Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Ti Bibeli So

Ohun Ti Bibeli So

Kí nìdí tó fi yẹ ká máa rántí ikú Jésù?

Irú ọjọ́ ọ̀la wo ni ikú Jésù mú kó ṣeé ṣe?Aísáyà 25:8; 33:24

Ikú Jésù ni ìṣẹ̀lẹ̀ tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìtàn ẹ̀dá èèyàn torí pé ó kú kó bàa lè dá àwa èèyàn pa dà sí ipò tó yẹ ká wà. Ọlọ́run kò dá èèyàn láti máa hùwà burúkú, láti ṣàìsàn tàbí láti máa kú. (Jẹ́nẹ́sísì 1:31) Àmọ́, nípasẹ̀ Ádámù tó jẹ́ ọkùnrin àkọ́kọ́ ni ẹ̀ṣẹ̀ fi wọ ayé. Jésù wá fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ kó lè gbà wá lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú.—Ka Mátíù 20:28; Róòmù 6:23.

Ìfẹ́ tí kò lẹ́gbẹ́ ni Ọlọ́run fi hàn nípa bó ṣe rán Ọmọ rẹ̀ wá sáyé láti wá kú fún wa. (1 Jòhánù 4:9, 10) Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa ṣe ètò ráńpẹ́ kan láti fi rántí ikú òun. Búrẹ́dì àti wáìnì ló sì ní kí wọ́n lò. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́dọọdún, ńṣe là ń fi hàn pé a mọrírì ìfẹ́ tí Ọlọ́run àti Jésù fi hàn sí wa.—Ka Lúùkù 22:19, 20.

Àwọn wo ló máa jẹ búrẹ́dì tí wọ́n á sì mu wáìnì?

Nígbà tí Jésù kọ́kọ́ sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti máa rántí ikú òun, ó sọ̀rọ̀ nípa májẹ̀mú tàbí àdéhùn kan. (Mátíù 26:26-28) Májẹ̀mú yìí ló ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún wọn àti àwọn kéréje míì láti di ọba àti àlùfáà pẹ̀lú Jésù ní ọ̀run. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù àwọn èèyàn ló máa ń ṣe ìrántí ikú Jésù, kìkì àwọn tó wà nínú májẹ̀mú yẹn ló máa jẹ Búrẹ́dì tí wọ́n sì máa mu wáìnì.—Ka Ìṣípayá 5:10.

Ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún ọdún méjì báyìí tí Jèhófà ti ń yan àwọn tó máa jẹ́ ọba. (Lúùkù 12:32) Iye wọ́n kéré gan-an tá a bá fi wé àwọn tó máa wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé.—Ka Ìṣípayá 7:4, 9, 17.