọ́n wà tí wọ́n ti ṣe kòńgẹ́ ìjàǹbá ọkọ̀ tó burú jáì, bí wọn ò ṣe pa dà délé mọ́ nìyẹn. Àwọn olólùfẹ́ àti alábàáṣiṣẹ́ wọn kò lè gbàgbé oró tí ikú yìí dá wọn.
Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ibi gbogbo ni ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú ti ń ṣẹlẹ̀ lónìí. Bí ogun ṣe ń pa sójà ló ń pa aráàlú. Ìwà ọ̀daràn àti ìwà ipá ń fojú àwọn aláìmọwọ́mẹsẹ̀ rí màbo. Ìjàǹbá àti àìsàn onírúurú kò mọ ọmọdé bẹ́ẹ̀ ni kò mọ àgbà tàbí ipò téèyàn wà láwùjọ. Àwọn àjálù gbankọgbì ń runlé rùnnà. Ẹ̀tanú àti ìwà ìrẹ́jẹ sì gbòde kan. Ó ṣeé ṣe kí ìwọ náà ti fara gbá ọ̀kan lára àwọn nǹkan yìí.
O lè wá máa bi ara rẹ pé:
Kí nìdí tí aburú fi ń ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn rere?
Ṣé ẹ̀bi Ọlọ́run ni gbogbo láabi tó ń ṣẹlẹ̀ yìí?
Ṣé àfọwọ́fà àwa èèyàn ni àbí wọ́n kàn ń ṣàdédé ṣẹlẹ̀?
Ṣé òfin Kámà, ìyẹn òfin àṣesílẹ̀-làbọ̀wábá táwọn èèyàn sọ pé ó ní í ṣe pẹ̀lú àkọ́wáyé ló fa àwọn ìṣòro tó ń bá wa fínra lónìí?
Tó bá jẹ́ lóòótọ́ ni Olódùmarè wà, kí nìdí tí kì í fi gba àwọn èèyàn lọ́wọ́ ewu?
Ǹjẹ́ ìwà ibi àti ìyà máa dópin?
Tá a bá fẹ́ rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí, ohun méjì kan wà tó yẹ ká kọ́kọ́ mọ̀. A gbọ́dọ̀ mọ ìdí tí nǹkan burúkú fi ń ṣẹlẹ̀, àti ohun tí Ọlọ́run máa ṣe sí i.
^ ìpínrọ̀ 3 A ti yí àwọn orúkọ náà pa dà.