Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | JÉSÙ GBÀ WÁ—LỌ́WỌ́ KÍ NI?

Iku ati Ajinde Jesu—Anfaani To Se fun E

Iku ati Ajinde Jesu—Anfaani To Se fun E

“Gba Jésù Olúwa gbọ́, ìwọ yóò sì rí ìgbàlà.”—Ìṣe 16:31.

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àti Sílà ló sọ ọ̀rọ̀ yìí fún ẹ̀ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n kan ní ìlú Fílípì, lágbègbè Makedóníà. Kí ni ọ̀rọ̀ yẹn túmọ̀ sí? Ká tó lè lóye bí ìgbàgbọ́ nínú Jésù ṣe máa gbà wá lọ́wọ́ ikú, a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ mọ ìdí tá a fi ń kú. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Bíbélì sọ nípa rẹ̀.

Ọlọ́run ò dá wa pé ká máa kú

“Jèhófà Ọlọ́run sì ń bá a lọ láti mú ọkùnrin náà, ó sì mú un tẹ̀ dó sínú ọgbà Édẹ́nì láti máa ro ó àti láti máa bójú tó o. Pẹ̀lúpẹ̀lù Jèhófà Ọlọ́run sì gbé àṣẹ yìí kalẹ̀ fún ọkùnrin náà pé: ‘Nínú gbogbo igi ọgbà ni kí ìwọ ti máa jẹ àjẹtẹ́rùn. Ṣùgbọ́n ní ti igi ìmọ̀ rere àti búburú, ìwọ kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú rẹ̀, nítorí ọjọ́ tí ìwọ bá jẹ nínú rẹ̀, dájúdájú, ìwọ yóò kú.’”—Jẹ́nẹ́sísì 2:15-17.

Ọlọ́run fi Ádámù sínú ọgbà kan tó ń jẹ́ Édẹ́nì níbi tí onírúurú àwọn ẹranko àti ewéko tútù tó ń mára tuni wà. Igi eléso tí Ádámù lè jẹ pọ̀ lọ jàra. Àmọ́, igi kan wà tí Ọlọ́run dìídì kìlọ̀ fún Ádámù pé kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú rẹ̀, ó ní tó bá jẹ ẹ́, ikú ló máa gbẹ̀yìn rẹ̀.

Ǹjẹ́ Ádámù lóye ìkìlọ̀ yẹn? Bẹ́ẹ̀ ni, torí pé ó mọ ohun tí ikú jẹ́, òun fúnra rẹ̀ ti rí i tí àwọn ẹranko kú. Tó bá jẹ́ pé Ọlọ́run dá Ádámù kí òun náà lè kú, ìkìlọ̀ náà kò ní nítumọ̀ kankan sí Ádámù torí á mọ̀ pé bóun jẹ ẹ́, bóun ò sì jẹ ẹ́, òun ṣì máa pàpà kú náà ni. Ṣùgbọ́n, Ádámù mọ̀ pé tí òun bá ṣègbọràn sí Ọlọ́run tí òun ò sì jẹ èso igi náà, ńṣe lòun á máa gbélé ayé lọ kánrin kése láìkú.

Àwọn kan rò pé ìbálòpọ̀ ni èso tí wọ́n jẹ túmọ̀ sí, àmọ́ kò lè jẹ́ bẹ́ẹ̀ torí Jèhófà sọ fún Ádámù àti Éfà pé: “Ẹ máa so èso, kí ẹ sì di púpọ̀, kí ẹ sì kún ilẹ̀ ayé, kí ẹ sì ṣèkáwọ́ rẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé igi kan ni Jèhófà ń tọ́ka sí. Jèhófà pe igi náà ní “igi ìmọ̀ rere àti búburú” torí pé ó dúró fún ẹ̀tọ́ tí Jèhófà ní láti máa pinnu ohun tó dáa àtohun tó burú fún àwa èèyàn. Ká sọ pé Ádámù ò jẹ nínú èso igi yẹn, á fi ara rẹ̀ hàn ní elétí ọmọ àti ẹni tó mọrírì gbogbo nǹkan tí Ẹlẹ́dàá rẹ̀ ṣe fún un.

Ádámù kú torí ó ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run

“Àti fún Ádámù [Ọlọ́run] wí pé: ‘Nítorí tí o . . . jẹ nínú igi náà tí mo pa àṣẹ yìí fún ọ nípa rẹ̀, . . . inú òógùn ojú rẹ ni ìwọ yóò ti máa jẹ oúnjẹ títí tí ìwọ yóò fi padà sí ilẹ̀, nítorí láti inú rẹ̀ ni a ti mú ọ jáde. Nítorí ekuru ni ọ́, ìwọ yóò sì padà sí ekuru.’”—Jẹ́nẹ́sísì 3:17, 19.

Ádámù jẹ èso igi tí Ọlọ́run sọ pé kò gbọ́dọ̀ jẹ. Ìwà àìgbọràn yìí kì í ṣe nǹkan kékeré rárá. Ńṣe ló dà bí ẹni dìídì ṣọ̀tẹ̀, tí gbogbo ohun tí Jèhófà ṣe fún un ò sì jọ ọ́ lọ́jú. Ádámù kẹ̀yìn sí Jèhófà nípa jíjẹ èso náà. Ìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé òun náà fẹ́ wà láyè ara rẹ̀ kó sì lómìnira, àmọ́, ohun tó ṣe yìí fa àjálù ńlá.

Ádámù kú gẹ́lẹ́ bí Jèhófà ṣe sọ tẹ́lẹ̀. “Ekuru ilẹ̀” ni Ọlọ́run fi mọ Ádámù, ó sì sọ fún un pé yóò “padà sí ilẹ̀.” Ádámù ko papòdà, kò sì di àkúdàáyà. Bí ekuru kò ṣe lẹ́mìí, bẹ́ẹ̀ náà ni Ádámù ò lẹ́mìí mọ́ nígbà tó kú.—Jẹ́nẹ́sísì 2:7; Oníwàásù 9:5, 10.

Torí a jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ádámù ni àwa náà ṣe ń kú

“Ẹ̀ṣẹ̀ ti tipasẹ̀ ènìyàn kan wọ ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, ikú sì tipa báyìí tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí pé gbogbo wọn ti dẹ́ṣẹ̀.”—Róòmù 5:12.

Àjálù tí àìgbọràn tàbí ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù fà kọjá àfẹnusọ. Ẹ̀ṣẹ̀ yìí mú kí Ádámù pàdánù àǹfààní láti wà láàyè títí gbére. Bákan náà, Ádámù di ẹlẹ́ṣẹ̀ tàbí aláìpé, àìpé yìí sì ni gbogbo àtọmọdọ́mọ rẹ̀ jogún látọ̀dọ̀ rẹ̀.

Ìdí nìyí tí àìpé ò fi yọ ẹnikẹ́ni sílẹ̀ torí àtọmọdọ́mọ Ádámù ni gbogbo wa. Àìpé yìí máa ń mú ká dẹ́ṣẹ̀, èyí ló sì ń fa ikú. Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé bí ọ̀rọ̀ yìí ṣe rí lára rẹ̀, ó ní: “Èmi jẹ́ ẹlẹ́ran ara, tí a ti tà sábẹ́ ẹ̀ṣẹ̀. Èmi abòṣì ènìyàn! Ta ni yóò gbà mí lọ́wọ́ ara tí ń kú ikú yìí?” Òun fúnra rẹ̀ dáhùn ìbéèrè yẹn, ó ní: “Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run nípasẹ̀ Jésù Kristi Olúwa wa!”—Róòmù 7:14, 24, 25.

Jésù fẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ ká lè wà láàyè títí láé

“Baba ti rán Ọmọ rẹ̀ jáde gẹ́gẹ́ bí Olùgbàlà ayé.”—1 Jòhánù 4:14.

Jèhófà Ọlọ́run ti ṣètò láti gbà wá lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Ètò náà ni pé ó rán àyànfẹ́ Ọmọ rẹ̀ láti ọ̀run wá sáyé bí èèyàn láti dá wa nídè. Bí Ádámù ṣe jẹ́ ẹni pípé kó tó dẹ́ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni Jésù jẹ́ ẹni pípé nígbà tí wọ́n bí i. Àmọ́, Jésù kò ṣe bí Ádámù, Bíbélì sọ nípa rẹ̀ pé, “kò dá ẹ̀ṣẹ̀ kankan.” (1 Pétérù 2:22) Torí pé ẹni pípé ni Jésù, ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú ò lágbára kankan lórí rẹ̀. Fún ìdí yìí, ó láǹfààní láti wà láàyè títí láé gẹ́gẹ́ bí ẹni pípé.

Àmọ́, Jèhófà fàyè gba àwọn ọ̀tá rẹ̀ láti pa Jésù. Nígbà tó di ọjọ́ kẹta, Jèhófà jí Jésù dìde gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí kó lè pa dà sọ́run. Ibẹ̀ ni Jésù ti fún Ọlọ́run ní ìtóye ìwàláàyè rẹ̀ pípé gẹ́gẹ́ bí ìràpadà ohun tí Ádámù àti àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀ pàdánù. Jèhófà tẹ́wọ́ gba ẹbọ ìpẹ̀tù yìí, èyí sì mú kó ṣeé ṣe fún gbogbo ẹni tó bá lo ìgbàgbọ́ nínú Jésù láti ní ìyè àìnípẹ̀kun.—Róòmù 3:23, 24; 1 Jòhánù 2:2.

Jésù tipa báyìí ra ohun tí Ádámù gbé sọnù pa dà. Ó kú nítorí tiwa, ká lè wà láàyè títí láé. Bíbélì sọ pé: “Jésù . . . kú, kí ó lè tọ́ ikú wò fún olúkúlùkù ènìyàn nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run.”—Hébérù 2:9.

Ohun tí Jésù ṣe yìí mú ká mọ irú ẹni tí Jèhófà jẹ́. Torí pé ìdájọ́ òdodo Jèhófà ga, kò ṣeé ṣe fún àwa èèyàn aláìpé láti gba ara wa lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Síbẹ̀, Jèhófà kò kọ ohun tó máa ná an, ńṣe ni ìfẹ́ àti àánú tó ní mú kó yọ̀ǹda Ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo láti pèsè ìràpadà tá a nílò.—Róòmù 5:6-8.

Jésù jíǹde, àwọn míì á sì jíǹde pẹ̀lú

“A ti gbé Kristi dìde kúrò nínú òkú, àkọ́so nínú àwọn tí ó ti sùn nínú ikú. Nítorí níwọ̀n bí ikú ti wá nípasẹ̀ ènìyàn kan, àjíǹde òkú pẹ̀lú wá nípasẹ̀ ènìyàn kan. Nítorí gan-an gẹ́gẹ́ bí gbogbo ènìyàn ti ń kú nínú Ádámù, bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni a ó sọ gbogbo ènìyàn di ààyè nínú Kristi.” —1 Kọ́ríńtì 15:20-22.

Kò sí àní-àní pé Jésù wá sáyé, ó sì kú, àmọ́ báwo la ṣe mọ̀ pé lóòótọ́ ló jíǹde? Ọ̀kan lára àwọn ẹ̀rí tó fìdí múlẹ̀ jù lọ nípa àjíǹde Jésù ni pé ó fara han ọ̀pọ̀ èèyàn ní àkókò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àti láwọn ibi tó yàtọ̀ síra. Kódà nígbà kan, ó fara han àwọn tó ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] èèyàn lọ. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tọ́ka sí òótọ́ yìí nínú lẹ́tà tó kọ sí àwọn ará Kọ́ríńtì, níbẹ̀, ó sọ pé lára àwọn tó rí Jésù lẹ́yìn tó jíǹde ṣì wà láyé. Ohun tó fẹ́ fàyọ ni pé àwọn wọ̀nyí lè jẹ́rìí sí i pé lóòótọ́ ni Jésù jíǹde.—1 Kọ́ríńtì 15:3-8.

Ó gbàfiyèsí wa pé Pọ́ọ̀lù pe Kristi ní “àkọ́so” nínú àwọn tó jíǹde, èyí fi hàn pé àwọn míì ṣì máa jíǹde lọ́jọ́ iwájú. Jésù fúnra rẹ̀ sọ pé àkókò kan ń bọ̀ tí “gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí” máa “jáde wá.”—Jòhánù 5:28, 29.

Tá a bá fẹ́ wà láàyè títí láé, a gbọ́dọ̀ lo ìgbàgbọ́ nínú Jésù

“Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.”—Jòhánù 3:16.

Ìwé tó bẹ̀rẹ̀ Bíbélì sọ bí ikú ṣe bẹ̀rẹ̀ àti bí Párádísè ṣe pòórá. Ìwé tó parí Bíbélì sọ bí Ọlọ́run ṣe máa mú ikú kúrò tó sì máa mú kí ayé di Párádísè. Tó bá dìgbà yẹn, àwa èèyàn máa gbádùn ìgbésí ayé wa títí láé. Ìwé Ìṣípayá 21:4 sọ pé: “Ikú kì yóò sì sí mọ́.” Kí ìlérí yìí lè dá wa lójú ẹsẹ 5 sọ pé: “Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ṣeé gbíyè lé, wọ́n sì jẹ́ òótọ́.” Ó dájú pé ohun tí Jèhófà bá ṣèlérí, dandan ni kó ṣẹ.

Ǹjẹ́ o gbà pé àwọn “ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ṣeé gbíyè lé, wọ́n sì jẹ́ òótọ́”? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, sapá láti kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Jésù Kristi kó o sì lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wà á rí ojúure Jèhófà. Bákan náà, wà á gbádùn ọ̀pọ̀ yanturu ìbùkún nísinsìnyí, wà á sì tún láǹfààní láti wà láàyè títí láé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé níbi tí “ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́.”