Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwòkọ́ṣe—Tímótì

Àwòkọ́ṣe—Tímótì

Àwòkọ́ṣe​—Tímótì

tímótì máa tó fi ilé sílẹ̀, kì í ṣe pé ó fẹ́ sá kúrò nílé o. Torí pé ó fẹ́ máa bá àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó jẹ́ míṣọ́nnárì ṣiṣẹ́ pọ̀ ló ṣe fẹ́ kúrò lọ́dọ̀ àwọn òbí rẹ̀! Tímótì tó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ọmọ ogún ọdún tàbí kó ti lé díẹ̀ lógún ọdún, jẹ́ ọ̀dọ́kùnrin tó ṣeé fọkàn tán, tí “àwọn ará ní Lísírà àti Íkóníónì sì ròyìn rẹ̀ dáadáa.” (Ìṣe 16:2) Ó dá Pọ́ọ̀lù lójú pé Tímótì á lè ṣe àwọn nǹkan ribiribi nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Bẹ́ẹ̀ náà sì lọ̀rọ̀ rí! Láwọn ọdún mélòó kan lẹ́yìn náà, Tímótì rìnrìn àjò lọ sáwọn ibi tó pọ̀, ó ń dá àwọn ìjọ sílẹ̀, ó sì ń gbé àwọn ará ró nípa tẹ̀mí. Àwọn ànímọ́ rere tí Tímótì ní wu Pọ́ọ̀lù gan-an, tó fi jẹ́ pé ní nǹkan bí ọdún mọ́kànlá lẹ́yìn náà, Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn ará nílùú Fílípì pé: “Èmi kò ní ẹlòmíràn tí ó ní ìtẹ̀sí-ọkàn bí tirẹ̀ tí yóò fi òótọ́ inú bójú tó àwọn ohun tí ó jẹmọ́ yín.”​—Fílípì 2:20.

Ǹjẹ́ ò ń yọ̀ǹda ara rẹ kí Ọlọ́run lè rí ẹ lò nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀? Tó o bá lè yọ̀ǹda ara rẹ, wàá rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbùkún gbà! Jèhófà mọyì àwọn ọ̀dọ́ tó ń “fi tinútinú yọ̀ǹda ara wọn” gan-an. (Sáàmù 110:3) Síwájú sí i, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà Ọlọ́run “kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ [rẹ].”​—Hébérù 6:10.