KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | KÍ NI ÈRÒ ỌLỌ́RUN NÍPA OGUN?
Èrò Ọlọ́run Nípa Ogun Lóde Òní
Lóde òní, àwọn kan máa ń fìtínà àwọn ẹlòmíì. Ọ̀pọ̀ sì ń ké pe Ọlọ́run pé kó gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn tó ń ni wọ́n lára, àmọ́ kò dá wọn lójú pé ìyà náà máa dópin. Ǹjẹ́ Ọlọ́run máa ń gbọ́ àdúrà wọn? Àwọn kan ń jagun kí wọ́n lè gba ara wọn lọ́wọ́ àwọn tó ń fara ni wọ́n. Àmọ́, ṣé Ọlọ́run fọwọ́ sí ogun bẹ́ẹ̀?
Òótọ́ ọ̀rọ̀ kan tó ń tuni nínú ni pé, Ọlọ́run ń rí gbogbo ìyà tó ń jẹ àwa èèyàn lóde òní, ó sì máa fòpin sí i. (Sáàmù 72:
Kì í ṣe àwọn èèyàn ni Ọlọ́run máa lò láti ja ogun yẹn. Jésù Kristi tó jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run àtàwọn ańgẹ́lì alágbára ni Ọlọ́run máa lò láti gbógun ti àwọn ẹni ibi. Àwọn ọmọ ogun ọ̀run yìí ló máa fòpin sí gbogbo ìnilára.
Èrò Ọlọ́run nípa ogun kò tíì yí pa dà títí dòní. Ó ṣì máa lo ogun láti fòpin sí ìnilára àti ìwà búburú. Àmọ́, bíi tí àwọn àkókò tó ti kọjá sẹ́yìn, Ọlọ́run nìkan ló máa ń pinnu ìgbà tí irú ogun bẹ́ẹ̀ máa wáyé àti àwọn tó máa ja ogun náà. Bá a ṣe sọ, Ọlọ́run ti pinnu pé ọjọ́ iwájú ni Jésù Kristi
Ọmọ rẹ̀ máa ja ogun tó máa fòpin sí ìwà ibi, tó sì máa gba àwọn tó ń jìyà sílẹ̀. Èyí fi hàn pé inú Ọlọ́run kò dùn sí ogun tí àwọn èèyàn ń jà lónìí láìka ohun yòówù kí wọ́n máa jà fún.Wo àpẹẹrẹ yìí: Ká sọ pé àwọn tẹ̀gbọ́ntàbúrò kan ń jà nígbà tí Bàbá wọn kò sí nílé. Nígbà tó yá, wọ́n fi ara wọn sílẹ̀, wọ́n sì pe bàbá wọn lórí fóònù kí wọ́n lè rojọ́ fún un. Ọ̀kan sọ fún bàbá wọn pé ẹnì kejì ló dá ìjà sílẹ̀. Ẹnì kejì sọ pé ẹni àkọ́kọ́ ló bú òun. Àwọn méjèèjì bẹ bàbá wọn pé kó wá dá sí ọ̀rọ̀ náà. Lẹ́yìn tí bàbá wọn gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu àwọn méjèèjì tán, ó sọ fún wọn pé kí wọ́n má jà mọ́, kí wọ́n sì dúró títí òun máa fi dé láti wá yanjú ìjà wọn. Àwọn ọmọ méjèèjì dúró díẹ̀ de bàbá wọn. Àmọ́, ká tó ṣẹ́jú pẹ́, wọ́n tún ti bẹ̀rẹ̀ ìjà. Nígbà tí bàbá wọn dé, inú rẹ̀ kò dùn sí àwọn méjèèjì, ó sì fìyà jẹ wọ́n torí pé wọn ò gbọ́ràn sí i lẹ́nu.
Lóde òní, àwọn orílẹ̀-èdè tó ń bára wọn jà máa ń bẹ Ọlọ́run pé kó jẹ́ kí àwọn ṣẹ́gun. Àmọ́ Ọlọ́run kì í gbè sẹ́yìn ẹnikẹ́ni nínú ogun táwọn èèyàn ń jà lónìí. Kàkà bẹ́ẹ̀, nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó sọ pé: “Ẹ má ṣe fi ibi san ibi fún ẹnì kankan.” Ó sì tún sọ pé: “Ẹ má ṣe gbẹ̀san ara yín.” (Róòmù 12:
Ọ̀kan lára àwọn ìbùkún tá a máa gbádùn lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run ni pé kò ní sí ogun mọ́. Jésù sọ nípa ìjọba yìí nínú àdúrà táwọn èèyàn mọ̀ sí Àdúrà Olúwa pé: “Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.” (Mátíù 6:10) Kì í ṣe ogun nìkan ni Ìjọba Ọlọ́run máa fòpin sí, ó tún máa mú ohun tó ń fa ogun kúrò, ìyẹn ìwà ìkà. * (Sáàmù 37:
Báwo ló ṣe máa pẹ́ tó kí Ìjọba Ọlọ́run tó mú gbogbo ìyà, ìnilára, àti ìwà ibi kúrò? Bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì ṣe ń ní ìmúṣẹ fi hàn pé a ti wà ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ayé Sátánì. (2 Tímótì 3:
Bá a ṣe sọ́ tẹ́lẹ̀, àwọn tó máa pa run nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì ni “àwọn tí kò ṣègbọràn sí ìhìn rere nípa Jésù Olúwa wa.” (2 Tẹsalóníkà 1:8) Rántí pé, Ọlọ́run kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run, títí kan àwọn ẹni ibi. (Ìsíkíẹ́lì 33:11) Torí pé “kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run” nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì, ó ń rí i dájú pé à ń wàásù ìhìn rere nípa Jésù Olúwa wa “ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè” kí òpin tó dé. (2 Pétérù 3:
^ ìpínrọ̀ 9 Ìjọba Ọlọ́run tún máa fòpin sí ikú tó jé ọ̀tá gbogbo èèyàn. Bó ṣe wà nínú àpilẹ̀kọ náà “Ohun Tí Bíbélì Sọ,” Ọlọ́run máa jí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tó ti kú dìde, títí kan ọ̀pọ̀ àwọn tó ti bógun lọ.
^ ìpínrọ̀ 10 Tó o bá fẹ́ àlàyé síwájú sí i nípa àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, wo orí 9 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.