Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Dádì Tàbí Mọ́mì Mi Fẹ́ Ẹlòmíì, Báwo Ni Mo Ṣe Lè Mú Un Mọ́ra?

Dádì Tàbí Mọ́mì Mi Fẹ́ Ẹlòmíì, Báwo Ni Mo Ṣe Lè Mú Un Mọ́ra?

ORÍ 5

Dádì Tàbí Mọ́mì Mi Fẹ́ Ẹlòmíì, Báwo Ni Mo Ṣe Lè Mú Un Mọ́ra?

INÚ dádì ẹ (tàbí mọ́mì ẹ) lè máa dùn ṣìnkìn lọ́jọ́ tó fẹ́ ẹlòmíì. Àmọ́ inú tìẹ lè má dùn rárá! Kí ló lè fà á? Ìdí ni pé bó ṣe fẹ́ ẹlòmíì lè jẹ́ kó o máa rò ó pé àwọn òbí rẹ kò tún lè pa dà sọ́dọ̀ ara wọn mọ́. Yàtọ̀ síyẹn, fífẹ́ tí dádì ẹ fẹ́ ẹlòmíì yẹn tún lè máa dùn ẹ́ gan-an tó bá jẹ́ pé kò pẹ́ sígbà tí mọ́mì ẹ tó o fẹ́ràn gan-an kú.

Báwo ló tiẹ̀ ṣe rí gan-an lára rẹ nígbà tí dádì tàbí mọ́mì ẹ fẹ́ ẹlòmíì? Fi àmì ✔ sí èyí tó bá sọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára ẹ nínú àwọn àpèjúwe tá a ṣe sísàlẹ̀ yìí.

□ Inú mi dùn

□ Ọkàn mi ò balẹ̀ mọ́

□ Ó ṣe mí bíi pé wọ́n dalẹ̀ mi

□ Mò ń jowú ẹni tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́

□ Ọkàn mi ń sọ pé mo jẹ́ ọ̀dàlẹ̀ torí pé mo wá ń fẹ́ràn ẹni tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́

Tó bá jẹ́ pé ohun tá a sọ kẹ́yìn yìí ló ṣe ẹ́, ohun tó ṣeé ṣe kó fà á ni pé o kò fẹ́ ṣe nǹkan tó máa bí èyí tí kò sí níbẹ̀ lára àwọn òbí rẹ nínú. Ohun yòówù kó fà á, àwọn nǹkan tó ń dùn ẹ́ tá a sọ yìí lè mú kó o bẹ̀rẹ̀ sí í fi ìbínú ṣe àwọn nǹkan tó lè fa wàhálà.

Bí àpẹẹrẹ, o lè bẹ̀rẹ̀ sí í dá wàhálà sílẹ̀ léraléra fún ẹni tí dádì tàbí mọ́mì ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ náà. O tiẹ̀ lè fẹ́ dá ìjà sílẹ̀ láàárín wọn, bóyá kí àwọn méjèèjì lè tú ká. Ṣùgbọ́n, òwe ìkìlọ̀ kan sọ pé: “Ẹni ti o ba yọ ile ara rẹ̀ lẹnu yoo jogun òfo,” ìyẹn ni pé ṣe ló máa pàdánù. (Òwe 11:29, Bibeli Yoruba Atọ́ka) Kò ní dáa kó o jẹ́ kí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí ẹ. Àwọn nǹkan míì wà tó o lè ṣe nípa àwọn ohun tó ń dùn ẹ́, tó jẹ́ pé ó máa ṣe ẹ́ láǹfààní. Bí àpẹẹrẹ, wo ìṣòro mélòó kan àti ohun tó o lè ṣe sí i.

Ìṣòro Àkọ́kọ́: Bí Wàá Ṣe Lè Máa Gbọ́ràn sí Ẹni Tó Ṣẹ̀ṣẹ̀ Di Òbí Rẹ Lẹ́nu

Kì í rọrùn láti jẹ́ kí ẹni tí bàbá tàbí ìyá ẹni fẹ́ máa darí ẹni. Tí wọ́n bá ní kó o ṣe nǹkan kan, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé kó o pariwo pé, ‘Ẹ̀yin ṣáà kọ́ lẹ bí mi!’ Tó o bá sọ bẹ́ẹ̀, inú ẹ lè dùn o, pé o ti sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ, àmọ́ ṣe nìyẹn máa fi hàn pé ọmọdé ṣì ń ṣe ẹ́.

Ṣùgbọ́n tó o bá ń ṣègbọràn sí ẹni tí dádì tàbí mọ́mì ẹ fẹ́, ọ̀nà kan nìyẹn tó o lè gbà fi hàn pé ò ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì tó sọ pé kó o “jẹ́ àgbàlagbà ninu èrò” rẹ. (1 Kọ́ríńtì 14:20, Ìròhìn Ayọ̀) Ojúṣe òbí sí ọmọ ni ẹni tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di òbí rẹ yìí ń ṣe o, nítorí náà, ó yẹ kó o máa bọ̀wọ̀ fún un.—Òwe 1:8; Éfésù 6:1-4.

Tí ẹni tí dádì tàbí mọ́mì ẹ fẹ́ bá bá ẹ wí, ó fi hàn pé ó fẹ́ràn rẹ àti pé ó ń fẹ́ kó o jẹ́ ọmọ dáadáa nìyẹn. (Òwe 13:24) Ọmọ ọdún méjìdínlógún [18] kan tó ń jẹ́ Yvonne sọ pé: “Ọkọ mọ́mì mi máa ń bá wa wí dáadáa, ohun tó sì yẹ kí bàbá èèyàn máa ṣe náà nìyẹn. Mo máa ń rò ó pé, tí mi ò bá gbọ́ràn sí wọn lẹ́nu, a jẹ́ pé ṣe ni mò ń sọ pé àṣedànù lásán ni gbogbo bí wọ́n ṣe ń tọ́jú wa tí wọ́n sì ń jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run látọjọ́ yìí. Àìmoore sì nìyẹn máa jẹ́.”

Àmọ́ o ṣì lè máa rí i pé wọ́n ń ṣe àwọn ohun tó kù díẹ̀ káàtó o. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, fi hàn pé o tí ‘ń di àgbà,’ kó o ṣe ohun tí Kólósè 3:13 sọ, pé: “Ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà lẹ́nì kìíní-kejì bí ẹnikẹ́ni bá ní ìdí fún ẹjọ́ lòdì sí ẹlòmíràn.”

Kọ àwọn ìwà dáadáa tí ẹni tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di òbí rẹ ní sórí ìlà tó wà nísàlẹ̀ yìí.

․․․․․

Tó o bá ń rántí àwọn ìwà dáadáa tó máa ń hù yìí, báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ kó o túbọ̀ bọ̀wọ̀ fún un?

․․․․․

Ìṣòro Kejì: Bí Wàá Ṣe Lè Máa Báwọn Fọwọ́ Sowọ́ Pọ̀

Ọmọ ọdún mẹ́rìnlélógún [24] kan tó ń jẹ́ Aaron sọ pé: “Ẹ̀ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni dádì mi lọ fẹ́ ẹlòmíì. Mo rí i pé èmi àti ìyàwó tí wọ́n kọ́kọ́ fẹ́ àtèyí tí wọ́n tún fẹ́ lẹ́ẹ̀kejì, títí kan àwọn ọmọ wọn kò rẹ́ rárá. Bí wọ́n bá ṣe ń dé, tí a ò tiẹ̀ tíì mọ ara wa, làwọn èèyàn á ti máa sọ pé kí n fẹ́ràn gbogbo wọn, mi ò sì mọ̀ wọ́n tẹ́lẹ̀ o. Gbogbo ẹ̀ kàn tiẹ̀ máa ń sú mi.”

Ìwọ náà lè ní àwọn ohun tó jẹ́ ìṣòro. Bí àpẹẹrẹ, ó lè jẹ́ pé ìwọ ni ọmọ tó dàgbà jù nínú ilé tẹ́lẹ̀ tàbí pé ìwọ nìkan làwọn òbí rẹ bí, àmọ́ kí ìyẹn ti wá yí pa dà báyìí. Tó bá jẹ́ ọkùnrin ni ẹ́, ó lè jẹ́ pé ìwọ lò ń bójú tó àwọn ohun tó ń lọ nínú ilé yín tẹ́lẹ̀, àmọ́ kí ọkọ mọ́mì ẹ ti wá gbapò yẹn mọ́ ẹ lọ́wọ́ báyìí. Ọ̀rọ̀ tìẹ sì lè dà bíi ti Yvonne tó sọ pé: “Dádì mi kì í ráyè gbọ́ ti mọ́mì mi, torí náà èmi àti Mọ́mì la jọ máa ń ṣe àwọn nǹkan pa pọ̀ ní gbogbo ìgbà. Àmọ́ nígbà tí Mọ́mì fẹ́ ọkọ míì, ọkọ wọn yìí máa ń gbọ́ tiwọn dáadáa. Ṣe ni wọ́n jọ máa ń ṣe àwọn nǹkan pa pọ̀, wọ́n sì jọ máa ń sọ̀rọ̀ dáadáa, ìyẹn wá jẹ́ kó máa ṣe mí bíi pé wọ́n ti gba mọ́mì mi mọ́ mi lọ́wọ́. Àmọ́ nígbà tó yá, mo gbà pé bó ṣe yẹ kó rí náà nìyẹn.”

Báwo lo ṣe lè ṣe bíi Yvonne kí ìwọ náà gbà pé bó ṣe yẹ kí nǹkan rí nìyẹn? Bíbélì sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí ìfòyebánilò yín di mímọ̀ fún gbogbo ènìyàn.” (Fílípì 4:5) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n tú sí “ìfòyebánilò” níbí túmọ̀ sí pé kéèyàn jẹ́ ẹni tí “kì í rin kinkin mọ́ nǹkan,” ìyẹn ẹni tí kì í sọ pé gbogbo ẹ̀tọ́ òun pátá ni òun gbọ́dọ̀ gbà. Báwo lo ṣe lè tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì yìí? (1) Má ṣe máa ronú ṣáá nípa bí àwọn nǹkan ṣe rí tẹ́lẹ̀. (Oníwàásù 7:10) (2) Múra tán láti yọ̀ǹda àwọn nǹkan kan, kó o sì gbà kí ẹ jọ máa ṣe àwọn nǹkan pa pọ̀, ìyẹn ìwọ àti ẹni tí dádì tàbí mọ́mì ẹ fẹ́ àtàwọn ọmọ rẹ̀. (1 Tímótì 6:18) (3) Má ṣe máa hùwà sí wọn bíi pé àjèjì ni wọ́n.

Èwo ló yẹ kó o ṣiṣẹ́ lé lórí jù nínú àwọn ohun mẹ́ta tá a sọ yìí? ․․․․․

Ìṣòro Kẹta: Bí Wọn Ò Bá Fọwọ́ Kan Náà Mú Gbogbo Yín

Ọmọ kan tó ń jẹ́ Tara sọ pé: “Ọkọ mọ́mì mi fẹ́ràn àwọn ọmọ tiẹ̀ gan-an ju èmi àti àǹtí mi lọ. Gbogbo nǹkan tí àwọn yẹn bá fẹ́ jẹ ló máa ń rà fún wọn, gbogbo fídíò tí wọ́n bá fẹ́ wò ló máa ń rẹ́ǹtì fún wọn. Kò sí nǹkan táwọn yẹn fẹ́ tí kì í ṣe fún wọn.” Irú nǹkan báyìí máa ń káni lára gan-an. Kí lo wá lè ṣe? Gbìyànjú láti lóye ìdí tí ẹni tí bàbá tàbí ìyá ẹni fẹ́ fi lè má fi ọwọ́ kan náà mú àwọn ọmọ tiẹ̀ àtàwọn ọmọ yòókù. Ó lè máà jẹ́ torí pé òun ló bí wọn, àmọ́ kó jẹ́ torí pé ó ti pẹ́ tí wọ́n ti mọwọ́ ara wọn. Ó ṣeé ṣe kí ìwọ náà fẹ́ràn bàbá tàbí ìyá tó bí ẹ ju ẹni tó di òbí rẹ yìí.

Ìyàtọ̀ wà nínú fífi ọwọ́ kan náà mú àwọn èèyàn àti ṣíṣe ohun tó tọ́ fún kálukú wọn. Àwa èèyàn kò dọ́gba, ohun tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa sì nílò yàtọ̀ síra. Nítorí náà, dípò tí wàá fi máa ronú ṣáá lórí bóyá ẹni tó di òbí rẹ yìí ń fi ọwọ́ kan náà mú gbogbo ẹ̀yin ọmọ, gbìyànjú láti wò ó bóyá ó ń ṣe àwọn ohun tó o nílò fún ẹ.

Kí làwọn ohun tó o nílò tí ẹni tó di òbí rẹ yìí ń ṣe fún ẹ?

․․․․․

Kí làwọn ohun tó o nílò tó o rò pé kò ṣe fún ẹ?

․․․․․

Tó o bá rò pé àwọn nǹkan kan wà tó o nílò tí ẹni tó di òbí rẹ yìí kò ṣe fún ẹ, o ò ṣe fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ bá a sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀?

Sùúrù Lérè!

Ó sábà máa ń gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún kí gbogbo àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di ìdílé kan náà tó wá mọwọ́ ara wọn dáadáa. Nígbà yẹn, wọ́n á ti mọ ìwà ara wọn, wọ́n á sì lè jọ máa ṣe àwọn nǹkan pọ̀ láìsí wàhálà. Torí náà ṣe ni kó o ní sùúrù! Má ṣe retí pé ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni gbogbo yín máa fẹ́ràn ara yín tàbí pé ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni gbogbo yín máa bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe bí ọmọ ìyá kan náà.

Nígbà tí màmá Thomas fẹ́ ẹlòmíì, bí nǹkan ṣe rí kò bá Thomas lára mu rárá. Ọmọ mẹ́rin ni màmá Thomas ní, ọkọ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ sì ní ọmọ mẹ́ta. Thomas sọ pé: “A máa ń bára wa jà, a máa ń bára wa fa ọ̀rọ̀, a máa ń fa wàhálà lóríṣiríṣi, a sì máa ń fojú ara wa rí màbo.” Báwo ni wọ́n ṣe wá yanjú ọ̀rọ̀ wọn? Thomas ní: “Nígbà tá a wá fi ìlànà Bíbélì sílò, gbogbo wàhálà yẹn yanjú.”

NÍNÚ ORÍ TÓ KÀN

Tó bá wá jẹ́ pé ọmọ ìyá àti bàbá kan náà ni ìwọ àtàwọn tẹ̀gbọ́n tàbúrò rẹ ńkọ́, àmọ́ tó jẹ́ pé wọ́n máa ń ṣe ohun tó ń bí ẹ nínú gan-an?

ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́

“Òpin ọ̀ràn kan ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀ sàn ju ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ rẹ̀ lọ. Onísùúrù sàn ju onírera ní ẹ̀mí.”—Oníwàásù 7:8.

ÌMỌ̀RÀN

Tí ìwọ àtàwọn ọmọ ẹni tí dádì tàbí mọ́mì rẹ fẹ́ bá bẹ̀rẹ̀ sí í gbé pọ̀, tẹ́ ò bá ṣọ́ra ẹ lè fẹ́ máa ní èrò ìṣekúṣe sí ara yín. Torí náà pinnu lọ́kàn rẹ pé o kò ní gba irú èrò bẹ́ẹ̀ láyè rárá, sì máa rí i dájú pé o kì í múra lọ́nà tó lè mú irú èrò yẹn wá sí wọn lọ́kàn àti pé o kì í hùwà lọ́nà bẹ́ẹ̀.

ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?

Bí ẹ̀yin tẹ́ ẹ wá látinú ìdílé ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ṣe pa pọ̀ di ìdílé kan yìí lè má fi bẹ́ẹ̀ rọrùn fáwọn ọmọ ẹni tí dádì (tàbí mọ́mì) ẹ fẹ́, àní bó ṣe jẹ́ pé ó lè má rọrùn fún ìwọ náà.

OHUN TÍ MÀÁ ṢE!

Màá máa rántí àwọn nǹkan rere tí ọkọ mọ́mì mi (tàbí ìyàwó dádì mi), ṣe fún ìdílé wa kí n lè túbọ̀ máa bọ̀wọ̀ fún un (kọ nǹkan rere méjì tó ti ṣe): ․․․․․

Tí àwọn ọmọ ẹni tí dádì tàbí mọ́mì mi fẹ́ bá ń bínú tí wọn ò jẹ́ ká jọ máa ṣe nǹkan pa pọ̀, bí màá ṣe fi ìlànà inú Róòmù 12:21 sílò ni pé: ․․․․․

Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ òbí mi tàbí ẹni tó di òbí mi nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․

KÍ LÈRÒ Ẹ?

● Kí ló lè máa ba ẹni tí dádì tàbí mọ́mì rẹ fẹ́ àtàwọn ọmọ rẹ̀ lẹ́rù bí ẹ ṣe fẹ́ jọ di ìdílé kan?

● Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kó o máa ronú nípa àwọn ohun dáadáa tó lè ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú láàárín ẹ̀yin tẹ́ ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ di ìdílé kan náà yìí?

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 38]

“Mọ́mì mi àti ọkọ tí wọ́n fẹ́ kọ ara wọn sílẹ̀. Àmọ́ títí dòní, kòríkòsùn lèmi àtàwọn ọmọ ọkọ wọn yẹn. Mo máa ń dúpẹ́ gan-an pé èmi àtàwọn ọmọ yẹn mọ́ra.”​—Tara

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 39]

Ó ń gba àkókò àti iṣẹ́ àṣekára láti po sìmẹ́ǹtì àti omi pọ̀ di ohun tó lágbára tó sì ní àlòpẹ́, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe ń gba àkókò àti iṣẹ́ àṣekára kí ìdílé méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó di ọ̀kan kí wọ́n sì mọwọ́ ara wọn