Ǹjẹ́ Òfin Tí Ọlọ́run Fún Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì Bá Ẹ̀tọ́ Mu?
NÍLÙÚ kan tó ti gòkè àgbà, ilé ẹjọ́ àwọn ọ̀daràn dájọ́ ikú fún àwọn ọkùnrin méjì kan láìwádìí ọ̀rọ̀ wọn dájú. Àṣé àṣìṣe wà nínú àwọn ẹ̀rí tí wọ́n kó jọ, àwọn ọkùnrin náà kò sì jẹ̀bi ẹ̀sùn ìpànìyàn tí wọ́n fi kàn wọ́n. Àwọn agbẹjọ́rò sapá gan-an lórí ẹjọ yìí, àmọ́ ìgbà tí ọ̀rọ̀ fi máa lójú, ẹ̀pa ò bóró mọ́, wọ́n ti pa ọ̀kan nínú àwọn ọkùnrin yẹn, ẹnì kejì ni wọ́n rí dá sílẹ̀.
Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ilé ẹjọ́ tí irú àṣìṣe yìí kò ti lè wáyé, ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi sọ pé: “Ìdájọ́ òdodo—ìdájọ́ òdodo ni kí ìwọ máa lépa.” (Diutarónómì 16:20) Táwọn adájọ́ bá tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yìí, ìlú á rójú. Òfin tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́ sọ pé wọn kò gbọ́dọ̀ ṣe ojúṣàájú tàbí kí wọ́n ṣe màdàrú nígbà tí wọ́n bá ń ṣe ìdájọ́. Ẹ jẹ́ ká wá wo àwọn Òfin náà ká lè rí i bóyá lóòtọ́ ni “gbogbo ọ̀nà [Ọlọ́run] jẹ́ ìdájọ́ òdodo.”—Diutarónómì 32:4.
ÀWỌN ADÁJỌ́ TÓ JẸ́ ỌLỌ́GBỌ́N, OLÓYE ÀTI ONÍRÌÍRÍ
Tí àwọn adájọ́ bá ṣe iṣẹ́ wọn bí iṣẹ́, tí wọn ò ṣe màdàrú, tí wọn ò sì gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, ọkàn àwọn aráàlú á balẹ̀. Irú àwọn adájọ́ bẹ́ẹ̀ ni Òfin Ọlọ́run sọ pé káwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá. Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ ìrìn-àjò wọn nínú aginjù, Ọlọ́run sọ fún Mósè pé kí ó wá ‘àwọn ọkùnrin tó dáńgájíá, tó bẹ̀rù Ọlọ́run, àwọn ọkùnrin tó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé, tó kórìíra ojúkòkòrò,’ kí wọ́n lè ṣe ìdájọ́ àwọn èèyàn náà. (Ẹ́kísódù 18:21, 22) Lẹ́yìn ogójì ọdún, Ọlọ́run tún sọ fún wọn pé kí wọ́n wá “àwọn ọkùnrin ọlọ́gbọ́n àti olóye àti onírìírí” tó máa ṣe onídàájọ́ àwọn èèyàn náà.—Diutarónómì 1:13-17.
Ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún mélòó kan lẹ́yìn ìgbà yẹn, Jèhóṣáfátì * Ọba Júúdà pàṣẹ fún àwọn onídàájọ́ pé: “Ẹ kíyè sí ohun tí ẹ ń ṣe, nítorí pé kì í ṣe ènìyàn ni ẹ ń ṣe ìdájọ́ fún bí kò ṣe Jèhófà; ó sì wà pẹ̀lú yín nínú ọ̀ràn ìdájọ́. Wàyí o, ẹ jẹ́ kí ìbẹ̀rùbojo Jèhófà wá wà lára yín. Ẹ kíyè sára, kí ẹ sì gbé ìgbésẹ̀, nítorí pé kò sí àìṣòdodo tàbí ojúsàájú tàbí gbígba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run wa.” (2 Kíróníkà 19:6, 7) Jèhóṣáfátì Ọba ń rán àwọn onídàájọ́ létí pé tí wọ́n bá ṣe ẹ̀tanú tàbí ojúkòkòrò nídìí ìdájọ́ wọn, ohunkóhun tó bá ṣẹlẹ̀, àwọn ni Ọlọ́run máa bi.
Ní gbogbo ìgbà tí àwọn onídàájọ́ ilẹ̀ Ísírẹ́lì tẹ̀ lé àwọn ìlànà yẹn, àlàáfíà wà, ọkàn àwọn èèyàn náà sì balẹ̀. Àmọ́, Òfin Ọlọ́run tún ní àwọn ìlànà kan tó lè ran àwọn adájọ́ lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìpinnu tó tọ́ láìfì sápá kan, kódà nínú àwọn ọ̀ràn tó ṣòro pàápàá. Kí ni àwọn ìlànà náà?
ÀWỌN ÌLÀNÀ TÓ MÁA JẸ́ KÍ WỌ́N ṢÈDÁJỌ́ LỌ́NÀ TÍ Ó TỌ́
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn tí wọ́n yàn láti jẹ́ onídàájọ́ gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tó gbọ́n tinú tẹ̀yìn, tí wọ́n sì kúnjú ìwọ̀n, síbẹ̀ wọn kò gbà wọ́n láyè láti fi ọgbọ́n orí ṣèdájọ́ lọ́nà tó bá ṣáà ti wù wọ́n. Jèhófà fún wọn ní ìlànà àti ìtọ́sọ́nà tó lè mú kí wọ́n dórí ìpinnu tó tọ́. Díẹ̀ lára àwọn ìlànà tí Ọlọ́run fún àwọn onídàájọ́ ní Ísírẹ́lì rèé.
Ṣe ìwádìí kínníkínní. Ọlọ́run tipasẹ̀ Mósè sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ adájọ́ pé: “Nígbà tí ẹ bá ń gbọ́ ẹjọ́ láàárín àwọn arákùnrin yín, ẹ gbọ́dọ̀ fi òdodo ṣe ìdájọ́.” (Diutarónómì 1:16) Àyàfi tí àwọn onídàájọ́ bá ṣe ìwádìí kínníkínní ni wọ́n tó lè ṣe ìdájọ́ lọ́nà tí ó tọ́. Ìdí nìyẹn tí Ọlọ́run fi sọ fún àwọn tó ń bójú tó ọ̀ràn tó bá ní í ṣe pẹ̀lú ìdájọ́ pé: “Kí ìwọ tọsẹ̀ rẹ̀, kí o sì ṣe àyẹ̀wò, kí ó sì wádìí kínníkínní.” Àwọ́n tí wọ́n jẹ́ adájọ́ nílé ẹjọ́ gbọ́dọ̀ rí i dájú pé ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan ọ̀daràn kan “jẹ́ òtítọ́” délẹ̀délẹ̀ kí wọ́n tó dá ẹjọ́ kankan.—Diutarónómì 13:14; 17:4.
Gbọ́rọ̀ lẹ́nu àwọn ẹlẹ́rìí. Kí ìwádìí wọn bàa lè kún, ó yẹ kí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu àwọn tí ọ̀rọ̀ náà ṣojú. Òfin Ọlọ́run sọ pé: “Kí ẹyọ ẹlẹ́rìí kan ṣoṣo má ṣe dìde sí ọkùnrin kan nípa ìṣìnà èyíkéyìí tàbí ẹ̀ṣẹ̀ èyíkéyìí, nínú ọ̀ràn ẹ̀ṣẹ̀ èyíkéyìí tí ó bá dá. Ẹnu ẹlẹ́rìí méjì tàbí ẹnu ẹlẹ́rìí mẹ́ta ni kí ọ̀ràn náà fẹsẹ̀ múlẹ̀ dáadáa.” (Diutarónómì 19:15) Òfin Ọlọ́run tún sọ fún àwọn tí ọ̀rọ̀ ṣojú wọn tàbí tí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́rìí pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ dara pọ̀ nínú sísọ ìròyìn tí kò jóòótọ́. Má fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ẹni burúkú nípa dídi ẹlẹ́rìí tí ń pète-pèrò ohun àìtọ́.”—Ẹ́kísódù 23:1.
Òótọ́ pọ́ńbélé ni àwọn tọ́rọ̀ kàn gbọ́dọ̀ sọ ní Ilé ẹjọ́. Ìdájọ́ tó wà fún ẹni tó bá parọ́ ní ilé ẹjọ́ máa ń mú kí gbogbo àwọn tọ́rọ̀ kàn ronú. Ó sọ pé: “Kí àwọn onídàájọ́ náà sì ṣàyẹ̀wò fínnífínní, bí ẹlẹ́rìí náà bá sì jẹ́ ẹlẹ́rìí èké, tí ó sì mú ẹ̀sùn èké wá lòdì sí arákùnrin rẹ̀, kí ẹ̀yin náà ṣe sí i, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti pète-pèrò láti ṣe sí arákùnrin rẹ̀, kí ìwọ sì mú ohun tí ó burú kúrò láàárín rẹ.” (Diutarónómì 19:18, 19) Nípa bẹ́ẹ̀, téèyàn kan bá parọ́ nílé ẹjọ́ nítorí àtirí ogún ẹnì kan gbà, iye ohun tó fẹ́ kí ẹni yẹn pàdánù gan-an ni òun fúnra rẹ̀ máa pàdánù. Tó bá sì jẹ́ pé ó parọ́ mọ́ aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ nítorí kí wọ́n lè pa onítọ̀hún, òun gan-an ni wọ́n máa pa. Èyí máa ń mú kí gbogbo àwọn tí ọ̀ràn kàn nílé ẹjọ́ sọ òtítọ́.
Má ṣe ojúsàájú nínú ìdájọ́. Nígbà tí àwọn adájọ́ bá ti gbé àwọn ẹ̀rí lóríṣiríṣi yẹ̀ wò, wọ́n á wá foríkorí láti dájọ́. Ìgbà yẹn gan-an ni wọ́n wá nílò Òfin Ọlọ́run tó ṣàrà ọ̀tọ̀ yìí: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ fi ojúsàájú bá ẹni rírẹlẹ̀ lò, ìwọ kò sì gbọ́dọ̀ ṣe ojúsàájú ẹni ńlá. Ìdájọ́ òdodo ni kí o fi ṣe ìdájọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ.” (Léfítíkù 19:15) Ńṣe ló yẹ kí àwọn onídàájọ́ máa gbé ìdájọ́ wọn ka àwọn ẹ̀rí tó jóòótọ́, wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí irú ẹni tí ẹnì kan jẹ́ tàbí ipò tó wà, nípa lórí ìdájọ́ wọn.
Àwọn ìlànà tí ó wà nínú Òfin tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yìí ṣì wúlò nílé ẹjọ́ lónìí. Tí àwọn tọ́rọ̀ kàn bá tẹ̀ lé àwọn ìlànà yìí, wọ́n ò ní ṣi ẹjọ́ dá.
ÀWỌN TÍ ÌLÀNÀ YÌÍ ṢE LÁǸFÀÀNÍ
Mósè béèrè lọ́wọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Orílẹ̀-èdè ńlá wo ni ó wà, tí ó ní àwọn ìlànà òdodo àti àwọn ìpinnu ìdájọ́ bí gbogbo òfin yìí tí mo ń fi sí iwájú yín lónìí?” (Diutarónómì 4:8) Ká sòótọ́, kò sí orílẹ̀-èdè míì tó tún ní àǹfààní yìí. Ọ̀dọ́ ni Sólómọ́nì nígbà tó jọba. Lábẹ́ ìjọba rẹ̀, àwọn èèyàn “gbé ní ààbò,” wọ́n lálàáfíà, nǹkan sì ń lọ déédéé fún wọn, “wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n sì ń yọ̀.”—1 Àwọn Ọba 4:20, 25.
Àmọ́, ó ṣeni láàánú pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run. Ọlọ́run wá gbẹnu wòlíì Jeremáyà sọ pé: “Wò ó! Àní wọ́n ti kọ ọ̀rọ̀ Jèhófà, ọgbọ́n wo sì ni wọ́n ní?” (Jeremáyà 8:9) Ohun tó jẹ́ àbájáde rẹ̀ ni pé ìlú Jerúsálẹ́mù wá di “ìlú ńlá ẹlẹ́bi ẹ̀jẹ̀” ó sì kún fún “ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí.” Nígbà tó yá, ìlú yẹn pa run, ó sì wà ní ahoro fún àádọ́rin ọdún.—Ìsíkíẹ́lì 22:2; Jeremáyà 25:11.
Lákòókò tí nǹkan ò fararọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni wòlíì Aísáyà gbé láyé. Àmọ́ ó la àwọn àkókò yẹn já, ó wá sọ̀rọ̀ kan tó jóòótọ́ nípa Jèhófà àti Òfin Rẹ̀, ó ní: “Nígbà tí àwọn ìdájọ́ bá ti ọ̀dọ̀ rẹ wá fún ilẹ̀ ayé, òdodo ni àwọn olùgbé ilẹ̀ eléso yóò kọ́ dájúdájú.”—Aísáyà 26:9.
Àmọ́, inú rẹ̀ dùn pé Jèhófà fún un ní àǹfààní láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa àkóso Mèsáyà Ọba, ìyẹn Jésù Kristi. Ó sọ pé: “Kì yóò sì ṣe ìdájọ́ nípasẹ̀ ohun èyíkéyìí tí ó hàn lásán sí ojú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fi ìbáwí tọ́ni sọ́nà ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí etí rẹ̀ wulẹ̀ gbọ́. Yóò sì fi òdodo ṣe ìdájọ́ àwọn ẹni rírẹlẹ̀, yóò sì fi ìdúróṣánṣán fúnni ní ìbáwí àfitọ́nisọ́nà nítorí àwọn ọlọ́kàn tútù ilẹ̀ ayé.” (Aísáyà 11:3, 4) Ẹ ò rí i pé ohun àgbàyanu ló ń dúró de gbogbo àwọn tó bá láǹfààní láti wà lábẹ́ àkóso Mèsáyà Ọba nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run bá dé!—Mátíù 6:10.
^ ìpínrọ̀ 6 Jèhóṣáfátì túmọ̀ sí “Jèhófà ni Onídàájọ́.”