Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Ṣàlàyé Ohun Tí Mo Gbà Gbọ́ Nípa Ọlọ́run?

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Ṣàlàyé Ohun Tí Mo Gbà Gbọ́ Nípa Ọlọ́run?

ORÍ 36

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Ṣàlàyé Ohun Tí Mo Gbà Gbọ́ Nípa Ọlọ́run?

Kí ló lè mú kó o máa lọ́ tìkọ̀ láti ṣàlàyé àwọn nǹkan tó o gbà gbọ́ fọ́mọ kíláàsì ẹ?

□ O ò ní ìmọ̀ Bíbélì

□ Wọ́n lè fi ẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́

□ O ò mọ bó o ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀

Ọ̀nà wo ló máa rọ̀ ẹ́ lọ́rùn pé kó o gbà ṣàlàyé àwọn nǹkan tó o gbà gbọ́?

□ Bíbá ẹnì kan ṣoṣo sọ̀rọ̀

□ Bíbá gbogbo ọmọ kíláàsì mi sọ̀rọ̀

□ Kíkọ àwọn nǹkan tí mo gbà gbọ́ sórí ìwé fáwọn èèyàn láti kà

Kọ orúkọ ọmọléèwé yín kan tó o rò pé ó lè fetí sọ́rọ̀ Bíbélì tó o bá dá a sílẹ̀. ․․․․․

Ó ṢEÉ ṢE kó jẹ́ pé àwọn ọmọléèwé ẹ kì í sábà sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run. Bó bá jẹ́ pé nǹkan míì bí eré ìdárayá, aṣọ, ọ̀rọ̀ ọkùnrin tàbí obìnrin lo dá sílẹ̀, inú wọn á dùn láti dá sí i. Àmọ́ bóyá lo máa rẹ́ni sún mọ́ ẹ, bó o bá ní ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lo fẹ́ bá wọn sọ.

Kì í ṣe pé wọn ò gba Ọlọ́run gbọ́ o, ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ tiẹ̀ gbà pé Ọlọ́run wà. Àmọ́ ọ̀pọ̀ wọn lojú máa ń tì láti sọ̀rọ̀ lọ sápá ibẹ̀ yẹn. Wọ́n máa ń rò pé ‘irú ọ̀rọ̀ yẹn kì í dùn.’

Ìwọ Ńkọ́?

Ó lè má máa yá ẹ lára láti sọ̀rọ̀ Ọlọ́run fáwọn ọmọléèwé yín lóòótọ́. Torí kò sẹ́ni tí ò fẹ́ káwọn èèyàn gba tòun, tí wọ́n bá wá lọ ń fèèyàn ṣe yẹ̀yẹ́, ìyẹn ló burú jù! Ṣé ọ̀rọ̀ lè rí bẹ́ẹ̀ nígbà tó o bá ń sọ ohun tó o gbà gbọ́? Dájúdájú, bẹ́ẹ̀ ni. Àwọn ọmọléèwé ẹ sì lè wá ṣe nǹkan tó máa yà ẹ́ lẹ́nu o. Ọ̀pọ̀ nínú wọn ló ń wá ìdáhùn sáwọn ìbéèrè bí: Ibo lọ̀rọ̀ ayé yìí ń lọ gan-an? Àti pé, Kí nìdí tíṣòro fi pọ̀ láyé yìí? Ó ṣeé ṣe kó tẹ́ wọn lọ́rùn láti bá ọmọdé ẹgbẹ́ wọn sọ irú àwọn ọ̀rọ̀ yẹn ju àgbàlagbà lọ.

Àmọ́ ṣá o, ó lè dà bíi pé ó ṣòro fún ẹ láti máa báwọn ojúgbà ẹ sọ̀rọ̀ ẹ̀sìn. Ká sòótọ́, kò dìgbà tó o bá sọra ẹ di aláṣejù, o ò sì ní láti rò pé o gbọ́dọ̀ sọ ohun tó tọ́ gan-an. Ṣíṣàlàyé nǹkan tó o gbà gbọ́ dà bí ìgbà tó o bá fẹ́ ta gìtá. Ó lè máà kọ́kọ́ rọrùn. Àmọ́ bó o bá ṣe fi ń dánra wò sí ló ṣe máa mọ́ ẹ lára sí, wàá sì wá mọ̀ ọ́n dáadáa tó bá yá. Báwo lo wá ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹ?

O lè kọ́kọ́ sọ nǹkan kan tínú àwọn ọmọléèwé ẹ máa dùn sí. Bí àpẹẹrẹ, tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ nípa ohun kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣẹlẹ̀ níléèwé yín, o lè sọ ohun tí Bíbélì sọ nípa ẹ̀ fún wọn. O sì lè lọ bá ẹnì kan ṣoṣo péré sọ̀rọ̀ lára àwọn ọmọ kíláàsì ẹ. Nǹkan míì tó sì tún rọrùn táwọn ọ̀dọ̀ kan ti ṣe ni pé, wọ́n kó àwọn ìwé tó dá lórí Bíbélì sórí tábìlì wọn níléèwé, wọ́n sì wá wò ó bóyá ọ̀kan lára àwọn ọmọ kíláàsì wọn máa wá wò ó. Lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n wá, ibẹ̀ sì lọ̀rọ̀ ti bẹ̀rẹ̀!

Èwo nínú àwọn ọ̀nà tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ tán yìí ni wàá fẹ́ láti lò? ․․․․․

Ṣáwọn ọ̀nà míì wà tó o rò pé o lè gbà ṣàlàyé àwọn nǹkan tó o gbà gbọ́ fáwọn ọmọ kíláàsì ẹ? Bó bá wà, kọ ọ́ sórí ìlà yìí.

․․․․․

Ìgbà míì wà tí iṣẹ́ iléèwé yín lè fún ẹ láǹfààní láti ṣàlàyé àwọn nǹkan tó o gbà gbọ́. Bí àpẹẹrẹ, kí lo máa ṣe bí wọ́n bá sọ̀rọ̀ nípa ẹfolúṣọ̀n nínú kíláàsì yín? Báwo lo ṣe máa ṣàlàyé nǹkan tó o bá gbà gbọ́ nípa ìṣẹ̀dá?

Bó O Ṣe Lè Ṣàlàyé Nípa Ìṣẹ̀dá

Ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Ryan sọ pé, “Nígbà tí wọ́n dá ọ̀rọ̀ ẹfolúṣọ̀n sílẹ̀ ní kíláàsì wa, ó yàtọ̀ pátápátá gbáà sí gbogbo ohun tí wọ́n ti fi kọ́ mi. Wọ́n ṣàlàyé ẹ̀ bíi pé òótọ́ ni, ìyẹn sì dojú ọ̀rọ̀ náà rú mọ́ mi lọ́wọ́.” Ohun tọ́mọbìnrin kan tó ń jẹ́ Raquel náà sọ ò yàtọ̀ síyẹn. Ó ní: “Jìnnìjìnnì bò mí nígbà tí tíṣà tó ń kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ nípa ìbágbépọ̀ ẹ̀dá sọ pé ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n ló kàn tá a máa kọ́. Mo mọ̀ pé ó máa di dandan pé kí n ṣàlàyé ohun tí mo gbà gbọ́ lórí ọ̀ràn tó máa ń fa àríyànjiyàn yìí.”

Báwo ló ṣe máa ń rí lára ẹ bí wọ́n bá dá ọ̀rọ̀ nípa ẹfolúṣọ̀n sílẹ̀ nínú kíláàsì yín? O gbà gbọ́ pé Ọlọ́run ló “dá ohun gbogbo.” (Ìṣípayá 4:11) O rí àwọn nǹkan mèremère láyìíká tó fi hàn pé Ẹlẹ́dàá olóye kan wà. Àmọ́ ohun tó wà nínú ìwé tí wọ́n fi ń kọ́ yín ni pé èèyàn kàn ṣàdédé wà ni, ohun tí tíṣà yín sì ń sọ náà nìyẹn. Ó wá lè máa ṣe ẹ́ bíi pé kí lo mọ̀ débi tí wàá fi máa báwọn ògbógi jiyàn?

Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ìwọ nìkan kọ́ ni kò gba ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n gbọ́. Ká sòótọ́, àwọn kan wà lára àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tí kò gba ẹ̀kọ́ náà gbọ́ pẹ̀lú. Ọ̀pọ̀ olùkọ́ àtàwọn ọmọléèwé ni kò sì gbà á gbọ́ pẹ̀lú.

Àmọ́, bó o bá fẹ́ ṣàlàyé nǹkan tó o gbà gbọ́ nípa àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá, o gbọ́dọ̀ mọ ohun tí Bíbélì fi kọ́ni gan-an lórí kókó yìí. Kò sídìí láti máa jiyàn lórí àwọn ohun tí Bíbélì ò bá ti ṣàlàyé ẹ̀ ní tààràtà. Gbé àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò.

Ìwé tí mo fi ń kẹ́kọ̀ọ́ sáyẹ́ǹsì sọ pé ilẹ̀ ayé, oòrùn, òṣùpá àtàwọn ìràwọ̀ ti wà láti àìmọye ọdún sẹ́yìn. Bíbélì sọ pé ilẹ̀ ayé àtàwọn nǹkan míì ti wà ṣáájú ọjọ́ àkọ́kọ́ ìṣẹ̀dá. Torí náà, ilẹ̀ ayé, oòrùn, òṣùpá àtàwọn ìràwọ̀ gbọ́dọ̀ ti wà fún àìmọye ọdún.—Jẹ́nẹ́sísì 1:1.

Tíṣà mi sọ pé kò sí ọ̀nà tí Ọlọ́run lè gbà dá ayé láàárín ọjọ́ mẹ́fà péré. Bíbélì ò sọ pé wákàtí mẹ́rìnlélógún [24] ni gígùn “ọjọ́” ìṣẹ̀dá kọ̀ọ̀kan.

Nínú kíláàsì wa, a jíròrò àwọn àpẹẹrẹ mélòó kan nípa ìyàtọ̀ tó ti bá àwọn ẹranko àtàwọn èèyàn látìgbà yìí wá. Bíbélì sọ pé Ọlọ́run dá àwọn nǹkan alààyè “ní irú tiwọn.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:20, 21) fara mọ́ èrò tó sọ pé látinú àwọn nǹkan tí kò lẹ́mìí làwọn nǹkan alààyè ti wá tàbí pé látinú ohun tín-tìn-tín kan ni Ọlọrun ti dá èèyàn. Àmọ́ ṣá o, “oríṣi” nǹkan abẹ̀mí kọ̀ọ̀kan lágbára láti mú oríṣi irú tiẹ̀ jáde. Torí náà, Bíbélì gbà pé ó ṣeé ṣe kí ìyípadà wáyé nínú “oríṣi” nǹkan alààyè kọ̀ọ̀kan.

Pẹ̀lú àwọn nǹkan tá a ti sọ nínú orí yìí, kí lo máa sọ bí tíṣà tàbí ọmọ kíláàsì yín kan bá sọ pé:

“Ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ti fi hàn pé látara ẹranko làwa èèyàn ti jáde wá.” ․․․․․

“Mi ò gba Ọlọ́run gbọ́ torí pé mi ò lè rí i.” ․․․․․

Jẹ́ Káwọn Nǹkan Tó O Gbà Gbọ́ Dá Ẹ Lójú!

Bó bá jẹ́ pé Kristẹni làwọn òbí ẹ, o lè gbà pé Ọlọ́run ló dá ohun gbogbo torí pé wọ́n ti fi kọ́ ẹ bẹ́ẹ̀. Àmọ́ ní báyìí tó o ti ń dàgbà, wàá fẹ́ fi “agbára ìmọnúúrò” tó o ní sin Ọlọ́run, ìyẹn sì máa fi hàn pé ohun tó o gbà gbọ́ lẹ́sẹ̀ nílẹ̀. (Róòmù 12:1) Torí náà, bi ara ẹ pé, ‘Kí nìdí tí mo fi gbà pé Ẹlẹ́dàá wà?’ Nígbà tí Sam tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlá [14] wo bí ara àwa èèyàn ṣe rí, ó sọ pé: “Nǹkan tó wà ńbẹ̀ pọ̀ gan-an ni, ó sì díjú gan-an, gbogbo ẹ̀ ló sì ń bára wọn ṣiṣẹ́ láìtàsé. Ara àwa èèyàn ò kàn lè ṣàdédé wà!” Holly tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16] náà gbà bẹ́ẹ̀. Ó sọ pé: “Látìgbà tí mo ti lárùn àtọ̀gbẹ, ọ̀pọ̀ nǹkan ni mo ti kọ́ nípa bí ara wa ṣe ń ṣiṣẹ́. Bí àpẹẹrẹ, ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ fún mi láti mọ bí ẹ̀yà ara kékeré kan tó ń jẹ́ pancreas, tó wà nínú ikùn, ṣe ń ṣiṣẹ́ lọ́nà pípabanbarì, láti mú kí ẹ̀jẹ̀ wà ní mímọ́ tónítóní káwọn ẹ̀yà ara yòókù sì máa ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ.”

Kọ àwọn nǹkan mẹ́ta tó mú kó o gbà gbọ́ pé Ẹlẹ́dàá wà síbí yìí.

1. ․․․․․

2. ․․․․․

3. ․․․․․

Kò yẹ kó o máa rò pé tìẹ yàtọ̀ tàbí kó o máa tijú torí pé o gba Ọlọ́run gbọ́, o sì gbà pé òun ló dá ohun gbogbo. Àwọn ẹ̀rí tó wà fi hàn pé ó bọ́gbọ́n mu láti gbà gbọ́ pé Ẹlẹ́dàá kan tó lóye ló dá wa.

Ju gbogbo ẹ̀ lọ, ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n gan-an ló gba kéèyàn ní ìgbàgbọ́ tí ò ṣe é fẹ̀rí tì lẹ́yìn, torí òun lèèyàn lè rí bí iṣẹ́ ìyanu tí kò sẹ́ni tó ṣe é! Bó o bá ro ọ̀rọ̀ yìí jinlẹ̀, wàá lè ṣàlàyé àwọn ohun tó o gbà gbọ́ nípa Ọlọ́run dáadáa.

NÍNÚ ORÍ TÓ KÀN

Àwọn ẹgbẹ́ ẹ ń ṣèrìbọmi. Ṣéwọ náà ti ṣe tán láti ṣèrìbọmi?

ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́

Èmi kò tijú ìhìn rere; ní ti tòótọ́, ó jẹ́ agbára Ọlọ́run fún ìgbàlà sí gbogbo ẹni tí ó ní ìgbàgbọ́.Róòmù 1:16.

ÌMỌ̀RÀN

Máa kíyè sí bó o ṣe ń ṣe nígbà tó o bá ń sọ ohun tó o gbà gbọ́ fáwọn ẹlòmíì. Bó bá hàn lójú ẹ pé ò ń tijú, àwọn ojúgbà ẹ lè bẹ̀rẹ̀ sí í fi ẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́. Àmọ́, tó o bá jẹ́ kóun tó ò ń sọ dá ẹ lójú báwọn ọmọléèwé ẹ náà ṣe máa ń sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn, wọ́n á máa fọ̀wọ̀ ẹ wọ̀ ẹ́.

ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?

Nígbà míì tí wọ́n bá ní káwọn tíṣà wá ṣàlàyé ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n, wọn kì í lè ṣàlàyé ẹ̀, wọ́n á wá rí i pé torí pé wọ́n fi kọ́ àwọn làwọn náà ṣe gbà á gbọ́.

OHUN TÍ MÀÁ ṢE!

Bí n bá fẹ́ bá ọmọ kíláàsì mi kan sọ̀rọ̀ látinú Bíbélì, ohun tí mo lè ṣe ni pé ․․․․․

Bí wọ́n bá bi mí pé kí nìdí tí mo fi gbà pé Ẹlẹ́dàá wà, ohun tí màá sọ ni pé ․․․․․

Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․

KÍ LÈRÒ Ẹ?

● Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kó o sọ nǹkan tó o gbà gbọ́ fáwọn ẹlòmíì?

● Àwọn ọ̀nà wo lo lè gbà ṣàlàyé àwọn nǹkan tó o gbà gbọ́ nípa ìṣẹ̀dá níléèwé yín?

● Báwo lo ṣe lè fi hàn pé o mọrírì àwọn nǹkan tí Ẹlẹ́dàá ohun gbogbo ṣe?—Ìṣe 17:26, 27.

[Ìsọfúnni tó wà ní ojú ìwé 299]

Ìpínlẹ̀ ìwàásù ni iléèwé wa, àwa nìkan la sì ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀.’’—Iraida

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 298]

Ṣíṣàlàyé ohun tó o gbà gbọ́ nípa Ọlọ́run dà bí ìgbà tó o fẹ́ máa ta gìtá, àfi kó o kọ́kọ́ kọ́ ọ, bó o bá sì ṣe ń lò ó sí, ni wàá máa mọwọ́ ẹ̀ sí

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 301]

O lè borí ẹ̀rù tó máa ń bà ẹ́ láti ṣàlàyé àwọn nǹkan tó o gbà gbọ́