Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Bí Mo Ṣe Ń Kẹ́dùn Dáa Báyìí?

Ṣé Bí Mo Ṣe Ń Kẹ́dùn Dáa Báyìí?

ORÍ 16

Ṣé Bí Mo Ṣe Ń Kẹ́dùn Dáa Báyìí?

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé, ọ̀rọ̀ nípa ikú òbí ẹni ni orí yìí dá lé, àwọn ìlànà tá a mẹ́nu bà níbẹ̀ wúlò nígbà tí èèyàn ẹni tàbí ọ̀rẹ́ ẹni bá ṣaláìsí.

“Nígbà tí Mọ́mì kú, ìdààmú bá mi, gbogbo nǹkan sì tojú sú mi. Torí pé Mọ́mì ló so ìdílé wa pọ̀.”​—Karyn.

IKÚ òbí jẹ́ ọ̀kan lára ohun tó máa ń dunni jù. Lẹ́yìn tó bá ṣẹlẹ̀, o lè bẹ̀rẹ̀ sí í ní oríṣiríṣi ẹ̀dùn ọkàn àti èrò tó ń dani lọ́kàn rú tó ò tíì ní rí. Ọmọ ọdún mẹ́tàlá [13] péré ni Brian nígbà tí àrùn ọkàn pa dádì ẹ̀. Ó sọ pé: “Lálẹ́ ọjọ́ tá a gbọ́ pé Dádì kú, ṣe la kàn ṣáà ń sunkún tá a sì ń dì mọ́ra wa.” Natalie, tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́wàá nígbà tí àrùn jẹjẹrẹ pa dádì ẹ̀, sọ pé: “Ṣe ni mo kàn ń wò suu. Ojú mi kàn dá. Kò tiẹ̀ ṣe mí bákan.”

Bí ẹnì kan bá kú, ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni bí kálukú ṣe ń kẹ́dùn. Bíbélì pàápàá sọ pé “olúkúlùkù” ní “ìyọnu àjàkálẹ̀ tirẹ̀ àti ìrora tirẹ̀.” (2 Kíróníkà 6:29) Tó o bá jẹ́ ẹni tí dádì tàbí mọ́mì rẹ̀ ṣaláìsí, ronú lórí ohun tí ẹsẹ Bíbélì yìí sọ, kó o wá sọ bí ikú dádì tàbí mọ́mì rẹ ṣe rí lára tìrẹ. Kọ (1) bó ṣe rí lára ẹ nígbà tó o kọ́kọ́ gbọ́ pé dádì tàbí mọ́mì ẹ ti kú àti (2) bó ṣe rí lára ẹ báyìí, sórí ìlà tó wà nísàlẹ̀ yìí. *

1 ․․․․․

2 ․․․․․

Ohun tó o kọ yìí lè wá jẹ́ kó o rí i pé ẹ̀dùn ọkàn rẹ nípa ikú dádì tàbí mọ́mì ẹ ti ń fúyẹ́ lọ́kàn rẹ. Ìyẹn ò sì burú. Pé ẹ̀dùn ọkàn rẹ ń fúyẹ́ kò fi hàn pé o ti gbàgbé òbí ẹ. Ohun tó o kọ sílẹ̀ sì lè fi hàn pé ọ̀rọ̀ náà ṣì ń dùn ẹ́, tàbí pé ó tiẹ̀ ń dùn ẹ́ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Ó tiẹ̀ lè jẹ́ pé ṣe ni ẹ̀dùn ọkàn rẹ kàn máa ń dédé wá, bí omi òkun tó ń ru gùdù ṣe máa ń dédé bì lu etíkun. Kò sóhun tó burú nínú ìyẹn náà, kódà tó bá tiẹ̀ ń wáyé ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún lẹ́yìn tí dádì tàbí mọ́mì ẹ kú. Ohun tó ṣe pàtàkì ni pé, Ọ̀nà yòówù kí ẹ̀dùn ọkàn rẹ máa gbà wá, kí lo lè ṣe sí i?

Bó bá ń ṣe ẹ́ bíi kó o sunkún, sun ún! Ẹkún sísun máa ń jẹ́ kí ìbànújẹ́ tó wà lọ́kàn ẹni fúyẹ́ nígbà tí èèyàn ẹni bá kú. Àmọ́, ó lè máa ṣe ìwọ náà bíi ti Alicia, tó jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19] nígbà tí mọ́mì rẹ̀ kú. Ó sọ pé: “Mo ronú pé bí mo bá kẹ́dùn ju bó ṣe yẹ lọ, lójú àwọn ẹlòmíì, ó lè dà bíi pé mi ò nígbàgbọ́.” Àmọ́, rò ó wò ná: Ẹni pípé tí ìgbàgbọ́ ẹ̀ lágbára gan-an ni Jésù Kristi. Síbẹ̀, ó “da omijé” lójú nígbà tó gbọ́ pé Lásárù ọ̀rẹ́ rẹ̀ kú. (Jòhánù 11:35) Torí náà, má ṣe jẹ́ kí ẹ̀rù bà ẹ́ láti sunkún. Ìyẹn kò fi hàn pé o kò nígbàgbọ́! Alicia sọ pé: “Nígbà tó yá mo wá sunkún. Ẹkún yẹn pọ̀! Ojoojúmọ́ ni mò ń sunkún.” *

Tó o bá ń dára ẹ lẹ́bi, má pa á mọ́ra! Karyn tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàlá, nígbà tí mọ́mì ẹ̀ kú, sọ pé: “Ní alaalẹ́, tí mo bá fẹ́ lọ sùn, mo sábà máa ń lọ sí yàrá òkè láti fẹnu ko Mọ́mì lẹ́nu. Àmọ́, alẹ́ ọjọ́ kan wà tí mi ò ṣe bẹ́ẹ̀. Ìgbà tí ilẹ̀ fi máa mọ́, Mọ́mì ti kú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé rírí tí mi ò rí Mọ́mì kí n tó lọ sùn lálẹ́ ọjọ́ yẹn ò ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú ikú wọn, síbẹ̀, ọkàn mi ń dá mi lẹ́bi pé mi ò lọ wò wọ́n, mo sì tún ń dará mi lẹ́bi torí gbogbo nǹkan tó ṣẹlẹ̀ láàárọ̀ ọjọ́ kejì. Ìdí ni pé Dádì lọ ṣiṣẹ́ níbì kan, wọ́n sì ní kí èmi àti àǹtí mi máa lọ wo Mọ́mì. Àmọ́, a pẹ́ ká tó sùn, a ò sì tètè jí láàárọ̀ ọjọ́ kejì. Ìgbà tí mo sì máa débẹ̀, Mọ́mì ò mí mọ́. Ọkàn mi dà rú, torí pé ara wọn ṣì le díẹ̀ nígbà tí Dádì jáde nílé!”

Ìwọ náà lè máa dára ẹ lẹ́bi bíi ti Karyn, torí àwọn nǹkan tó yẹ kó o ṣe àmọ́ tó ò ṣe. Kó o wá máa kábàámọ̀ pé, ‘Ká ní mo mọ̀ ni, ǹ bá ti sọ pé kí Dádì lọ rí dókítà.’ Tàbí kó o máa sọ pé, ‘Ká ní mo mọ̀ ni, kí n ti lọ wo Mọ́mì ṣáájú ìgbà yẹn.’ Bí irú èrò yẹn bá ń da ọkàn ẹ láàmú, ohun tó o gbọ́dọ̀ rántí rèé: Kò sóhun tó burú nínú kéèyàn kábàámọ̀ torí ohun tó rò pé ó yẹ kóun ti ṣe. Àmọ́, òótọ́ ibẹ̀ ni pé, ká ló o mọ̀ pé ibi tọ́rọ̀ máa já sí nìyẹn, ọ̀tọ̀ ni nǹkan tó ò bá ṣe. Àmọ́, o kò mọ̀. Torí náà, kò sídìí tó fi yẹ kó o máa dára rẹ lẹ́bi. Ìwọ kọ́ lo fa ikú dádì tàbí mọ́mì ẹ o! *

Sọ bó ṣe ń ṣe ẹ́ fún àwọn ẹlòmíì. Òwe 12:25 sọ pé: ‘Ọ̀rọ̀ rere máa ń múni yọ̀.’ Bó o bá pa bó ṣe ń ṣe ẹ́ mọ́ra, ó lè mú kó ṣòro fún ẹ láti borí ẹ̀dùn ọkàn rẹ. Àmọ́ tó o bá sọ bó ṣe ń ṣe ẹ́ fún ẹnì kan tó o fọkàn tán, wàá lè gbọ́ “ọ̀rọ̀ rere” tí ń gbéni ró nígbà tí inú rẹ bà jẹ́.

Bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀. Ọkàn rẹ lè bẹ̀rẹ̀ sí í balẹ̀ tó o bá gbàdúrà, tó o ‘tú ọkàn-àyà rẹ jáde’ fún Jèhófà Ọlọ́run. (Sáàmù 62:8) Èyí kì í wulẹ̀ ṣe torí kára kàn lè tù ẹ́ o. Ṣé o rí i, bó o bá gbàdúrà, ńṣe lò ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo, ẹni tí ń tù wá nínú nínú gbogbo ìpọ́njú wa.” (2 Kọ́ríńtì 1:3, 4) Ọ̀kan lára ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ń pèsè ìtùnú jẹ́ nípasẹ̀ Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀. (Róòmù 15:4) O tiẹ̀ lè kọ àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó o rí pé ó máa ń tù ẹ́ nínú síbì kan, kó o sì jẹ́ kó máa wà lárọ̀ọ́wọ́tó rẹ nígbà gbogbo. *

Ẹ̀dùn ọkàn torí ikú èèyàn ẹni kì í ṣe ohun tó máa ń lọ bọ̀rọ̀. Àmọ́ ọ̀rọ̀ inú Bíbélì lè tù ẹ́ nínú, torí ó mú un dá wa lójú pé, nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí pé òun máa mú wá, “ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́.” (Ìṣípayá 21:3, 4) Ìwọ náà lè rí i pé bó o bá ń ṣàṣàrò lórí irú àwọn ìlérí yìí, ó máa jẹ́ kí ìbànújẹ́ rẹ lórí ikú dádì tàbí mọ́mì rẹ fúyẹ́ lọ́kàn rẹ.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ ìpínrọ̀ 6 Tó bá ṣì ṣòro fún ẹ láti kọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára ẹ sílẹ̀ báyìí, o lè kọ ọ́ nígbà míì.

^ ìpínrọ̀ 10 Má rò pé ọ̀ranyàn ni kó o sunkún torí bó ṣe dùn ẹ́ tó. Bí kálukú ṣe ń kẹ́dùn yàtọ̀ síra. Ohun tó ṣe pàtàkì ni pé: Tí omijé bá fẹ́ máa dà lójú rẹ, ó lè jẹ́ pé “ìgbà sísunkún” tìrẹ nìyẹn.​—Oníwàásù 3:4.

^ ìpínrọ̀ 12 Bí irú èrò yìí ò bá yéé dà ẹ́ láàmú, sọ ohun tó wà lọ́kàn ẹ fún òbí ẹ kan tó ṣì wà láàyè tàbí àgbàlagbà míì. Bó bá wá yá, wàá rí ìdí tí kò fi yẹ kó o máa dára rẹ lẹ́bi mọ́.

^ ìpínrọ̀ 14 Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ti tu àwọn èèyàn kan nínú: Sáàmù 34:18; 102:17; 147:3; Aísáyà 25:8; Jòhánù 5:28, 29.

ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́

“[Ọlọ́run] yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”​—Ìṣípayá 21:4.

ÌMỌ̀RÀN

Kọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ sílẹ̀. Bó o bá ń kọ ohun tí ò ń rò nípa òbí rẹ tó ṣaláìsí, ìyẹn máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ gan-an kí ẹ̀dùn ọkàn rẹ lè fúyẹ́.

ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?

Kò burú láti sunkún. Kódà àwọn ọkùnrin tí ìgbàgbọ́ wọn lágbára gan-an, irú bí Ábúráhámù, Jósẹ́fù, Dáfídì àti Jésù pàápàá sunkún nígbà téèyàn wọn kú.​—Jẹ́nẹ́sísì 23:2; 50:1; 2 Sámúẹ́lì 1:11, 12; 18:33; Jòhánù 11:35.

OHUN TÍ MÀÁ ṢE!

Tí ìbànújẹ́ mi bá pọ̀ lápọ̀jù, màá ․․․․․

Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ òbí mi tó wà láàyè nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․

KÍ LÈRÒ Ẹ?

● Kí nìdí tó fi dáa pé kó o máa rántí àwọn nǹkan dáadáa tó o mọ̀ nípa òbí rẹ tó ṣaláìsí?

● Tó o bá ń kọ èrò ọkàn rẹ sílẹ̀, kí nìdí tí ìyẹn fi máa jẹ́ kí ẹ̀dùn ọkàn rẹ lè fúyẹ́?

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 112]

“Ṣe ni mo bo ìbànújẹ́ mi mọ́ra. Ká ní mo sọ tinú mi jáde ni, ara ì bá tù mí gan-an. Ìyẹn ì bá sì jẹ́ kí ọkàn mi fúyẹ́.”​—David

[Àpótí/​Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 113]

CHANTELLE

“Nǹkan bí ọdún márùn-ún ni dádì mi fi ṣàìsàn, ṣe ni àìsàn yẹn sì ń le sí i. Ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16] ni mí nígbà tí wọ́n pa ara wọn. Lẹ́yìn náà, mọ́mì mi máa ń sọ gbogbo bí nǹkan ṣe ń lọ sí fún èmi àti bọ̀dá mi. Wọ́n tiẹ̀ jẹ́ káwa náà dá sí àwọn ìpinnu tó jẹ mọ́ ètò ìsìnkú dádì wa. Gbogbo ìyẹn ò jẹ́ ká banú jẹ́ jù. Ó jọ pé ó máa ń dun àwọn ọmọdé tó bá ń ṣe wọ́n bíi pé wọ́n ń fi àwọn nǹkan kan pa mọ́ fún wọn, pàápàá irú nǹkan ńlá bí èyí. Nígbà tó yá, kò wá ṣòro fún mi láti máa sọ̀rọ̀ nípa ikú dádì mi. Tó bá wá ń ṣe mí bíi kí n sunkún, màá rọra wá ibì kan lọ tàbí kí n lọ sọ́dọ̀ ọ̀rẹ́ mi kan, láti lọ sunkún. Ìmọ̀ràn mi ni pé: Tó bá ń wù ẹ́ láti sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ nípa ikú òbí rẹ, o lè sọ fún èèyàn rẹ tàbí ọ̀rẹ́ rẹ. Àmọ́ ṣáà ti rí i pé o ò pa ẹ̀dùn ọkàn rẹ mọ́ra.”

[Àpótí/​Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 113, 114]

LEAH

“Nígbà tí mo wà ní ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19], àrùn rọpá-rọsẹ̀ tó le gan-an ṣe mọ́mì mi. Lẹ́yìn tí wọ́n kú, mo wò ó pé mo ní láti mọ́kàn le. Torí, ìbànújẹ́ dádì mi á ti pọ̀ jù tí wọ́n bá rí i pé mi ò lè mú un mọ́ra. Látìgbà tí mo ti wà ní kékeré, tí ara mi ò bá yá tàbí tínú mi ò bá dùn, kíá ni Mọ́mì á ti wá nǹkan kan ṣe sí i. Mo rántí bí ọwọ́ wọn ṣe máa ń tù mí lára tí wọ́n bá ń wò ó bóyá ara mi ń gbóná. Mo máa ń ṣàárò wọn gan-an ni. Ó sábà máa ń ṣe mí bíi pé kí n pa ẹ̀dùn ọkàn mi mọ́ra, ìyẹn ò sì dáa. Nígbà míì mo máa ń wo àwọn fọ́tò wa kí n bàa lè sunkún. Ọkàn mi tún máa ń fúyẹ́ tí n bá sọ ohun tó wà lọ́kàn mi fáwọn ọ̀rẹ́ mi. Bíbélì sọ pé àwọn tó ti kú máa jíǹde sí Párádísè lórí ilẹ̀ ayé. (Jòhánù 5:28, 29) Torí náà, tí n bá ti ń fi sọ́kàn pé mo tún máa pa dà rí mọ́mì mi, tí mo sì ń ronú nípa ohun tí mo ní láti ṣe kí n lè rí wọn nígbà àjíǹde, ìbànújẹ́ mi máa ń dín kù.”

[Àpótí/​Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 114]

BETHANY

“Ó máa ń wù mí kí n rántí pé mo sọ fún Dádì pé mo fẹ́ràn wọn gan-an. Mo mọ̀ pé màá ti sọ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ o, mi ò kàn ṣáà rántí ni. Ì bá sì wù mí kí n máa rántí o. Ọmọ ọdún márùn-ún péré ni mí nígbà tí wọ́n kú. Àrùn rọpá-rọsẹ̀ mú Dádì nígbà tí wọ́n ń sùn lóru, wọ́n bá sáré gbé wọn lọ sí ilé ìwòsàn. Nígbà tí mo máa jí láàárọ̀ ọjọ́ kejì, mo gbọ́ pé Dádì ti kú. Lẹ́yìn ìgbà yẹn, mi kì í fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa dádì mi, àmọ́ nígbà tó yá inú mi máa ń dùn tí n bá ń gbọ́ ọ̀rọ̀ nípa wọn torí ìyẹn jẹ́ kí n túbọ̀ mọ̀ wọ́n dáadáa. Ìmọ̀ràn mi fún gbogbo ẹni tí òbí rẹ̀ ti ṣaláìsí ni pé: Gbìyànjú láti máa rántí gbogbo nǹkan dáadáa tí ìwọ àti òbí rẹ máa ń ṣe nígbà tẹ́ ẹ jọ wà pọ̀ kó o sì máa kọ ọ́ sílẹ̀ kó o má bàa gbàgbé. Lẹ́yìn náà, máa ṣe ohun táá jẹ́ kó o ní ìgbàgbọ́ tó lágbára tí wàá fi lè wà níbẹ̀ nígbà tí Ọlọ́run bá jí òbí rẹ dìde nínú ayé tuntun.”

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 116]

Tí mo kọ èrò mi sí

Kọ Èrò Ọkàn Rẹ

Kọ díẹ̀ sílẹ̀ lára àwọn nǹkan dáadáa tó ò ń rántí nípa dádì tàbí mọ́mì rẹ. ․․․․․

Kọ ohun tí ì bá wù ẹ́ pé kó o ti sọ fún dádì tàbí mọ́mì rẹ nígbà tí wọ́n ṣì wà láàyè. ․․․․․

Jẹ́ ká sọ pé o ní àbúrò kan tó máa ń dára ẹ̀ lẹ́bi nítorí ikú dádì tàbí mọ́mì yín. Kọ ohun tí wàá sọ fún un láti tù ú nínú. (Èyí lè jẹ́ kó o ní èrò tó tọ́ nípa bó ṣe yẹ kí ọ̀rọ̀ náà rí lára ìwọ gan-an.) ․․․․․

Kọ ohun méjì tàbí mẹ́ta tí ì bá ti wù ẹ́ kó o mọ̀ nípa dádì tàbí mọ́mì ẹ tó kú, kó o sì sọ fún òbí rẹ tó wà láàyè pé wàá fẹ́ kẹ́ ẹ jọ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. ․․․․․

Ka Ìṣe 24:15. Báwo ni ohun tó wà nínú ẹsẹ Bíbélì yìí ṣe lè jẹ́ kí ẹ̀dùn ọkàn rẹ nípa ikú dádì tàbí mọ́mì ẹ fúyẹ́? ․․․․․

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 115]

Nígbà míì, ẹ̀dùn ọkàn èèyàn kàn lè ṣàdédé wá, bí omi òkun tó ń ru gùdù ṣe máa ń dédé bì lu etíkun