Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Pétérù Ni Póòpù Àkọ́kọ́?

Ṣé Pétérù Ni Póòpù Àkọ́kọ́?

“Wọ́n ti yan Kádínà Jorge Mario Bergoglio, S.J. gẹ́gẹ́ bíi Póòpù, òun sì ni póòpù karùndínláàádọ́rin lérúgba [265] tó rọ́pò Pétérù.”VATICAN INFORMATION SERVICE, VATICAN CITY, MARCH 13, 2013.

“Bíṣọ́ọ̀bù ìlú Róòmù ni olórí gbogbo Ṣọ́ọ̀ṣì pátápátá torí pé òun ló rọ́pò Pétérù Mímọ́, ìyẹn ẹni tí Jésù fún ní ọlá àṣẹ gẹ́gẹ́ bí olórí.”THE PRIMACY OF THE BISHOP OF ROME DURING THE FIRST THREE CENTURIES, 1903, LÁTỌWỌ́ VINCENT ERMONI.

“Ẹni tó bá sọ pé . . . Póòpù ìlú Róòmù kọ́ ló rọ́pò Pétérù Mímọ́ ti sọ̀rọ̀ òdì, a sì máa yọ ọ́ kúrò nínú ìjọ.”—THE FIRST VATICAN COUNCIL, JULY 18, 1870.

Ọ̀PỌ̀ àwọn ọmọ ìjọ Kátólíìkì kárí ayé ló gbà pé ìlànà tí wọ́n fi lélẹ̀ níbi àpérò àkọ́kọ́ tí wọ́n ṣe ní ìlú Vatican lọ́dún 1870 jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì tó fìdí múlẹ̀ jù lọ, tí kò sì ní yí pa dà. Ṣùgbọ́n, ó yẹ ká béèrè pé, ṣé ẹ̀kọ́ yìí bá Bíbélì mu? Ṣé Póòpù Francis ló rọ́pò àpọ́sítélì Pétérù? Àti pé, ṣé Pétérù ni póòpù àkọ́kọ́ lóòótọ́?

“NÍ ORÍ ÀPÁTA YÌÍ NI N ÓO KỌ́ ÌJỌ MI LÉ”

Òye wọn nípa ohun tó wà nínú Mátíù 16:16-19 àti Jòhánù 21:15-17 ni wọ́n gbé ìlànà tí wọ́n fi lélẹ̀ níbi àpérò náà kà. Ìjíròrò tó wáyé láàárín Jésù àti Pétérù nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí àtàwọn ẹsẹ Bíbélì míì jẹ́ ká rí i pé iṣẹ́ ribiribi ni àpọ́sítélì Pétérù ṣe nígbà tí wọ́n dá ìjọ Kristẹni sílẹ̀. Kódà nígbà tí Jésù kọ́kọ́ pàdé Pétérù, ńṣe ló fún un lórúkọ tó fi hàn pé ìgbàgbọ́ rẹ̀ máa lágbára bí àpáta. (Jòhánù 1:42) Àmọ́, ṣé Kristi sọ Pétérù di ọ̀gá àwọn tó kù?

Nínú Mátíù 16:17, 18, Jésù sọ fún Pétérù pé: “Mo sọ fún ọ pé: Peteru ni ọ́ [orúkọ yìí túmọ̀ sí “Òkúta Kan”], ní orí àpáta yìí ni n óo kọ́ ìjọ mi lé.” * Ṣé ohun tí Jésù ń sọ ni pé orí Pétérù tó jẹ́ èèyàn ni òun máa kọ́ ìjọ òun lé? Ṣé Pétérù ló máa jẹ́ olórí gbogbo àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù? Báwo ni àwọn àpọ́sítélì yòókù ṣe lóye ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí? Àwọn Ìwé Ìhìn Rere jẹ́ ká mọ̀ pé ní àwọn ìgbà mélòó kan lẹ́yìn ìjíròrò náà, àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ṣì bá ara wọn jiyàn lórí ẹni tó tóbi jù láàárín wọn. (Mátíù 20:20-27; Máàkù 9:33-35; Lúùkù 22:24-26) Tó bá jẹ́ pé Jésù ti sọ Pétérù di olórí wọn, ǹjẹ́ ìdí kankan máa wà fún wọn láti máa bá ara wọn jiyàn lórí ẹni tó tóbi jù láàárín wọn?

Báwo ni Pétérù fúnra rẹ̀ ṣe lóye ọ̀rọ̀ Jésù? Nítorí pé ọmọ Ísírẹ́lì ni Pétérù, ó ṣeé ṣe kó mọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó sọ̀rọ̀ nípa “àpáta” tàbí “òkúta ìpìlẹ̀ ilé.” (Aísáyà 8:13, 14; 28:16; Sekaráyà 3:9) Nínú lẹ́tà tó kọ sáwọn onígbàgbọ́ bíi tiẹ̀, ó ṣàlàyé pé Jésù Kristi Olúwa tó jẹ́ Mèsáyà ni “òkúta ìpìlẹ̀ ilé” tí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ náà ń tọ́ka sí. Pétérù lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà pe’tra (ọ̀rọ̀ kan náà tí Jésù lò nínú Mátíù 16:18) fún Kristi nìkan.1 Pétérù 2:4-8.

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù tó jẹ́ olóòótọ́. Àmọ́, ṣé Pọ́ọ̀lù ronú pé Jésù ti sọ Pétérù di olórí àwọn ọmọlẹ́yìn tó kù? Pọ́ọ̀lù gbà pé iṣẹ́ ribiribi ni Pétérù ń ṣe nínú ìjọ Kristẹni, ó tiẹ̀ sọ pé Pétérù wà lára àwọn tó dà bí “òpó nínú ìjọ.” Lójú Pọ́ọ̀lù, kì í ṣe Pétérù nìkan ló dà bí ‘òpó’ nínú ìjọ. (Gálátíà 2:9) Bákan náà, tó bá jẹ́ pé Jésù ti sọ Pétérù di olórí ìjọ Kristẹni, ṣé àwọn onígbàgbọ́ tó kù á máa wò ó bí ẹni tó kàn dà bí òpó nínú ìjọ?

Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń kọ̀wé nípa ìwà kan tó kù-díẹ̀-káàtó tí Pétérù hù, Pọ́ọ̀lù fi ọ̀wọ̀ hàn, síbẹ̀ ó sojú abẹ níkòó, ó ní: “Mo ta kò ó lójúkojú nítorí ó ṣe ohun ìbáwí.” (Gálátíà 2:11-14) Pọ́ọ̀lù kò gbà pé Jésù kọ ìjọ rẹ̀ sórí Pétérù tàbí sórí èèyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ èyíkéyìí. Dípò bẹ́ẹ̀, ohun tó gbà gbọ́ ni pé Jésù Kristi fúnra rẹ̀ ni ìpìlẹ̀ ìjọ Kristẹni. Lójú Pọ́ọ̀lù, “òkúta náà ni Kristi.”1 Kọ́ríńtì 3:9-11; 10:4.

“PETERU NI Ọ́ . . . ”

Báwo ló ṣe yẹ káwa náà lóye ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé: “Peteru ni ọ́, ní orí àpáta yìí ni n óo kọ́ ìjọ mi lé”? Ká tó lè lóye àyọkà kan dáadáa, a gbọ́dọ̀ ka ohun tí wọ́n ń bá bọ̀ àti ohun tí wọ́n sọ tẹ̀ lé e. Ọ̀rọ̀ wo ni Jésù àti Pétérù ń bá bọ̀? Jésù ṣẹ̀ṣẹ̀ bi àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ta ni ẹ rò pé mo jẹ́?” Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Pétérù dáhùn pé: “Ìwọ ni Mèsáyà, Ọmọ Ọlọ́run Alààyè.” Jésù gbóríyìn fún Pétérù, ó wá sọ fún un pé òun máa kọ́ “ìjọ” òun sórí “àpáta” tó fìdí múlẹ̀ dáadáa, ìyẹn Jésù fúnra rẹ̀ ẹni tí Pétérù ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀.Mátíù 16:15-18.

Báwo ló ṣe yẹ ká lóye ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé: “Peteru ni ọ́, ní orí àpáta yìí ni n óo kọ́ ìjọ mi lé”?

Èyí mú kí ọ̀pọ̀ “àwọn Bàbá Ìjọ” gbà pé Kristi ni àpáta tí Mátíù 16:18 ń sọ. Bí àpẹẹrẹ, Augustine tó gbáyé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kárùn-ún kọ̀wé pé: “Olúwa sọ pé: ‘Orí àpáta yìí ni èmi yóò kọ́ ìjọ mi sí,’ ìdí ni pé Pétérù sọ fún un pé: ‘Ìwọ ni Kristi Ọmọ Ọlọ́run Alààyè.’ Torí náà, orí àpáta tí ìwọ jẹ́wọ́ rẹ̀ ni èmi yóò kọ́ ìjọ mi lé.” Augustine tẹnu mọ́ ọn pé “Àpáta náà (Petra) ni Kristi.”

Tí wọ́n bá gbé ọ̀rọ̀ Augustine àtàwọn míì ka ìlànà ẹ̀sìn Kátólíìkì ti lọ́ọ́lọ́ọ́, asọ̀rọ̀ òdì ni wọ́n máa kà wọ́n sí. Kódà, Ulrich Luz láti ilẹ̀ Switzerland tó jẹ́ onímọ̀ nípa ẹ̀sìn sọ pé, tí wọ́n bá fi ìlànà tí wọ́n gbé kalẹ̀ ní àpérò tó wáyé ní ìlú Vatican lọ́dún 1870 díwọ̀n èrò tí ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀mọ̀wé Bíbélì ní nípa póòpù lóde òní, ńṣe ni wọ́n máa kà wọ́n sí asọ̀rọ̀ òdì.

ṢÉ ÀWỌN PÓÒPÙ LÓ Ń RỌ́PÒ PÉTÉRÙ?

Àpọ́sítélì Pétérù kò mọ nǹkan kan nípa oyè “póòpù.” Òótọ́ kan ni pé títí wọ ọgọ́rùn-ún ọdún kẹsàn-án, ọ̀pọ̀ àwọn bíṣọ́ọ̀bù tí kò wá láti Róòmù ló ń pe ara wọn ní póòpù. Síbẹ̀, kò sẹ́ni tó kà á sí oyè pàtàkì nígbà yẹn lọ́hùn-ún títí tó fi di ìparí ọgọ́rùn-ún ọdún kọkànlá. Bákan náà, àwọn Kristẹni ìgbàanì kò gbà pé Jésù sọ Pétérù di olórí ìjọ Kristẹni, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ pé ẹlòmíì máa gbapò rẹ̀. Fún ìdí yìí, ọ̀mọ̀wé ilẹ̀ Jámánì kan tó ń jẹ́ Martin Hengel sọ pé kò sí ẹ̀rí kankan nínú Bíbélì tàbí nínú ìtàn àwọn Kristẹni ìgbàanì tó jẹ́ ká mọ̀ pé póòpù ni olórí ìjọ Kristẹni.

Ní paríparí rẹ̀: Ṣé Pétérù ni póòpù àkọ́kọ́? Ǹjẹ́ Pétérù ní àwọn arọ́pò? Ṣé ẹ̀kọ́ tí ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì fi ń kọ́ni pé póòpù ni olórí ìjọ Kristẹni bá Bíbélì mu? Rárá ni ìdáhùn sí gbogbo àwọn ìbéèrè yìí. Òótọ́ kan ni pé Jésù kọ́ ìjọ rẹ̀, ṣùgbọ́n orí ara rẹ̀ ló kọ́ ìjọ tòótọ́ náà sí. (Éfésù 2:20) Ìbéèrè tó ṣe pàtàkì tó yẹ kí kálukú wa bi ara rẹ̀ ni pé, Ṣé mò ń dara pọ̀ mọ́ ìjọ tòótọ́ náà?

^ ìpínrọ̀ 8 Gbogbo ẹsẹ Bíbélì tá a fà yọ nínú àpilẹ̀kọ yìí jẹ́ láti inú Bíbélì Ìròyìn Ayọ̀.